Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Lọjọ́ Iwájú Àwọn Ìlú Ńlá Ṣe Máa Rí O?

Báwo Lọjọ́ Iwájú Àwọn Ìlú Ńlá Ṣe Máa Rí O?

Báwo Lọjọ́ Iwájú Àwọn Ìlú Ńlá Ṣe Máa Rí O?

“BÍ A bá yẹ àwọn ìlú ńlá wa wò, ọjọ́ ọ̀la wa là ń yẹ̀ wò yẹn.” Ohun tí Ismail Serageldin ti Báǹkì Àgbáyé sọ nìyẹn. Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo nǹkan táa ti rí títí di àkókò yìí, ọjọ́ ọ̀la ọ̀hún kò dà bí ẹni pé á dára.

Inú wa dùn pé, akitiyan ńláǹlà ń lọ lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé rọ̀ṣọ̀mù láwọn àgbègbè ìgboro. Láìpẹ́ yìí ní New York City, wọ́n parí ṣíṣàtúnṣe Gbàgede Times tó wà ní Manhattan. Tẹ́lẹ̀, kò sẹ́ni tí kò mọ gbàgede yìí mọ́ àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè, egbòogi olóró, àti ìwà ọ̀daràn. Ní báyìí, àwọn ibi ìtajà àti ibi ìwòran ló kún òpópó náà—ńṣe ló ń fa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùṣèbẹ̀wò mọ́ra. Naples, ní Ítálì, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn National Geographic ṣe sọ, jẹ́ “ìlú mèremère kan, tó lajú dáadáa, àní tó tiẹ̀ fìgbà kan jẹ́ ẹgbẹ́ pẹ̀lú London àti Paris” àmọ́ ó di ahoro nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Naples, di ibi táà bá kúkú máa pè nílùú ìwà ọ̀daràn àti ìdàrúdàpọ̀. Àmọ́ ṣá, nígbà tí wọ́n yan ìlú ńlá yẹn gẹ́gẹ́ bí ibi àpérò ètò ìṣèlú lọ́dún 1994, ńṣe ló wá dà bí ẹni pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ ẹ́ dó, nítorí àwọn àtúnṣe ńláǹlà tí wọ́n ṣe sígboro ìlú náà.

Dájúdájú, àwọn ìlú ńlá tó láàbò, tó sì mọ́ tónítóní kò ní ṣàì náni ní ohun kan. Kí ààbò tó gbé pẹ́ẹ́lí tó lè wà, àwọn ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ pọ̀ sí i. Ohun mìíràn tó tún lè náni ni àìlè fi àṣírí ẹni pa mọ́. Àwọn àgbègbè kan wà tó jẹ́ pé tọ̀sántòru làwọn kámẹ́rà àtàwọn ọlọ́pàá tí kò wọṣọ iṣẹ́ máa ń ṣọ́ ibẹ̀. Bí o ṣe ń gba ọgbà ìtura kan kọjá, tóò ń kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn orísun omi àtọwọ́dá, àwọn ère gbígbẹ́, tàbí lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọgbà tí wọ́n gbin òdòdó sí, o lè máa lọ ní tìẹ láìmọ̀ pé àwọn kan ń yẹ̀ ọ́ wò.

Mímú ipò nǹkan sunwọ̀n sí i nígbà míì máa ń kó àwọn mẹ̀kúnnù sí ìnáwó ńlá. Ronú nípa ohun táwọn ìdílé kan tówó gọbọi ń wọlé fún máa ń ṣe—wọ́n á kó lọ sádùúgbò táwọn mẹ̀kúnnù máa ń gbé. Ohun tó sì máa ń fa èyí ni ètò ọrọ̀ ajé tí ò dúró sójú kan—nígbà tó jẹ́ pé “iṣẹ́ táwọn èèyàn ń fọwọ́ ṣe tẹ́lẹ̀ ti di èyí tí ẹ̀rọ ń ṣe.” (Gentrification of the City, tí Neil Smith àti Peter Williams kọ) Báwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń fọwọ́ ṣe ṣe ń di èyí tí ò sí mọ́, tó wá di pé àwọn tó mọṣẹ́ dunjú àtàwọn tó lóye iṣẹ́ dáadáa layé tún nílò ti mú kó di dandan láti máa kọ́ àwọn ilé táwọn olówó ń gbé. Ọ̀pọ̀ àwọn amọṣẹ́dunjú tí wọ́n ń gbowó rẹpẹtẹ ló tẹ́ lọ́rùn láti tún àwọn ilé ṣe níbi táwọn mẹ̀kúnnù ń gbé dípò tí wọ́n á fi máa gbé lágbègbè ìlú ńlá.

Òótọ́ ni pé èyí máa ń mú kí ìdàgbàsókè bá àwọn àdúgbò wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n báwọn àdúgbò ṣe ń dàgbà sókè, bẹ́ẹ̀ náà làwọn nǹkan ṣe ń gbówó lórí. Ó wá di pé àwọn mẹ̀kúnnù ò rówó tí wọ́n lè fi gbé láwọn àdúgbò tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ tí wọ́n sì ti wà fún ọ̀pọ̀ ọdún!

Ṣe Àwọn Ìlú Ńlá Yóò Túká Ni?

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe làwọn ìlú ńlá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ àwọn ìyípadà tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ mú wá. Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lo Íńtánẹ́ẹ̀tì láti rajà kí wọ́n sì tún fi ṣòwò lè ní àbájáde tó gbàfiyèsí. Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tuntun ti jẹ́ kó rọrùn fún àwọn okòwò kan láti fìdí kalẹ̀ sáwọn ẹ̀yìn odi ìlú ńlá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣìṣẹ́ ló sì ń lọ síbẹ̀.

Bí fífi kọ̀ǹpútà rajà àti fífi ṣiṣẹ́ ṣe wá di ohun tó gbajúmọ̀, ó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn má nífẹ̀ẹ́ mọ́ sí lílọ sáwọn àgbègbè okòwò táwọn èèyàn ti pọ̀ pìtìmù. Ìwé náà Cities in Civilization sọ pé: “A ń fojú inú wò ó pé ó máa ṣeé ṣe fáwọn òṣìṣẹ́ tí àkókò iṣẹ́ wọn kì í yí padà, pàápàá àwọn tó ń ṣiṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ láti máa ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe látinú ilé wọn tàbí láwọn ilé iṣẹ́ tó wà ládùúgbò wọn, . . . èyí kò ní jẹ́ kí ojú títì kún ju bó ṣe yẹ lọ.” Moshe Safdie tó jẹ́ ayàwòrán ilé sọ bákan náà pé: “Pẹ̀lú ìdàgbàsókè tuntun yìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn abúlé lè wà káàkiri àgbáyé, a ó sì lo kọ̀ǹpútà àti Íńtánẹ́ẹ̀tì láti fún gbogbo wọn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ní ìgbádùn táwọn ará ìgboro ń jẹ àti ọrọ̀ táwọn ará ìlú ńlá ní.”

Báwo Lọjọ́ Iwájú Àwọn Ìlú Ńlá Ṣe Máa Rí O?

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn gbà pé ká tiẹ̀ yọ ti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kúrò, àwọn ìlú ńlá ń pèsè àwọn ohun kan àtàwọn àǹfààní kan tí yóò ṣì máa fa àwọn èèyàn mọ́ra. Ohun yòówù kọ́jọ́ iwájú jẹ́, àwọn ìlú ńlá òde òní wà nínú wàhálà ní lọ́ọ́lọ́ọ́! Kò sì sí ìrètí pé a óò rí ojútùú láìpẹ́ sáwọn ìṣòro tó pọ̀ bí eléèmọ̀ nípa ilé gbígbé àti ìmọ́tótó tó ń dojú kọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tálákà tí wọ́n wà nígboro. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò tíì sí ẹnì kan tó tíì rí ọ̀nà láti mú ìwà jàǹdùkú, bíba àyíká jẹ́, tàbí sísọ ìgboro deléèérí kúrò.

Àwọn kan lè sọ pé bí ìjọba bá ná owó gọbọi sáwọn ìlú ńlá àbùṣe-bùṣe. Ṣùgbọ́n báa bá ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ àṣeyọrí tí ọ̀pọ̀ ìjọba ní nípa bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn nǹkan tí wọ́n ní, ṣé a wá lè sọ pé wọ́n lówó tí ó tó láti mú káwọn ìṣòro tó wà láwọn ìlú ńlá dàwátì? Láwọn ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, ìwé náà, The Death and Life of Great American Cities sọ pé: “A máa ń tan ara wa jẹ pé ká ní a lówó tó pọ̀ tó ni . . . , gbogbo àwọn àdúgbò játijàti wa la máa mú kúrò . . . Àmọ́ wo ohun tó ti jẹ́ àbárèbábọ̀ bílíọ̀nù bíi mélòó kan táa ti ná sórí títún àdúgbò ṣe: Àwọn ilé tí kò gbówó lórí àmọ́ tí wọ́n ti wá di ibùdó ìwà ìpáǹle, ìwà bàsèjẹ́ àti àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tó ti di aláìnírètí dípò àwọn àdúgbò játijàti táa retí pé kí wọ́n rọ́pò.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣì jẹ́ òótọ́ dọ̀la.

Àmọ́ bówó ò bá lè yanjú ìṣòro ọ̀hún, kí wá lójútùú rẹ̀? A ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé àwọn èèyàn ló wà láwọn ìlú ńlá, kì í kàn ṣe ilé àti òpópónà nìkan. Nítorí náà, ní àbárèbábọ̀, àwọn èèyàn ló gbọ́dọ̀ yí padà báa bá fẹ́ kí ìgbésí ayé nílùú ńlá sunwọ̀n sí i. Lewis Mumford sọ nínú ìwé The City in History pé: “Ohun tó lè mú kí ìlú kan dára láyé yìí ni bí àwọn èèyàn bá ṣe bìkítà tí wọ́n sì ń hùwà dáadáa sí.” Báa bá sì fẹ́ mú ìwà ìjoògùnyó, iṣẹ́ aṣẹ́wó, ìbàyíkájẹ́, sísọ ìgboro deléèérí, àìsí ẹ̀tọ́ ọgbọọgba, ìwà bàsèjẹ́, kíkọ ìkọkúkọ sára nǹkan, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ kúrò, ohun táa nílò ju mímú kí iye àwọn ọlọ́pàá pọ̀ sí i tàbí títún àwọn ilé kùn lọ́dà lọ. Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ rí ìrànwọ́ gbà láti ṣe àwọn ìyípadà tó pabanbarì nínú bí wọ́n ṣe ń ronú àti bí wọ́n ṣe ń hùwà.

Àkóso Gbọ́dọ̀ Yí Padà

Ó hàn gbangba pé ṣíṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ ti kọjá agbára ẹ̀dá ènìyàn. Nítorí náà, gbogbo akitiyan láti yanjú ìṣòro àwọn ìlú ńlá lónìí—bó ti wù kí wọ́n dára tó—pàbó ni yóò máa já sí. Bó ti wù ó rí, ìrètí ń bẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ìṣòro tó wà nígboro lónìí tún jẹ́ àpẹẹrẹ kan sí i tó fi hàn pé èèyàn ò lágbára láti bójú tó ayé wa dáadáa. Ńṣe làwọn ìlú ńlá wa òde òní tí kò rí bó ṣe yẹ kó rí, tó kún fún ìdàrúdàpọ̀ jẹ́ ìmúṣẹ ohun tó wà nínú Bíbélì nínú ìwé Jeremáyà 10:23 pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Akitiyan ènìyàn láti ṣe olórí ara rẹ̀ ti yọrí sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìbànújẹ́—àwọn ìṣòro tó jẹ́ pé ńṣe láwọn ìlú ńlá wa wulẹ̀ jẹ́ ká rí wọn dáadáa.

Àwọn tó ń gbé ìlú ńlá káàkiri àgbáyé lè rí ìtùnú nínú ìlérí Bíbélì tó wà nínú Ìṣípayá 11:18, pé Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” Dípò tí ì bá fi sọ pé nǹkan ò lè dáa, ńṣe ló ń tọ́ka sí ọjọ́ iwájú kan tó dára fún ìran ènìyàn. Ó ṣèlérí pé Ọlọ́run yóò lo Ìjọba kan láti ṣàkóso ayé wa. (Dáníẹ́lì 2:44) Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn èèyàn ò tún ní wà ní ipò òṣì tó kọjá sísọ mọ́, a ò ní dù wọ́n ní ilé tó dára àti ìmọ́tótó, a ó máa fi ọ̀wọ̀ tiwọn wọ̀ wọ́n, a kò sì ní fi ohun ayọ̀ dù wọ́n mọ́. Lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba Ọlọ́run, àwọn èèyàn á gbádùn aásìkí nípa tara, ìlera tó jí pépé, àti ilé tó dára.—Aísáyà 33:24; 65:21-23.

Ayé tuntun yìí ni ojútùú kan ṣoṣo tòótọ́ tó wà fún àwọn ìṣòro táwọn ìlú ńlá ń kojú lónìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Ìsapá gidi ń lọ lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé láwọn àgbègbè ìgboro sunwọ̀n sí i

Naples, Italy

Ìlú Ńlá New York, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Sydney, Ọsirélíà

[Credit Line]

SuperStock

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ayé tuntun Ọlọ́run pèsè ojútùú fún àwọn ìṣòro tó ń bá àwọn tó ń gbé ìlú ńlá fínra lónìí