Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Àwọn Ògo Wẹẹrẹ Àtàwọn Ajá

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tó wà nínú ìwé ìròyìn El Universal ti Ìlú Mẹ́síkò ṣe sọ, àwọn ògo wẹẹrẹ tí wọ́n bá fi sílẹ̀ láìsí àbójútó níbi tájá wà, wà nínú ewu kí ajá bù wọ́n jẹ́. Ìròyìn náà sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn ọmọdé ló máa ń fa ìgbéjàkò náà ní gbogbo ìgbà, tí ajá náà yóò sì jà láti gbèjà ara rẹ̀.” Láàárín ọdún márùn-ún tó kọjá, ilé ìwòsàn kan ní Mẹ́síkò tọ́jú àwọn ọmọdé mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n lé nírínwó [426] tí ajá bù jẹ. Ìdá méjìlá nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọdé tí ajá bù jẹ yìí ló jẹ́ pé àpá tí ajá náà dá sí wọn lára kò lè parẹ́ láéláé. Ìròyìn náà wá rọ àwọn òbí láti jẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ àwọn ohun pàtàkì tí ajá kórìíra, ìyẹn ni pé: Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ohun ìṣeré ajá, má ṣe fọwọ́ kan ilé wọn tàbí kóo máa fi ohun tí wọ́n fi ń jẹun ṣeré; má ṣe sún mọ́ ajá nígbà tó bá ń jẹun tàbí tó bá ń sùn; má fà á nírù tàbí gùn ún bí ẹṣin.

Ìṣòro Gbígbẹ̀mí Ara Ẹni ní Japan

Ọ̀pọ̀ àwọn ará Japan ló ń sọ pé, “ó dà bí ẹni pé ilẹ̀ Japan ò rọ́wọ́ mú mọ́” kò sì tún “mọ ohun tó ń ṣe mọ́,” bóyá ètò ọrọ̀ ajé tí kò rí bó ṣe yẹ kó rí ló fà á. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ti mú káwọn èèyàn máa “gbẹ̀mí ara wọn lọ ràì láti nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.” Ìwé ìròyìn náà fi kún un pé: “Ní àwùjọ kan tí nǹkan tètè máa ń ti èèyàn lójú, àìníṣẹ́lọ́wọ́ tó gogò ti sọ ọ̀pọ̀ ọkùnrin dẹni tó soríkọ́, wọ́n ti joyè alárìnká, tí wọ́n sì máa ń kúrò nílé látàárọ̀ dalẹ̀ káwọn èèyàn lè rò pé wọ́n níṣẹ́ gidi kan lọ́wọ́.” Nígbà táwọn kan bá ṣàníyàn títí tí ìtìjú sì mú wọn, wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé ikú yá ju ẹ̀sín lọ, káwọn kúkú gbẹ̀mí ara àwọn. Ọ̀mọ̀wé Yukio Saito sọ pé: “Àwọn èèyàn ò nírètí. Wọn ò ní nǹkankan tí wọ́n ń lépa pé kọ́wọ́ àwọn tẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, bí ìgbà tí gbogbo nǹkan sì túbọ̀ ń dojú rú lọ̀rọ̀ jọ lójú wọn. . . . Gbígbẹ̀mí ara ẹni ti wá ń gbèèràn bíi pápá tí ń jó nígbà ọyẹ́.” Kíkó sẹ́nu ọkọ̀ ojú irin ti wá wọ́pọ̀ bí eléèmọ̀. Ọ̀nà àtikápá ìṣòro yìí ló mú kí ilé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin kan lọ fi ọ̀dà aláwọ̀ ewé kun àwọn ojú irin tí ọkọ̀ rélùwéè máa ń gbà kọjá, láti lè mú kí ẹni tó fẹ́ gbẹ̀mí ara rẹ̀ náà yí èrò rẹ̀ padà, bákan náà ni ilé iṣẹ́ yìí tún ri àwọn dígí sí ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ọ̀nà ojú irin tí ọkọ̀ rélùwéè máa ń gbà láti lè mú kí ẹnì kan tó fẹ́ fò jánà láti pa ara rẹ̀ dúró díẹ̀ kí ó sì tún orí rẹ̀ rò. Ilé iṣẹ́ yìí tún ti gé gbogbo ẹ̀ka igi àti ewé tó wà lẹ́bàá ọ̀nà ọkọ̀ rélùwéè kẹ́ni tó fẹ́ gbẹ̀mí ara rẹ̀ náà máa baà ríbi sá pa mọ́ sí. Àmọ́ o, àwọn ògbógí ti sọ pé láìjẹ́ pé ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè náà bá kọ́fẹ padà, pàbó ni gbogbo akitiyan yìí máa já sí.

Èdè Àìyedè àti Ìgbéyàwó

Ìwé ìròyìn Time sọ pé ìwádìí tuntun kan tí Andrew Christensen ti Yunifásítì California tó wà ní Los Angeles ṣe fi hàn pé “àwọn tọkọtaya tí wọn kò bá le koko mọ́ra wọn jù tó sì jẹ́ pé ìtùnbí-ìnùbí ni wọ́n fi ń yanjú èdè àìyedè tí wọ́n bá ní, ni ìgbéyàwó wọn máa ń kẹ́sẹ járí jù lọ.” Nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ni iyàn jíjà túbọ̀ máa ń mú kí èdè àìyedè túbọ̀ le sí i.

Máa Sùn Dáadáa

Ọ̀gbẹ́ni Stanley Coren, tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú ní Yunifásítì British Columbia sọ pé: “Àwùjọ tiwa yìí jẹ́ ọ̀kan ti a fi oorun dù lọ́nà tó léwu.” Àìsun oorun tó bó ṣe yẹ wà lára ohun tó fa jàǹbá runlérùnnà tó ṣẹlẹ̀ ní Erékùṣù Three Mile, òun náà ló sì tún fa ti ọkọ̀ ojú omi agbépo Exxon Valdez, tí epo tó gbé tú dànù. Ìwé ìròyìn Maclean’s ti Kánádà sọ pé, iye jàǹbá ọkọ̀ tí títòògbé ń fà ní Àríwá Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lọ́dọọdún lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000]. Ògbógí kan nípa oorun sísùn ní Yunifásítì Stanford, Dókítà William Dement wá kìlọ̀ pé: “Àwọn èèyàn ò mọ̀ ní ti gidi bó ṣe yẹ kí oorun tí wọ́n máa sùn pọ̀ tó.” Béèyàn bá fẹ́ máa sùn dáadáa, àwọn olùṣèwádìí dámọ̀ràn pé: Máà jẹ́ kí jíjẹ oúnjẹ alẹ́ rẹ̀ dín ní wákàtí mẹ́ta sígbà tóo máa lọ sùn. Máa sùn kóo sì máa jí ní àkókò kan náà lójoojúmọ́. Má ṣe gbé tẹlifíṣọ̀n tàbí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà sínú iyàrá tí o ń sùn. Má ṣe mu kaféènì, ọtí líle, tàbí tábà. Wọ ìbọ̀sẹ̀ kí àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ lè móoru nígbà tóo bá sùn. Fi omi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ ṣanra kóo tó lọ sùn. Máa ṣe eré ìmárale lójoojúmọ́—kì í ṣe nígbà tóo bá ti fẹ́ sùn ṣá o. Ìwé ìròyìn Maclean wá sọ ní paríparì rẹ̀ pé: “Bí o kò bá rí oorun sùn, dìde kóo wá nǹkankan ṣe. Bóo bá rí i pé ó ti wá rẹ̀ ọ́ dáadáa, ìgbà náà ni kóo padà lọ sùn, kóo sì dìde ní àkókò tóo máa ń jí tẹ́lẹ̀.”

Ìmọ́tótó Ilé Ìdáná Ń Borí Àrùn

Ìwé ìròyìn The Vancouver Sun ti Kánádà sọ pé, “omi ìṣídọ̀tí ni ọ̀gbàgbà tó lè gbà ọ́” lọ́wọ́ àwọn kòkòrò àrùn tí wọ́n máa ń fara pamọ́ sí ilé ìdáná táa ń lò déédéé. Ìwé ìròyìn ọ̀hún fúnni láwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí: Po ọgbọ̀n mìlílítà omi ìṣídọ̀tí mọ́ lítà mẹ́rin omi lílọ́wọ́ọ́rọ́, kì í ṣe gbígbóná o. Bóo bá lo omi gbígbóná, ńṣe ló máa mú kí omi ìṣídọ̀tí náà bá ooru jáde. Ki aṣọ tó mọ́ tónítóní sínú omi tí o ti pò yìí kí o sì fi nu orí ibi ti o ti ń dáná. Jẹ́ kí atẹ́gùn fẹ́ sí ilé ìdáná náà kó bàa lè gbẹ. Bóo bá jẹ́ kí atẹ́gùn fẹ́ sí omi ìṣídọ̀tí tóo fi nu ilé ìdáná rẹ yìí, yóò jẹ́ káwọn kòkòrò púpọ̀ sí i kú. Fi omi gbígbóná tóo ti po ọṣẹ mọ́ fọ àwọn àwo rẹ, lẹ́yìn náà kóo rẹ wọ́n sínú omi tóo ti pò pẹ̀lú omi ìṣídọ̀tí láti lè pa àwọn kòkòrò wọn. Kò sí ràlẹ̀rálẹ̀ kẹ́míkà kankan tó máa ṣẹ́ kù lára àwọn àwo yẹn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gbẹ. Máa fọ kànrìnkàn, aṣọ tóo fi ń nu àwo, àtàwọn búrọ́ọ̀ṣì tóo fi ń fọ nǹkan lójoojúmọ́, sì fi àpòpọ̀ omi ìṣídọ̀tí àti omi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́ ṣàn wọ́n. Máa fọ ọwọ́ rẹ dáadáa, pàápàá abẹ́ àwọn èékánná kí o lè dín ewu fífi ọwọ́ ara rẹ kó àìsàn sínú oúnjẹ rẹ kù.

Àwọn Èdè Táa Ń Wu Léwu

Ní gbogbo Amẹ́ríkà, Mẹ́síkò nìkan làwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ ti ń sọ èdè àbínibí. Ní àfikún sí i, báa bá ti mú Íńdíà àti China, Mẹ́síkò ló ṣe ipò kẹta báa bá ka àwọn èdè àbínibí táwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ ṣì ń sọ lágbàáyé. Ìwé ìròyìn The News ti ìlú Mẹ́síkò sọ pé, púpọ̀ lára àwọn èdè wọ̀nyí ló ti ń parẹ́. Rafael Tovar y de Teresa tó jẹ́ olùdarí Ìgbìmọ̀ Tó Wà fún Àṣà àti Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé ṣàlàyé pé, nínú èdè ìbílẹ̀ tó fi díẹ̀ dín sí ọgọ́rùn-ún táwọn èèyàn ń sọ ní Mẹ́síkò níparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ìwọ̀nba méjìlélọ́gọ́ta péré ló ṣẹ́ kù báyìí. Mẹ́rìndínlógún lára ìwọ̀nba tó ṣẹ́ kù yìí ló sì jẹ́ pé iye àwọn èèyàn tó ń sọ wọ́n kò tó ẹgbẹ̀rún. Ohun kan tó ń dáyà foni ni pé, bí àwọn èdè yìí bá lọ láú, kò sẹ́ni tó máa mọ orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn igi lédè ìbílẹ̀ mọ́, yóò sì wá di pé kò sẹ́ni tó máa mọ bí wọ́n ṣe ń fi àwọn igi wọ̀nyí wo àìsàn.

Bóo Bá Fẹ́ Lúwẹ̀ẹ́, Má Mutí O

Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Klaus Wilkens tó jẹ́ ààrẹ Ẹgbẹ́ Agbẹ̀mílà ti Jámánì ṣe sọ, ní ọdún 1998, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó kú sómi ní Jámánì ló jẹ́ pé “ńṣe ni wọ́n mu ọtí líle kọjá ààlà.” Ìwé ìròyìn nípa ìlera tó ń jẹ́ Apotheken Umschau náà tún sọ pé ní ọdún 1998, irínwó ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [477] jàǹbá àwọn tó kú sómi ló ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Jámánì. Mímu ọtí líle àti lílọ lúwẹ̀ẹ́ léwu, nítorí pé ọtí líle ò ní jẹ́ kéèyàn lè ṣàkóso ara rẹ̀ àtàwọn iṣu ẹran ara dáadáa, bákan náà láá jẹ́ kéèyàn máa ronú pé òun lè ṣe àwọn nǹkan tágbára rẹ̀ ò ká. Èyí ló mú kí ẹgbẹ́ agbẹ̀mílà ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: ‘Bóo bá fẹ́ lúwẹ̀ẹ́, má mutí o!’

Pa Kòkòrò Kóo Gbowó

Ìwé ìròyìn The Times of India sọ pé ẹ̀ka tó ń bójú tó igbó ìjọba ní ìpínlẹ̀ Uttar Pradesh lórílẹ̀-èdè Íńdíà, ti ké gbàjarè sáwọn èèyàn láti gbógun ti àwọn kòkòrò hoplo oníyẹ̀ẹ́ tí wọn ò gùn ju sẹ̀ǹtímítà méjì àtààbọ̀ lọ, tí wọ́n fẹ́ ba igbó kan tí igi sal tó wà nínú rẹ̀ tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n ó lé ẹgbàárùn-ún [650,000] jẹ́. Pẹ̀lú bí àwọn kòkòrò yìí ṣe pọ̀ sí i lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àfàìmọ̀ kí wọ́n má run ẹ̀yà igi yìí o. Ńṣe làwọn kòkòrò yìí máa ń lu ihò fóó-fòò-fó sára èèpo àti ìtì igi yìí, tí èyí yóò sì mú kí igi náà gbẹ, kó sì kú. “Pańpẹ́ onígi” ni ẹ̀ka tó ń bójú tó igbó ìjọba náà ń lò báyìí láti mú àwọn kòkòrò wọ̀nyí. Wọ́n máa ń da èèpo ẹ̀yìn ọ̀dọ́ igi sal yìí káàkiri ibi tí àwọn kòkòrò náà bá wà. Omi tó ń sun jáde lára àwọn èèpo igi yìí máa ń fa àwọn kòkòrò náà mọ́ra ó sì máa ń pa wọ́n bí ọtí, èyí á wá jẹ́ kó rọrùn láti mú wọn. Wọ́n ti gba àwọn ọmọdékùnrin láti ṣe iṣẹ́ táa ń wí yìí, bí ẹnì kan bá sì ti pa kòkòrò kan, wọn yóò san paisa márùndínláàádọ́rin (nǹkan bíi sẹ́ǹtì méjì) fún un.

Ìṣòro Tó Ń Bá Àwọn Tó Ti Fẹ̀yìn Tì Lẹ́nu Iṣẹ́ Fínra

Gbígbà láti tètè fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ lè ní àwọn àǹfààní kan, àmọ́ ó tún lè ṣe ìpalára ńlá fún bí o ṣe ń hùwà. Ìwé ìròyìn Diário de Pernambuco ti Brazil sọ pé, àwọn tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìjọba tẹ́lẹ̀ máa ń ṣàròyé pé àwọn ìṣòro bí ‘àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ìkanra, àìláàbò, àti pípàdánù àwọn ànímọ́ wọn máa ń bá àwọn fínra títí kan ìsoríkọ́, tó sì máa wá dà bí ẹni pé ayé àwọn ti rún jégé.’ Gẹ́gẹ́ bí Guido Schachnik tó jẹ́ onímọ̀ ipò ọjọ́ ogbó ṣe sọ, “ó wọ́pọ̀ gan an pé káwọn ọkùnrin tí wọ́n tètè fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ máa mutí kiri, tí àwọn obìnrin náà á sì wá di ẹni tó ń kó oògùn jẹ ràì.” Afìṣemọ̀rònú kan tó ń jẹ́ Graça Santos sọ pé, kí gbogbo àwọn tó bá ń ronú àtifẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ “ṣọ́ra fún wíwọ oko gbèsè, kí wọ́n wá nǹkan mìíràn ṣe, kí wọ́n sì gba ìmọ̀ràn lórí bí wọn kò ṣe ni kọrùn bọ gbèsè tí wọn ò ní lè san.”

Àrùn Éèdì àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ní Zambia

Bí àrùn éèdì ṣe ń fojoojúmọ́ gbilẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Zambia kò jẹ́ kí iṣẹ́ àgbẹ̀ rí bó ṣe yẹ kó rí mọ́ o. Ìwé ìròyìn Zambia Daily Mail sọ pé lára àwọn ohun tá ò gbọ́dọ̀ kóyán ẹ̀ kéré nínú ọ̀rọ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ àṣekára táwọn àgbẹ̀ àtàwọn olùrànlọ́wọ́ wọn máa ń ṣe. Àmọ́ èyí tó pọ̀ nínú àwọn agbo òṣìṣẹ́ yìí ni àrùn éèdì ń lù pa. Ìwé ìròyìn Daily Mail sọ pé: “Bí àwọn àgbẹ̀ bá kú, kì í sẹ́ni tó máa ṣiṣẹ́ mọ́ nínú oko tí èyí á sì wá mú kí àwọn nǹkan tó ń ti oko jáde lọ sílẹ̀ gidi gan an. Èyí ló sì ń fà á táwọn ìdílé kì í rí oúnjẹ tó tó jẹ, tá wá di pé ipò òṣì á gbòde kan.” Gẹ́gẹ́ bí Daniel Mbepa tó jẹ́ alákòóso ẹkùn Mansa ní Zambia ṣe sọ, ohun tó lè yanjú ọ̀ràn yìí ò ju pé kí àwọn àgbẹ̀ wọ̀nyí má ṣe ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn yàtọ̀ sí ìyàwó wọn. Ó ní: “Ó ṣeé ṣe láti kápá ìṣòro àrùn éèdì báwọn èèyàn bá yé ṣe ìṣekúṣe kiri.”