Ẹ̀kọ́ Táwọn Èèyàn Kọ́ Látinú Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Loida
Ẹ̀kọ́ Táwọn Èèyàn Kọ́ Látinú Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Loida
ÀPILẸ̀KỌ náà “Bí Loida Ṣe Di Ẹni Tó Ń Sọ̀rọ̀” (September 8, 2000) ti mú kí àwọn òǹkàwé wa sọ̀rọ̀ lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan. Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ní àrùn tí kò jẹ́ kí ọpọlọ rẹ̀ lè darí ìséraró àti ìsọ̀rọ̀ rẹ̀, tí kò sì lè sọ̀rọ̀, títí tó fi pé ọmọ ọdún méjìdínlógún wú ọ̀pọ̀ èèyàn lórí gan-an ni. Ẹ gbọ́ díẹ̀ lára ohun táwọn èèyàn sọ tó tẹ̀ wá lọ́wọ́.
“Ńṣe ni mo kàn ń ké ṣáá nígbà ti mo ka ohun tí Loida kọ sí àwọn ìdílé rẹ̀ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Mo máa gbìyànjú kárakára láti ṣàfarawé ìgboyà àti okun tó ní láìka bí ipò tó wà ṣe le koko sí.”—K. G.
“Èmi ò níṣòro àìlera ní tèmi o, àmọ́ nígbà míì, màá kàn rí i pé mo máa ń ṣàròyé nípa oríṣiríṣi nǹkan ni. Lẹ́yìn tí mo ka ìtàn Loida, ńṣe ni mo kúnlẹ̀ tí mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jọ̀wọ́ má ṣe bínú fún bí mi ò ṣe mọrírì ìlera tó jí pépé tí mo ní.”—R. H.
“Onírúurú àìsàn ló wà lára àbúrò mi ọkùnrin látìgbà tí wọ́n ti bí i ní 1980, àrùn tí kò jẹ́ kí ọpọlọ rẹ̀ lè darí ìséraró àti ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ ń ṣe é pàápàá, kò sì lè sọ̀rọ̀. Ìrírí yìí fún ìdílé mi níṣìírí láti má ṣe jẹ́ kó sú wa bó ti wù kí nǹkan le tó.”—L. W.
“Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni mí, ìgbà gbogbo ni mo sì máa ń ronú pé èmi nìkan ni mo níṣòro. Á wù mí láti rí Loida nínú Párádísè ká sì jọ sọ̀rọ̀ dáadáa. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí mo kọ orúkọ wọn sínú àkọsílẹ̀ mi tí màá fẹ́ láti rí ká sì jọ máa ṣọ̀rẹ́ títí láé.”—R. K.
“Àpilẹ̀kọ yìí wú mi lórí púpọ̀púpọ̀. Onírúurú àìsàn ọpọlọ àti ti ara ló ti fojú mi rí màbo. Kíkà tí mo kà nípa bí Loida ṣe ń fojú sọ́nà tó láti wà nínú ayé tuntun Ọlọ́run túbọ̀ mú kí èmi náà yán hànhàn gidi gan-an láti wà níbẹ̀.”—P. B.
“Èmi náà ní àrùn tí kò jẹ́ kí ọpọlọ mi lè darí ìséraró, àmọ́ mo ṣì lè sọ̀rọ̀ ní tèmi. Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ kí ń mọ̀ pé Jèhófà ń rí gbogbo nǹkan tó ń bá wa fínra, pé ó sì tún mọrírì ohun tí a bá lè ṣe lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti sìn ín.”—D. J.
“Ohun tó wú mi lórí jù lọ ni bí mo ṣe kà nípa bí Loida ṣe ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà nígbà tó ṣì wà ní kékeré àti bó ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni àwa tára wa túbọ̀ ṣe ṣámúṣámú lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ lára Loida.”—A. R.
“Ìtàn Loida ti mú kí ń sakun láti túbọ̀ ronú nípa àwọn ẹlòmíràn àti nípa ohun tí mo lè ṣe fún wọn. Mi ò fojú kékeré wo àǹfààní tí mo ní láti lè bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run.”—B. M.
“Àpilẹ̀kọ yìí mà ṣàrà ọ̀tọ̀ o! A mọ tọkọtaya kan tí wọ́n wà ní ìjọ kan tó wà nítòsí wa tí wọ́n ní ọmọbìnrin kan tí àrùn tí kò jẹ́ kí ọpọlọ rẹ̀ lè darí ìséraró àti ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ ń ṣe. Mo máa fi káàdì ìkíni kan ránṣẹ́ sí wọn ní òní yìí láti lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé mo mọrírì wọn àti pé mo mọrírì gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe fún ọmọ wọn yìí.”—T. G.
“Nígbà mìíràn tí mo bá sorí kọ́, ńṣe ni mo máa ń di anìkànjọpọ́n, àmọ́ ńṣe ni Loida máa ń kó àwọn èèyàn mọ́ra. Ohun tí mo ń tiraka láti ṣe gan-an nìyẹn. Mo tún gbọ́dọ̀ túbọ̀ gbìyànjú láti dà bíi Loida kí n sì gbàdúrà sí Jèhófà nígbà tí ipò àwọn nǹkan bá dà mí lọ́kàn rú.”—N. D.
“Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni mí, ikọ́ fée sì ń bá mi jà. Nígbà míì mo máa ń ronú pé àìsàn mi ló burú jù lọ láyé, àmọ́ ìrírí yìí tí mo kà ti jẹ́ kí n mọ̀ pé kì í ṣe bí mo ṣe ronú lọ̀ràn rí. Ẹ ṣeun púpọ̀ fún ìrírí yìí tó fún wa nírètí bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń báni nínú jẹ́.”—M. C.