Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Àwọn Ìlú Ńlá Ń kún Sí I”

“Àwọn Ìlú Ńlá Ń kún Sí I”

“Àwọn Ìlú Ńlá Ń kún Sí I”

“Aráyé ń ṣí kiri lọ́wọ́ táa wà yìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ, èyí tó sì pọ̀ jù lọ nínú àwọn tó fẹ́ gbé ìgbésí ayé tó rọ̀ṣọ̀mù ló ń ṣí lọ sí ìlú ńlá.”

OHUN TÍ ìwé Foreign Affairs sọ nìyẹn nínú ọ̀rọ̀ tó fi ṣáájú àpilẹ̀kọ kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Àwọn Ìlú Ńlá Tó Ń Kún Sí I Láwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Gòkè Àgbà.” Àpilẹ̀kọ náà sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló jẹ́ pé “àwọn iná tó ń tàn yinrin-yinrin láwọn ìlú ńlá ló fà wọ́n mọ́ra, tàbí kó jẹ́ pé rìgbòrìyẹ̀ òṣèlú àti ti ètò ọrọ̀ ajé, iye àwọn èèyàn tó pọ̀ lápọ̀jù, àti àyíká tó bàjẹ́ ló mú àwọn kan ṣí lọ sí ìlú ńlá.”

Báwo làwọn ìlú ńlá ṣe ń yára kún sí i tó? Àwọn kan fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, àwọn èèyàn ń ya wìtìwìtì wọ àwọn ìlú ńlá lọ́nà tó ń múni kọ háà ní iye tó lé ní mílíọ̀nù kan lọ́sẹ̀! Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, àwọn ìlú ńlá tí wọ́n lé ní igba ló jẹ́ pé iye èèyàn tó ń gbé inú wọn lé ní mílíọ̀nù kan. Àwọn bí ogún ló jẹ́ pé iye èèyàn inú wọn tó mílíọ̀nù mẹ́wàá! Kò sì sí ọ̀ràn pé iye yẹn máa lọ sílẹ̀. Wo ìlú Èkó tó wà ní Nàìjíríà bí àpẹẹrẹ. Ìròyìn kan tí Ẹ̀ka Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Àgbáyé gbé jáde sọ pé, “tó bá fi máa di ọdún 2015, iye àwọn èèyàn tó máa fi ìlú Èkó ṣe ilé lè fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, èyí á jẹ́ kí ìlú Èkó tó wà ní ipò kẹtàlá nínú àwọn ìlú tó léèyàn jù lọ lágbàáyé wá sí ipò kẹta.”

Ọ̀pọ̀ ògbógi ló sọ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí kì í ṣe nǹkan tó dára fún ọjọ́ iwájú. Federico Mayor, tó jẹ́ olùdarí àgbà fún Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè nígbà kan rí sọ pé tó bá fi máa di ọdún 2035, “ẹgbẹ̀rún mẹ́ta mílíọ̀nù àwọn èèyàn mìíràn ni wọ́n máa tún kún iye àwọn tó ń gbé ìlú ńlá tó wà lónìí.” Láti lè bójú tó àwọn ènìyàn tí iye wọn pọ̀ yamùrá yìí, “ó máa di pé ká tẹ ẹgbẹ̀rún kan ìlú ńlá dó títí ogójì ọdún tó ń bọ̀ tí mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn á sì máa gbé inú ọ̀kọ̀ọ̀kan, ìyẹn túmọ̀ sí títẹ ìlú ńlá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n dó lọ́dún kan.”

Bákan náà làwọn ògbógi onímọ̀ tún sọ pé bí àwọn ìlú ńlá ṣe ń yára kún bámúbámú yìí ń ṣàkóbá tó pọ̀ fún àwọn ìlú ńlá níbi gbogbo káàkiri àgbáyé. Èyí ò sì yọ àwọn ìlú ńlá tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ti rí já jẹ ní ti ọrọ̀ ajé sílẹ̀. Àwọn ìṣòro wo làwọn ìlú ńlá ń bá fínra, báwo lèyí sì ṣe lè nípa lórí ìwọ pẹ̀lú? Ṣé ọ̀nà àbáyọ ń bẹ? Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lée yóò ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀ràn ṣíṣekókó yìí.