Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrètí Wo Ló Ń bẹ Pé A Óò Kápá Ohun Ìjà?

Ìrètí Wo Ló Ń bẹ Pé A Óò Kápá Ohun Ìjà?

Ìrètí Wo Ló Ń bẹ Pé A Óò Kápá Ohun Ìjà?

LÁWỌN ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ìjọba jákèjádò ayé ti jíròrò àwọn ọ̀nà láti ṣẹ́pá títa àwọn nǹkan ìjà lọ́nà tí kò bófin mu. Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gbogbo Gbòò Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti gbé kókó ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò. Oríṣiríṣi ìròyìn ni wọ́n ti kọ, wọ́n dá onírúurú àbá, ọ̀pọ̀ ìpinnu ni wọ́n sì ti mú lò. Àmọ́ àwọn olùṣelámèyítọ́ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé tó bá jẹ́ àwọn tó ń ṣe fàyàwọ́ ẹ̀ nìkan ni wọ́n dájú sọ, á jẹ́ pé àwọn tó ń fi nǹkan ìjà ọ̀hún ṣòwò ní pẹrẹu—ìyẹn àwọn ìjọba fúnra wọn—bọ́ lọ́wọ́ àyẹ̀wò nìyẹn.

Ká sòótọ́, nǹkan kan ṣì wà láàárín títa ohun ìjà lọ́nà tó bófin mu àti lọ́nà tí kò bófin mu tí kò tíì ṣe kedere sáráyé. Ọ̀pọ̀ ohun ìjà tí wọ́n sọ pé kò bófin mu ni wọ́n ti tà lọ́nà tó bófin mu rí. Àwọn ohun ìjà táwọn èèyàn sábàá máa ń jí tí wọ́n sì ń tà ní fàyàwọ́ ló jẹ́ pé owó làwọn ẹ̀ka ológun àti ẹ̀ka ọlọ́pàá ti kọ́kọ́ fi rà wọ́n. Síwájú sí i, kì í ṣohun àjèjì láti tún àwọn ohun ìjà tà fún ẹlòmíràn láìjẹ́ pé ẹni tó kọ́kọ́ rà á mọ̀ nípa rẹ̀ tàbí pé wọ́n gba àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé àtìgbàdégbà náà, Arms Control Today sọ pé: “Àwọn ìjọba àpapọ̀ gbọ́dọ̀ ṣe ju kìkì gbígbégbèésẹ̀ lórí títa àwọn ohun ìjà tó rọrùn láti lò, àwọn fúnra wọn gbọ́dọ̀ wo ipa tí wọ́n ń kó nínú ṣíṣe òwò ohun ìjà tí wọ́n sọ pé ó bófin mu ní lọ́ọ́lọ́ọ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló ń retí pé bó pẹ́ bó yá àwọn orílẹ̀-èdè á ṣe nǹkan kan sọ́rọ̀ títa àwọn ohun ìjà kéékèèké, akọ̀ròyìn kan sọ pé: “Níbi tó jẹ́ pé àwọn márùn-ún tó jẹ́ òpómúléró nínú mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ [aláàbò ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè] ló ń ta ohun ìjà tó ju ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ohun ìjà tí wọ́n ń tà lágbàáyé, ẹ máà jẹ́ ká fọkàn sí i pé wọ́n máa ṣe nǹkan kan sí i.”

Ohun tó tún ń dá kún àìlèṣẹ́pá àwọn ohun ìjà kéékèèké tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni pé, ó rọrùn láti ṣe irú àwọn ohun ìjà bẹ́ẹ̀ jáde. Nígbà tó jẹ́ pé kìkì orílẹ̀-èdè bíi méjìlá péré ló ń pèsè àwọn nǹkan ìjà dídíjú bí ọkọ̀ ogun alágbàá, ọkọ̀ ogun òfuurufú àti tojú omi, nǹkan bí àádọ́ta orílẹ̀-èdè ló ní àwọn tó lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún [300] tí ń ṣe ohun ìjà kéékèèké jáde. Kì í ṣe pé báwọn tó ń pèsè ohun ìjà yìí ṣe ń pọ̀ sí i túbọ̀ ń dá kún títò táwọn ìjọba ń to àwọn ohun ìjà jọ pelemọ nìkan ni o, àmọ́, ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń fún àwọn ẹgbẹ́ ológun, àwọn ẹgbẹ́ ọlọ̀tẹ̀, àtàwọn àjọ ọ̀daràn láǹfààní láti máa rí àwọn nǹkan ìjà yìí lò.

Ọ̀ràn Tó Di Awuyewuye Ńlá

Títí débi táa dé yìí, lílo àwọn ohun ìjà kéékèèké ní àwọn orílẹ̀-èdè tógun ti ń jà ló gbà wá lọ́kàn. Síbẹ̀síbẹ̀, kíkápá ìbọn ti di awuyewuye ńlá láwọn orílẹ̀-èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí wàhálà, tógun ò sí. Àwọn tó jẹ́ abẹnugan nídìí òfin fún kíkápá ìbọn ń tẹnu mọ́ ọn pé, ńṣe ni ìbọn púpọ̀ ń yọrí sí ìpànìyàn púpọ̀. Wọ́n sojú abẹ níkòó pé ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, níbi tí wọn ò ti fọwọ́ gírí mú ọ̀ràn lílo ìbọn tí ìbọn sì pọ̀ rẹpẹtẹ, ìpíndọ́gba ìpànìyàn lórí ẹnì kọ̀ọ̀kan ga sókè, àmọ́, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, níbi tí wọn ò ti gba gbẹ̀rẹ́ lórí ọ̀ràn lílo ìbọn, ìpíndọ́gba ìpànìyàn níbẹ̀ lọ sílẹ̀. Kíá làwọn tí kò fẹ́ kí wọ́n ṣòfin láti kápá ìbọn takò wọ́n pé ní ilẹ̀ Switzerland, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn ibẹ̀ ló láǹfààní láti lo ìbọn, àmọ́ ìpànìyàn kò tó nǹkan kan níbẹ̀.

Kí ọ̀ràn ọ̀hún lè túbọ̀ dojú rú sí i, àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe fi hàn pé Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gan an ló wá ní ìpíndọ́gba tó ga sókè nínú ikú tí kì í e ti ìbn ju ti gbogbo ikú tó kù lápapọ̀ nínú ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Yúróòpù. Síbẹ̀ náà, àwọn orílẹ̀-èdè míì wà, tí ikú tí kì í e ti ìbn ti ga ju ti gbogbo ikú tó ń ṣẹlẹ̀ ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lápapọ̀.

Ó jẹ́ àṣà tó wọ́pọ̀ pé káwọn èèyàn máa lo àkọsílẹ̀ oníṣirò tàbí kí wọ́n ṣì í lò láti fi ti èrò wọn lẹ́yìn. Ní ti ọ̀ràn kíkápá ìbọn yìí, àfi bí ẹni pé kò sí àlàyé kan tí wọ́n máa ṣe nípa rẹ̀ tí kò tún ní sí àlàyé mìí tó máa takò ó, táá sì dà bí ẹni pé kéèyàn gbà á gbọ́. Ọ̀ràn dídíjú gbáà lọ̀ràn ọ̀hún. Àmọ́ o, ibi táwọn ògbógi fẹnu kò sí ni pé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń fa ìpànìyàn àti ìwà ọ̀daràn tí ń lọ sókè sí i yàtọ̀ sí níní ìbọn lọ́wọ́.

Ńṣe ni Ẹgbẹ́ Oníbọn Ti Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tó jẹ́ ẹgbẹ́ tẹ́nu ẹ̀ tólẹ̀ ṣáà ń tẹnu mọ́ ọn pé: “Ìbọn kì í fúnra ẹ̀ pààyàn; àwọn èèyàn ló ń pààyàn.” Táa bá wò ó lọ́nà yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe ìbọn láti pààyàn ni, kò lè fúnra ẹ̀ pààyàn. Èèyàn kan gbọ́dọ̀ yìn ín, yálà kó mọ̀ọ́mọ̀ tàbí kó ṣèèṣì. Àmọ́ ká sòótọ́, àwọn kan á ṣì jiyàn pé, ńṣe ni ìbọn túbọ̀ mú kí pípààyàn rọrùn fáwọn èèyàn.

Fífi Idà Rọ Abẹ Ohun Ìtúlẹ̀

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Bíbélì sọ, kì í ṣe wíwulẹ̀ gba ìbọn lọ́wọ́ àwọn tó jẹ́ pé èrò láti pààyàn ló wà lọ́kàn wọn ló máa yanjú ìṣòro kéèyàn máa para wọn. Ìṣòro àwùjọ ènìyàn ni ìwà ọ̀daràn jẹ́, kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ níní ohun ìjà lọ́wọ́. Ojútùú ẹ̀ gan an ni pé, àwọn èèyàn fúnra wọn gbọ́dọ̀ yí ìwà wọn àti èrò ọkàn wọn padà. Ọlọ́run mí sí wòlíì Aísáyà láti kọ̀wé pé: “Dájúdájú, [Ọlọ́run] yóò ṣe ìdájọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì mú àwọn ọ̀ràn tọ́ ní ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:4.

Eléyìí kì í ṣe alá kan tí kò lè ṣẹ báwọn èèyàn kan ṣe rò o. Lónìí, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ń ní ìmúṣẹ láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ jákèjádò ayé. Yíyí àwọn ohun ìjà wọn padà sí ohun èlò àlàáfíà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ń fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí wọ́n ní láti múnú Ọlọ́run dùn hàn, àti láti gbé lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn mìíràn. Láìpẹ́, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run olúkúlùkù ẹni tó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé yóò máa gbé nínú ojúlówó àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀. (Míkà 4:3, 4) Ìbọn kò ní pààyàn mọ́. Àwọn èèyàn kò ní pa ara wọn mọ́. Irinṣẹ́ ikú kò ní sí mọ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

‘Wọn yóò fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀’