Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí La Lè Rí Kọ́ Látinú Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ Kọjá?

Kí La Lè Rí Kọ́ Látinú Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ Kọjá?

Kí La Lè Rí Kọ́ Látinú Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ Kọjá?

“Kò sóhun tó ṣe pàtàkì fáwọn òpìtàn ju pé kí wọ́n sọ nípa bí nǹkan kan ṣe ṣẹlẹ̀ àtohun tó yọrí sí.”—GERALD SCHLABACH, IGBÁKEJÌ Ọ̀JỌ̀GBỌ́N NÍNÚ ÌTÀN.

Ì BÉÈRÈ táwọn òpìtàn sábà máa ń béèrè ni pé, Báwo àti kí nìdí tàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan fi ṣẹlẹ̀? Fún àpẹẹrẹ, a gbọ́ ọ nínú ìtàn pé Ilẹ̀ Ọba Róòmù ṣubú. Àmọ́ kí ló mú kó ṣubú? Ṣé nítorí ìwà ìbàjẹ́ ni, àbí kẹ̀ fàájì àṣejù ló fà á? Ṣé ilẹ̀ ọba náà ti wá tóbi kọjá ohun tó ṣe é ṣàkóso ni, tí owó táwọn ológun rẹ̀ sì ń béèrè pọ̀ kọjá ààlà? Ṣé àwọn ọ̀tá tí ilẹ̀ Róòmù ní ti wá pọ̀ lápọ̀jù ni tágbára rẹ̀ kò sì ká wọn mọ́?

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àfi bí ẹni pé ọ̀sán kan òru kan ni ètò ìjọba Kọ́múníìsì apá Ìlà Oòrùn Yúróòpù, táwọn èèyàn tí ń wò gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá fún Ìwọ̀ Oòrùn ayé bẹ̀rẹ̀ sí wó lulẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Àmọ́ kí ló fà á? Àwọn ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú rẹ̀? Irú àwọn ìbéèrè yìí làwọn òpìtàn máa ń gbìyànjú àtiwá ìdáhùn sí. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń wá ìdáhùn sí wọn, dé àyè wo gan an ni ẹ̀tanú fi máa ń nípa lórí ohun tí wọ́n ń ṣe?

Ṣé A Lè Fọkàn Tán Ohun Táwọn Òpìtàn Sọ?

Iṣẹ́ àwọn òpìtàn kọjá tàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, bí ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ni wọ́n rí. Wọ́n máa ń wádìí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, wọ́n máa ń béèrè ìbéèrè lórí rẹ̀, wọ́n sì máa ń ṣelámèyítọ́ irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. A mọ̀ pé òtítọ́ ni wọ́n ń wá, ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n ń wá gan-an kì í yéni kedere lọ́pọ̀ ìgbà. Ọ̀kan lára ìdí tó fa èyí ni pé iṣẹ́ wọ́n ní púpọ̀ ọ́ ṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn, bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò ṣeé ṣe fáwọn òpìtàn láti rí ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn—àgàgà ohun tó wà lọ́kàn àwọn tó ti kú. Àwọn òpìtàn tún lè ní àwọn èrò kan tàbí àwọn ẹ̀tanú kan lọ́kàn tẹ́lẹ̀. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé nígbà míì tí wọ́n bá ṣe ìwé kan tó dára gan an, ó lè jẹ́ látinú ìtumọ̀ tiwọn fúnra wọn ni—ìyẹn ohun tó jẹ́ èrò òpìtàn yẹn gangan.

Ó dájú pé, bí òpìtàn kan bá ní èrò tirẹ̀ kò fi dandan túmọ̀ sí pé iṣẹ́ rẹ̀ kò péye. Àwọn ìtàn Bíbélì tó wà nínú ìwé Sámúẹ́lì, Àwọn Ọba, àti Kíróníkà ní àwọn àkọsílẹ̀ kan náà nínú tó sì jẹ́ pé àwọn èèyàn márùn ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló kọ wọ́n, síbẹ̀ a lè rí i pé wọn kò ní ohun kan táa lè fi bẹ́ẹ̀ sọ pé wọ́n fi takora tàbí tí kò mú kí wọ́n péye. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú àwọn Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin inú Bíbélì. Àní sẹ́, púpọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì ló ṣàkọsílẹ̀ àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ àtàwọn àṣìṣe tí kò bọ́gbọ́n mu tiwọn fúnra wọn—èyí sì jẹ́ ohun tó ṣọ̀wọ́n láàárín àwọn tó ń ṣe irú iṣẹ́ náà.—Númérì 20:9-12; Diutarónómì 32:48-52.

Yàtọ̀ sáwọn ẹ̀tanú tó ṣeé ṣe kó wà, kókó pàtàkì mìíràn tó yẹ kéèyàn gbé yẹ̀ wò nígbà tó bá ń kà nípa ohun tó ti kọjá ni ète tẹ́ni náà fi kọ ọ́. Michael Stanford, nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní A Companion to the Study of History sọ pé: “Èèyàn gbọ́dọ̀ fura gidigidi sí ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ tí ẹnì kàn tó ń ṣi agbára lò tàbí tí àwọn kan tó fẹ́ dé ipò agbára tàbí àwọn ọ̀rẹ́ wọn bá sọ nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá.” Ète tí ń kọni lóminú tún máa ń fara hàn nígbà tí ìwé ìtàn kan bá ń lo ọgbọ́n àyínìke tàbí tó tiẹ̀ ń dìídì sọ nípa ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti níní ìfọkànsìn fún un. Ó bani nínú jẹ́ pé irú nǹkan báyìí máa ń fara hàn nínú ìwé táwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ń lò. Òfin ìjọba orílẹ̀-èdè kan tiẹ̀ dìídì sọ pé ète tí wọ́n fi ń kọ́ni nípa ìtàn ni “láti mú ìfẹ́ àti ìfọkànsìn fún orílẹ̀-èdè ẹni di èyí tó lágbára lọ́kàn àwọn èèyàn . . . nítorí pé níní ìmọ̀ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè ẹni láwọn ìgbà tó kọjá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń mórí ẹni yá láti fọkàn sin orílẹ̀-èdè ẹni.”

Yíyí Ìtàn Po

Nígbà míì, kì í ṣe pé ìtàn máa ń ní ẹ̀tanú nínú nìkan ni; ṣùgbọ́n wọ́n tún máa ń yí i po. Fún àpẹẹrẹ, ìwé Truth in History sọ pé ilẹ̀ Soviet Union ọjọ́un “yọ orúkọ Trotsky kúrò nínú àkọsílẹ̀ pátápátá, débi pé òtítọ́ pé olórí ìjọba yìí ti fìgbà kan wà rí ti pòórá.” Ta tiẹ̀ ni Trotsky? Aṣáájú kan ló jẹ́ lásìkò Ìyípadà Tegbòtigaga tó wáyé ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà tí Bolshevik ṣagbátẹrù rẹ̀, òun ló wà nípò kejì sí Lenin. Lẹ́yìn ikú Lenin, Trotsky ní gbólóhùn asọ̀ pẹ̀lú Stalin, ni wọ́n bá yọ ọ́ kúrò nínú Ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì, wọ́n sì pa á lẹ́yìn náà. Kódà wọn ò jẹ́ kórúkọ rẹ̀ kankan ṣẹ́ kù sílẹ̀ nínú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ ilẹ̀ Soviet. Irú fífèrú yí ìtàn po bẹ́ẹ̀, àní títí débi sísun ìwé àwọn èèyàn tí kò bá fara mọ́ tiwọn nínú iná, ti di àṣà fún púpọ̀ lára àwọn ìjọba aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀.

Àmọ́, kì í ṣe pé àṣà yíyí ìtàn po ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ o, ó ti wà láti ìgbà ayé Íjíbítì àti Ásíríà. Àwọn fáráò, àwọn ọba, àtàwọn olú ọba tí wọ́n jẹ́ agbéraga máa ń rí sí i pé ìtàn nípa ohun táwọn ṣe ni a sọ kọjá bó ṣe yẹ. Nítorí náà, kò sígbà tí wọn kì í fọ́nnu nípa àṣeyọrí wọn, bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọn ò jẹ́ fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohunkóhun tó bá kó ìtìjú tàbí àbùkù bá wọn, wọ́n lè yọ ìyẹn kúrò nínú ìtàn tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ kọ ọ́ sílẹ̀ rárá, irú bí i pé wọ́n ṣẹ́gun wọn lójú ogun. Ní ìyàtọ̀ gédégbé, ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó wà nínú Bíbélì sọ nípa ìṣubú, ó sì tún sọ nípa ànímọ́ dídára tí àwọn ọba àti àwọn ọmọ abẹ́ wọn ní.

Báwo làwọn òpìtàn ṣe ń mọ̀ bóyá àwọn àkọsílẹ̀ ògbólógbòó kan péye? Wọ́n máa ń fi wọ́n wéra pẹ̀lú àwọn nǹkan bíi ìwé owó orí tó ti pẹ́, àwọn ìlànà òfin, ìpolówó ọjà fún lílu ẹrú ní gbàǹjo, àwọn lẹ́tà ìdókòwò àti ti àdáni àti àwọn àkọsílẹ̀ wọn, àwọn ohun tí wọ́n kọ sára àfọ́kù ìkòkò, àkọsílẹ̀ nípa ìgbòkègbodò ọkọ ojú omi, àtàwọn ohun tí wọ́n rí nínú àwọn sàréè àti ilẹ̀ ìsìnkú. Oríṣiríṣi àwọn nǹkan yìí sábà máa ń pèsè àfikún ẹ̀rí tàbí kó tànmọ́lẹ̀ tó yàtọ̀ sórí àwọn àkọsílẹ̀. Níbi tí wọn kò bá ti rí àlàyé sí ohun kan tàbí tí nǹkan kan kò bá dá wọn lójú, àwọn tó jẹ́ òpìtàn gidi sábà máa ń sọ ọ́ jáde, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè pèsè àbá èrò orí tiwọn láti fi dí àwọn àlàfo náà. Ohun tó wù kó ṣẹlẹ̀, táwọn òǹkàwé tó gbọ́n bá ń wá àlàyé kíkún nípa ohun kan, kì í ṣe ẹyọ ìwé kanṣoṣo ni wọ́n sábà máa ń kàn sí.

Láìka gbogbo ìṣòro tí òpìtàn kan lè dojú kọ sí, ìwé rẹ̀ ṣì lè ní ìsọfúnni tó wúlò nínú. Ìwé ìtàn kan sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn láti kọ ìtàn àwọn ohun pàtàkì tó ti ṣẹlẹ̀ látìgbà ìwáṣẹ̀ ènìyàn, síbẹ̀ wọ́n ṣe pàtàkì fún wa, wọ́n tilẹ̀ pọndandan pàápàá.” Yàtọ̀ sí pé ìtàn máa ń jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ó tún lè jẹ́ ká ní òye tó pọ̀ sí i nípa ohun tó fa ipò tí ẹ̀dá ènìyàn wà lónìí. Fún àpẹẹrẹ, kì í pẹ́ rárá táa fi ń ri í pé ìhùwàsí àwọn èèyàn tó wà láyé ọjọ́un kò yàtọ̀ rárá sí tàwọn tó ń gbé ayé lọ́jọ́ òní. Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ léraléra yìí ti ní ipa pàtàkì tó kó nínú ìtàn, bóyá òun ló fà á táwọn èèyàn fi máa ń sọ ọ̀rọ̀ náà pé, bí ó ti wà látètèkọ́ṣe, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì máa rí lọ. Àmọ́ ṣé ọ̀rọ̀ yẹn bọ́gbọ́n mu?

Ṣé Bó Ṣe Wà Látètèkọ́ṣe Ni Yóò Máa Rí Lọ?

Ǹjẹ́ a lè fi ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú lọ́nà tó pé pérépéré? Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan wà tó máa ń ṣẹlẹ̀ léraléra. Fún àpẹẹrẹ, Henry Kissinger, tó jẹ́ Olùdarí Ètò Òde ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nígbà kan sọ pé: “Kò sí ọ̀kankan nínú gbogbo ọ̀làjú tó ti wà rí tí kò ṣubú.” Ó fi kún un pé: “Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá jẹ́ ìròyìn nípa àwọn ìsapá tó ti forí ṣánpọ́n, àwọn ohun táa fojú sọ́nà fún, àmọ́ tọ́wọ́ kò tẹ̀. . . . Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn kan, èèyàn gbọ́dọ̀ gbà pé ìgbàkígbà ni nǹkan ìbànújẹ́ lè ṣẹlẹ̀.”

Kò sí ọ̀kankan nínú àwọn ilẹ̀ ọba tó jẹ́ pé bákan náà ni wọ́n ṣe ṣubú. Òru ọjọ́ kan ni Bábílónì ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Gíríìsì ní tiẹ̀ pín sí oríṣiríṣi ìjọba lẹ́yìn ikú Alẹkisáńdà Ńlá, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó juwọ́ sílẹ̀ fún Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Àmọ́ ọ̀nà tí Róòmù gbà ṣubú ṣì ń fa arukutu. Gerald Schlabach tó jẹ́ òpìtàn béèrè pé: “Ìgbà wo ni Róòmù ṣubú? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣubú rárá? Nkan kan yí padà ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù láàárín ọdún 400 àti 600 Sànmánì Tiwa. Àmọ́ púpọ̀ ṣì ń bá a lọ.” a Ó ṣe kedere pé, apá kan lára àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ṣì máa ń ṣẹlẹ̀, nígbà táwọn kan kì í padà ṣẹlẹ̀ mọ́.

Ẹ̀kọ́ kan tó máa ń wá sójú táyé nígbà gbogbo nínú ìtàn ènìyàn ni bí ìṣàkóso wọn ṣe máa ń kùnà. Àtọdúnmọ́dún ni ìṣàkóso dídára ti máa ń dojú rú ṣáá nítorí ìfẹ́ ara ẹni, àìmọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́la, ojú kòkòrò, ìwà ìbàjẹ́, ojúsàájú, àti àgàgà, ìfẹ́ òdì láti fẹ́ gba agbára kí wọ́n má sì fẹ́ fi í sílẹ̀ mọ́. Ìdí rèé tí ìtàn fi kún fún ìjà lọ́tùn-ún lósì, àwọn àdéhùn tó forí ṣánpọ́n, ogun, ìwà ipá láàárín àwùjọ, ṣíṣe ojúsàájú nídìí pípín ọrọ̀, àti ètò ọrọ̀ ajé tó fọ́ yángá.

Fún àpẹẹrẹ, kíyè sí ohun tí ìwé The Columbia History of the World sọ nípa bí ọ̀làjú àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé ṣe nípa lórí àwọn ará yòókù láyé, ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí Columbus àti Cortes ti jẹ́ kí ojú àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù là sí oríṣiríṣi nǹkan tán, ni ìfẹ́ àwọn èèyàn ọ̀hún fún ohun tí wọ́n lè rí gbà, èrè, àti òkìkí bá ru sókè, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tẹ́wọ́ gba ọ̀làjú àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé, àmọ́, èyí tí wọ́n gbà ní tipátipá ló pọ̀ jù, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ bó ti rí ní gbogbo ayé pátá nìyẹn. Bí ìfẹ́ wọn láti túbọ̀ gbòòrò sí i ti ń tì wọ́n gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, pẹ̀lú àwọn ohun ìjà àkòtagìrì tó wà níkàáwọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ làwọn aṣẹ́gun yìí sọ ìyókù gbogbo ayé di ara agbára Yúróòpù ní tipátipá . . . Ká má fa ọ̀rọ̀ gùn, àwọn èèyàn ilẹ̀ yìí [Áfíríkà, Éṣíà, àtàwọn ilẹ̀ àgbègbè Amẹ́ríkà] ló forí fá ìkóninífà aláìláàánú tí kò dáwọ́ dúró yẹn.” Òtítọ́ gbáà lọ̀rọ̀ táa rí nínú Bíbélì ní Oníwàásù 8:9 pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀”!

Bóyá àkọsílẹ̀ tí ń bani nínú jẹ́ yìí lohun tó sún onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan láti sọ pé, kìkì ohun táa lè rí kọ́ nínú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ni pé ènìyàn kó rí ẹ̀kọ́ kankan kọ́ nínú wọn. Jeremáyà 10:23 sọ pé: “Ọ̀na enia kò si ni ipa ara rẹ̀: kò si ni ipá enia ti nrin, lati tọ́ iṣisẹ rẹ̀.” (Bibeli Mim) Ṣíṣàì lè tọ́ ìṣísẹ̀ wa yìí yẹ kó jẹ́ ọ̀ràn tó kàn wá gbọ̀ngbọ̀n lónìí. Kì nídìí? Ìdí ni pé, àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra lónìí pọ̀ wọ́n sì tóbi, débi pé kò tíì sírú wọn rí nínú ìtàn. Nítorí náà, báwo la ṣe fẹ́ kojú wọn?

Àwọn Ìṣòro Tí Kò Lẹ́gbẹ́

Nínú gbogbo ìtàn ẹ̀dá ènìyàn látòkèdélẹ̀, kò tíì sígbà kankan táwọn nǹkan bíi pípa igbó run, ìṣànlọ erùpẹ̀, sísọ igbó di aṣálẹ̀, àkúrun àwọn ohun ọ̀gbìn títí kan ọ̀wọ́ àwọn ẹranko kan lọ́nà tó bùáyà, afẹ́fẹ́ ozone tó ń dín kù, ìbàyíkájẹ́, mímóoru tí ayé ń móoru, àwọn agbami òkun tí wọ́n ti lò lálòyọ́, àti iye ènìyàn tí ń pọ̀ sí i lọ́nà tó yamùrá jẹ́ àwọn ohun tó ń para pọ̀ halẹ̀ mọ́ ayé.

Ìwé kan tó ń jẹ́ A Green History of the World sọ pé: “Ìṣòro mìíràn tó tún ń kojú àwùjọ òde òní ni ti bí nǹkan ṣe ń sáré yí padà kíákíá.” Ed Ayres tí í ṣe olóòtú ìwé ìròyìn World Watch kọ̀wé pé: “Ohun tó ń kojú wa báyìí kọjá ohun tí ẹnikẹ́ni nínú wa tíì ní ìrírí rẹ̀ rí débi pé, nǹkan ọ̀hún kò tiẹ̀ yé wa rárá, kódà bí ẹ̀rí jaburata tilẹ̀ wà yí wa ká. Ìkọlù ńlá gbáà ni ‘nǹkan’ náà jẹ́ fún wa, ó sì ń yí ọ̀nà ìgbésí ayé wa àtàwọn ohun táa ń fojú rí padà lọ́nà tó ga, ìyẹn nínú ayé tó jẹ́ pé òun ló ti ń so ẹ̀mí wa ró bọ̀.”

Lójú àwọn ìṣòro yìí àtàwọn mìíràn tó fara pẹ́ ẹ, òpìtàn Pardon E. Tillinghast sọ pé: “Ọ̀nà táwùjọ forí lé ti túbọ̀ di èyí tó lọ́jú pọ̀ pátápátá, àwọn ìṣòro ọ̀hún sì ń kó ìpayà bá ọ̀pọ̀ nínú wa. Ìtọ́sọ́nà wo wá làwọn òpìtàn amọṣẹ́dunjú ní fún àwọn èèyàn tọ́kàn wọn ti pòrúurùu lónìí? Ó dà bí ẹni pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí.”

Àwọn òpìtàn amọṣẹ́dunjú lè má mọ ohun tí wọ́n lè ṣe tàbí ìmọ̀ràn tí wọ́n lè fúnni, àmọ́ ó dájú hán-ún pé ọ̀rọ̀ ti Ẹlẹ́dàá wa kò rí bẹ́ẹ̀. Àní sẹ́, ó sọ tẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, aráyé yóò ní ìrírí “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1-5) Àmọ́ Ọlọ́run tiẹ̀ tún ti ṣe ju ohun táwọn òpìtàn kò lágbára láti ṣe lọ—ó ti fọ̀nà tí a lè gbà rójútùú hàn wá, gẹ́gẹ́ bí a óò ti rí i nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àkíyèsí Schlabach bá àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Dáníẹ́lì mu pé, ara Ilẹ̀ Ọba Róòmù fúnra rẹ̀ ni ẹni tí yóò gbapò rẹ̀ yóò ti jáde wá. Wo orí 4 àti 9 nínú ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

“Èèyàn gbọ́dọ̀ fura gidigidi sí ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ tí ẹnì kàn tó ń ṣi agbára lò . . . bá sọ nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá.”—ÒPÌTÀN MICHAEL STANFORD LÓ SỌ BẸ́Ẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Olú Ọba Nero

[Credit Line]

Roma, Musei Capitolini

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ní gbogbo ìran ni “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀”

[Àwọn Credit Line]

“The Conquerors,” látọwọ́ Pierre Fritel. Títí kan (láti apá òsì sí ọ̀tún): Ramses Kejì, Attila, Hannibal, Tamerlane, Julius Caesar (láàárín), Napoléon Kìíní, Alẹkisáńdà Ńlá, Nebukadinésárì, àti Charlemagne. Látinú ìwé The Library of Historic Characters and Famous Events, Ìdìpọ̀ Kẹta, 1895; àwọn ọkọ̀ òfuurufú: fọ́tò USAF