Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Yóò Lọ Síbẹ̀—Ṣé Ìwọ Náà Á Lọ?

Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Yóò Lọ Síbẹ̀—Ṣé Ìwọ Náà Á Lọ?

Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Yóò Lọ Síbẹ̀—Ṣé Ìwọ Náà Á Lọ?

Níbo ni wọ́n ń lọ? Síbi ayẹyẹ ọdọọdún ti ìrántí ikú Jésù Kristi ni. Lọ́dún 2000, àròpọ̀ mílíọ̀nù mẹ́rìnlá, ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógójì ó lé ẹgbàafà àti mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [14,872,086] ló péjọ jákèjádò ayé.

Èé ṣe tàwọn èèyàn fi ń lọ? Nítorí ohun tí ikú Kristi túmọ̀ sí fún ìran ènìyàn ni. Ó túmọ̀ sí ìtura tó ti sún mọ́lé báyìí kúrò lọ́wọ́ àìsàn, ìyà, àti ikú. Kódà, àwọn olólùfẹ́ tó ti kú ni a óò jí dìde sínú Párádísè ilẹ̀ ayé.

Báwo ni ikú Jésù ṣe máa mú irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀ wá? A ké sí ọ láti wá mọ̀ ọ́n. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyọ̀ láti rí ọ kí o dára pọ̀ mọ́ wọn fún àṣeyẹ pàtàkì yìí.

Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ ilé rẹ jù lọ. Ọjọ́ tó bọ́ sí lọ́dún yìí ni Sunday, April 8, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Wádìí àkókò tí a óò bẹ̀rẹ̀ gan-an lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò rẹ.