Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ìsọfúnni Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Àlá Jẹ́?

Ṣé Ìsọfúnni Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Àlá Jẹ́?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ìsọfúnni Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Àlá Jẹ́?

AGBỌ́ pé nípasẹ̀ àlá ni Elias Howe fi rí iṣẹ́ ọnà tó lò láti ṣe maṣíìnì ìránṣọ. Mozart tó jẹ́ kọrinkọrin sọ pé ojú àlá lòún ti rí púpọ̀ lára àwọn àkọlé tí òun fún ohùn orin òun. Bákan náà ni Friedrich August Kekule von Stradonitz sọ pé ojú alá kan tí òun lá lòún ti rí bí èérún benzene á ṣe rí. Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì í ṣohun tétí ò gbọ́ rí. Jálẹ̀ ìtàn, ọ̀pọ̀ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ló ka àlá sí nǹkan tí kì í ṣe ojú lásán. Àwọn kan gbà pé bí ojúmọ́ tó ń mọ́ ṣe jẹ́ òótọ́ náà ni àlá ṣe jẹ́ òótọ́.

Bíbélì ní àwọn àkọsílẹ̀ bíi mélòó kan nínú tó fi àlá hàn gẹ́gẹ́ bí orísun ìsọfúnni pàtàkì—ìyẹn ọ̀nà kan tí Ọlọ́run ń gbà bá èèyàn sọ̀rọ̀. (Onídàájọ́ 7:13, 14; 1 Àwọn Ọba 3:5) Fún àpẹẹrẹ, Ọlọ́run bá Ábúráhámù, Jékọ́bù, àti Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ lójú àlá. (Jẹ́nẹ́sísì 28:10-19; 31:10-13; 37:5-11) Nebukadinésárì, ọba Bábílónì pẹ̀lú rí àwọn àlá alásọtẹ́lẹ̀ gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Dáníẹ́lì 2:1, 28-45) Nítorí náà, ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti gbà gbọ́ pé, lónìí sẹ́, àwọn àlá kan wà tí wọ́n jẹ́ ìsọfúnni látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?

Àwọn Àlá Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Nínú Bíbélì, ìdí kan pàtó ló máa ń fa àwọn àlá tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Lóòótọ́, àwọn ìgbà míì wà tẹ́ni tó lá àlá náà kò ní mọ ohun tó túmọ̀ sí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, “Olùṣí àwọn àṣírí payá” fúnra rẹ̀ máa ń pèsè àlàyé kó má bàa sí iyèméjì nípa ìtumọ̀ àlá náà. (Dáníẹ́lì 2:28, 29; Ámósì 3:7) Àwọn àlá tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kì í rúni lójú bíi tàwọn àlá tí a máa ń lá.

Nígbà míì, Ọlọ́run máa ń lo àlá láti fi dáàbò bo àwọn èèyàn tí wọ́n ṣe pàtàkì nínú mímú ète rẹ̀ ṣẹ. Kò fi dandan túmọ̀ sí pé àwọn tó rí irú àlá bẹ́ẹ̀ gbà jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, àwọn awòràwọ̀ tó lọ bẹ Jésù ọmọdé náà wò kò padà sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù apààyàn yẹn gẹgẹ bó ṣe sọ pé kí wọ́n ṣe. Kí nìdí? Wọ́n ti gba ìkìlọ̀ lójú àlá. (Mátíù 2:7-12) Èyí fún Jósẹ́fù, tó jẹ́ alágbàtọ́ Jésù ní àkókò tí ó tó láti sá lọ sí Íjíbítì pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tóun náà rí gbà lójú àlá. Èyí dá ẹ̀mí ọmọdé náà, Jésù sí.—Mátíù 2:13-15.

Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ìgbà yìí, Fáráò ọba Íjíbítì lá àlá kan níbi tó ti rí àwọn ṣírí ọkà jíjọjú méje àti àwọn màlúù sísanra méje tí ìrísí wọn yàtọ̀ sí ti àwọn ṣírí ọkà méje tó ti gbẹ àtàwọn màlúù méje tí wọ́n rù hangogo. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, Jósẹ́fù túmọ̀ àlá náà lọ́nà tó ṣe rẹ́gí: Ilẹ̀ Íjíbítì yóò gbádùn ọdún méje ọ̀pọ̀ tí ọdún méje ìyàn yóò sì tẹ̀ lé e. Mímọ èyí ṣáájú jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn ará Íjíbítì láti múra sílẹ̀ kí wọ́n sì kó oúnjẹ jọ pelemọ. Èyí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti dá àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù sí àti láti mú wọn wá sí Íjíbítì.—Jẹ́nẹ́sísì, orí 41; Ge 45:5-8.

Ọba Nebukadinésárì ti Bábílónì náà lá àlá kan. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìdìde àti ìṣubú àwọn agbára ayé tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú èyí tí yóò nípa ní tààràtà lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Dáníẹ́lì 2:31-43) Lẹ́yìn náà, ó tún lá àlá mìíràn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣubú òun fúnra rẹ̀, bí yóò ṣe ya wèrè àti bí yóò ṣe sàn padà lẹ́yìn náà. Àlá alásọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ gbígbòòrò, ó tọ́ka sí ìgbékalẹ̀ Ìjọba Mèsáyà, èyí tí Ọlọ́run yóò lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.—Dáníẹ́lì 4:10-37.

Lónìí Ńkọ́?

Òótọ́ ni pé Ọlọ́run lo àlá láti bá àwọn kan sọ̀rọ̀. Àmọ́ Bíbélì fi hàn pé èyí ṣọ̀wọ́n gidigidi. Àlá kò fìgbà kankan jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tí Ọlọ́run ń lò láti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run olóòótọ́ ló wà tí wọn kò gba ìsọfúnni kankan rí lójú àlá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Lílò tí Ọlọ́run lo àlá láti bá èèyàn sọ̀rọ̀ lá lè fi wéra pẹ̀lú bí Ó ṣe pín Òkun Pupa níyà. A mọ̀ pé ẹ̀ẹ̀kan ló ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́, ó dájú pé kì í ṣe báyẹn ló ṣe ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ lò nígbà gbogbo.—Ẹ́kísódù 14:21.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé oríṣiríṣi ọ̀nà àgbàyanu ni ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbà ṣiṣẹ́ lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “A fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n fún ẹnì kan nípasẹ̀ ẹ̀mí, a fún òmíràn ní ọ̀rọ̀ ìmọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí kan náà ti fúnni, a fún òmíràn ní ìgbàgbọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan náà, a fún òmíràn ní àwọn ẹ̀bùn ìmúniláradá nípasẹ̀ ẹ̀mí kan ṣoṣo náà, síbẹ̀, a fún òmíràn ní ọ̀nà ìṣiṣẹ́ àwọn iṣẹ́ agbára, a fún òmíràn ní ìsọtẹ́lẹ̀, a fún òmíràn ní fífi òye mọ àwọn àsọjáde onímìísí, a fún òmíràn ní onírúurú ahọ́n àjèjì, a sì fún òmíràn ní ìtumọ̀ àwọn ahọ́n àjèjì.” (1 Kọ́ríńtì 12:8-10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò dìídì mẹ́nu kan àlá tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àwọn Kristẹni kan wà tó hàn gbangba pé Ọlọ́run fi àlá bá wọn sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì 2:28.—Ìṣe 16:9, 10.

Bó ti wù kó rí, àpọ́sítélì náà sọ nípa àwọn ẹ̀bùn pàtàkì yìí pé: “Yálà àwọn ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ wà, a óò mú wọn wá sí òpin; yálà àwọn ahọ́n àjèjì wà, wọn yóò ṣíwọ́; yálà ìmọ̀ wà, a óò mú un wá sí òpin.” (1 Kọ́ríńtì 13:8) Ẹ̀rí fi hàn pé lára àwọn ẹ̀bùn tí yóò “wá sí òpin” ni onírúurú ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà báni sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, Ọlọ́run kò tún fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àwọn ẹ̀bùn pàtàkì yìí mọ́.

Lónìí, àwọn ògbógi ṣì ń gbìyànjú láti mọ bí àlá ṣe ń ṣiṣẹ́, àti pé bóyá ó ní nǹkan kan tó wúlò fún tàbí kò ní. Bíbélì kò tan ìmọ́lẹ̀ kankan sórí irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Àmọ́ o, Bíbélì kìlọ̀ fún àwọn tó rin kinkin mọ́ ọn pé àwọn ń wá kí Ọlọ́run báwọn sọ̀rọ̀ nínú àlá. Ní Sekaráyà 10:2, ó sọ pé ‘Àwọn woṣẹ́woṣẹ́, . . . àlá tí kò ní láárí ni wọ́n ń rọ́.’ Ọlọ́run tún kìlọ̀ pé a ò gbọ́dọ̀ máa wá àwọn àmì. (Diutarónómì 18:10-12) Lójú àwọn ìkìlọ̀ wọ̀nyí, àwọn Kristẹni lónìí kò jẹ́ retí láti gba ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nínú àwọn àlá wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n wo àlá bí ohun kan tó kàn ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá sùn.