Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Lọ Sáwọn Ìpàdé Ìjọ?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Lọ Sáwọn Ìpàdé Ìjọ?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Lọ Sáwọn Ìpàdé Ìjọ?

“MO MÁA ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tẹ́lẹ̀, àmọ́ ń kìí lọ mọ́ báyìí.” “Kò dìgbà téèyàn bá lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kó tó lè sin Ọlọ́run, o lè sìn ín níbikíbi tó bá wù ọ́.” “Mo gba Ọlọ́run àti Bíbélì gbọ́, àmọ́ mi ò gbà pé ó pọndandan kéèyàn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì.” Ṣé ìwọ náà ti gbọ́ àwọn gbólóhùn bí èyí rí? Ńṣe ni iye àwọn èèyàn tí wọ́n ń sọ irú gbólóhùn báwọ̀nyí túbọ̀ ń pọ̀ sí i, pàápàá jù lọ́ nílẹ̀ aláwọ̀ funfun. Àwọn èèyàn tí wọ́n máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tẹ́lẹ̀ kò rò pé ó tún pọndandan láti lọ mọ́. Kí tiẹ̀ ni Bíbélì sọ nípa lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì?

Ọ̀rọ̀ náà “ṣọ́ọ̀ṣì” àti “àwọn ìjọ” ni a lò níye ìgbà tó ju àádọ́fà lọ nínú ìtumọ̀ Bíbélì King James Version. Àwọn Bíbélì mìíràn sì tún lo àwọn gbólóhùn wọ̀nyí. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí “ìjọ” láìlábùlà túmọ̀ sí “kíké síni,” tàbí, lédè mìíràn àwọn ènìyàn tó péjọ. Fún àpẹẹrẹ, ìwé Ìṣe 7:38, Bibeli Mimọ sọ pé Mósè “wà ninu ijọ ni ijù,” ìyẹn ni pé ó wà láàárín orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó péjọ. Ìwé Mímọ́ tún sọ níbòmíràn pé “inunibini nla kan dide si ijọ,” èyí tó ń tọ́ka sí àwùjọ àwọn Kristẹni tí wọ́n wà ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 8:1, Bibeli Mim) Nínú ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ, ó kí “ìjọ inu ile [Fílémónì],” ìyẹn ìjọ tó ń pàdé pọ̀ níbẹ̀.—Fílémónì 2, Bibeli Mim.

Ó hàn gbangba pé, ọ̀rọ̀ náà “ìjọ” gẹ́gẹ́ bí a ti lò ó nínú Bíbélì dúró fún àwùjọ àwọn olùjọ́sìn, kì í ṣe ibi ìjọsìn. Clement ti Alẹkisáńdíríà tó jẹ́ olùkọ́ni nípa ẹ̀sìn ní ọ̀rúndún kejì kín èyí lẹ́yìn, ó kọ̀wé pé: “Ohun tí èmi ń pè ní Ìjọ kì í ṣe ibi tí àwọn ènìyàn péjọ sí bí kò ṣe àwọn ènìyàn àyànfẹ́ tí wọ́n péjọ.” Bọ́ràn bá tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ṣé dandan ni pé káwọn Kristẹni péjọ sí ibì kan ní pàtó tàbí sínú ilé kan kí Ọlọ́run tó lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn?

Bí Wọ́n Ṣe Ń Jọ́sìn ní Orílẹ̀ Èdè Ísírẹ́lì

Òfin Mósè béèrè pé kí gbogbo àwọn ọkùnrin Júù máa kóra jọ pọ̀ síbì kan pàtó fún ayẹyẹ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́dọọdún. Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin àtàwọn ògo wẹẹrẹ sì máa ń pésẹ̀ pẹ̀lú. (Diutarónómì 16:16; Lúùkù 2:41-44) Àwọn àkókò kan wà tí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì kọ́ àwọn ènìyàn tó péjọ lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì ka Òfin Ọlọ́run fún wọn. “Wọ́n ń làdí rẹ̀, wọ́n sì ń fi ìtumọ̀ sí i; wọ́n sì ń mú kí ìwé kíkà náà yéni.” (Nehemáyà 8:8) Ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ nípa àwọn ọdún Sábáàtì ni pé: “Pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké àti àtìpó tí ó wà nínú àwọn ẹnubodè rẹ, kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́, bí wọn yóò ti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín, kí wọ́n sì kíyè sára láti mú gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ṣe.”—Diutarónómì 31:12.

Inú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù nìkan lèèyàn ti lè rú ẹbọ sí Ọlọ́run kónítọ̀hún sì tún gba ìtọ́ni látọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà. (Diutarónómì 12:5-7; 2 Kíróníkà 7:12) Nígbà tó yá, wọ́n ṣètò àwọn ilé mìíràn téèyàn ti lè jọ́sìn ní Ísírẹ́lì, ìyẹn làwọn sínágọ́gù. Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ibi téèyàn ti lè ka Ìwé Mímọ́ tó sì tún lè ti gbàdúrà. Pẹ̀lú gbogbo èyí, tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni olórí ibi ìjọsìn. Ohun tí òǹkọ̀wé Bíbélì náà Lúùkù kọ jẹ́ ká lóye èyí. Ó sọ nípa obìnrin arúgbó kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ánà, ẹni tó jẹ́ pé “kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ, tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ lóru àti lọ́sàn-án pẹ̀lú ààwẹ̀ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.” (Lúùkù 2:36, 37) Ṣíṣe ìjọsìn tòótọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ni Ánà gbájú mọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ipa ọ̀nà kan náà yìí sì ni àwọn Júù mìíràn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run tẹ̀ lé.

Ìjọsìn Tòótọ́ Lẹ́yìn Tí Kristi Kú

Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ò sí lábẹ́ Òfin Mósè mọ́ lẹ́yìn tí Jésù ti kú, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jẹ́ dandan pé kí wọ́n lọ jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì mọ́. (Gálátíà 3:23-25) Síbẹ̀, wọ́n ṣì ń kóra jọ pọ̀ láti gbàdúrà àti láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kò sí pé wọ́n kọ́ àwọn ilé fàkìà-fakia fún ìjọsìn, kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ilé àdáni àti àwọn ibi tí èrò pọ̀ sí ni wọ́n ń lò. (Ìṣe 2:1, 2; 12:12; 19:9; Róòmù 16:4, 5) Kò sí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tàbí ṣekárími aláyẹyẹ ìsìn nínú àwọn ìpàdé táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n jẹ́ kí ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe wọ́n rọ àwọn èèyàn lọ́rùn.

Pẹ̀lú bí ìwà táwọn èèyàn ń hù ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù ṣe burú jáì tó, ńṣe làwọn ìlànà Bíbélì táwọn Kristẹni ń kọ́ ní àwọn ìpàdé wọn mú wọn yàtọ̀ gédégbé sí àwọn èèyàn mìíràn. Kódà, ńṣe làwọn aláìgbàgbọ́ tí wọ́n wá sípàdé náà fún ìgbà àkọ́kọ́ polongo pé: “Ọlọ́run wà láàárín yín ní ti tòótọ́.” (1 Kọ́ríńtì 14:24, 25) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run wà láàárín wọn ní tòótọ́. “Nítorí náà, ní tòótọ́, àwọn ìjọ ń bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—Ìṣe 16:5.

Ǹjẹ́ Kristẹni kan nígbà yẹn ì bá ti rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run ká sọ pé inú àwọn tẹ́ńpìlì àwọn kèfèrí ló ti ń jọ́sìn tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ló ń jọ́sìn fúnra rẹ̀? Bíbélì fúnni ní ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere lórí ọ̀ràn yìí: Àwọn olùjọ́sìn tí a tẹ́wọ́ gbà gbọ́dọ̀ di apá kan ṣọ́ọ̀ṣì tòótọ́ kan ṣoṣo náà, tàbí ìjọ, ìyẹn àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ tó jẹ́ “ara kan.” Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tòótọ́, tí a mọ̀ sí àwọn Kristẹni.—Éfésù 4:4, 5; Ìṣe 11:26.

Lóde Òní Ńkọ́?

Dípò tí Bíbélì ì bá fi gbà wá níyànjú láti jọ́sìn nínú ìjọ, ohun tó sọ fún wa ni pé ká jọ́sìn pẹ̀lú ìj, “ìjọ Ọlọ́run alààyè,” àwọn ènìyàn tí wọ́n ń “jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (1 Tímótì 3:15; Jòhánù 4:24) Àwọn ìpàdé ìsìn tí Ọlọ́run fọwọ́ sí gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ènìyàn ní “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:11) Wọ́n ní láti ran àwọn tó bá péjọ lọ́wọ́ láti di Kristẹni tó dàgbà dénú, tó lè “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:14.

Àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tiraka láti tẹ̀ lé. Àwọn ìjọ wọn tí iye rẹ̀ lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́rin ààbọ̀ ó lé egbèje [91,400] máa ń péjọ déédéé láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì fún ara wọn níṣìírí lẹ́nì kìíní-kejì, wọ́n ń ṣe èyí láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, ní ilé àdáni, àtàwọn ibòmíràn tí wọ́n lè kóra jọ sí. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.”—Hébérù 10:24, 25.