Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ogun Náà Ò Dáṣẹ́ Ìwàásù Wa Dúró

Ogun Náà Ò Dáṣẹ́ Ìwàásù Wa Dúró

Ogun Náà Ò Dáṣẹ́ Ìwàásù Wa Dúró

GẸ́GẸ́ BÍ LEODEGARIO BARLAAN ṢE SỌ Ọ́

Ní 1942, nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ilẹ̀ Japan àti ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣì ń bá ìjàkadì wọn nìṣó nítorí ilẹ̀ Philippines tí í ṣe ìlú mi. Mo wà ní abúlé tó ń jẹ́ Tabonan tó wà lórí òkè ńlá, níbi tí àwọn ọmọ ogun adàlúrú tí wọ́n ń bá àwọn ará Japan jà ti fi mí sí ọgbà ẹ̀wọ̀n. Wọ́n nà mí, wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé ńṣe ni mò ń ṣe amí, wọ́n sì tún halẹ̀ mọ́ mi pé àwọn máa pa mí. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí mo ṣe kó sínú wàhálà yìí àti bí mo ṣe yè bọ́.

ÌLÚ San Carlos, Pangasinan, la gbé bí mi ní January 24, 1914. Ní àwọn ọdún 1930, Bàbá rán mi lọ sí ilé ẹ̀kọ́ láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀. Mo máa ń lọ sí Máàsì ní àwọn ọjọ́ Sunday, tí àlùfáà yóò sì máa sọ̀rọ̀ nípa Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù. Fún ìdí yìí, mo fẹ́ láti kà wọ́n.

Lọ́jọ́ kan, mo kó owó tí mo tù jọ láti inú ẹ̀fọ́ tí mo tà mo sì gbọ̀nà ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé láti lọ ra ẹ̀dà kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere náà. Dípò tí wọn ò bá fi fún mi, ìwé pẹlẹbẹ kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní The Way to Heaven, ni wọ́n gbé lé mi lọ́wọ́ tí kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere náà nínú rẹ̀. Èyí já mi kulẹ̀ gbáà. Lẹ́yìn náà ni mo gbéra ó di Manila láti lọ ra àwọn Ìwé Ìhìn Rere wọ̀nyí. Ibẹ̀ ni arákùnrin màmá mi tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ti fún mi ní odindi Bíbélì.

Ní Manila, mo pàdé ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí, tó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń ṣàyọlò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wú mi lórí púpọ̀. Ọ̀dọ̀ wọn sì ni mo ti rí ìdáhùn tó tẹ́ mi lọ́rùn sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Lọ́jọ́ kan, arákùnrin màmá mi yẹn tó ń jẹ́ Ricardo Uson, mú mi lọ sí ìpàdé ní ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Báa ṣe sún mọ́ ibẹ̀ báyìí ni mo bá bẹ́ná lu sìgá. Ìgbà tí arákùnrin màmá mi yìí máa sọ̀rọ̀, ó ní: “Ju sìgá ọwọ́ ẹ nù. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í mu sìgá.” Bí mo ṣe ju sìgá náà nù nìyẹn o tí mo sì ṣíwọ́ sìgá mímu. Mo pàdé Joseph Dos Santos, tó jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka, bẹ́ẹ̀ náà ni mo pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn. Lónìí, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, mo ṣì ń rántí àwọn Kristẹni dáadáa wọ̀nyẹn.

Ìfẹ́ Mi Láti Sin Ọlọ́run

Nígbà tó di October 1937, tí mo ṣì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga ti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ tó wà ní Los Baños, n kì í lọ sí Máàsì mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì àti àwọn ìwé tí arákùnrin màmá mi yẹn fún mi ni mo máa ń kà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá sí ilé ẹ̀kọ́ gíga wa tí mo sì bá ọ̀kan lára wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elvira Alinsod sọ̀rọ̀, àbájáde rẹ̀ ni pé ìfẹ́ tí mo ní láti sin Jèhófà Ọlọ́run túbọ̀ lágbára sí i.

Nígbà tí mo sọ fún àwon olùkọ́ mi pé mo fẹ́ ṣíwọ́ lílọ sí ilé ìwé, wọ́n béèrè lọ́wọ́ mi pé: “Ta ló máa máa gbọ́ bùkátà rẹ?” Mo ṣàlàyé fún wọn pé ó dá mi lójú pé bí mo bá sin Ọlọ́run, yóò ràn mí lọ́wọ́. Lẹ́yìn tí mo ṣíwọ́ lílọ sí ilé ìwé, mo lọ sí ọ́fíìsì Watch Tower Society tí mo sì sọ fún wọn pé mo fẹ́ yọ̀ǹda ara mi, mo ṣàlàyé pé: “Mo ti ka ìwé Loyalty, Riches, àti Where Are the Dead? Nísinsìnyí mo fẹ́ sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí alákòókò kíkún.” Ni wọ́n bá ní kí n lọ sí Ẹkùn Ìpínlẹ̀ Cebu láti lọ bá àwọn arákùnrin mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìwàásù

Ní July 15, 1938, Salvador Liwag wá pàdé mi létíkun nígbà tí mo gúnlẹ̀ sí erékùṣù Cebu. Lọ́jọ́ kejì, mo bẹ̀rẹ̀ sí wàásù láti ilé dé ilé. Kì í ṣe pé ẹnì kan kọ́ mi pé báyìí làá ṣe é. Màá kàn fún onílé ní káàdì ìjẹ́rìí táa ń lò nígbà yẹn lọ́hùn-ún, èyí tó láwọn ìsọfúnni nípa iṣẹ́ wa nínú. Ká sòótọ́, ìwọ̀nba gbólóhùn méjì péré ni mo mọ̀ nínú èdè Cebuano, ìyẹn èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Báyìí sì ni mo ṣe bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi.

Gbàrà táa bá wọ inú ìlú kan tá ò dé rí láti wàásù, àṣà wa ni láti kọ́kọ́ lọ sí ilé ìjọba. Ibẹ̀ ni Arákùnrin Liwag yóò ti wàásù fún olórí ìlú; Arákùnrin Pablo Bautista ní tirẹ̀ yóò wàásù fún ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá; Conrado Daclan yóò sì wàásù fún adájọ́. Èmi ni yóò sì bá alábòójútó ilé ìfìwéránṣẹ́ sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà la óò wá lọ sí ibùdókọ̀, àgọ́ ọlọ́pàá, àwọn ilé ìtajà, àti ilé ẹ̀kọ́. Bákan náà la tún máa ń lọ bá àwọn ènìyàn nínú ilé wọn. A máa ń fi ìwé tí a ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a pe orúkọ rẹ̀ ní Enemies lọ àwọn èèyàn. Bí mo ṣe ń fara wé bí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mi ṣe ń wàásù, bẹ́ẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè Cebuano díẹ̀díẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ìwé sóde. Láàárín oṣù mẹ́ta, a kárí gbogbo ẹkùn ìpínlẹ̀ Cebu tó ní ìlú mẹ́rìnléláàádọ́ta. Ní mo bá béèrè lọ́wọ́ Arákùnrin Liwag pé: “Ṣé mo lè ṣe ìrìbọmi báyìí?”

Ló bá dáhùn ó ní: “Ó ṣì kù díẹ̀, arákùnrin.” La bá tún lọ sí erékùṣù mìíràn tó ń jẹ́ Bohol, níbi tí a ti wàásù fún oṣù kan àtààbọ̀, tí a sì wàásù ní ìlú mẹ́rìndínlógójì. Ni mo bá tún sọ pé mo fẹ́ ṣe ìrìbọmi. Wọ́n sì tún sọ fún mi pé: “Ó ṣì kù díẹ̀, Arákùnrin Barlaan.” Nígbà táa sì wá kárí gbogbo Erékùṣù Bohol àti Camiguin tán, la bá tún lọ sí erékùṣù ńlá ti Mindanao táa sì wàásù ní Ìlú Ńlá Cagayan de Oro.

Lákòókò yìí gan-an ni Virginio Cruz dara pọ̀ mọ́ wa. Olùkọ́ kan ní ilé ẹ̀kọ́ girama ni tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó ti ṣíwọ́ iṣẹ́ olùkọ́ láti lè di aṣáájú ọ̀nà. Bẹ́ẹ̀ la ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìlú mìíràn títí táa fi dé ibi Adágún Lanao. Nígbà táa dé ibẹ̀ ni mo bá tún béèrè pé ṣé mo lè ṣe ìrìbọmi. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, nígbà tó di December 28, 1938, lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́fà tí mo ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà, Arákùnrin Cruz ṣe ìrìbọmi fún mi nínú Adágún Lanao ní ìlú Lumbatan.

A Rí Ìbùkún Gbà Nítorí Pé A Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọ́run

Ìgbà tó yá mo dara pọ̀ mọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà mẹ́ta ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Negros Occidental. Àwọn ni Arákùnrin Fulgencio de Jesus, Arábìnrin Esperanza de Jesus àti Arábìnrin Natividad Santos, táa máa ń pè ní Naty. A jọ wàásù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ní ẹkùn ìpínlẹ̀ yẹn ni. Ó di pé ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà, nítorí pé àwọn sáà mìíràn wà tó jẹ́ pé owó tó máa wà lọ́wọ́ wa kì í tó nǹkan. Lọ́jọ́ kan la fẹ́ ra ẹja láti fi jẹ ìrẹsì wa. Mo rí ọkùnrin kan ní etíkun tí mo sì sọ fún un pé mo fẹ́ ra ẹja díẹ̀, àmọ́ gbogbo ẹja ọ̀gbẹ́ni yìí ló ti kó lọ sọ́jà. Àmọ́, ẹja tí ọkùnrin yìí tọ́jú láti fi gbádùn ẹ̀mí ara rẹ̀ ló wá fún mi. Mo béèrè pé èló ni. Ìgbà tó sì máa dáhùn, ó ní: “Má ṣèyọnu, lọ fìyẹn ṣara rindin.”

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí mo ṣe fẹ́ máa lọ báyìí, ló wá sọ sí mi lọ́kàn pé ẹja kan péré kò lè tó èèyàn mẹ́rin jẹ. Bí mo ṣe ń lọ tí mo dé ibi odò pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ kan báyìí, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí ẹja kan tó wà lórí àpáta, omi ṣì wà lára rẹ̀. Mo ronú pé, ‘Ó ṣeé ṣe kó ti kú.’ Ni mo bá sún mọ́bẹ̀ pé kí n mú un, ó yà mí lẹ́nu láti rí i pé kò tíì kú. Mo yáa kì í mọ́lẹ̀, mo wà á mú pinpin, lọ́wọ́ kan náà ni mo rántí ìlérí tí Jésù ṣe pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:33.

Ogun Níwá, Ogun Lẹ́yìn, A sì Ń Wàásù

Nígbà tí àwùjọ àwa táa jẹ́ aṣáájú ọ̀nà ti pọ̀ dórí mẹ́sàn-án, la bá pín ara wa sí ọ̀nà méjì. Wọ́n yan àwùjọ tí wọ́n pín mi sí láti lọ sí erékùṣù Cebu. December 1941 ni báyìí, eruku Ogun Àgbáyé Kejì ṣì ń kù lálá ní ilẹ̀ Philippines. Nígbà táa wà ní ìlú Tuburan, lóru ọjọ́ kan nígbà táa ń sùn lọ́wọ́ ni ọ̀gá sójà kan lórílẹ̀ èdè Philippine níbẹ̀, wá sí iyàrá wa tó sì sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ dìde, àwọn sójà ń wáa yín o.” Wọ́n fura sí wa pé ńṣe là ń ṣe amí fún ilẹ̀ Japan, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò ní gbogbo òru náà.

Nígbà tó yá, wọ́n fi wá sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà nínú ilé ìjọba. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ogun ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n wà nílùú Cebu sọ pé ká fún àwọn ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan gbogbo àwọn ìwé wa káwọn bàa lè mọ̀ bóyá ilẹ̀ Japan là ń ṣe amí fún. Àìmọye àwọn aráàlú ló wá wò wá lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n fẹ́ wá wo bí àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n jẹ́ amí fáwọn ará Japan ṣe rí. Àwọn kan béèrè ìbéèrè, a sì wàásù fún wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run.

Lẹ́yìn táa ti lo ọjọ́ márùn-ún ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, ni ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá bá gba ìsọfúnni kan lórí wáyà láti orílé iṣẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tó pàṣẹ fún un pé kó tú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó sọ fún wa pé a ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́ nítorí pé ìgbà ogun la wà. A ṣàlàyé fún un pé a ò lè dáwọ́ wíwàásù dúró nítorí pé Ọlọ́run ló pàṣẹ fún wa láti ṣe iṣẹ́ náà. (Ìṣe 5:28, 29) Ni inú bá bí ọ̀gá yìí tó sì sọ fún wa pé: “Bẹ́ẹ bá tún wàásù pẹ́nrẹ́n, ńṣe ni mo máa ní kí wọ́n pa yín.”

Láwọn ọjọ́ bíi mélòó kan tó tẹ̀ lé e, ọ̀gá ọlọ́pàá yìí tún bẹ̀rẹ̀ sí wá wa kiri kó bàa lè tún fàṣẹ ọba mú wa. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ikọ̀ kan tó jẹ́ ti ẹgbẹ́ Ológun Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà dá wa dúró, tí ọ̀gá ọlọ́pàá kan tó ń jẹ́ Soriano sì béèrè lọ́wọ́ Arábìnrin Santos pé: “Ṣé ẹ ò ní dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù yìí dúró ni?”

Ni arábìnrin yìí bá dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni o.”

Ọ̀gá ọlọ́pàá yìí tún béèrè pé: “Ká sọ pé a mú yín lọ síwájú ikọ̀ tó ń yìnbọn pani ńkọ́?”

Arábìnrin wa sì tún fèsì pé: “Ìyẹn ò lè yí ìpinnu wa padà o.”

Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìdáhùn wa yìí, ni wọ́n bá kó wa sínú ọkọ̀ akẹ́rù kan tí wọ́n sì wà wá lọ sí Ìlú Cebu, níbi táa ti fara hàn níwájú Edmund, Ọ̀gá Sójà. Nígbà tí ọ̀gá ọlọ́pàá tó ń jẹ́ Soriano ń fi wá han Edmund, Ọ̀gá Sójà, ó ní: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìwọ̀nyí. Ilẹ̀ Japan ni wọ́n ń ṣamí fún!”

Ni ọ̀gá sójà yìí bá bi í pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àbí kí lo wí? Mo mọ̀ wọ́n dáadáa ní Amẹ́ríkà kẹ̀. Wọn kì í ṣe amí o! Wọn kì í dá sí tọ̀tún, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dá sí tòsì.” Ló bá yíjú sí wa, ó ní: “A ò ní dá yín sílẹ̀ nítorí pé ẹ kì í dá sí tọ̀tún tòsì.” Wọ́n tì wá mọ́ inú iyàrá kan tí wọ́n máa ń kó nǹkan sí, nígbà tó sì yá ni Edmund, Ọ̀gá Sójà, bá tún béèrè lọ́wọ́ wa pé: “Ṣé ẹ ṣì ń bá a lọ tí ẹ ò dá sí tọ̀tún, tí ẹ ò dá sí tòsì ni?”

A tún dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.”

Ni òun náà bá tún wá sọ pé: “A jẹ́ pé a ò ní tú yín sílẹ̀ nìyẹn, nítorí pé báa bá tú yín sílẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ńṣe lẹ tún máa bẹ̀rẹ̀ sí wàásù, àwọn tẹ́ẹ bá sì yí padà náà kò tún ní dá sí tọ̀tún, wọn ò sì ní dá sí tòsì. Bí gbogbo èèyàn bá sì ti wá sọ pé àwọn ò ní dá sí tọ̀tún, àwọn ò sì ní dá sí tòsì, a jẹ́ pé kò ní sí ẹnì kankan tó máa jagun mọ́ nìyẹn.”

A Lómìnira Láti Tún Wàásù

Nígbà tó yá, wọ́n kó wa lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Ìlú Cebu. Bó ṣe wá di April 10, 1942 báyìí, ni àwọn ará Japan bá gbógun ti ìlú náà. Ńṣe ni bọ́ǹbù ń ró gbẹ̀mù, tó ń ró kẹ̀ù ní gbogbo ìlú, tó fi di pé iná bẹ̀rẹ̀ sí jó! Wọ́dà kan rí Arábìnrin Santos, tí iyàrá ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi í sí sún mọ́ ojúde ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ni wọ́dà yìí bá figbe ta, ó ní: “Págà! Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò tíì jáde! Ẹ ṣílẹ̀kùn, kẹ́ẹ sì jẹ́ kí wọ́n jáde!” A dúpẹ́ fún ààbò tí Jèhófà pèsè.

Lọ́gán la forí lé orí òkè láti lọ wá àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa. A rí ọ̀kan ní ìlú Compostela. Òléwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù ni arákùnrin yìí tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí ó ti pinnu láti dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró kó sì ṣí lọ sí Ìlú Cebu láti lọ máa ta ọjà oríṣiríṣi. Àmọ́ ní tiwa, ìpinnu wa ni láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run nìṣó láìka ohun yòówù ó ṣẹlẹ̀ sí.

Àìmọye ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ náà Comfort All That Mourn ló wà lọ́wọ́ wa, a sì ṣiṣẹ́ kára gan-an láti pín ìwé náà fún àwọn ènìyàn. Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n dún kookò mọ́ wa, tí wọ́n sọ fún wa pé bí àwọn ará Japan bá rí wa, pé ńṣe ni wọ́n máa bẹ́ wa lórí. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n dá ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun adàlúrú kan tí kì í fẹ́ rí ọmọ Japan kankan sójú sílẹ̀, tí wọ́n sì mú ẹni tó ti dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró láti lọ ṣòwò ní Ìlú Cebu. Ó bà wá nínú jẹ́ gan-an nígbà táa gbọ́ pé wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ilẹ̀ Japan ló ń ṣamí fún tí wọ́n sì tìtorí èyí pa á.

Wọ́n Ní Amí Ni Wá

Ní gbogbo àkókò yìí, ńṣe là ń wàásù ní àwọn orí òkè. Lọ́jọ́ kan la gbọ́ nípa obìnrin kan tó nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ wa, àmọ́, ọ̀pọ̀ ibùdó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adàlúrú tó ń pa àwọn ará Japan yìí la máa gbà kọjá ká tó lè dé ibi tí obìnrin yìí wà. Nígbà táa dé abúlé Mangabon níbi tí obìnrin yìí ń gbé, ni àwọn ṣọ́jà tí wọ́n pabùdó síbẹ̀ bá rí wa tí wọ́n sì bú mọ́ wa pé: “Kí lẹ wá ṣe níbí?”

Lèmi náà bá dá wọn lóhùn pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, ṣé ẹ fẹ́ gbọ́ ìhìn iṣẹ́ tí a ń fi ẹ̀rọ giramafóònù jẹ́ fún àwọn ènìyàn?” Nígbà tí wọ́n dá wa lóhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, mo gbé àwo tó ní àsọyé The Value of Knowledge nínú sí i. Nígbà tó yá, wọ́n yẹ ara wa wò, wọ́n sì béèrè onírúurú ìbéèrè lọ́wọ́ wa, lẹ́yìn náà ni wọ́n mú wa lọ sí orílé-iṣẹ́ àwọn ọmọ ogun adàlúrú tó wà ní abúlé Tabonan. Ńṣe la bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà pé kí Jèhófà pa wá mọ́ nítorí a ti máa ń gbọ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo èèyàn tí wọ́n bá mú lọ síbẹ̀ ni wọ́n máa ń pa.

Wọ́n tì wá mọ́lé, wọ́n sì tún ṣe wá níṣekúṣe. Èyí ló mú kí ọ̀ràn wa débi ohun tí mo sọ ní ìbẹ̀rẹ̀, tí wọ́n nà mí, tí ọ̀gá ṣọ́jà náà sì nàka sí mi tó sọ pé: “Amí ni ọ́!” Wọ́n fìyà jẹ wá fún sáà díẹ̀ kan, àmọ́ dípò tí wọn ì bá fi pa wá, ńṣe ni wọ́n sọ pé ká lọ fẹ̀wọ̀n jura pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekúdórógbó.

Àbúrò mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Bernabe wà lára àwọn aṣáájú ọ̀nà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ní Tabonan. Láràárọ̀ ni wọ́n á sọ pé kí gbogbo àwa ẹlẹ́wọ̀n kọ orin orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń pè ní, “Kí Ọlọ́run Bù Kún Amẹ́ríkà” àti òmíràn tí wọ́n ń pè ní, “Kí Ọlọ́run Bù Kún Àwọn Ará Philippines.” Dípò táwa táa jẹ́ Ẹlẹ́rìí ì bá fi kọ orin yìí, orin tó ní àkọlé náà, “Ta Ní Ń bẹ Níhà Ọ̀dọ̀ Olúwa?” la kàn ń kọ lọ ràì. Ó tiẹ̀ ní àkókò kan tí ṣọ́jà tó wà pẹ̀lú wa bú mọ́ wa pé: “Ńṣe la máa gbé ẹnikẹ́ni tí kò bá kọ orin ‘Kí Ọlọ́run Bù Kún Amẹ́ríkà’ kọ́ igi bọn-ọ̀n-ní tó wà lọ́hùn-ún yẹn!” Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo dídún tí wọ́n ń dún kookò mọ́ wa yìí, wọn ò pa ẹnì kan nínú wa. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n kó wa lọ sí oríṣiríṣi ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ní parí-parì gbogbo ẹ̀, ìwé àṣẹ tí wọ́n ní kí wọ́n fi dá mi sílẹ̀ tí déètì tí wọ́n kọ sínú rẹ̀ jẹ́ July 1943, dé. Àmọ́, ó kéré, ó pọ̀, mo ti ṣẹ̀wọ̀n fún oṣù mẹ́jọ àti ọjọ́ mẹ́wàá.

Fífi Gbogbo Ìgbésí Ayé Wàásù

Ìfẹ́ wa láti rí àwọn táa ti wàásù fún tẹ́lẹ̀ tí wọ́n sì fìfẹ́ hàn mú wa gòkè lọ sí ìlú Toledo tó jẹ́ ọgọ́ta kìlómítà. A dá ìpàdé tí a ń ṣe déédéé sílẹ̀ níbẹ̀, bọ́jọ́ sì ṣe ń gorí ọjọ́ ni ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn náà ṣe ìrìbọmi. Nígbà tó di ọdún 1945, ogun wá sópin. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bí ọdún mẹ́sàn-án tí mo ti ṣe ìrìbọmi, mo ní àǹfààní láti lọ sí àpéjọpọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́, èyí tí a ṣe ní Pápá Eré Sísá ti Santa Ana ní ìlú Manila. Iye èèyàn tó tó nǹkan bí igba mọ́kànlélógún [4,200] ló tẹ́tí sí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Ayọ̀ Gbogbo Ènìyàn.”

Kó tó di pé ogun bẹ̀rẹ̀, nǹkan bí okòó dín nírínwó [380] àwọn Ẹlẹ́rìí ló wà ní Philippines, àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 1947, iye wọn ti di ẹgbẹ̀rìnlá ó dín ọgọ́rùn-ún [2,700]! Láti ìgbà náà wá ní mo sì ti ń bá a lọ ní gbígbádùn ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àǹfààní nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Láti ọdún 1948 títí di ọdún 1950, mo sìn bí alábòójútó arìnrìn-àjò ní ẹkùn Surigao. Nígbà tó di ọdún 1951, mo gbé Natividad Santos, tó ti wàásù tìgboyà-tìgboyà pẹ̀lú ẹgbẹ́ wa nígbà tí ogun ń gbóná janjan níyàwó. Lẹ́yìn táa ṣe ìgbéyàwó, a ṣe iṣẹ́ arìnrìn-àjò wa jákèjádò Mindanao láti ọdún 1954 títí di 1972.

A di aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní ọdún 1972, ká lè wà nítòsí àwọn òbí wa tí wọ́n ti darúgbó ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ orí àwa méjèèjì ti lé ní ọgọ́rin ọdún báyìí, a ṣì ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nìṣó, àwa méjèèjì sì ti lo àròpọ̀ ọdún tó lé ní ọgọ́fà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Inú wa mà dùn gidigidi o láti rí bí iye àwọn tó ń pòkìkí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní orílẹ̀-èdè Philippines ṣe ti lé ní ẹgbàá márùnlélọ́gọ́ta [130,000]! Ìfẹ́ wa ṣì ni láti máa ran àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti wá mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ìrètí fún gbígbádùn àlàáfíà àti ayọ̀ tòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

Wọ́n fura sí wa pé ńṣe là ń ṣe amí fún ilẹ̀ Japan, wọ́n sì torí bẹ́ẹ̀ fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò ní gbogbo òru náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwa àti àwọn ọ̀rẹ́ wa ní Erékùṣù Bohol lọ́dún 1963. Èmi àti ìyàwó mi la wà ní ibì kẹrin àti ìkarùn-ún bẹ́ẹ bá kà á láti apá ọ̀tún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Èmi àti ìyàwó mi rèé lónìí

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]

Àwòrán apá ẹ̀yìn: Fọ́tò U.S. Signal Corps