Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Fa Ìṣòro—Àwọn Ìlú ńlá?

Kí Ló Fa Ìṣòro—Àwọn Ìlú ńlá?

Kí Ló Fa Ìṣòro—Àwọn Ìlú ńlá?

“Ó yá! Ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú ńlá kan dó fún ara wa kí a sì tún kọ́ ilé gogoro tí téńté rẹ̀ dé ọ̀run, . . . kí a má bàa tú ká sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 11:4.

ÀWỌN ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí wọ́n sọ ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọdún sẹ́yìn ni wọ́n fi kéde kíkọ́ ìlú ńlá tó ń jẹ́ Bábélì.

Bábélì tó di Bábílónì níkẹyìn ni wọ́n tẹ̀ dó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣínárì tó jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá nígbà kan rí, tí ó wà ní Mesopotámíà. Ìlú ńlá yìí kọ́ ni àkọ́kọ́ tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì bí ọ̀pọ̀ ti rò. Ní ti gidi, àwọn ìlú ńlá ti wà ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà. Kéènì apààyàn ló tẹ ìlú ńlá àkọ́kọ́ tó wà lákọọ́lẹ̀ dó. (Jẹ́nẹ́sísì 4:17) Bóyá ìlú ńlá náà, tí wọ́n pè ní Énọ́kù kàn lè fi díẹ̀ tóbi ju ibùdó tàbí abúlé lọ ni. Àmọ́ ìlú tó tóbi gan-an ni Bábélì ní tiẹ̀, òun sì ni ojúkò ìjọsìn èké tí ilé ìsìn tó ga fíofío kan sì wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n, ńṣe ni Bábélì àti ilé gogoro rẹ̀ tó lórúkọ burúkú náà takò Ọlọ́run lọ́nà tó bùáyà. (Jẹ́nẹ́sísì 9:7) Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, Ọlọ́run dá sọ́rọ̀ náà ó sì da àwọn kọ́lékọ́lé ọ̀hún lédè rú, èyí ló fòpin sí ète ọ̀kan wọn láti di olókìkí nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Jẹ́nẹ́sísì 11:5-9, sọ pé Ọlọ́run “tú wọn ká kúrò níbẹ̀ sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”

Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé títú táwọn èèyàn tú káàkiri yìí ló mú káwọn ìlú ńlá bẹ̀rẹ̀ sí tàn kálẹ̀. Ṣé bí ìlú bá kúkú tóbi, ó máa ń pèsè ààbò báwọn ọ̀tá bá gbógun dé. Àwọn ìlú ńlá máa ń pèsè àyè fún àwọn àgbẹ̀ láti kó àwọn irè oko sí kí wọ́n sì tún ríbi tà wọ́n. Ọ̀rọ̀ kárà-kátà tó sì dé ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ìlú ńlá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn nǹkan mìíràn yàtọ̀ sí iṣẹ́ àgbẹ̀ láti gbọ́ bùkátà ara wọn. Ìwé The Rise of Cities sọ pé: “Táwọn olùgbé ìlú ńlá bá ti lè bọ́ lọ́wọ́ ìgbésí ayé akúṣẹ̀ẹ́ tí wọ́n ń gbé, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe onírúurú iṣẹ́ ọwọ́ bíi: híhun apẹ̀rẹ̀, mímọ̀kòkò, rírànwú, híhunṣọ, fífi awọ dárà, ṣíṣe iṣẹ́ káfíńtà àti bíríkìlà—èyíkéyìí tó bá ti máa mówó wọlé.”

Ibi téèyàn ti lè ta irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ làwọn ìlú ńlá jẹ́. Gbé àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìyàn ńlá kan tó ṣẹlẹ̀ ní Íjíbítì yẹ̀ wò. Jósẹ́fù tó jẹ́ igbá kejì ọba rí i pé ó máa dáa káwọn èèyàn náà tẹ̀dó sáwọn ìlú ńlá. Kí ló dé? Ó hàn gbangba pé èyí yóò mú kí ìpínkiri oúnjẹ tó kù túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i.—Jẹ́nẹ́sísì 47:21.

Àwọn ìlú ńlá tún mú kí ètò ìbánisọ̀rọ̀ àti àjọṣe láàárín àwọn èèyàn túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i lákòókò tí ohun ìrìnnà kì í fi bẹ́ẹ̀ yára tí kò sì pọ̀. Èyí mú kí ìyípadà tó wáyé nínú ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ yára kánkán. Àwọn ìlú ńlá wá di ibi tí wọ́n ti ń hùmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí wọ́n sì ń gbé ìdàgbàsókè rẹ̀ lárugẹ. Bí àkọ̀tun èrò ṣe ń jẹ yọ, bẹ́ẹ̀ náà làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn nǹkan lọ́tun-lọ́tun nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ìsìn, àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí.

Ibi Tí Wọ́n Fojú Sí, Ọ̀nà Ò Gbabẹ̀

Àwọn ìlú ńlá ṣì ń báa lọ lóde òní láti pèsè àwọn àǹfààní tó pọ̀ bí irú èyí. Abájọ, nígbà náà tó fi jẹ́ pé àìmọye mílíọ̀nù èèyàn, àgàgà láwọn orílẹ̀-èdè tí ìgbésí ayé ò ti dẹrùn ni wọ́n máa ń fẹ́ lọ sáwọn ìlú ńlá. Àmọ́ ṣá, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ṣí lọ sáwọn ìlú ńlá ló jẹ́ pé ọwọ́ wọn kì í tẹ ìgbésí ayé tó sàn jù tí wọ́n fojú sọ́nà fún. Ìwé Vital Signs 1998 sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí Àjọ Tó Ń Rí sí Iye Ènìyàn ṣe, irú ìgbésí ayé táwọn èèyàn ń gbé ní ọ̀pọ̀ ìlú ńlá tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lónìí ló jẹ́ pé ó burú ju èyí táwọn tó wà láwọn ìgbèríko ń gbé lọ.” Kí ló mú kí ọ̀ràn náà rí bẹ́ẹ̀?

Henry G. Cisneros sọ nínú ìwé náà The Human Face of the Urban Environment pé: “Nígbà táwọn èèyàn tí kò rí já jẹ bá kórí jọ sí àgbègbè kan, ńṣe nìṣòro wọn á túbọ̀ máa bùyààrì sí i. . . . Bí iye àwọn tí kò rí já jẹ ṣe ń pọ̀ sí i, pàápàá jù lọ àwọn tí kò gbajúmọ̀ ti jẹ́ kí àìríṣẹ́ṣe ròkè lálá, iye èèyàn tó gbára lé àwọn ilé iṣẹ́ afẹ́dàáfẹ́re wá pọ̀ rẹpẹtẹ tó sì jẹ́ fún àkókò gígùn, ìṣòro àìlera gba ìlú kan, èyí tó sì ń múni ta gìrì níbẹ̀ ni ìwà ọ̀daràn tó gbalẹ̀ kan.” Ohun kan náà ni ìwé Mega-city Growth and the Future sọ pé: “Rírọ́ táwọn èèyàn ń rọ́ gìrọ́gìrọ́ lọ sáwọn ìlú ńlá ló máa ń fa ìṣòro àìríṣẹ́ṣe tó kọjá kèrémí, tí àwọn mìíràn ò sì ríṣẹ́ tó pójú owó ṣe nítorí pé iye àwọn èèyàn tó ń wáṣẹ́ pọ̀ ju iṣẹ́ tó wà níta lọ.”

Ńṣe làwọn ọmọdé tí wọ́n ti dọmọ asùnta ń pọ̀ sí i lọ́nà tó ń bani nínú jẹ́, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé ipò òṣì tó wà láwọn ìlú ńlá ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà kò ṣeé fẹnu sọ. Àwọn kan fojú bù ú pé nǹkan bí ọgbọ̀n mílíọ̀nù ọmọ asùnta ló wà lágbàáyé! Ìwé Mega-city Growth and the Future sọ pé: “Ipò òṣì àtàwọn ìṣòro mìíràn ti já okùn àjọṣe tó wà láàárín ìdílé tó fi di pé àwọn ọmọdé tí wọ́n di ọmọ asùnta ní láti lọ wá bí wọ́n ṣe máa tọ́jú ara wọn.” Ó di pé káwọn ọmọ wọ̀nyí máa ṣa nǹkan kiri lórí àkìtàn, kí wọ́n máa ṣagbe, tàbí kí wọ́n máa ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan lọ́jà kí wọ́n bàa lè máa gbé ìgbésí ayé òṣì àti àre wọn nìṣó.

Àwọn Nǹkan Mìíràn Tí Kò Dùn-Ún Gbọ́

Ipò òṣì lè fa ìwà ọ̀daràn. Ní ìlú ńlá kan tó ní àwọn ilé mèremère àtàwọn nǹkan tó jojú ní gbèsè ní Gúúsù Amẹ́ríkà, ìwà jàǹdùkú ti wọ́pọ̀ débi pé gádígádí làwọn èèyàn ń fi irin dí ojú fèrèsé àti ẹnu ọ̀nà wọn. Ńṣe làwọn aráàlú, látorí àwọn tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ títí kan àwọn tí wọ́n tòṣì jù lọ, bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ọgbà onírin láti dáàbò bo ara wọn àti dúkìá wọn. Èyí ti sọ wọ́n di ẹlẹ́wọ̀n ọ̀sán gangan. Káwọn mìíràn tiẹ̀ tó kọ́ ilé wọn tán ni wọ́n ti ṣe ọgbà onírin yí i ká.

Síwájú sí i, bí iye èèyàn tó wà ní ìlú ńlá kan bá pọ̀ gan an, èyí kò ní jẹ́ kí irú ìlú ńlá bẹ́ẹ̀ lágbára láti pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí bí omi àti ìmọ́tótó tó péye. Àwọn kan fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ní ìlú ńlá kan tó wà ní ilẹ̀ Éṣíà, wọ́n nílò ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] ilé ìgbọ̀nsẹ̀ gbogbo gbòò. Àmọ́ ṣá, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé kìkì igba péré ni ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀!

A ò gbọ́dọ̀ gbójú fo ipa tí kò dára tí àpọ̀jù èèyàn ń ní lórí àyíká. Bí ààlà àwọn ìlú ńlá ṣe ń gbòòrò sí i, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ilẹ̀ tí wọ́n fi ń dáko ń pòórá. Olórí Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè nígbà kan rí, Federico Mayor sọ pé: “Ohun àmúṣagbára táwọn ìlú ńlá ń lò pọ̀ kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ, gbogbo ìpèsè omi ni wọ́n á lò tán pátápátá, tí wọ́n á sì jẹ gbogbo oúnjẹ tán àtàwọn ohun èèlò. . . . Gbogbo ilẹ̀ tó wà láyìíká wọn ló ti ṣá pátápátá tí kò lè pèsè ohun táwọn èèyàn nílò tàbí ibi tí wọ́n lè da àwọn nǹkan tí ò wúlò sí.”

Àwọn Ìṣòro Ìlú Ńlá Ní Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ìwọ̀-Oòrùn Ayé

Ipò nǹkan ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé lè má fi bẹ́ẹ̀ burú, síbẹ̀ yánpọnyánrin tó máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn ìlú ńlá ṣì wà ńbẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ìwé náà The Crisis of America’s Cities sọ pé: “Ìwà jàǹdùkú tó gàgaàrá ló kún inú àwọn ìlú ńlá lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lónìí. . . . Ìwà jàǹdùkú láwọn ìlú ńlá orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà náà pọ̀ débi pé, àwọn ìwé ìròyìn ìṣègùn ti bẹ̀rẹ̀ sí fàyè kan sílẹ̀ nínú ìwé ìròyìn yìí láti fi kọ àwọn ìròyìn nípa ìwà jàǹdùkú gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ọ̀ràn ìlera pàtàkì ti ọjọ́ wa.” Òtítọ́ hán-ún ni pé ìwà jàǹdùkú jẹ́ ìṣòro kan tó ń bá ọ̀pọ̀ ìlú ńlá fínra káàkiri àgbáyé.

Bí ìgbésí ayé ní ìlú ńlá ṣe ń polúkúrúmuṣu sí i ló fà á tí àwọn agbanisíṣẹ́ ò fi fẹ́ràn ìlú ńlá mọ́. Ìwé The Human Face of the Urban Environment sọ pé: “Wọ́n ti kó okòwò lọ sí àrọko tàbí lọ sókè òkun, àwọn ilé iṣẹ́ ti di èyí tí wọ́n tì pa, kìkì ‘ilẹ̀ tí wọ́n ti ṣe níṣekúṣe ló kù’—àwọn ilé tó ṣófo ló wà lórí ilẹ̀ tí wọ́n ti sọ di eléèérí, pẹ̀lú àwọn èròjà onímájèlé tí wọ́n rì mọ́lẹ̀, gbogbo ìwọ̀nyí ò sì lè jẹ́ kí ìdàgbàsókè wà.” Àbájáde rẹ̀ ni pé, ní ọ̀pọ̀ ìlú ńlá, ibi táwọn èèyàn tí kò rí já jẹ pọ̀ sí jù ni àwọn àgbègbè “tàwọn èèyàn ò ti kọbiara sí ìṣòro ìbàyíkájẹ́—àwọn ibi tí kò sẹ́ni tó ń bójú tó àwọn pàǹtí ẹlẹ́gbin; tómi tó mọ́ gaara kò tó; táwọn eku àtàwọn kòkòrò ti máa ń tan àkìtàn tí wọ́n á sì tún gba ibi tí wọ́n ń gbé kan; táwọn ọmọ kéékèèké ti ń jẹ òjé inú ọ̀dà tí wọ́n fi kun àwọn ilé tó ti di ẹgẹrẹmìtì . . . níbi tó ti jẹ́ pé kóńkó jabele ni, kálukú ló ń ṣe tiẹ̀.” Ní irú àyíká bí èyí, ìwà jàǹdùkú, ìwà ipá, àti àìnírètí máa ń pọ̀ gan-an.

Kò tán síbẹ̀ o, kò rọrùn fáwọn ìlú ńlá ní orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé láti pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn fáwọn èèyàn. Lọ́dún 1981, Pat Choate àti Susan Walter tí wọ́n jẹ́ òǹkọ̀wé kọ ìwé kan tí wọ́n fún ní àkọlé tó gbàfiyèsí náà America in Ruins—The Decaying Infrastructure. Wọ́n sọ nínú ìwé náà pé: “Àwọn ìpèsè amáyédẹrùn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń yára bàjẹ́ sí i ju bí wọn ṣe ń tètè tún wọn ṣe lọ.” Àwọn òǹkọ̀wé yìí figbe bọnu nípa àwọn afárá tó ń dípẹtà, àwọn títì tó ń bàjẹ́, àti bí wọn ò ṣe bójú tó àwọn ìdọ̀tí mọ́ láwọn ìlú ńlá.

Ogún ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ìlú ńlá bíi New York ṣì ní àwọn ìpèsè amáyédẹrùn tó ti dìdàkudà. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn New York Magazine sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ gbígbẹ́ Ihò Omi Kẹta. Wọ́n ti dáwọ́ lé e láti nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn báyìí òun ni wọ́n sì pè ní “ohun amáyédẹrùn tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ kan ṣoṣo tí wọ́n tíì dáwọ́ lé ní Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé.” Owó tí wọ́n ti run sórí ẹ̀ ti tó nǹkan bíi bílíọ̀nù márùn-ún dọ́là. Bí wọ́n bá parí ẹ̀, ihò omi yìí á máa pèsè bílíọ̀nù mẹ́ta lítà omi fún New York City lójúmọ́. Òǹkọ̀wé náà sọ pé: “Ohun tó mú kí wọ́n máa gbẹ́ ihò àgbẹ́kúdórógbó yìí ò ju láti pèsè ihò omi táwọn èèyàn á máa lò nígbà tí wọ́n bá ń ṣàtúnṣe èyí tó ti wà tẹ́lẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ látìgbà tí wọ́n ti ṣe wọ́n ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún.” Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The New York Times ṣe sọ, ó máa ná wọn tó àádọ́rùn-ún bílíọ̀nù dọ́là láti ṣàtúnṣe àwọn ohun amáyédẹrùn tó kù tó ti di kọ̀ǹdẹ̀ nínú ìlú ńlá náà, àwọn bí àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀, àwọn páìpù tí ń gbé omi kiri, títì, àtàwọn afárá.

Kì í ṣe ìlú New York nìkan ló níṣòro pípèsè àwọn ohun kòṣeémánìí fáwọn aráàlú. Ní ti gidi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló fà á tí àwọn ìlú ńlá tó pọ̀ fi ń dìdàkudà. Ní February ọdún 1998, ṣìbáṣìbo bá ìlú Auckland ní New Zealand fún ohun tó lé ní ọ̀sẹ̀ méjì gbáko nítorí pé wọ́n mú iná mànàmáná lọ. Àwọn èèyàn tó ń gbé ní Melbourne ní Ọsirélíà, ni wọn ò rí omi gbígbóná lò fún odindi ọjọ́ mẹ́tàlá nígbà tí wọ́n ti gáàsì pa nítorí ìjàǹbá tó ṣẹlẹ̀ nílé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ṣe àwọn nǹkan jáde.

Ìṣòro kan tún wà o, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìlú ńlá ló kàn, ìyẹn ni súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀. Moshe Safdie tó jẹ́ ayàwòrán ilé sọ pé: “Ìforígbárí tó lágbára, tí kò dára rárá ń bẹ láàárín àwọn ìlú ńlá àti ètò ìrìnnà inú wọn. . . . Ó ti wá di pé káwọn ìlú ńlá tí wọ́n ti wà látọjọ́ pípẹ́ wá tún àwọn àgbègbè ìṣòwò wọn kọ́ lọ́nà tó fi máa láyè tí ó tó fún ètò ìrìnnà ọkọ̀ èyí tí wọn ò tiẹ̀ ronú kàn nígbà tí wọ́n ń kọ́ àwọn ilé náà tẹ́lẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The New York Times ṣe sọ, “ojoojúmọ́ ayé” ni súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ máa ń wáyé láwọn ìlú ńlá bíi Cairo, Bangkok, àti São Paulo.

Pẹ̀lú gbogbo àwọn ìṣòro tó pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní yìí, àwọn èèyàn ò mà yéé rọ́ gìrọ́gìrọ́ lọ sáwọn ìlú ńlá o. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The UNESCO Courier sọ pé, “ó dáa o, kò dáa o, ó jọ pé ìlú ńlá ń mú káwọn èèyàn gbérí kí wọ́n sì lómìnira, ó ń fún wọn láǹfààní, ó sì ń fa àwọn èèyàn mọ́ra púpọ̀púpọ̀.” Àmọ́ báwo lọjọ́ iwájú àwọn ìlú ńlá lágbàáyé ṣe máa rí? Ǹjẹ́ ojútùú kankan tiẹ̀ wà sáwọn ìṣòro wọn?

Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

“Rírọ́ táwọn èèyàn ń rọ́ gìrọ́gìrọ́ lọ sáwọn ìlú ńlá ló máa ń fa ìṣòro àìríṣẹ́ṣe tó kọjá kèrémí, táwọn mìíràn ò sì ríṣẹ́ tó pójú owó ṣe”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọ̀pọ̀ ìlú ńlá ni súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ń bá fínra

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn ọmọ asùnta ló jẹ́ pé fúnra wọn ni wọ́n ń wá bí wọ́n á ṣe tọ́jú ara wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ibi tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ìlú ńlá fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀