Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Ìjà Kéékèèké, Ìṣòro Ńláńlá

Ohun Ìjà Kéékèèké, Ìṣòro Ńláńlá

Ohun Ìjà Kéékèèké, Ìṣòro Ńláńlá

FÚN ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, orí ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé lọ̀rọ̀ bí nǹkan ìjà ṣe máa kásẹ̀ ńlẹ̀ dá lé. Èyí ò sì fi bẹ́ẹ̀ ya èèyàn lẹ́nu, níwọ̀n bí ẹyọ bọ́ǹbù kan ti lè pa odindi ìlú ńlá kan run. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, láìdàbí àwọn ohun ìjà kéékèèké, ó ti lé ni àádọ́ta ọdún báyìí tí wọ́n ti lo àwọn ohun ìjà alágbára ńlá yẹn gbẹ̀yìn nínú ogun.

John Keegan, òpìtàn ológun kan tá ò lè fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn kọ̀wé pé: “Àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kò tíì pa ẹnì kankan látọjọ́ kẹsàn-án oṣù Kẹjọ, ọdún 1945 wá. Àádọ́ta mílíọ̀nù àwọn tó ti kú nínú ogun látìgbà yẹn wá ló jẹ́ pé àwọn ohun ìjà tí ò lówó lórí, tí wọ́n ṣe jáde ní yanturu, àtàwọn ọta kéékèèké tówó wọn ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́n ju tàwọn rédíò àtẹ̀bàpò àti bátìrì wọn lọ, tó ti kúnnú ayé báyìí ló ń pa wọ́n. Nítorí pé àwọn ohun ìjà olówó pọ́ọ́kú kì í fi bẹ́ẹ̀ gbẹ̀mí àwọn èèyàn láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, àyàfi láwọn ibì kọ̀ọ̀kan tí títa oògùn olóró àti ìpayà ọ̀rọ̀ òṣèlú ti wọ́pọ̀, nítorí bẹ́ẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ yìí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ohun tí lílo àwọn irinṣẹ́ panipani yìí ti dá sílẹ̀ lẹ́nu ìgbà tí wọ́n ti mú wọn jáde.”

Kò sẹ́ni tó lè sọ pé iye báyìí làwọn ohun ìjà kéékèèké àtèyí tó rọrùn láti lò tó wà lọ́wọ́ àwọn èèyàn, àmọ́ àwọn ògbógi fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, àwọn ìbọn bí i ti ológun lè máa lọ sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] mílíọ̀nù. Láfikún síyẹn, àìmọye àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìbọn àgbéléjìká àtàwọn ìbọn ìléwọ́ àgbélérọ làwọn aráàlú tún ní lọ́wọ́. Síwájú sí i, wọn ò dáwọ́ ṣíṣe àwọn ohun ìjà yìí dúró o, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń kó wọn wá sọ́jà fún títà lọ́dọọdún.

Àwọn Ohun Ìjà Táwọn Èèyàn Yàn Láàyò

Kí ló mú káwọn ohun ìjà kéékèèké di èyí táwọn èèyàn yàn láàyò nínú àwọn ogun lọ́ọ́lọ́ọ́? Ìjà tó ń ṣẹlẹ̀ àti ipò òṣì wà lára àwọn ìdí tó fà á. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ogun tí wọ́n jà láwọn ọdún 1990 ló jẹ́ pé láwọn orílẹ̀-èdè to tòṣì ni wọ́n ti jà wọ́n—tí wọ́n tòṣì débi pé wọn ò lágbára láti ra ohun ìjà ìgbàlódé. Àwọn ohun ìjà kéékèèké àtàwọn tó rọrùn láti lò kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́n. Fún àpẹẹrẹ, àádọ́ta mílíọ̀nù dọ́là, tó jẹ́ pé òun ló máa tó ra ọkọ̀ ogun òfuurufú kan ti tó láti ra ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] ìbọn àgbéléjìká fáwọn tó fẹ́ jagun.

Nígbà míì, èèyàn máa ń rí àwọn ohun ìjà kéékèèké àtàwọn tó rọrùn láti lò yìí rà lọ́pọ̀kúyọ̀kú. Ọ̀pọ̀ jaburata àwọn ohun ìjà yìí ló jẹ́ pé àwọn ológun kan tó ń dín ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn àtàwọn ohun ìjà wọn kù kàn máa ń fi tọrẹ, tàbí kẹ̀ káwọn èèyàn máa tún wọn lò látinú ogun kan sí òmíràn. Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn nǹkan ìjà yìí pọ̀ débi pé, dọ́là mẹ́fà péré ni wọ́n ń tà wọ́n, wọ́n sì lè fi ewúrẹ́ kan, adìyẹ, tàbí àpò aṣọ kan tó ti gbó rà wọ́n.

Síbẹ̀, láìfi ti bí owó wọn kò ṣe wọ́n àti bí wọ́n ṣe wà káàkiri pè, àwọn ìdí kan tún wà tó mú káwọn ohun ìjà kéékèèké ọ̀hún gbayì bẹ́ẹ̀. Olóró ni wọ́n. Tí wọ́n bá ṣíná ìbọn àgbéléjìká kan bolẹ̀, ó lè yin ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọta láàárín ìṣẹ́jú kan láìdáwọ́dúró. Ó tún rọrùn láti lò àti láti ṣètọ́jú wọn. Wọ́n lè kọ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá kan ní bí wọ́n ṣe ń tú ìbọn àgbéléjìká kan palẹ̀ àti bí wọ́n ṣe ń dè é padà. Ọmọ kékeré kan tún lè tètè mọ bí wọ́n ṣe ń na ìbọn sáàárín èrò kó sì yìn ín.

Nǹkan mìí tó tún mú káwọn ìbọn yìí wọ́pọ̀ ni pé, ẹ̀mí wọn máa ń yi, wọ́n sì lè máa ṣiṣẹ́ lọ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Wọ́n ṣì ń lo àwọn ìbọn àgbéléjìká irú bíi AK-47 àti M16 táwọn jagunjagun lò nígbà Ogun Vietnam nínú àwọn ogun tí wọ́n ń jà lónìí. Àwọn ìbọn kan tí wọ́n ń lò ní Áfíríkà ló jẹ́ pé àtìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní ni wọ́n ti ṣe wọ́n. Láfikún sí i, ó rọrùn láti kó ìbọn láti ibì kan sí ibòmíràn àti láti fi wọ́n pa mọ́. Ẹṣin kan tí wọ́n di ìbọn rù dáadáa lè kó bíi méjìlá lọ síbi táwọn ọmọ ogun wà nínú igbó kìjikìji kan tàbí lórí òkè jíjìnnà kan. Ọ̀wọ́ àwọn ẹṣin kan sì lè kó ìbọn tó máa tóó lò fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan.

Àjọṣe Tó Wà Láàárín Ìbọn, Oògùn Líle, àti Dáyámọ́ńdì

Iṣẹ́ ńlá gbáà ni iṣẹ́ kíkó ìbọn kiri lágbàáyé jẹ́. Wọ́n máa ń kó ọ̀pọ̀ ìbọn láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn lọ́nà tó bófin mu. Lẹ́yìn tí Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ parí ní Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn ayé, àwọn ìjọba dín àwọn ológun wọn kù, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn nǹkan ìjà wọn tó pọ̀ lápọ̀jù tọrẹ fáwọn tí wọ́n fẹ́ràn tàbí kí wọ́n tà á fún wọn. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí òǹkọ̀wé kan ní Ilé Ẹ̀kọ́ fún Wíwá Àlàáfíà tó wà ní Oslo, lórílẹ̀-èdè Norway kọ, láti ọdún 1995, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan ṣoṣo ti fi àwọn ìbọn àgbéléjìká, ìbọn ìléwọ́, ẹ̀rọ arọ̀jò ọta, àtàwọn bọ́ǹbù àfọwọ́jù tó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] tọrẹ. Wọ́n ronú pé fífi àwọn ohun ìjà yìí tọrẹ kò lè ná àwọn lówó tó káwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ máa tú wọn palẹ̀ tàbí máa kó wọn pa mọ́, káwọn sì tún máa dáàbò bò wọ́n. Àwọn tó ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ẹ̀ fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, ó ṣeé ṣe kí owó àwọn ohun ìjà kéékèèké àtèyí tó rọrùn láti lò tó ń gba ẹnubodè kọjá lọ́dọọdún, tó sì jẹ́ lọ́nà tó bófin mu tó bílíọ̀nù mẹ́ta dọ́là.

Àmọ́ o, èyí tí wọ́n ń tà lọ́nà tí kò bófin mu tiẹ̀ tún lè pọ̀ jùyẹn lọ fíìfíì. Títà ni wọ́n sábà máa ń ta àwọn ohun ìjà tí wọ́n bá fi fàyàwọ́ kó wọlé. Nínú àwọn ogun kan tí wọ́n jà nílẹ̀ Áfíríkà, kì í ṣe owó làwọn ẹgbẹ́ ológun fi ra àwọn ohun ìjà kéékèèké àtèyí tó rọrùn láti lò tówó wọn tó ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù dọ́là o, àwọn dáyámọ́ńdì tí wọ́n jí kó lágbègbè tí wọ́n ti ń wà á ni wọ́n fi rà á. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Níbi táwọn olùṣàkóso bá ti ń hùwà ìbàjẹ́, àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ kì í lójú àánú, bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe máa ń rọrùn tó láti gba àwọn ẹnubodè kọjá . . . Dáyámọ́ńdì ti wá di ohun tó fa ìsìnrú, ìpànìyàn, gígé ẹ̀yà ara èèyàn, àìrílégbé tó pọ̀ jáǹrẹrẹ àti ètò ìṣòwò tó ti wógbá.” Ẹ ò ri pé ohun ẹ̀gàn gbáà ni pé, òkúta iyebíye kan tí wọ́n fi san owó ìbọn àgbéléjìká ni wọ́n tún wá ń tà lówó gọbọi nínú ṣọ́ọ̀bù ohun ọ̀ṣọ́ láti lò ó gẹ́gẹ́ bí ohun àmì fún ìfẹ́ tí kò lópin!

Àjọṣe kan tún wà láàárín àwọn ohun ìjà àtàwọn oògùn líle tí wọ́n ń tà láìbófinmu. Kì í ṣe nǹkan tuntun láti rí àwọn àjọ ọ̀daràn kí wọ́n máa ṣe fàyàwọ́ oògùn líle kí wọ́n sì máa fi ṣe pàṣípààrọ̀ fún ìbọn. Ìyẹn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ àwọn ohun ìjà di owó tí wọ́n fi ń ra oògùn líle.

Ibi Táwọn Ohun Ìjà Ń Kẹ́yìn sí Lẹ́yìn Ogun

Bógun bá ti parí, ọwọ́ àwọn ọ̀daràn làwọn ìbọn tí wọ́n lò nínú ogun sábàá máa ń balẹ̀ sí. Ìwọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè kan lápá gúúsù Áfíríkà, tó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe bọ́ nínú wàhálà òṣèlú tán ni wọ́n tún kó sí tàwọn ọ̀daràn. Ìwà ipá òṣèlú gbẹ̀mí àwọn èèyàn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] láàárín ọdún mẹ́ta péré. Nígbà tí wàhálà yẹn dópin, ni ìwà ipá tàwọn ọ̀daràn bá di èyí tó búrẹ́kẹ́. Ìbáradíje láàárín àwọn awakọ̀ takisí yọrí sí “ogun takisí,” ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí i háyà àwọn jàǹdùkú láti máa yìnbọn pa àwọn èrò ọkọ̀ àtàwọn awakọ̀ iléeṣẹ́ tí wọ́n ń bára wọn díje ọ̀hún. Wọn ò bojú wẹ̀yìn bí wọ́n ti ń lo àwọn ìbọn àgbéléjìká ti àwọn ológun fún ìdigunjalè àtàwọn ìwà ọ̀daràn mìíràn. Lọ́dún àìpẹ́ yìí, iye àwọn tí wọ́n fìbọn pa wọ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá [11,000], ìyẹn ni iye tó ṣì ga jù lọ ṣìkejì láwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ò jagun tí wọ́n sì ń para wọn bẹ́ẹ̀.

Mímọ̀ pé àwọn ọ̀daràn máa ń dìhámọ́ra tí wọ́n sì jẹ́ eléwu máa ń kó ìbẹ̀rù àti jìnnìjìnnì báwọn èèyàn. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, inú odi ni ká kúkú sọ pé àwọn ọlọ́rọ̀ ibẹ̀ ń gbé, tí wọ́n á mọ ògiri tòun ti fẹ́ǹsì tí iná mànàmáná wà lára ẹ̀ yíra wọn ká, tí wọ́n á sì tún máa ṣọ́ ọ tọ̀sántòru. Àwọn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà náà kò túra sílẹ̀ o. Bọ́rọ̀ sì tún ṣe rí pàápàá nìyẹn láwọn ibi tí ogun kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í jà.

Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àti ilẹ̀ tí ogun wà àti èyí tí ogun “kò sí” ni ìbọn ti ń dá kún àìsí ìfọ̀kànbalẹ̀. Kò sẹ́dàá èèyàn náà tó lè díwọ̀n bí iṣẹ́ ibi tí ìbọn ń ṣe ti pọ̀ tó; bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mọ bí iye àwọn tó ti kú, àwọn tó ti ṣèṣe, àwọn tí ọ̀fọ̀ ti ṣẹ̀, àtàwọn tí ìbọn ti fọ́ ìgbésí ayé wọn yángá ṣe pọ̀ tó. Síbẹ̀, a mọ̀ pé dẹ́múdẹ́mú làwọn nǹkan ìjà kúnnú ayé, tí iye wọn sì túbọ̀ ń ròkè sí i. Ńṣe làwọn tó ń pariwo pé kí wọ́n wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ ọ̀hún túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àmọ́ kí ni wọ́n lè ṣe sí i? Kí ni wọn yóò ṣe? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Oníjà Tẹ́lẹ̀ Rí Kan Rí I Pé “Ìwà Ẹ̀gọ̀ Pátápátá Gbáà” Lòún Hù

Ọmọdékùnrin kan tó jẹ́ sójà, tó jà nínú ogun tó sọ àwọn táa sọ̀rọ̀ wọn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ dẹni tó sá kúrò nílùú, ṣàdédé rí ara rẹ̀ tó dẹni tí kò ríkan-ṣèkan mọ́ tí kò sì ní kọ́bọ̀ lọ́wọ́ nínú ìlú tó ti bá wọn jà láti gbà. Pẹ̀lú ìbànújẹ́ kíkorò ló fi ń sọ nípa rírí tó rí ọmọ aṣáájú rẹ̀ kan tó ń gun alùpùpù olówó gegere kiri ìlú, táwọn tó sì jẹ́ ọ̀gá nínú ìjà náà nígbà yẹn náà ń jẹ ara wọn lẹ́sẹ̀ nítorí agbára, tí wọ́n sì bára wọn díje láti dọ̀gá. Oníjà náà sọ pé: “Nígbà tí mo ronú nípa ọdún márùn-ún tí mo lò nínú igbó, tí mo ń pa àwọn èèyàn tí wọ́n sì ń yìnbọn sí mi, mo rí i pé ìwà ẹ̀gọ̀ pátápátá gbáà ni mo hù. A wulẹ̀ ń lo ìgbésí ayé tiwa lásán fáwọn tó jẹ́ pé tó bá dọ̀la, wọn ò ní rántí bí wọ́n ṣe dépò tí wọ́n wà ni.”

[Credit Line]

Ọmọdékùnrin tó jẹ́ sójà: Nanzer/Sipa Press

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

“Kò Síbi Tóo Lè Sá Pa Mọ́ Sí”

Bó ti wá wù káwọn ohun ìjà tí wọ́n ń lò lóde òní lóró tó, ó níbi tágbára wọ́n mọ. Ọta nìkan ni wọ́n ń yìn jáde. Wọn ò lè pa àwọn èèyàn tí wọ́n sá sẹ́yìn ògiri lílágbára tàbí sẹ́yìn odi. Tí jìnnìjìnnì ìjà bá sì mú sójà kan, ìbọn ẹ̀ lè má ṣe déédéé ibi tó nà án sí. Ká tiẹ̀ ní kò sí nǹkankan tó dí i lọ́wọ́, gbogbo ibi tí ọta yẹn lè rìn dé kò ju ọ̀tà lé nírínwó [460] mítà lọ.

Ẹgbẹ́ ológun Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti wá ojútùú sírú “àwọn ìṣòro” yẹn—ìbọn àgbéléjìká tuntun kan, tí wọ́n fọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga ṣe, tí kò sóhun tí kò lè ṣe tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ohun Ìjà Tó Kóhun Gbogbo Já (OICW) ti dé báyìí o. Ó fúyẹ́ débi pé sójà kan ṣoṣo lè lò ó, kì í ṣe ọta nìkan ni OICW ọ̀hún ń yìn o, ó tún máa ń yin àwọn nǹkan onímìlímítà ogún tó ń bú gbàù—ìyẹn àwọn bọ́ǹbù kéékèèké. Ohun àrà tí kò lẹ́gbẹ́ kan tó tún lè ṣe nìyí: Ó lè pa ọ̀tá tó sá pa mọ́ sẹ́yìn odi. Gbogbo ohun tí sójà náà á ṣe kò ju kó na ìbọn rẹ̀ sókè tàbí sẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tẹ́ni tó fẹ́ yìn ín fún dúró sí. Fúnra ìbọn yẹn ló máa wọ́nà dé ọ̀dọ̀ ẹni yẹn, tí yóò to àwọn nǹkan tín-tìn-tín abánáṣiṣẹ́ sínú àwọn bọ́ǹbù kéékèèké náà, táá sì wá bú nígbà tó yẹ gan an, ní dídáná àwọn bọ́ǹbù náà bo ẹni yẹn. Ẹnì kan tó jẹ́ aṣojú fún iléeṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ lórí ohun ìjà náà sọ pé: “Agbára aláìlẹ́gbẹ́ tó ní yìí yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà láti kàn máa yìnbọn síbikíbi tó bá wù wọ́n ni.” Awò ojú lílágbára tí ohun ìjà náà tún ní á jẹ́ kó lè ṣiṣẹ́ dáadáa kódà nínú òkùnkùn pàápàá.

Àwọn tó ṣe é fi ìyangàn sọ pé, ní ti ìbọn yìí o, “kò síbi tóo lè sá pa mọ́ sí,” wọ́n tún sọ pé ìlọ́po márùn-ún ni ohun ìjà yìí fi lóró ju M16 lọ, tó sì fi ìlọ́po méjì ju ti ìbọn ajubọ́ǹbù M203 lọ. Àwọn sójà tó ń lò ó kò ní láti bẹ̀rù bóyá kò ní ṣe déédéé ibi tí àwọ́n nà án sí; kí wọ́n ṣáà ti wo inú awò ojú yẹn kí wọ́n sì yìn ín láti dáná ọta àti bọ́ǹbù inú ẹ̀ bolẹ̀ ni. Tí gbogbo nǹkan bá lọ níbàámu pẹ̀lú ètò wọn, wọ́n á lo OICW yìí fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 2007.

Àmọ́, àwọn olùṣelámèyítọ́ wá ń béèrè àwọn ìbéèrè kan o: Báwo làwọn sójà ṣe máa lè lo ìbọn yìí láàárín èrò ládùúgbò kan táwọn ọ̀tá tí wọ́n ń bá jà ti dàpọ̀ mọ́ àwọn aráàlú tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í ta OICW náà fáwọn ológun jákèjádò ayé, táwọn ìyẹn sì lè kọjú ẹ̀ sáwọn èèyàn tiwọn fúnra wọn? Àti pé kí lò máa tún ṣẹlẹ̀ tí ohun ìjà náà bá lọ bọ́ sọ́wọ́ àwọn akópayàbáni àtàwọn ọ̀daràn?

[Credit Line]

Alliant Techsystems

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Wọn sábà máa ń ta àwọn ohun ìjà kéékèèké ní pàṣípààrọ̀ fún dáyámọ́ńdì àti oògùn olóró