Sísọ Aṣálẹ̀ Di Ilẹ̀ Eléso
Sísọ Aṣálẹ̀ Di Ilẹ̀ Eléso
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN Jí! NÍ ÍŃDÍÀ
Báwo làwọn àgbègbè aṣálẹ̀ Ladakh, àdúgbò kan níhà àríwá Íńdíà ṣe lè di èyí tó túbọ̀ ń méso jáde? Ìbéèrè yìí ló gba Tsewang Norphel, ẹnjiníà kan tó ti fẹ̀yìn tì lọ́kàn. Omi tó ń ṣàn wá látinú ìṣàn yìnyín tó wà lórí Òkè Ńlá Himalaya máa ń bẹ̀rẹ̀ dídà ní oṣù June, kì í dà lóṣù April nígbà tí òjò kì í fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ táwọn àgbẹ̀ sì nílò omi láti bomi rin oko wọn. Norphel bá wọn rí ojútùú kan tó gbéṣẹ́: Ìyẹn ni pé kí wọ́n kọ́ ìṣàn yìnyín àtọwọ́dá kan sí apá ìsàlẹ̀ ibi tí yìnyín ti máa ń kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í yòrò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Íńdíà náà The Week ṣe sọ, Norphel àtàwọn alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ dídarí omi orí òkè ńlá kan gba ojú odò àtọwọ́dá kan tó gùn ní igba mítà tó sì ya sí àádọ́rin ọ̀nà. Látibẹ̀ lomi yìí ti rọra ń ṣàn lọ gba gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ńlá náà ní ìwọ̀n tó ṣeé darí, tí yóò sì ti dì kí ó tó dé ibi ògiri tí wọ́n mọ láti dá a dúró nísàlẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ńlá náà. Díẹ̀díẹ̀, yìnyín yìí á gbára jọ di ìṣàn yìnyín àtọwọ́dá, tí yóò sì wá bo ògiri náà mọ́lẹ̀ níkẹyìn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé abẹ́ òjìji òkè ńlá náà ni ìṣàn yìnyín yìí wà, ó dìgbà tí ìwọ̀n ooru bá lọ sókè ní oṣù April kí ó tó yòrò, táá sì wá pèsè omi tí wọ́n nílò gidigidi láti fi bomi rinlẹ̀ lásìkò yẹn.
Ǹjẹ́ èròǹgbà kíkọ́ ìṣàn yìnyín àtọwọ́dá náà yọrí sí rere? Ká sọ tòótọ́, èrò Norphel yìí ṣiṣẹ́ gan an ni, débi pé, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, irú àwọn ìṣàn yìnyín bẹ́ẹ̀ mẹ́wàá ni wọ́n ti kọ́ sí Ladakh, iṣẹ́ sì tún ń lọ lọ́wọ́ láti kọ́ sí i. Irú ìṣàn yìnyín yìí kan tí wọ́n kọ́ bẹ́ẹ̀, tí gíga rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan, ọ̀ọ́dúnrún ó lé mọ́kànléláàádọ́rin [1,371] mítà ń pèsè omi tó tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lítà. Kí ló sì ná wọn? Ìwé ìròyìn The Week sọ pé: “Ṣíṣe ìṣàn yìnyín àtọwọ́dá kan máa ń gba nǹkan bí oṣù méjì, tó sì ń náni ní ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀sán [1,860] dọ́là, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú owó yìí ló jẹ́ owó táa san fáwọn òṣìṣẹ́.”
Ó dájú pé ọgbọ́n ìhùmọ̀ ènìyàn, nígbà tí wọ́n bá lò ó lọ́nà tó tọ́ lè ṣàǹfààní. Ìwọ tiẹ̀ wo ohun tó kàmàmà tí aráyé yóò gbé ṣe lábẹ́ ìdarí Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run! Bíbélì ṣèlérí pé: “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì. . . . Omi yóò ti ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀.” (Aísáyà 35:1, 6) Ohun ìdùnnú gbáà ló máa jẹ́ o láti kópa nínú sísọ ilẹ̀ ayé wa di ẹlẹ́wà!
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
Arvind Jain, Ìwé Ìròyìn The Week