Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 25. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)

1. Kí lorúkọ tí wọ́n ń pe ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ti àwọn Júù? (Ìṣe 5:27)

2. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Jòhánù ti tọ́ka sí i, àárín àkókò wo ni Jésù mú àwọn ohun kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ète Ọlọ́run wá sí ìparí aláṣeyọrísírere? (Ìṣípayá 1:10)

3. Àwọn ohun ìjà mẹ́ta wo ló wà lọ́wọ́ Gòláyátì nígbà tó wá bá Dáfídì jà? (1 Sámúẹ́lì 17:45)

4. Ta ni aya Hóséà? (Hóséà 1:3)

5. Ta lẹni tó wá mọ̀ pé àwọn ará Síríà tó sàga ti Samáríà ti fẹsẹ̀ fẹ? (2 Àwọn Ọba 7:3-5)

6. Kí lóhun tí Ahasuwérúsì ọba Páṣíà yọ̀ǹda ní gbogbo ilẹ̀ àkóso rẹ̀ lásìkò tó fi Ẹ́sítérì ṣe ayaba rẹ̀? (Ẹ́sítérì 2:18)

7. Kété lẹ́yìn tí Jèhófà dá Ádámù, kí ló sọ pé kò dára fún un? (Jẹ́nẹ́sísì 2:18)

8. Kí ni Jèhófà pàṣẹ pé kí Jóṣúà ṣe fáwọn ẹṣin tó jẹ́ ti àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì, tó tipa bẹ́ẹ̀ fún Ísírẹ́lì níṣìírí láti gbára lé Jèhófà fún ààbò? (Jóṣúà 11:6)

9. Kí lohun tó lè yí ìbínú padà? (Òwe 15:1)

10. Kí ló dé tí ọ̀pọ̀ lára àwọn sáàmù fi ní àkọlé níwájú? (Sáàmù 3-9)

11. Ọ̀rọ̀ wo ni Jóòbù lò láti fi hàn gbangba pé òun yèbọ́ láìsí ohun kankan tó ṣẹ́ kù fóun? (Jóòbù 19:20)

12. Ilé ta ni Jésù wà nígbà táwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí fẹ̀sùn kàn án pé ó ń jẹ ó sì ń mu pẹ̀lú àwọn agbowó orí àtàwọn ẹlẹ́ṣẹ̀? (Lúùkù 5:29, 30)

13. Apá wo lára ẹran tí wọ́n fi ṣèrúbọ ni Òfin Mósè kà léèwọ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ? (Léfítíkù 7:23-25)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Sànhẹ́dírìn

2. “Ọjọ́ Olúwa”

3. Idà, ọ̀kọ̀, àti ẹ̀ṣín

4. Gómérì

5. Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́rin

6. Ìdáríjì ọba

7. Láti “máa wà nìṣó ní òun nìkan”

8. Láti já àwọn ẹṣin wọn ní pátì kí ó sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn

9. Ìdáhùn pẹ̀lẹ́

10. Láti dá ẹni tó kọ ọ́ mọ̀, láti pèsè ìtọ́ni lórí ohùn orin, àti láti pèsè àlàyé ìpìlẹ̀ tàbí ète tí wọ́n fi kọ sáàmù náà

11. “Awọ eyín mi”

12. Ilé Léfì, tàbí Mátíù

13. Ọ̀rá