Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ Kọjá—Ǹjẹ́ ó Yẹ Ká Gbà Wọ́n Gbọ́?

Àwọn Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ Kọjá—Ǹjẹ́ ó Yẹ Ká Gbà Wọ́n Gbọ́?

Àwọn Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ Kọjá—Ǹjẹ́ ó Yẹ Ká Gbà Wọ́n Gbọ́?

“Níní ìmọ̀ nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá máa ń jẹ́ ká ní . . . èrò pé a jẹ́ ara ẹgbẹ́ kan tó ti wà láti ìrandíran ṣáájú kí wọ́n tó bí wa, tí á sì tún máa bá a lọ fún àìmọye àkókò lẹ́yìn táa bá kú.”—A COMPANION TO THE STUDY OF HISTORY, LÁTỌWỌ́ MICHAEL STANFORD.

B Í ÌGBÀ tí a ń pàdánù ohun pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé ni, tí a ò bá mọ̀ nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá. Láìsí ìtàn, ńṣe ni ìwọ, ìdílé rẹ, ẹ̀yà tóo jẹ́, tàbí orílẹ̀-èdè rẹ pàápàá á dà bí ìgbà tí ẹ ò ní orírun, tí ẹ ò ní ìbẹ̀rẹ̀. Á wá dà bí ẹni pé àkókò tí a ń gbé lọ́wọ́lọ́wọ́ kò ní ìpìlẹ̀ kankan, bí ẹni pé kò nítumọ̀ rárá.

Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá lè pèsè àgbájọ ẹ̀kọ́ tó lè wúlò fún gbígbé ìgbésí ayé wa. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún jíjìn sọ́fìn irú àṣìṣe kan náà tó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn kan rí léraléra. Ńṣe ló rí gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ọgbọ́n orí kan ti sọ ọ́ pé, ó di dandan káwọn èèyàn tí kì í rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá tún tún àṣìṣe kan náà ṣe. Mímọ̀ nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nígbà kan rí lè jẹ́ kí òye àwọn ìgbà ọ̀làjú tó ti kọjá yé wa, àwọn nǹkan àgbàyanu táwọn èèyàn ṣàwárí, àwọn èèyàn tó fani mọ́ra, àti gbígba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wo nǹkan.

Àmọ́ nígbà tó jẹ́ pé àwọn èèyàn ayé ọjọ́un àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà náà lọ́hùn ún ni ìtàn ń sọ nípa rẹ̀, báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá ó yẹ ká gbà á gbọ́? Báa bá máa rí nǹkan tó níláárí kọ́ nínú ìtàn, ó ṣe kedere nígbà náà pé, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí táa gbé karí òtítọ́. Táa bá sì ti rí ohun tó jẹ́ òtítọ́, ńṣe ló yẹ ká tẹ́wọ́ gbà á, kódà ká tilẹ̀ ní ìyẹn lè má fìgbà gbogbo rọrùn fún wa láti ṣe. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá lè dà bí ọgbà òdòdó kan—tó láwọn ẹwà tiẹ̀ tó sì tún láwọn ẹ̀gún pẹ̀lú; ó lè fani mọ́ra, ó sì tún lè gúnni.

Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé eléyìí, a óò gbé àwọn apá díẹ̀ yẹ̀ wò nínú ìtàn ènìyàn, èyí tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti díwọ̀n bí àwọn ohun tí a ń kà ṣe péye tó. A óò tún ṣàyẹ̀wò bí àwọn ìtàn tó ṣeé gbà gbọ́ ṣe lè ṣàǹfààní fáwọn òǹkàwé tó ń fòye mọ nǹkan.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ọbabìnrin Nefertiti

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá?

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Nefertiti: Ägyptisches Museum der Staatlichen Museen Preußischer Kulturbesitz, Berlin

Lára àkámọ́: Iléeṣẹ́ British Museum ló fún wa láṣẹ láti ya fọ́tò yìí