Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àìṣègbè Jí! Wú U Lórí

Àìṣègbè Jí! Wú U Lórí

Àìṣègbè Jí! Wú U Lórí

Ọ̀JỌ̀GBỌ́N YUNIFÁSÍTÌ KAN ní Sípéènì kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society tó wà ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún láti fi ìmọrírì rẹ̀ hàn fún Jí! Ó sọ pé:

“Mo gba méjì lára ẹ̀dà ìwé ìròyìn Jí! lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Mo rí i pé oríṣiríṣi àpilẹ̀kọ tó lárinrin ló wà nínú wọn. Èmi ò sí lára àwùjọ ìsìn èyíkéyìí ní tèmi o, àmọ́ mo mọrírì àìṣègbè ìwé ìròyìn náà. Ọ̀nà tí ẹ gbà gbé àwọn àwòrán inú ẹ kalẹ̀ kò lẹ́gbẹ́, bó sì ṣe jíròrò àwọn kókó tó wà nínú rẹ̀ fi hàn pé kò ṣojúsàájú, ó tún bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu pàápàá. Ẹ káre láé fún akitiyan yín.”

Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú rẹ̀, ńṣe ni Jí! máa ń ṣàkójọ onírúurú àwọn ẹ̀rí láti inú oríṣiríṣi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì láti ran àwọn tí yóò kà á lọ́wọ́ kí wọ́n ba lè rí ohun kan tó ṣe gúnmọ́ kọ́. Ọ̀nà kan náà yìí la gbà kọ ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé 32 náà, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I? Fún àpẹẹrẹ, ohun tí ìwé náà sọ gẹ́lẹ́ lábẹ́ àwọn àkọlé kékeré bí “Iwalaaye Ha Pilẹṣẹ Nipasẹ Èèṣì Bi?” àti “Ìṣètò Ń Beere Fun Olùṣètò Kan” ni àwọn gbajúgbajà ọ̀mọ̀ràn ní ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà, ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè tíntìntín, àti ẹ̀kọ́ físíìsì kín lẹ́yìn.

O lè rí ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ náà Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I? gbà tóo bá kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí táa tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Ìṣùpọ̀ ìràwọ̀: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Anglo-Australian Observatory, David Malin ni olùyàwòrán