Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Títukọ̀ Lọ Dójú Ikú

Títukọ̀ Lọ Dójú Ikú

Títukọ̀ Lọ Dójú Ikú

Látọwọ́ akọ̀ròyìn Jí! ní ilẹ̀ Faransé

Ẹ JẸ́ ká fojú inú wo bí ìran náà ti gbayì tó. Àwọn èrò dúró, wọ́n tẹjú mọ́ bí agánrán ọkọ̀ òkun alájẹ̀ ti ọba ilẹ̀ Faransé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ti ń fi etíkun Mẹditaréníà ní Marseilles sílẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ okun rírẹwà jù lọ tó tíì rìnrìn àjò lórí òkun rí. Wọ́n fi iṣẹ́ ọnà dídíjú àti góòlù tó pọ̀ rẹpẹtẹ tòun ti péálì dárà si lára lápá ẹ̀yìn. Lápá òkè, àwọn aṣọ tí wọ́n fi abẹ́rẹ́ ṣọnà sí lára tún pa kún ẹwà ọlọ́ba rẹ̀ lọ́nà tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀. Bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ ti ń tàn yòò lára ohun àrà tí wọ́n náwó lé kọjá ààlà yìí, pẹ̀lú ìwúrí làwọn kan fi bẹ̀rẹ̀ síí ronú nípa irú ẹni tí Ọba Louis Kẹrìnlá jẹ́, ìyẹn “Ọba Oòrùn.”

Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lo ọkọ̀ okun alájẹ̀ fún ogun jíjà mọ́, síbẹ̀, ńṣe ni Ọba Louis Kẹrìnlá pinnu pé òún á túbọ̀ sọ ọkọ̀ okun tòun di púpọ̀ kí ó di ogójì—ìyẹn ni ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun alájẹ̀ tó tíì pọ̀ jù lọ ní Mẹditaréníà. Àwọn ògbógi fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, ogún á tiẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ̀ jù fún ohun tó nílò. Kí ni ète rẹ̀ fún níní ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀?

Jean-Baptiste Colbert, tó jẹ́ bọ́ba-jíròrò rẹ̀ sọ pé: “Kò sí nǹkan tó lè sọ títóbi ọba kan, tó sì túbọ̀ lè mú un gbayì láàárín àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè tó níní ọkọ̀ òkun.” Ká sòótọ́, ìdí pàtàkì tó mú Louis kó ọkọ̀ òkun jọ bẹ́ẹ̀ ni pé kó lè gbayì. Àmọ́, kí ni iyì yẹn ná an?

Ìwọ wo ìyà tó jẹ ọmọ èèyàn. Nínú ọkọ̀ òkun kan tí kò ju mítà márùndínláàádọ́ta ní gígùn, tí fífẹ̀ rẹ̀ kò sì ju mítà mẹ́sàn-án lọ ní wọ́n kó àwọn atukọ̀ tí wọ́n jẹ́ àádọ́ta lé nírínwó [450] sí. Inú ibi tó há gádígádí yìí ní wọ́n ń gbé tí wọ́n sì ti ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ oṣù láìdáwọ́dúró. Gbogbo ara wọn ti di kìkìdá egbò nítorí atẹ́gùn tó ń fẹ́ wá látinú okun oníyọ̀ náà, bẹ́ẹ̀ sì ni àpá nínà tí wọ́n ń nà wọ́n nígbà gbogbo kún ara wọn yánna-yànna. Ìdajì lára wọn ló máa kú nínú ohun táwọn òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Faransé pè ní “ohun tó bayé àwọn ọkùnrin jẹ́ jù lọ” ní ilẹ̀ Faransé.

Àní sẹ́, ohun táwọn kan fi ń ṣayọ̀ yọ̀ tí wọ́n sì ń ṣògo nínú rẹ̀ ló jẹ́ ọ̀ràn ìbànújẹ́ àti ikú fáwọn mìíràn. Níbo gan lọba yẹn ti rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn atukọ̀ tí wọ́n ń tukọ̀ àwọn ọkọ òkun rẹ̀ tó jẹ́ ogójì?

Rírí Àwọn Atukọ̀

Ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú, àwọn ọkùnrin olómìnira làwọn atukọ̀ ọkọ̀ òkun tàbí galeotti, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń pè wọ́n, iṣẹ́ tó gbayì ni wọ́n sì mọ iṣẹ́ atukọ̀ sí nígbà yẹn. Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, ọ̀rọ̀ ò jẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́. Díẹ̀ lára àwọn atukọ̀ náà, tí wọ́n jẹ́ ará Turkey ni wọ́n rà wá láti Ilẹ̀ Ọba Ottoman. Mùsùlùmí lèyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ nínú wọn jẹ́ ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì. Wọ́n tún máa ń lo àwọ́n tí wọ́n bá kó lójú ogun.

Àwọn òpìtàn ilẹ̀ Faransé sọ pé: “Ó dájú pé lára àwọn ìwà tó kóni nírìíra jù lọ tó sì tún jẹ́ ti òpònú tí wọ́n hù ni mímú agbo òṣìṣẹ́ wọn ‘lágbára’ nípa lílọ kó àwọn jagunjagun Àmẹ́ríńdíà dà sínú ọkọ̀ òkun Ọba Oòrùn náà.” Àṣìṣe ni kíkó tí wọ́n kó àwọn Àmẹ́ríńdíà náà já sí fún wọn o. Lọ́dún 1689, wọ́n dá wọn padà sílé nígbà tí àwọn Àmẹ́ríńdíà halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ Faransé tó kọ́kọ́ tẹ̀dó.

Bó ti wù kó rí, iṣẹ́ ìlépa ipò ọlá tí Louis lọ dáwọ́ lé ń béèrè fún àwọn atukọ̀ púpọ̀ sí i. Colbert bá a rí ojútùú sí i. Ó sọ ohun tí ọba fẹ́ fáwọn adájọ́ pé, “kí wọ́n dẹ́bi fáwọn ọ̀daràn tó pọ̀ jù lọ, àti pé àwọn tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún ni kí wọ́n rán lọ̀ sínú àwọn ọkọ̀ òkun náà kí wọ́n kúkú lọ máa tukọ̀ níbẹ̀.” Kì í ṣe nǹkan tuntun láti máa lo àwọn ọ̀daràn ní irú ọ̀nà yìí. Wọ́n ti lo àwọn ẹlẹ́wọ̀n rí gẹ́gẹ́ bí ẹrú nínú ọkọ̀ ojú omi, lásìkò táwọn àti Ítálì jọ jagun ní nǹkan bí ọ̀rúndún méjì ṣáájú ìgbà yẹn. Àmọ́ o, kò tíì sí iye tí wọ́n rán lọ sínú ọkọ̀ òkun tí ó tó ti ìgbà ìṣàkóso Louis Kẹrìnlá àti Louis Kẹẹ̀ẹ́dógún, ìyẹn ọmọ tí ọmọ ọmọ rẹ̀ bí. Láàárín ọdún 1680 sí 1748, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta [60,000] ni wọ́n dájọ́ fún láti lọ tukọ̀. Àwọn wo ló di ẹrú nínú ọkọ̀ òkun yìí?

Àwọn Wo Ni Wọ́n Lọ Ṣà?

Nǹkan bí ìdajì lára àwọn tí wọ́n kó lọ sínú àwọn ọkọ̀ okun náà ló jẹ́ pé ọ̀ràn tí wọ́n dá kò tó nǹkan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn tó pààyàn dórí àwọn olè kéékèèké. Ọ̀nà yìí kan náà ni wọ́n fi ń fìyà jẹ àwọn tó ṣe fàyàwọ́, tó jẹ́ pé nígbà míì, àwọn ló máa ń pọ̀ jù nínú àwọn tó ń ṣe atukọ̀.

Láfikún sí i, wọ́n tún máa ń fipá mú àwọn èèyàn tí kò fi bẹ́ẹ̀ bẹ́gbẹ́ mu láti lọ ṣiṣẹ́ nínú àwọn ọkọ̀ òkun ọ̀hún. Lọ́dún 1666, ọ̀gá tó ń bójú tó wọn ní Marseilles kọ̀wé pé: “Màá fẹ́ kí wọ́n pa á láṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn tí wọ́n jẹ́ òkú ọ̀lẹ, àwọn arìnrìn-àjò onísìn, . . . àwọn Alárìnkiri àtàwọn tí kò níbi tí wọ́n ń forí lé dà sínú àwọn ọkọ̀ òkun náà. . . . Ìyẹn á jẹ́ káwọn tó ń dá òórùn palẹ̀ dá nílẹ̀.” Nípa bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú òfin awúrúju tí wọ́n fi bojú pé ìtọ́jú ìlú làwọn ń ṣe, ni wọ́n bá kó àwọn Alárìnkiri àtàwọn onírìn-àrè dà mọ́ wọn. Àní lọ́dún 1660, wọ́n tiẹ̀ tún fipá kó àwọn arìnrìn-àjò onísìn ará Poland kan tó ń bẹ ibi mímọ́ kan wò ní ilẹ̀ Faransé mọ́ àwọn tí wọ́n ń ṣà kiri!

Ibòmíràn tí wọ́n tún ti ń rí òṣìṣẹ́ ni látinú àwọn ọmọ ogun tó sá, tó jẹ́ pé lẹ́yìn tọ́wọ́ wọn bá tẹ̀ wọ́n, wọ́n á dájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére fún wọn nínú ọkọ̀ òkun. Gígé ni wọ́n máa ń gé imú àti etí àwọn ìsáǹsá yìí, tí wọ́n á fi nǹkan dá àpá sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn, tí wọ́n á sì fá wọn lórí kodoro. Lásìkò tí Ọba Louis Kẹrìnlá ń ja onírúurú ogun lọ́dún 1685 sí 1715, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún [17,000] àwọn ìsáǹsá ní wọ́n kó lọ sínú àwọn ọkọ̀ òkun náà. Kí lohun tó ń dúró de àwọn ọkùnrin yìí níbẹ̀?

Ohun Tójú Wọn Rí

Ká sòótọ́, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dìgbà táwọn atukọ̀ yìí bá dé ojú okun kí ìyà wọn tó bẹ̀rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n á wà nínú àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n kan fún bí oṣù mẹ́fà, kó to di pé wọ́n á fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n mọ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ẹlẹ́wọ̀n míì, tí wọ́n á sì wọ́ wọ́n tuuru lọ sí Marseilles. Fún àwọn kan, irú bí àwọn tí wọ́n kó wá láti Brittany tàbí Paris, ìrìn tipátipá ẹlẹ́gbẹ̀rin kìlómítà tí ń kó jìnnìjìnnì báni yìí máa ń gbà ju oṣù kan lọ. Ẹnì kàn tó gbé ayé nígbà yẹn sọ pé ìyẹn jẹ́ “ìyà tó burú jù lọ tí wọ́n fi ń jẹ àwọn ẹlẹ́wọ̀n.” Ojú ọ̀nà ni púpọ̀ wọn kú sí.

Àmọ́ o, kì í kàn ṣe jíjìnnà tí ìrìn-àjò náà jìnnà tàbí oúnjẹ tí ò tó nǹkan tí wọ́n ń fún wọn jẹ lójúmọ́ ló ń pa wọn. Ìṣekúṣe làwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń ṣe àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà. Ìnàkunà àti àìsí oúnjẹ pẹ̀lú oorun sì bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ̀mí wọn. Síwájú sí i, àwọn èèyàn tó wà lójú ọ̀nà ilẹ̀ Faransé táwọn ọkùnrin náà máa ń gbà kọjá ní gbogbo ìgbà kì í fi bẹ́ẹ̀ fojú àánú hàn sí wọn. Wọn tiẹ̀ sọ pé nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà tọrọ omi lọ́wọ́ àwọn obìnrin tó wà ládùúgbò náà, ohun tí wọ́n fi fún un lésì ni pé: “Rìn ńlẹ̀, rìn ńlẹ̀! Wàá mu omi á sú ẹ níbi tí o ń lọ!”

Ìdajì Wọn Ni Kò Yè É

Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n rán lọ sẹ́wọ̀n níbẹ̀ ni kò rí òkun rí láyé wọn, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kí wọ́n rí ọkọ̀ òkun rí. Nítorí náà, ìjayà ńlá gbáà ni bíbá tí wọ́n bá ara wọn létíkun Marseilles jẹ́ fún wọn. Bí ẹran ni wọ́n ṣe máa ń kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà pa pọ̀ sínú ọkọ̀ òkun ṣíṣófo kan tí wọ́n á sì wá yẹ̀ wọ́n wò, kò yàtọ̀ sí bí ọ̀kan nínú wọn ṣe kọ̀wé pé, bíi “màlúù tí wọ́n lọ rà lọ́jà” làwọ́n rí. Nínú ètò ọkọ̀ òkun náà, wọ́n á gba kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni nípa wọn sílẹ̀, wọ́n á wá fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní nọ́ńbà èyí tí wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí lò fún wọ́n dípò orúkọ wọn. Òpìtàn kan sọ pé: “Kò sí àní-àní pé dídi apá kan àwùjọ àwọn atukọ̀ ọkọ̀ òkun náà ń fa ìpòrúurùu ọkàn tó ga, wàhálà tó sì ń kó bá ìrònú òun ìhùwà àti ara kì í ṣe kékeré.” Àmọ́, kékeré lèyí jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìyà tó ṣì ń dúró dè wọ́n o.

Nínú àyè kékeré kan tí kò ju mítà méjì ó lé díẹ̀ ní gígùn àti mítà kan ó lé díẹ̀ ní fífẹ̀, ni àwọn ọkùnrin márùn-ún ń gbé tí wọ́n sì ń tukọ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù láìdáwọ́dúró tí ẹsẹ̀ wọn sì wà ní dídè mọ́ àwọn àga gbọọrọ. Àyè tí atukọ̀ kọ̀ọ̀kan ní kò ju sẹ̀ǹtímítà márùndínláàádọ́ta lọ fún jíjókòó. Àyè ọ̀hún há débi pé, àwọn ọkùnrin náà kì í lè ṣẹ́ apá wọn po rárá nígbà tí wọ́n bá ń fa àjẹ̀ náà mọ́ra, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ gún tó mítà méjìlá tó sì wúwo níwọ̀n àádóje kìlógíráàmù [130]. Fífi àjẹ̀ wa ọkọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí láìdáwọ́dúró jẹ́ iṣẹ́ tó ṣòro gan an tó máa ń já iṣan àwọn atukọ̀ náà, tó sì ń tán wọn lókun àti agbára. Òpìtàn kan sọ pé: “Ohun téèyàn lè fi wé ni iṣẹ́ tó lè koko jù lọ tí wọ́n ń ṣe ní ilẹ̀ olóoru.”

Àwọn ọkọ̀ òkun alájẹ̀ kì í ga sókè, nǹkan táwọn atukọ̀ náà sì fi kọjá omi sókè kò ju mítà kan lọ. Fún ìdí yẹn, ìgbà gbogbo ni ara wọn máa ń rẹ, inú omi sì ni ẹsẹ̀ wọn máa ń wà bí wọ́n ti ń tukọ̀ lọ, tí atẹ́gùn oníyọ̀ sì ti sọ ẹran ara wọn di elégbò. Oúnjẹ tí wọ́n ń fún wọ́n lójúmọ́ kò tó nǹkan. Òpìtàn kan sọ pé: “Kò sóhun táwọn ẹlẹ́wọ̀n yìí kì í ṣe láti rí i pé ẹ̀mí àwọn kò bọ́.” Ọ̀rọ̀ pé wọ́n ń ráyè sá lọ kò ṣẹlẹ̀. Owó tí wọ́n ń san fún mímú àwọn tó bá sá lọ túbọ̀ sún àwọn mẹ̀kúnnù àdúgbò náà láti dara pọ̀ nínú ṣíṣọdẹ èyíkéyìí nínú wọn tó bá gbìyànjú láti sá lọ. Kìkì ìkan nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló máa ń ṣeé ṣe fún.

Wọ́n kì í fi bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé ẹjọ́ ẹ̀wọ̀n tí wọ́n bá dá. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, atukọ̀ kan tí wọ́n dá ẹ̀wọ̀n ọdún díẹ̀ fún ṣì lè wà níbi tó tí ń tukọ̀ lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lẹ́yìn ìgbà yẹn. Nǹkan bí ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn ọkùnrin náà ló máa ń kú láàárín ọdún mẹ́ta àkọ́kọ́. Táa bá kó gbogbo wọn pọ̀, ìdajì àwọn atukọ̀ náà ni kì í yè é. Iye àwọn tó ń kú lára àwọn tí ń tukọ̀ náà kò yàtọ̀ sí iye àwọn tí kò tukọ̀ mọ́ tí ń kú. Láàárín ìgbà òtútù ọdún 1709 sí 1710, ìdá kan nínú mẹ́ta wọn ló kú nítorí àìsí oúnjẹ àti òtútù tó légbá kan. Ohun tó bani nínú jẹ́ ni pé, nítorí ìsìn táwọn kan ń ṣe ni wọ́n ṣe bá ara wọn nídìí àwọn ọkọ̀ òkun náà.

Wọ́n Dá Wọn Lẹ́bi Nítorí Ìgbàgbọ́ Wọn

Ní ọdún 1685, Ọba Louis Kẹrìnlá fagi lé Òfin Nantes, èyí ló mú kí wọ́n fòfin de ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì ní ilẹ̀ Faransé. a Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ àwọn onísìn Pùròtẹ́sítáńtì ni wọ́n dájọ́ fún pé kó lọ sẹ́wọ̀n nínú ọkọ̀ òkun nítorí kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti di ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tàbí nítorí pé wọ́n gbìyànjú láti sa fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀. Wọ́n ti gbìyànjú lílo irú ọ̀nà yìí láti fìyà jẹ “àwọn aládàámọ̀” lọ́dún 1545, ìyẹn nígbà tí wọ́n rán Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo b tó jẹ́ ẹgbẹ̀ta lọ sínú ọkọ̀ òkun lórí àṣẹ tí Ọba Francis Kìíní pa. Lábẹ́ ìṣàkóso Louis Kẹrìnlá, tí wọ́n ń pè ní ọba tó tẹ́wọ́ gba ìsìn Kristẹni gan an, inúnibíni yìí tún wá légbá kan sí i.

Kí nìdí tí wọ́n fi ń kó àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì lọ sínú ọkọ̀ òkun alájẹ̀? Ẹnì kan tó jẹ́ agbèfọ́ba sọ ìdí: “Kò tún sí ọ̀nà míì tí wọ́n lè fi yí àwọn aládàámọ̀ náà lọ́kàn padà sí ẹ̀sìn Kátólíìkì ju kí wọ́n fipá mú wọn lọ.” Òpìtàn kan fi kún un pé: “Ohun tó wà lọ́kàn ọba náà ni pé táwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n dẹ́bi fún yẹn bá ti lè fojú gán-án-ní òkun, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ló máa pa ìsìn tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ nǹkan rúbọ fún tì.” Àmọ́ o, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ló kọ̀ láti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn nítorí àtigba ìdásílẹ̀. Fún ìdí yẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n má ń nà wọ́n ní ìnà ìkà ní gbangba ìta, àwọn àlùfáà Kátólíìkì tó wà nídìí ọkọ̀ òkun náà ló sì máa ń súnná sí èyí. Àwọn kan lára wọn kú; àwọn mìíràn sì ń gbé àpá náà kiri fún ìyókù ìgbésí ayé wọn.

Láìka ìwà ìkà rírorò yìí sí, àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì kò dáwọ́ ṣíṣàjọpín ìgbàgbọ́ wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn dúró. Ohun tó jẹ́ àbájáde èyí ni pé, àwọn kan di Pùròtẹ́sítáǹtì, títí kan àlùfáà Kátólíìkì kan pàápàá ó kéré tán. Wọ́n kó àwọn tí wọ́n kà sí eléwu jù lọ kúrò nínú ọkọ̀ ojú omi náà, wọ́n sì sọ wọ́n sínú àjàalẹ̀, ìyẹn àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé. Síbẹ̀síbẹ̀, eléyìí kò dí àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tí ń tukọ̀ òkun alájẹ̀ yìí lọ́wọ́ láti ran ara wọn lọ́wọ́, débi tí wọ́n tún ṣètò kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà fáwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí kò mọ̀wé kà.

Àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà kò gbàgbé ìdí tí wọ́n fi ń ṣenúnibíni sí wọn. Pierre Serres tó jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì kọ̀wé pé: “Bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ mí tó, bẹ́ẹ̀ ni mo túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tí mo ń torí ẹ̀ jìyà tó.” Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló jẹ́ ìyàlẹ́nu fún láti gbọ́ nípa inúnibíni tí ilẹ̀ Faransé ń ṣe nítorí ìsìn. Lọ́dún 1713, Ọbabìnrin Anne ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣàṣeyọrí nínú jíjà fún ìdásílẹ̀ púpọ̀ lára àwọn tí wọ́n ti dẹ́bi fún. Ó wá yani lẹ́nu pé, lílé ni wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n ti kọ́kọ́ fòfin dè pé wọn ò gbọ́dọ̀ fi ilẹ̀ Faransé sílẹ̀.

Òpin Àwọn Ọkọ̀ Òkun Náà

Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, lílo àwọn ọkọ̀ òkun alájẹ̀ di ohun ìgbàgbé, èyí jẹ́ nítorí ìtẹ̀síwájú tó dé bá ọkọ̀ òkun àti ọkọ̀ ogun orí omi, àti nítorí àìrí owó ná sí i mọ́. Ìṣòro àìsí owó lọ́wọ́ Ọba Louis Kẹrìnlá yìí mú un dín iye àwọn ọkọ̀ òkun náà kù. Nígbà tó fi máa di 1720, ọkọ̀ ojú omi mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré ló kù, iṣẹ́ wọn kò sì fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan mọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, Marseilles láwọn atukọ̀ yìí ń fìdí kalẹ̀ sí, wọ́n sì di apá kan àwọn oníṣẹ́ òwò ìlú náà, wọ́n ń ṣiṣẹ́ láwọn iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe ọṣẹ nítòsí ibẹ̀ tàbí kí wọ́n máa ta àwọn aṣọ tí wọ́n bá hun. Níkẹyìn, lọ́dún 1748, wọ́n gbé òfin kan jáde tó jẹ́ pé òun ló kúkú wá rẹ́yìn àwọn ọkọ̀ òkun náà.

Àwọn ará ilẹ̀ Faransé kò lè gbàgbé ọ̀rọ̀ ọkọ̀ òkun náà láé. Bí wàhálà kan bá kojú wọn pẹ́nrẹ́n, ohun táwọn èèyàn ilẹ̀ Faransé sábà máa ń sọ ni pé: “Quelle galère!” tàbí lédè mìíràn, “Ọkọ̀ òkun mà rèé o!” Ọ̀pọ̀ ohun táa mọ̀ nípa bí ìgbésí ayé ṣe rí nínú àwọn ọkọ̀ òkun ọ̀hún la rí látinú àkọsílẹ̀ àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì nípa ohun tójú wọn rí nígbà tí wọ́n jẹ́ atukọ̀ nínú àwọn ọkọ̀ òkun náà. Láìka kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ìsìn amúni-lọ́kàn-gbọgbẹ́ yìí sí, ó ṣeé ṣe fún wọn láti dá àjọ kan tó ní àjọṣe tọ̀túntòsì sílẹ̀ tí ìwà rere sì tì lẹ́yìn. Ìfaradà wọn àti ìrètí tí wọ́n ní ló jẹ́ kí wọ́n lè là á já, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì fìgbà kan ronú láti juwọ́ sílẹ̀.

Ó yẹ fún àfiyèsí pé, kódà nígbà táwọn òpìtàn ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀tanú ẹ̀sìn tó ṣẹlẹ̀ lásìkò yẹn, wọ́n sọ pé ó ya àwọn lẹ́nu pé àwọn adájọ́ pẹ̀lú ṣe tán láti “fìyà jẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ àti olódodo lọ́nà kan náà tí wọ́n máa gbà fìyà jẹ àwọn ọ̀daràn tó burú jáì.”

Láìsí àní-àní, bí a ti ń rántí àwọn ẹrú tó bára wọn nínú àwọn ọkọ̀ òkun alájẹ̀ yìí, ó jẹ́ ẹ̀rí alágbára nípa ìwà àìsí ìdájọ́ òdodo tó burú jáì táwọn ẹ̀dá ènìyàn ti hù sáwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn. Dájúdájú, “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Inú wa dùn pé, àkókò náà ti dé tán, nígbà tí Alákòóso tí Ọlọ́run ti yàn náà, Jésù Kristi, “yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́.”—Sáàmù 72:12-14.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ilé Ìṣọ́ August 15, 1998, ojú ìwé 25-29.

b Wo Ile-Iṣọ Naa February 1, 1982, ojú ìwé 27.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Inú ipò tí ń ṣeni láàánú ni wọ́n ti ń tukọ̀

[Credit Line]

© Musée de la Marine, Paris

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ohun tí wọ́n fi èdè Faransé kọ sókè àwòrán yìí kà pé: “Ọ̀nà tó dájú tó sì tọ́ láti yí àwọn aládàámọ̀ padà sí ìgbàgbọ́ Kátólíìkì.” Ọdún 1686 ni déètì tí wọ́n kọ sára àwòrán náà

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Ojú ìwé 2, 12, àti 15: © Cliché Bibliothèque nationale de France, Paris