Ọ̀nà Tí Wọ́n Ń Gbà Jagun Lóde Òní
Ọ̀nà Tí Wọ́n Ń Gbà Jagun Lóde Òní
KÍÁKÍÁ, wọn ti ṣètò ibùdó kan fún bíbójú tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ lé méjìdínláàádọ́ta [1,548] àwọn tógun lé nílùú, tí wọ́n sá dé lójijì láti orílẹ̀-èdè kan tí kò jìnnà nílẹ̀ Áfíríkà. Wọ́n fi kakí aláwọ̀ búlúù àti àwọ̀ ìyeyè ta àwọn àgọ́ tó fìdí múlẹ̀ sórí ilẹ̀ ẹlẹ́rẹ̀ tí wọ́n ṣán oko rẹ̀ nínú igbó kan tí ọ̀pẹ kún fọ́fọ́. Kò sí iná mànàmáná tàbí aṣọ tí wọ́n lè tẹ́ sùn, bẹ́ẹ̀ ni kò sómi ẹ̀rọ tàbí ilé ìgbọ̀nsẹ̀. Òjò ń rọ̀. Àwọn tí ogun lé dé náà fi igi la ọ̀nà fún ọ̀gbàrá kí omi má baà ya kúnnú àwọn àgọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ làwọn ẹgbẹ́ aṣèrànwọ́ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń sá sókè-sódò láti rí i pé àwọ́n mú kí gbígbé níbẹ̀ wọn rọrùn díẹ̀.
Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn tógun lé nílùú yìí ti rọ́nà wọ ọkọ̀ ojú omi kan tó ti di jẹ̀kúrẹdí, láti bọ́ lọ́wọ́ ogun abẹ́lé tó ti fọ́ orílẹ̀-èdè wọn túútúú fún ọ̀pọ̀ ọdún. Kì í ṣe ọkọ̀ ogun alágbàá ni wọ́n fi jagun ọ̀hún bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lo ẹ̀rọ ajubọ́ǹbù o. Gbogbo ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí nǹkan bí àádọ́jọ [150] sójà tí wọ́n dìhámọ́ra pẹ̀lú ìbọn àgbéléjìká já wọ inú orílẹ̀-èdè náà. Láàárín àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, àwọn sójà náà bẹ̀rẹ̀ sí í lọ láti abúlé kan sí òmíràn, tí wọ́n ń fipá gbowó lọ́wọ́ àwọn aráàlú, tí wọ́n ń sọ àwọn èèyàn di sójà, pípa ni wọ́n sì ń pa ẹnikẹ́ni tí kò bá jẹ́ kí wọ́n rójú ṣe tiwọn. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n kápá gbogbo orílẹ̀-èdè náà.
Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Esther wà lára àwọn tí ogun lé dé náà. O sọ pé: “Ohun tó burú jù lọ tí mo tíì rí rí láyé mi ni bí mo ṣe pàdánù ọkọ mi nínú ogun yìí. Ńṣe ni wọ́n
yìnbọn pá a. Inú ìbẹ̀rù la máa ń wà. Báa bá gbọ́ tẹ́nì kan pariwo, ńṣe la máa rò pé àwọn tó fẹ́ pa wá ló dé. Ìgbàkigbà téèyàn bá rí ẹnì kan tó gbébọn, olúwarẹ̀ á rò pé ó fẹ́ pa òun ni. Ara mi kì í lélẹ̀ nígbà kankan. Ibùdó ìsádi níbí nìkan ni mo ti ń róorun sùn lóru. Nígbà tí mo wà nílé, n kì í lè sùn. Bi ọmọ kékeré tí kò mọ nǹkankan ni mo ṣe ń sùn níbí.”Òǹkọ̀wé Jí! béèrè pé, “Ṣé nínú àgọ́ tó rẹ fún omi yìí náà?”
Esther bú sẹ́rìn-ín. O sọ pé: “Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé inú ilẹ̀ ẹlẹ́rẹ̀ yìí ni màá sùn sí, màá ṣì sùn gbádùn ju bí mo ṣe ń sùn níbi tí mo ti wá lọ.”
Ambrose, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá, ti lo èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé ẹ̀ ní sísá kúrò lágbègbè ogun kan sí òmíràn pẹ̀lú ìdílé rẹ̀. O sọ pé: “Ó wù mí kí àlàáfíà dé kí n lè padà sí iléèwé. Ó ṣe tán, mo ti ń dàgbà.”
Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni Kpana, ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé kí lohun tó rántí nígbà tó ṣì kéré gan an, kò tiẹ̀ rò ó lẹ́ẹ̀mejì tó fi dáhùn pé: “Ogun ni! Ìjà ṣáá!”
Irú ogun táwọn èèyàn wọ̀nyí sá fún ti di èyí tó wọ́pọ̀ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé kan sọ, nínú ogun ńlá mọ́kàndínláàádọ́ta tí wọ́n jà láti ọdún 1990, mẹ́rìndínláàádọ́ta nínú ẹ̀ ló jẹ́ pé àwọn ohun ìjà tó rọrùn láti lò ni wọ́n fi jà wọ́n. Láìdàbí idà tàbí ọ̀kọ̀ tó jẹ́ pé ó ń béèrè fún kíkọ́ bí wọ́n ṣe ń lò wọ́n dáadáa nínú ìjà, tó sì tún ń béèrè fún okun, àwọn nǹkan ìjà kéékèèké ti mú kógun jíjà ṣeé ṣe fáwọn kòmọ̀kan àtàwọn tó tún mọṣẹ́ ọ̀hún bákan náà. a Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń lo àwọn ọ̀dọ́langba àtàwọn ọmọdé láti jà, wọ́n sì máa ń fipá mú wọn kó ẹrù ẹlẹ́rù, kí wọ́n sọ àwọn èèyàn daláàbọ̀ ara, kí wọ́n sì tún máa pààyàn.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìjà yìí ló jẹ́ pé kì í ṣe láàárín orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn ló ti ń ṣẹlẹ̀, àmọ́ láàárín àwọn èèyàn tó jẹ́ ọ̀kan náà ni. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe àwọn sójà tí wọ́n dá lẹ́kọ̀ọ́ lójú ogun ló máa ń ja àwọn ìjà yìí, bí kò ṣe àwọn ará ìlú ńlá, ìlú kékeré àtàwọn ará abúlé. Nítorí pé kì í ṣe àwọn tí wọ́n dá lẹ́kọ̀ọ́ ló ń ja púpọ̀ nínú àwọn ìjà yìí, kì í fi bẹ́ẹ̀ sí ìbẹ̀rù láti má ṣe rú àwọn òfin tó wà nídìí iṣẹ́ ológun. Ìdí nìyẹn tí gbígbógun tàwọn ọkùnrin tí kò ní nǹkan ìgbèjà, àwọn obìnrin, àtàwọn ọmọdé fi wọ́pọ̀ níbi gbogbo. A gbọ́ pé nínú àwọn ogun òde òní, ohun tó lé ní ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n ń pa ló jẹ́ pé ará ìlú ni wọ́n. Nínú irú àwọn ogun yẹn, àwọn ohun ìjà kéékèèké àtèyí tó rọrùn láti lò ń kó ipa tó pọ̀ jù nínú wọn.
A mọ̀ pé, ìbọn ò lè fúnra ẹ̀ dá ìjà sílẹ̀—nítorí pé kí ẹ̀tù ìbọn tiẹ̀ tó dé làwọn èèyàn ti ń jà. Àmọ́, ìbọn tí wọ́n tò jọ pelemọ lè fún ogun jíjà ní ìṣírí dípò wíwá ọ̀nà bí aáwọ̀ ṣe máa yanjú. Àwọn nǹkan ìjà lè máà jẹ́ kógun parí bọ̀rọ̀ kí ó sì mú kí pípa àwọn èèyàn nípakúpa túbọ̀ pọ̀ sí i.
Nígbà tó jẹ́ pé àwọn ohun ìjà tí wọ́n ń lò nínú àwọn ogun òde òní rọrùn ún lò, ohun tó ti tìdí wọn yọ burú jáì. Láàárín àwọn ọdún 1990, àwọn èèyàn tí irú àwọn ohun ìjà bẹ́ẹ̀ pa lé ní mílíọ̀nù mẹ́rin. Àwọn tó lé lógójì mílíọ̀nù ti di yálà ẹni tí ogun lé nílùú tàbí tí wọ́n ṣí lọ síbòmíràn. Àwọn nǹkan ìjà kéékèèké yìí ti sọ ètò ìṣèlú, ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ètò ọ̀rọ̀-ajé, àti àyíká àwọn àwùjọ tógun ti fà ya yìí di aláìlágbára mọ́. Owó tó sì ń ná àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká láti pèsè ìrànwọ́ pàjáwìrì, títọ́jú àwọn tógun lé nílùú, pípẹ̀tù síjà, àti kíkó àwọn ológun lọ láti dá sí ọ̀ràn náà kọjá iye owó táa lè finú rò lọ.
Kí wá ló fà á tó jẹ́ pé àwọn ohun ìjà kéékèèké ló wá di ohun tí wọ́n ń lò jù lọ nínú ìjà òde-òní? Ibo ni wọ́n ti ń rí wọn? Kí ni wọ́n lè ṣe láti dín wọn kù tàbí mú iṣẹ́ oró tí wọ́n ń ṣe kúrò? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gbólóhùn náà “àwọn ohun ìjà kéékèèké” ń tọ́ka sáwọn ìbọn àgbéléjìká àtàwọn ìbọn ìléwọ́—ìyẹn làwọn nǹkan ìjà tẹ́nì kan ṣoṣo lè mú dání; ọ̀rọ̀ náà “àwọn ohun ìjà tó rọrùn ún lò” kan àwọn ọkọ̀ ogun tí wọ́n ṣe ìbọn mọ́, àwọn ìbọn arọ̀jò ọta, àtàwọn ohun àfọwọ́jù abúgbàù, tó jẹ́ pé kò gbà ju èèyàn méjì péré nígbà míì láti lò wọ́n.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]
FỌ́TÒ UN 186797/J. Isaac