Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìṣirò Nípa Àrùn Éèdì Ń Kóbànújẹ́ Ńláǹlà Báni!

Ìṣirò Nípa Àrùn Éèdì Ń Kóbànújẹ́ Ńláǹlà Báni!

Ìṣirò Nípa Àrùn Éèdì Ń Kóbànújẹ́ Ńláǹlà Báni!

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ

ỌMỌ ọdún méjìlá ni Thembeka tó ń gbé ní abúléko kan lápá gúúsù Áfíríkà. Àrùn éèdì (AIDS) ti pa àwọn òbí rẹ̀, òun ló wá kù tó ń bójú tó àwọn àbúrò rẹ̀ obìnrin kéékèèké mẹ́ta, tọ́jọ́ orí wọn jẹ́ ọdún mẹ́wàá, mẹ́fà, àti mẹ́rin. Akọ̀ròyìn kan sọ pé: “Kò síbì kankan táwọn ọmọdébìnrin yìí ti lè rówó ná, ohun táwọn olójú àánú tó wà ládùúgbò bá fún wọn nìkan ni wọ́n gbára lé . . . bíi kí wọ́n fún wọn ní búrẹ́dì díẹ̀ àti ọ̀dùnkún bíi mélòó kan.” Àwòrán àwọn ọmọdébìnrin mẹ́rin aláìlóbìí náà wà lójú ewé àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn Gúúsù Áfíríkà kan tó sọ̀rọ̀ nípa Ìpàdé Àpérò Àgbáyé Lórí Àrùn Éèdì ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlá, tí wọ́n ṣe ní July 2000, ní ìlú Durban, lórílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà.

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ tó ti di aláìlóbìí nítorí àrùn éèdì ló ń kojú irú ìṣòro kan náà bíi ti Thembeka àtàwọn àbúrò rẹ̀. Ìpàdé àpérò náà jíròrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè fi kojú wàhálà àrùn éèdì tó ń fojoojúmọ́ gogò sí i, bí ìlàlóye lórí dídènà àrùn éèdì nípa lílo kọ́ńdọ̀mù; ṣíṣàmúlò ìtọ́jú àrùn éèdì tí kò gbówó lórí, èyí tó ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó báyìí; àti títúbọ̀ fowó ṣètìlẹ́yìn fún mímú abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àrùn éèdì jáde. Wọn kò tún ṣàìmẹ́nu kan bó ṣe jẹ́ pé àwọn obìnrin, pàápàá àwọn ọ̀dọ́bìnrin ló lè tètè kó àrùn náà jù lọ.

O báni nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí àrùn éèdì ti pa àwọn òbí wọn làwọn ọkùnrin kan máa ń wá kiri, nítorí wọ́n gbà gbọ́ pé ọ̀nà tí àwọn lè gbà bọ́ nínú kíkó àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń tàtaré rẹ̀ ni níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú irú àwọn wúńdíá bẹ́ẹ̀. Láfikún sí i, ọ̀pọ̀ ọkùnrin ni kò ní gbé ọ̀dọ́bìnrin kan níyàwó láìṣe pé ó bá kọ́kọ́ bímọ fún wọn. Fún ìdí yìí, wọ́n máa ń wo kọ́ńdọ̀mù pé ńṣe ló ń ṣèdíwọ́ fún ìgbéyàwó àti dídi ìyá ọmọ.

Ó dunni pé, ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin ni kò mọ ewu tó wà nínú àrùn éèdì yìí rárá. Ìwé ìròyìn kan ní Gúúsù Áfíríkà tí wọ́n ń pè ní Sowetan fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìròyìn kan tí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé (UNICEF) gbé jáde níbi ìpàdé àpérò ọ̀hún, ó sọ pé: “Ìwádìí tí àjọ UNICEF ṣe fi hàn pé ìpín mọ́kànléláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́bìnrin, tọ́jọ́ orí wọn jẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mọ́kàndínlógún ní Gúúsù Áfíríkà ni kò mọ̀ pé ẹnì kan tára rẹ̀ jọ pé ó le dáadáa lè ti kó kòkòrò àrùn éèdì, àti pé ó lè tàtaré rẹ̀ sí wọn.”

Kókó mìíràn tó tún ń dá kún títan àrùn éèdì kálẹ̀ ni fífi ìbálòpọ̀ fìtínà àwọn obìnrin. Ranjeni Munusamy, tó wà níbi àpérò náà sọ nínú ìwé ìròyìn Sunday Times ti ìlú Johannesburg ní Gúúsù Áfíríkà pé: “Híhùwà ipá sáwọn obìnrin, èyí tó jẹ́ ọ̀nà tó burú jù lọ táwọn ọkùnrin fi ń ṣi agbára wọn lò ṣì ni wàhálà tó tóbi jù tó ń ṣèdíwọ́ fún dídènà kòkòrò àrùn éèdì àti títọ́jú àrùn náà. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n ń gbà ṣe èyí, bíi fífipá báni lòpọ̀, ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan, lílu aya ẹni àti fífi ìbálòpọ̀ fìtínà ẹni, tó túmọ̀ sí pé ńṣe ni wọ́n máa ń fi ọ̀ranyàn bá wọn lòpọ̀, tíyẹn gan-an sì jẹ́ ohun kan tó léwu tó ń fa àkóràn kòkòrò àrùn éèdì.”

Ìṣirò tí wọ́n gbé jáde níbi àpérò náà bani lẹ́rù, gẹ́gẹ́ bí ṣáàtì tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí ti fi hàn. Wọ́n fojú bù ú pé, lójoojúmọ́ làwọn ọ̀dọ́ tó tó ẹgbẹ̀rún méje àtàwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tó tó ẹgbẹ̀rún kan ń kó kòkòrò àrùn éèdì. Láàárín ọdún kan, ìyẹn lọ́dún 1999, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógójì [860,000] àwọn ọmọdé ní àgbègbè gúúsù aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà ló pàdánù àwọn olùkọ́ wọn nítorí àrùn éèdì.

Níbàámu pẹ̀lú ìwádìí kan tí Ẹgbẹ́ Oníṣègùn Tí Ń Ṣèwádìí ní Gúúsù Áfíríkà gbé jáde, mílíọ̀nù mẹ́rin àti ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [4,200,000] ènìyàn ló ti kó kòkòrò àrùn éèdì ní ilẹ̀ Gúúsù Áfíríkà, ìyẹn sì dúró fún ẹnì kan nínú gbogbo ènìyàn mẹ́wàá ní orílẹ̀-èdè náà. Ọ̀ràn tàwọn orílẹ̀-èdè kan tó wà nítòsí wọn tiẹ̀ tún burú jùyẹn lọ. Ìwé ìròyìn The Natal Witness sọ pé, Ẹ̀ka Ìjọba fún Ètò Ìkànìyàn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fojú bù ú pé: “Kò ní pẹ́ mọ o, tí iye àwọn olùgbé àwọn orílẹ̀-èdè kan níbi tí àrùn éèdì ti ń jà ràn-ìn ní ilẹ̀ Áfíríkà fi máa bẹ̀rẹ̀ sí lọ sílẹ̀, bí àrùn náà ṣe ń pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn, tí iye ọdún tí wọ́n á sì máa gbé láyé kò ní ju nǹkan bí ọgbọ́n ọdún lọ tó bá fi máa di ìparí ẹ̀wádún yìí.”

Ọ̀ràn àrùn éèdì bíbani nínú jẹ́ yìí jẹ́ àfikún ẹ̀rí pé ìran ènìyàn ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” èyí tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀ “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1-5) Àwọn tó fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, ń fojú sọ́nà fún mímú àrùn éèdì àtàwọn ìṣòro mìíràn tó ń yọ aráyé lẹ́nu kúrò pátápátá títí ayé. Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ bíbójútó àwọn àlámọ̀rí ayé. Nínú ayé tuntun òdodo, ipò òṣì àti ìnilára yóò di nǹkan ìgbàgbé. (Sáàmù 72:12-14; 2 Pétérù 3:13) Dípò ìyẹn, àwọn olùgbé ayé yóò ní ìlera pípé, kò sì ní sí ìkankan nínú wọ́n tí yóò wí pé: “Àìsàn ń ṣe mí.”—Aísáyà 33:24.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

Nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́tàlá [13,000,000] àwọn ọmọdé jákèjádò ayé ló ti di aláìlóbìí nítorí àrùn éèdì

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 13]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

IYE ÀWỌN ÀGBÀLAGBÀ (ỌJỌ́ ORÍ 15 sí 49) TÓ NÍ ÀRÙN ÉÈDÌ, ÌPARÍ ỌDÚN 1999

Àríwá Amẹ́ríkà 890,000

Caribbean 350,000

Látìn Amẹ́ríkà 1,200,000

Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù 520,000

Ìhà Ìlà Oòrùn àti Àárín Gbùngbùn Yúróòpù 410,000

Àríwá Áfíríkà àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé 210,000

Àgbègbè Gúúsù Aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà 23,400,000

Gúúsù àti Ìhà Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà 5,400,000

Ìlà Oòrùn Éṣíà àti Pàsífíìkì 530,000

Ọsirélíà àti New Zealand 15,000

[Credit Line]

Orísun: UNAIDS

[Graph/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN ÀGBÀLAGBÀ (ỌJỌ́ ORÍ 15 sí 49) TÓ NÍ ÀRÙN ÉÈDÌ NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ ÁFÍRÍKÀ MẸ́RÌNDÍNLÓGÚN, ÌPARÍ ỌDÚN 1999

1 Botswana 35.8%

2 Swaziland 25.2

3 Zimbabwe 25.0

4 Lesotho 23.5

5 Zambia 20.0

6 Gúúsù Áfíríkà 20.0

7 Namibia 19.5

8 Màláwì 16.0

9 Kẹ́ńyà 14.0

10 C.A.R. 14.0

11 Mòsáńbíìkì 13.2

12 Djibouti 11.7

13 Burundi 11.3

14 Rwanda 11.2

15 Côte d’Ivoire 10.7

16 Etiópíà 10.6

[Credit Line]

Orísun: UNAIDS

[Àwòrán]

Thembeka àtàwọn àbúrò rẹ̀

[Credit Line]

Fọ́tò: Brett Eloff