Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Títọ́jú Irúgbìn Pa Mọ́

Ìwé ìròyìn National Post ti Kánádà sọ pé: “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé tó bá fi máa di àádọ́ta ọdún sígbà táa wà yìí, ohun tó tó ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ohun ọ̀gbìn tó wà lágbàáyé lè pa run yán-ányán-án.” Láti lè dáàbò bo àwọn irúgbìn tó wà nínú ewu, Ilé Iṣẹ́ Aláyélúwà ti Ọgbà Ìmọ̀ Nípa Ewéko ní Kew, ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ti dá ètò kan tó ń jẹ́ Àkójọ Irúgbìn ti Mìlẹ́níọ̀mù (MSB) sílẹ̀. Ìwé ìròyìn náà ṣàlàyé pé: “Iṣẹ́ ètò MSB yìí ni láti ṣa ohun tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n irú ọ̀wọ́ àwọn irúgbìn kan jọ kí wọ́n sì fi wọ́n pa mọ́—ìyẹn ju ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn nǹkan ọ̀gbìn tó ń so èso lọ.” Àwọn olùṣekòkárí ètò MSB nírètí láti lo àwọn irúgbìn náà nígbà tó bá jẹ́ dandan fún mímú àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti kórè wọn kọjá ààlà bọ̀ sípò, fún dídín ṣíṣeé ṣe pé kí ìyàn mú kù, àti láti pèsè irúgbìn fáwọn tó ń ṣe oògùn ìbílẹ̀ àtàwọn apoògùn. Roger Smith, tó jẹ́ olórí fún ètò fífi irúgbìn pa mọ́ náà sọ pé: “Àwọn irúgbìn tó wúlò jù lọ fún èèyàn àti ẹranko ló sábà máa ń kọ́kọ́ pòórá.”

Àrùn Ọkàn Tí Kò La Ìrora Lọ

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ àmì tó wọ́pọ̀ jù lọ tẹ́nì kan tó lárùn ọkàn máa ń rí—ìyẹn ni bí ìgbà tí wọ́n bá fi ẹ̀mú mú èèyàn láyà. Àmọ́, àwọn tó mọ̀ pé “ìdá kan lára ìdá mẹ́ta àwọn tó lárùn náà ni àyà kì í dùn rárá nígbà tí àrùn náà bá dé sí wọn” kò tó nǹkan kan ni ohun tí ìwé ìròyìn Time sọ. Ìyẹn jẹ́ ká mọ ìdí “táwọn tó ní àrùn ọkàn àmọ́ tí àyà ò dùn wọ́n kì í fi í fìgbà gbogbo lọ sí ọsibítù lásìkò—ní ìpíndọ́gba wákàtí méjì sígbà tó yẹ kí wọ́n lọ” ni ohun tí ìwádìí kan tí The Journal of the American Medical Association tẹ̀ jáde sọ. Àmọ́ o, fífi ìtọ́jú tó lè gbẹ̀mí ẹni là falẹ̀ lọ́nà èyíkéyìí léwu. Kí lo tún lè máa kíyè sí? Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Bóyá ni kì í ṣe pé àmì pàtàkì mìíràn tí o ní láti kíyè sí ni bí ó bá ṣòro gidigidi fún ọ láti mí délẹ̀.” Àwọn àmì mìíràn tó tún ṣeé ṣe kí o rí gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà sọ ni, kí èébì máa gbéèyàn, lílàágùn lódìlódì, àti “‘àyà títa èyíkéyìí’ tó jẹ́ pé bóo bá ti rìn pẹ́nrẹ́n tàbí tóo bá ṣáà ti lo ara fún nǹkan kan ló máa burú sí i.”

Àwọn Ọmọ ìka ẹsẹ̀ Tó Ń Di Nǹkan Mú Gírígírí

Ó rọrùn fún àwọn ọmọọ́lé láti sáré gba àjà ilé tó ń dán kọ̀rọ̀ bíi dígí kọjá. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n ti lo ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún nídìí gbígbìyànjú láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn ronú pé ó dà bíi pé àwọ́n ti lè rí àlàyé ṣe báyìí. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn Science News sọ, àwùjọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti dorí ìpinnu náà pe “nǹkan kan tó ń lẹ̀ mọ̀dẹ̀mọ̀dẹ̀ lọ́nà yíyani lẹ́nu máa ń yọ jáde bí àwọn irun tín-tìn-tín tó wà lábẹ́ ẹsẹ̀ ọmọọ́lé bá ti ń gba orí àwọn nǹkan kọjá. Àwọn ohun tó ń gbá nǹkan mú, tí wọ́n ń pè ní spatulae tó wẹ́ gidigidi máa ń jáde lábẹ́ irun tín-tìn-tín kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí ọmọọ́lé kan bá dá ẹsẹ̀ rẹ̀ lé nǹkan, àwọn spatulae tó tó nǹkan bíi bílíọ̀nù kan tí wọ́n bo ẹsẹ rẹ̀ pitimu á wá di ilẹ̀ mú débi pé kò ní lè jábọ́.” Àwọn olùṣèwádìí tún sọ pé ọ̀nà táwọn ọmọọ́lé ń gbà da ẹsẹ̀ dé nǹkan “fi hàn dájúdájú pé ńṣe ni wọ́n máa ń tẹ àwọn irun tín-tìn-tín abẹ́ ẹsẹ̀ wọn mọ́ nǹkan náà, tí wọ́n á sì máa wá wọ́ ẹsẹ lọ.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé ńṣe ni bí wọ́n ṣe ń ṣe yìí túbọ̀ mú kí “bí irun abẹ́ ẹsẹ̀ tín-ń-tínní kan ṣe ń dilẹ̀ mú túbọ̀ lágbára sí i ní ìlọ́po mẹ́wàá táa bá fi wéra pẹ̀lú fífẹsẹ̀ tẹlẹ̀ lásán.”

Ìbànújẹ́ Dorí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìkì Kodò Lórí Àṣẹ Tí Ìjọba Pa

“Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì ti fara ya” fún jíjẹ́ tí wọn kò jẹ́ kí ẹ̀sìn tí olúkúlùkù ọmọ Ilẹ̀ Gíríìsì ń ṣe máa fara hàn mọ́ lórí “káàdì ìdánimọ̀ Orílẹ̀-Èdè” náà. Bí ìròyìn tó tọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Gbè Ìròyìn Jáde wá ti sọ nìyẹn. Ìpinnu náà wáyé látàrí ìròyìn tó wá látọwọ́ Àjọ Tí Ń Jà Fẹ́tọ̀ọ́ Ọmọnìyàn Ti Ìjọba Àpapọ̀ ní Ìlú Helsinki lọ́dún 1998, tó “sọ pé ilẹ̀ Gíríìsì ń dá àwọn tí kì í ṣe ara ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì yà sọ́tọ̀ àti pé àmì onísìn tí wọ́n fi tipátipá fi sára àwọn káàdì ìdánimọ̀ náà máa ń fa ṣíṣe ojúsàájú nígbà tí wọ́n bá ń gbani síṣẹ́ àti nínú ọwọ́ táwọn ọlọ́pàá fi ń mú èèyàn.” Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ náà ti sọ, ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì sọ pé ìyípadà yìí yóò “mú kí àwọn káàdì ìdánimọ̀ náà wà níbàámu pẹ̀lú ìlànà Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù àti òfin tí orílẹ̀-èdè náà ṣe lọ́dún 1997 tó fún àwọn èèyàn láyè láti fi ọ̀ràn ìkọ̀kọ̀ wọn pa mọ́.” Àmọ́ ní báyìí o, aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì ti ṣàpèjúwe àwọn tó ń fẹ́ kí wọ́n mú ọ̀rọ̀ ẹlẹ́sìn dé kúrò nínú àwọn káàdì náà gẹ́gẹ́ bí àwọn tó jẹ́ ti “agbo ọmọ ogun èṣù.”

Ilẹ̀ China Gbéjà Ko Ìjì Eléruku

Ìwé ìròyìn China Today sọ pé, ìjì eléruku to máa ń wá láti àgbègbè aṣálẹ̀ ní Àárín Gbùngbùn Mongolia ti gba àárín àríwá China kọjá láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ó sì ba ọ̀pọ̀ irè oko àtàwọn ohun ọ̀sìn tówó wọn tó ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù dọ́là jẹ́. Lọ́dún 2000 yìí, ìjì eléruku yìí ti jà dé àwọn ibi jíjìnnà bíi Beijing, tí í ṣe olú ìlú náà. Ìjì afẹ́yanrìn kan tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1998 ba oko ọ̀gbìn oníhóró tó ń lọ sí nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáje [33,000] hẹ́kítà jẹ́ tó sì pa ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́fà [110,000] àwọn ẹran agbéléjẹ̀. Bí àwọn èèyàn ṣe ń lo ilẹ̀ ní ìlòkulò lohun pàtàkì tí wọ́n sọ pé ó fà á. Ọ̀pọ̀ àwọn ibi gbígbòòrò tí koríko bò tẹ́lẹ̀ ló ti di aṣálẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, lọ́dún 1984, àwọn èèyàn Ningsia Hui Oníjọba Ara Ẹni, tí wọ́n wà ni ìhà àríwá China, bẹ̀rẹ̀ sí wa ilẹ̀ nítorí egbò licorice, tí wọ́n fẹ́ lò fún egbòogi ilẹ̀ China kan. Ìwé ìròyìn China Today sọ pé: “Kò pé ọdún mẹ́wàá tí wọ́n fi pa ilẹ̀ oníkoríko ọlọ́gbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000] hẹ́kítà run, tí wọ́n sì sọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáje ó lé ọ̀ọ́dúnrún àti mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [13,333] hẹ́kítà ilẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn di aṣálẹ̀.” Àwọn ohun tó fa àgbègbè aṣálẹ̀ míì ni jíjẹ́ kí àwọn ẹran máa jẹ koríko àgbègbè kan lájẹjù àti lílo àwọn orísun tí wọ́n ti ń rí omi ládùúgbò náà lálòjù. Láti borí ìṣòro ọ̀hún, kí wọ́n sì dá sísọ ọ̀pọ̀ àgbègbè di aṣálẹ̀ dúró, wọ́n ti sapá gidigidi láti tún àwọn igi àti koríko gbìn.

Jíjí Orúkọ Ẹlòmíràn Lò

Ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn El Economista ti Ìlú Mẹ́síkò ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé kóo ṣọ́ra fáwọn ọ̀daràn tó jẹ́ pé wọ́n lè fi orúkọ rẹ lu àwọn tí ń tajà àwìn ní jìbìtì. Lẹ́yìn táwọn ọ̀daràn náà bá ti rí ìsọfúnni gbà nípa rẹ nípa jíjí lẹ́tà tàbí àpamọ́wọ́ rẹ, wọ́n á wá fi orúkọ rẹ gba káàdì ìrajà àwìn àmọ́ àdírẹ́sì tiwọn ni wọ́n máa ní kí wọ́n fi ọjà náà ránṣẹ́ sí. Lẹ́yìn náà wọ́n á lo orúkọ rẹ láti fi ra àwọn nǹkan tàbí kí wọ́n fi yá àwọn ohun ìní kan láti orí tẹlifóònù tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ìwé ìròyìn náà sọ pé ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún, ó tiẹ̀ lè gba ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún pàápàá káwọn tó kàgbákò ìwà ọ̀daràn yìí tó lè bọ́ nínú wáhálà yìí. Báwo lo wá ṣe lè dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olè tó ń jí orúkọ èèyàn lò? Ìwé ìròyìn El Economista kìlọ̀ pé: Rí i dájú pé o kì í kó àwọn ìwé ẹ̀rí ṣíṣe pàtàkì lọ́wọ́ àyàfi tóo bá máa nílò wọn nìkan, máa ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ohun tóo bá fi káàdì ìrajà àwìn rẹ rà kí o sì máa lò wọ́n láti fi yẹ àkọsílẹ̀ ìwé ìṣirò owó rẹ wò, rí i pé o kọ́kọ́ ya àwọn ìwé tóo fi rajà láwìn sí wẹ́wẹ́ ná kóo tó dà wọ́n nù, má fi ìsọfúnni tó jẹ́ tara ẹ ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà, sì rí i pé gbogbo nọ́ńbà káàdì ìrajà àwìn rẹ, déètì tí iṣẹ́ wọn máa dópin, àti nọ́ńbà tẹlifóònù ẹni tó kọ káàdì náà jáde fún ẹ lo kọ sílẹ̀, kí o bàa lè ṣàlàyé tó bá ṣẹlẹ̀ pé káàdì náà sọ nù tàbí pé wọ́n jí i lọ.

Ogun Tí Kò Tọ́ Ni Wọ́n Ń Bá Kòkòrò Bakitéríà Jà

Ìwé ìròyìn USA Today sọ pé: “Àwọn oníbàárà ní Amẹ́ríkà ń gbógun ti àwọn kòkòrò àrùn inú ilé láìyẹ.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà ti sọ, Stuart Levy, tó jẹ́ oníṣègùn àti onímọ̀ nípa àwọn ohun alààyè tín-tìn-tín ní Yunifásítì Tufts sọ pé, “ńṣe ni pípọ̀ táwọn èròjà tó ń gbógun ti kòkòrò bakitéríà ń pọ̀ sí i . . . túbọ̀ ń mú káwọn kòkòrò bakitéríà máa yọjú, tó sì jẹ́ pé kì í ṣe kìkì pé ọṣẹ agbógunti kòkòrò bakitéríà kò ràn wọ́n mọ́ nìkan ni, àmọ́ àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn pẹ̀lú kò ràn wọ́n mọ́.” Levy ní, ńṣe ni lílo àwọn èròjà agbógunti bakitéríà láti fi pa àwọn kòkòrò tó wà láyìíká ilé dà bíi fífi “kùmọ̀ pa eṣinṣin.” Lódìkejì sí ìyẹn, àwọn ohun táa fi ń mú kí ilé wà ní mímọ́ tónítóní bíi bílíìṣì, omi hydrogen peroxide, àti omi gbígbóná pẹ̀lú ọṣẹ máa ń mú ìdọ̀tí kúrò láìsí pé wọ́n ń ran àwọn kòkòrò bakitéríà lọ́wọ́ láti yíra padà di nǹkan mìí táwọn ohun táa mẹ́nu kàn yìí kò lè káwọ́. Levy sọ pé: “Alájọṣe wa làwọn kòkòrò bakitéríà jẹ́. Kò yẹ ká máa bá wọn fa wàhálà.”

Àwọn Ará Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Ló Gbégbá Orókè Nídìí Tẹlifíṣọ̀n Wíwò

Ìwé ìròyìn ìlú London kan, The Independent sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn ará Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń lo iye àkókò tí wọ́n ń lò lẹ́nu iṣẹ́ lọ́sẹ̀ nídìí wíwo tẹlifíṣọ̀n.” Níbàámu pẹ̀lú ohun táwọn olùwádìí sọ, ní ìpíndọ́gba, àwọn ará Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń fi wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wo tẹlifíṣọ̀n lọ́sẹ̀, tí ìpín mọ́kànlélógún nínú ọgọ́rùn-ún sì ń lo wákàtí mẹ́rìndínlógójì nídìí ẹ̀ lọ́sẹ̀. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Kì í ṣe kìkì àwọn ọ̀dọ́ nìkan ló ń lo àkókò ré kọjá ààlà nídìí ẹ̀ o, níwọ̀n bí ìwádìí náà ti fi hàn pé bákan náà lọ̀rọ̀ rí fáwọn ọkùnrin àtobìnrin, àtàwọn àgbàlagbà.” Ìdílé kan tó máa ń fi nǹkan bí ọgbọ̀n wákàtí wo tẹlifíṣọ̀n lọ́sẹ̀ sọ pé, tẹlifíṣọ̀n ń pèsè “ohun tí àwọ́n nílò láti gbé ọkàn àwọn síbòmíràn.” Àmọ́ irú àwòjù bẹ́ẹ̀ lóhun tó ń náni o. Ìwé ìròyìn The Guardian Weekly ti ìlú London sọ pé, nínú ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa orílẹ̀-èdè tí iye wọn jẹ́ ogún, “gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ni” Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì “fi kọjá àwọn tó kù nínú tẹlifíṣọ̀n wíwò.” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, “ẹ̀yìn-ẹ̀yìn ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wà nínú ohun mẹ́ta pàtàkì jù lọ tí wọ́n fi díwọ̀n mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà.”

Ẹ̀kọ́ Nípa Ìbálòpọ̀ Látàárọ̀ Ọjọ́

Ìwé ìròyìn Bangkok Post sọ pé kò ní pẹ́ mọ́, táwọn ọmọ àfànítẹ̀tẹ́ ní Bangkok, ní ilẹ̀ Thailand á fi bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìbálòpọ̀. Ìròyìn ọ̀hún sọ ohun tí Dókítà Suwanna Vorakamin tó jẹ́ ọ̀gá ní ẹ̀ka Ìfètòsọ́mọbíbí àti Ṣíṣàkóso Iye Ènìyàn sọ pe, “wọn yóò fún àwọn olùkọ́ àtàwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera ní àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láti lè máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lórí ìbálòpọ̀ kí wọ́n sì máa bá wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lọ́nà ti ìlànà sáyẹ́ǹsì.” Níbàámu pẹ̀lú ìwé ìròyìn náà, dókítà náà fi kún un pé: “Kì í ṣe ète àtifún ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ọmọdé tí kò tíì dàgbà níṣìírí ni bíbẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìbálòpọ̀ wà fún. . . . Ẹ̀kọ́ tí wọ́n bá fún àwọn ọmọ náà nígbà tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré á jẹ́ kí wọ́n lè yàgò fún ìwàkiwà àti ewu níní oyún tí wọn kò fẹ́ nígbà tí wọ́n bá dàgbà di ọ̀dọ́langba.”