Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Màá Ṣe Sọ fún Un Pé Mi Ò Ṣe?

Báwo Ni Màá Ṣe Sọ fún Un Pé Mi Ò Ṣe?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Màá Ṣe Sọ fún Un Pé Mi Ò Ṣe?

“Arákùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í fìfẹ́ hàn sí mi nínú ìjọ wa nígbà ẹ̀ẹ̀rùn yìí. Mi ò fìgbà kan gba tiẹ̀. Ìṣòro tí mo wá ní ni pé, mi ò mọ bí mo ṣe lè sọ fún un pé mí ò ṣe láìní bà á lọ́kàn jẹ́.”—Elizabeth. a

“ṢÉ MO lè mọ̀ ẹ́ ju báyìí lọ?” Ṣé ọ̀dọ́kùnrin kan ti bi ẹ́ nírú ìbéèrè yẹn rí? Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́bìnrin kan, b inú ẹ lè kọ́kọ́ dùn kórí ẹ sì wú—kóo tiẹ̀ yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀! Àmọ́ o, ó tún lè dà ẹ́ lọ́kàn rú débi pé oò ní mọ ohun tí wàá fi fèsì padà.

Tí ẹnì kan bá sọ fún ẹ pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó lè mú onírúurú èrò wá sí ẹ lọ́kàn. Èyí lè túbọ̀ rí bẹ́ẹ̀ tó bá lọ jẹ́ pé o ti dàgbà tẹ́ni tí ń lọ́kọ, tíyẹn sì wá mú kóo wà nípò láti dáhùn sí irú àfiyèsí bẹ́ẹ̀! c Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀nà tí wàá gbà dáhùn sinmi púpọ̀ lórí irú ẹni tó bi ẹ́ ní ìbéèrè ọ̀hún. Tó bá jẹ́ ẹni tó mọ nǹkan tó ń ṣe ni, tí ọkàn rẹ sì tún fà sí i, ó lè má ṣòro fún ọ láti fún un lésì. Ká wá ní ó lọ jẹ́ ẹni tó hàn gbangba pé kò láwọn ànímọ́ tó máa mú un kó jẹ́ ọkọ gidi ńkọ́? Tàbí kẹ̀, ká tiẹ̀ ní pé pẹ̀lú gbogbo àwọn ànímọ́ dídára tó ní, ńṣe ni kò kàn tiẹ̀ wù ẹ́ ńkọ́?

Tún wo ọ̀ràn ọ̀dọ́bìnrin kan tó ti ń bá ẹnì kan ròde fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ tó wá rí i pé kì í ṣe irú ẹni yẹn lòún máa fẹ́ láti lo ìyókù ìgbésí ayé òun pẹ̀lú rẹ̀. Dípò kó jáwọ́ nínú àjọṣe yẹn, ńṣe ló ṣáà ń tẹ̀ lé e kiri. Ó wá ń bi ara rẹ̀ pé: “Báwo ni mo ṣe fẹ́ sọ fún un pé mi ò ṣe mọ́?”

Bí Ìfẹ́ Ẹnì Kan Kò Bá Sí Lọ́kàn Ẹ

Láyé àwọn baba ńlá, ó hàn gbangba pé ẹni táwọn òbí bá ti yàn làwọn èèyàn ń fẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 24:2-4, 8) Láwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn Kristẹni ló lómìnira láti yan ẹni tí wọ́n máa fẹ́ fúnra wọn. Òté kan tí Bíbélì kàn fi lé e ni pé—Kristẹni kan gbọ́dọ̀ gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 7:39.

Ṣé eléyìí wá túmọ̀ sí pé dandan ni kóo fẹ́ ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti jẹ́ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ tó sọ pé òún nífẹ̀ẹ́ rẹ tàbí tóo ti bá dájọ́ àjọròde fúngbà díẹ̀? Ó dára, wo àpẹẹrẹ ọ̀dọ́bìnrin kan nínú Bíbélì, tó wá láti ìgbèríko kan ní Àárín Ìhà Ìlà Oòrùn Ṣúnémù. Sólómọ́nì tó jẹ́ ọba rẹ̀ rí i, ìfẹ́ rẹ̀ sì kó wọ Sólómọ́nì lọ́kàn gidigidi. Àmọ́ nígbà tó ń gbìyànjú láti máa lé e kiri, kì í ṣe pé ọ̀dọ́bìnrin náà kọ̀ fún un nìkan ni àmọ́ ó tún bẹ àwọn obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ ní àgbàlá ọba náà pé: “Ẹ má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru sókè.” (Orin Sólómọ́nì 2:7) Omidan ọlọ́gbọ́n yìí kò fẹ́ káwọn ẹlòmíràn ti òun lọ ṣe ìpinnu kan nítorí ìgbónára lásán. Ìfẹ́ Sólómọ́nì kò kàn tiẹ̀ sí lọ́kàn rẹ̀ ni, nítorí ó ti nífẹ̀ẹ́ olùṣọ́ àgùntàn kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́.

Ẹ̀kọ́ pàtàkì lèyí jẹ́ fún àwọn tó ń wọ̀nà láti ṣègbéyàwó lónìí: Ìfẹ́ kì í ṣọ̀ràn ẹni o rí o bá lọ. Nítorí náà, àní lẹ́yìn tí obìnrin kan bá tiẹ̀ ti ń dájọ́ àjọròde pẹ̀lú ẹnì kan, ó lè rí i pé ìfẹ́ ẹni náà kò sí lọ́kàn òun. Ó lè jẹ́ pé àwọn èrò rẹ̀ dá lórí àwọn ìṣesí kan tó kù díẹ̀ káàtó tí ó rí nínú ìwà ẹni náà. Bóyá kẹ̀ ńṣe ni kò kàn tiẹ̀ wù ú. Ìwà òmùgọ̀ ló máa jẹ́ láti fọwọ́ rọ́ irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Pé o kàn rọ́ irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ tì kò túmọ̀ sí pé wọ́n máa lọ. d Tamara sọ nípa ẹnì kan tó ti ń fẹ́ rí pé: “Àìmọye nǹkan ló ń ṣe mí níyèméjì nípa rẹ̀. Kì í kàn í ṣe àwọn èrò pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ o, àmọ́ àwọn tó ń dà mí láàmú débi pé tí mo bá wà pẹ̀lú rẹ̀ ọkàn mi kì í balẹ̀.” Ó wá rí i pé, nítorí àwọn iyèméjì yìí, ohun tó dára jù lọ ni kóun fòpin sí àjọṣe náà.

Ohun Tó Máa Ń Mú Kí Ó Ṣòro Láti Kọ̀

Síbẹ̀, kì í rọrùn rárá láti sọ fún ọ̀dọ́kùnrin kan pé olúwarẹ̀ kò ṣe. Bíi ti Elizabeth táa mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀, ẹ̀rù lè máa bà ọ́ pé o ò fẹ́ ṣe ohun tó máa bà á lọ́kàn jẹ́. Lóòótọ́, ó yẹ ká bìkítà nípa ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn. Bíbélì gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn láti ‘fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú wọ ara wọn láṣọ’ kí wọ́n sì ṣe sáwọn ẹlòmíràn bí wọ́n ṣe máa fẹ́ kí wọ́n ṣe sáwọn náà. (Kólósè 3:12; Mátíù 7:12) Àmọ́ ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé kóo wá máa díbọ́n torí pé o ò fẹ́ já ọ̀dọ́kùnrin yìí kulẹ̀ tàbí pé o ò fẹ́ ṣe ohun tó máa bà á lọ́kàn jẹ́? Bópẹ́ bóyá, ó dájú pé ọ̀dọ́kùnrin náà á mọ ohun tóo ń rò lọ́kàn, ńṣe ni àìsọ òótọ́ lásìkò àti sísún tí o ń sún ọjọ́ tóo fẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún un síwájú á wulẹ̀ tún dá kún ìrora yẹn. Èyí tó máa wá burú jù ni pé kóo lọ fẹ́ ọ̀dọ́kùnrin yìí nítorí pé àánú rẹ̀ ń ṣe ọ́. Ṣíṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹnì kan nítorí pé àánú rẹ̀ ń ṣe ọ́ jẹ́ ìpìlẹ̀ burúkú láti kọ́ ìgbéyàwó lé.

Ó sì lè jẹ́ pé àwọn èrò kan wà tó ń jà gùdù lọ́kàn ẹ pé, ‘Tí mi ò bá fẹ́ ẹni yìí, mo mà lè máà rí ẹlòmíràn mọ́.’ Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Teen ṣe sọ ọ́, ọ̀dọ́bìnrin kan lè máa ronú pé: “Kì í ṣe ‘irú ọkùnrin yẹn lẹni tó wù mí láti fẹ́,’ àmọ́ òun lẹni tí mo rí ní báyìí—ìwọ sì rèé, o ò fẹ́ láti dá wà.” Kó sírọ́ níbẹ̀ pé ìfẹ́ láti ní alábàákẹ́gbẹ́ máa ń lágbára. Àmọ́, títẹ́ ìfẹ́ yìí lọ́rùn lọ́nà tó bójú mu ju wíwulẹ̀ fẹ́ ọ̀dọ́kùnrin èyíkéyìí. Ó kan rírí ẹnì kan tí wàá lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní tòótọ́ tó sì dáńgájíá láti mú àwọn ohun àìgbọ́dọ̀máṣe tí Ìwé Mímọ́ béèrè fún nínú ìgbéyàwó ṣẹ. (Éfésù 5:33) Nítorí náà, má fìkánjú ṣe ìpinnu láti fẹ́nì kan! Ọ̀pọ̀ ló ti kábàámọ̀ fífi ìkánjú ṣe ìgbéyàwó.

Síbẹ̀, àwọn kan ṣì lè máa fẹ́ ọ̀dọ́kùnrin kan lọ kódà lẹ́yìn tí wọ́n ti mọ̀ pé ó láwọn ìwà kan tí kò dára rárá. Wọ́n á ní ‘bí mó bá fún un lákòókò díẹ̀ sí i, ó ṣì lè yí padà.’ Ṣé èyí bọ́gbọ́n mu lóòótọ́? Ó ṣe tán, àwọn ìwà tí kò dára àti ìṣesí burúkú sábà máa ń dìídì jẹ́ apá kan èèyàn ni tó sì máa ń ṣòro púpọ̀ láti yí wọn padà. Ká tiẹ̀ wá sọ pé ó ṣe àwọn ìyípadà kan lójijì àti ní kíákíá, ṣe ó dá ọ lójú lóòótọ́ pé bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe máa báa lọ? Irú ipò kan bí èyí ló mú kí ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Karen fi ọgbọ́n pinnu láti jáwọ́ lọ́rọ̀ fífẹ́ ọ̀dọ́kùnrin kan nígbà tó rí i pé góńgó àwọn kò bára mu. Ó jẹ́wọ́ pé “kò rọrùn rárá, nítorí ìrísí rẹ̀ fà mí mọ́ra gan-an ni. Àmọ́ mo mọ̀ pé ohun tó tọ́ fún mi láti ṣe nìyẹn.”

Fọgbọ́n Ṣe É

Kò sí àní-àní pé kì í ṣe ohun tó rọrùn ni láti sọ fún ẹnì kan pé o ò ṣe. Ńṣe ló dà bí ẹrù kan tí ohun tó lè fọ́ wà nínú ẹ̀, o gbọ́dọ̀ fọgbọ́n ṣe é. Àwọn àbá kan rèé tó lè ṣèrànwọ́.

Jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwọn òbí rẹ tàbí ẹlòmíràn tó dàgbà dénú nínú ìjọ. Wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá ojú ẹ ló wà lókè jù.

Sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere kí o sì sojú abẹ níkòó. Má ṣe jẹ́ kí ọ̀dọ́kùnrin náà ní iyèméjì kankan lọ́kàn nípa bọ́ràn náà ti rí lára rẹ. Kìkì sísọ pé “Rárá, mi ò ṣe” ti tó láti mú kí ẹni yòówù tó ń wá ìyàwó jáwọ́. Bó bá pọndandan, là á mọ́lẹ̀ pé o ò ṣe, o lè sọ pé, “Ẹ má bínú o, àmọ́, mi ò fibì kankan nífẹ̀ẹ́ sí àjọṣe yìí.” Ṣọ́ra, kí o má lọ ṣe ohun kan tó máa fi hàn pé tó bá rọ̀ ẹ́ díẹ̀ sí i, o lè yíhùn padà. Jíjẹ́ kó ṣe kedere pé ìfẹ́ rẹ̀ kò sí lọ́kàn rẹ ti tó láti jẹ́ kí ohun tí o ń sọ yé e kí ìyẹn sì túbọ̀ mú un rọrùn fún un láti borí ìjákulẹ̀ rẹ̀.

Bóo ti ń sọ òótọ́ inú rẹ, fọgbọ́n ṣe é. Òwe 12:18 sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì láti sọ ojú abẹ níkòó, ohun tí Bíbélì sọ ni pé àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu wa gbọ́dọ̀ jẹ́ “pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.”—Kólósè 4:6.

Má yẹ ìpinnu rẹ. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí wọ́n lérò rere, tó jẹ́ pé wọ́n lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ àwọn ohun tó mú kóo ṣèpinnu tóo ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí i rọ̀ ọ́ pé kóo tún gbìyànjú ẹ̀ wò lẹ́ẹ̀kan sí i. Àmọ́ o, níkẹyìn, ìw àti ìpinnu tóo bá ṣe ló máa kù—kì í ṣe àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n rò pé dáadáa rẹ làwọ́n ń wá.

Jẹ́ kí ìṣesí rẹ bá ọ̀rọ̀ rẹ mu. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ẹ̀yin méjèèjì lè ti jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, ìwà ẹ̀dá sì ni pé kí ẹ ṣì fẹ́ kí nǹkan máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà, ìyẹn kì í ṣe ohun tó gbéṣẹ́ tàbí tó lè ṣeé ṣe mọ́. Ìwà rẹ̀ sí ọ ti mú ọ̀rọ̀ ìfẹ́ lọ́wọ́. Ṣé ó wá yẹ kí o rò pé ó lè wulẹ̀ gbàgbé àwọn èrò yẹn kó sì ṣe bí ẹni pé kò sí nǹkan kan? Nítorí náà, nígbà tó jẹ́ pé ó dára lóòótọ́ kẹ́yìn méjèèjì fún ara yín lọ́wọ̀, àfàìmọ̀ ni sísọ̀rọ̀ papọ̀ ṣáá lórí tẹlifóònù tàbí lílo ọ̀pọ̀ àkókò papọ̀ ní ẹ̀yin nìkan kò fi ní dá kún wàhálà rẹ̀. Ìyẹn lè dà bí ẹni pé ńṣe lo ń fi ìmọ̀lára rẹ̀ ṣeré, èyí kò sì ní fi àánú hàn.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni láti máa “sọ òtítọ́” pẹ̀lú ara wọn. (Éfésù 4:25) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ṣòro, àmọ́ ó lè ran ẹ̀yin méjèèjì lọ́wọ́ láti máa bá ìgbésí ayé yín nìṣó.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́bìnrin la darí àpilẹ̀kọ yìí sí ní tààràtà, àwọn ìlànà inú rẹ̀ wúlò fáwọn ọ̀dọ́kùnrin pẹ̀lú.

c Àwọn ewu tó wà nínú dídájọ́-àjọròde nígbà téèyàn ṣì kéré gan an la jíròrò nínú ìtẹ̀jáde ti February 8, 2001.

d Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ṣé Kí Awa Pínyàsọ́tọ̀ọ̀tọ̀ Ni?” tó jáde nínú Jí! ti January 22, 1989.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

Ìfẹ́ kì í ṣọ̀ràn ẹni o rí o bá lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Sọ èrò ọkàn rẹ jáde lọ́nà to ṣe kedere kí o sì sojú abẹ níkòó