Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Ìyà Àìsíwèé Ń Jẹ Ibi Ìkówèésí Tuntun ní Alẹkisáńdíríà

Arabarìbì ibi ìkówèésí ní Alẹkisáńdíríà ni ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé “ó lókìkí fún níní gbogbo ìwé tó ní í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ ènìyàn pátá lákòókò Kristi, . . . àmọ́ iná jó o kanlẹ̀ lọ́dún 47 Ṣáájú Sànmánì Tiwa tó sì wá dàwátì yán-án-yán lọ́dún 7 Sànmánì Tiwa.” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Áráàbù mìíràn àti látọ̀dọ̀ Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ilẹ̀ Íjíbítì ti kọ́ ibi ìkówèésí tuntun míì sí Alẹkisáńdíríà èyí tó retí pé yóò gbayì ju tàkọ́kọ́ lọ. “Ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ni àjà mẹ́rin àkọ́kọ́ wà. Ìkùdu omi tó ń dán yinrin yí ibi ìkówèésí yìí ká, ó ní ẹ̀rọ agbéniròkè mẹ́tàdínlógún, ó ní àwọn fèrèsé tó ń fọ ara wọn mọ́ àti ètò ààbò kan tó lágbára débi pé tíná bá jó, ó lè pa á láìsí pé ó ń fi ẹ̀kán omi kan sílẹ̀ lára ìwé kankan.” Àmọ́ o, ìwé ìròyìn The Wall Street Journal náà ń báa lọ pé, “nǹkan pàtàkì kan wà tó bu ilé ìkówèésí yìí kù. Ìyẹn ni ìwé.” Ìwé ìròyìn náà fi kún un pé lẹ́yìn tí wọ́n ti ná ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù dọ́là láàárín ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n fi kọ́ ọ, “owó tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ríra ìwé sínú ibi ìkówèésí tuntun náà kéré débi pé, . . . Mohsen Zahran tó jẹ́ ọ̀gá ibẹ̀ ní láti lọ máa tọrọ ìwé tó jẹ́ pé kìkì iyì tí wọ́n ní kò ju pé ọ̀fẹ́ ni wọ́n fún wọn lọ.” Ọ̀gbẹ́ni Zahran sọ pé àwọn ò wulẹ̀ wá alábòójútó fún ibi ìkówèésí náà nítorí pé “apá [àwọn] kò ní ká sísanwó oṣù ẹni náà.” Ibi ìkówèésí náà ní àyè tó pọ̀ tó láti gba ìdìpọ̀ ìwé tó jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́jọ.

Ìrora Láìsọ́gbẹ́

Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Àwọn èèyàn tí ẹsẹ̀ wọn kán tàbí tí apá wọn ti gé kúrò sábàá máa ń ní ìrora lílekoko tó jọ pé ó ń wá látinú ẹsẹ̀ tàbí apá tí kò sí mọ́ náà, tàbí kí wọ́n mọ̀ ọ́n lára tẹ́nì kan bá fọwọ́ kan ojú ẹsẹ̀ tàbí apá tó ti gé kúrò náà.” Ìwé ìròyìn náà ṣàlàyé pé: “Bí ojú ibi tó gé náà bá ti kú tàìtai—nítorí gígé tí wọ́n gé e kúrò tàbí pé jàǹbá ti ṣẹlẹ̀ sí okùn ògóóró ẹ̀yìn—àwọn iṣan tó wà nítòsí á bẹ̀rẹ̀ sí i ṣiṣẹ́ lọ sápá ibẹ̀, tí wọ́n á sì gba iṣẹ́ ibẹ̀ ṣe.” O fi kún un pé: “Èyí ló sábàá máa ń mú káwọn èèyàn máa nímọ̀lára bíi pé ẹsẹ̀ tàbí apá tó gé náà ṣì wà níbẹ̀, tàbí kí wọ́n máa jẹ̀rora ìgbà gbogbo.”

Iṣẹ́ Ń Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Tẹ́nu Wọn Ń Rùn

Ana Cristina Kolbe tó jẹ́ olùtọ́jú eyín sọ nínú ìwé ìròyìn nípa ọrọ̀ ajé ti ilẹ̀ Brazil náà, Exame pé: “Kì í ṣe àsọdùn o láti sọ pé [ẹnu rírùn] máa ń ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ iṣẹ́.” Leandro Cerdeira tó jẹ́ agbanisíṣẹ́ fi kún un pé: “Láwọn tọ́ràn tiwọn burú gan an, wọ́n máa ń pàdánù iṣẹ́ kan tẹ̀ lé òmíràn láìmọ ohun pàtó tó ń fà á.” Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ìlú ńlá méjì ní ilẹ̀ Brazil, ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tí wọ́n yẹ̀ wò ni ẹnu rírùn ń bá fínra. Lára àwọn ohun tó ń fà á jù lọ ni másùnmáwo àti oúnjẹ tí kò ṣara lóore. Láti lè dín bí ó ti ń ṣeni kù, Dókítà Kolbe dámọ̀ràn pé káwọn tó níṣòro náà lọ fún ìsinmi ọlọ́jọ́ díẹ̀ kí wọ́n sì jẹ́ kí ẹ̀fọ́ tí wọ́n ń jẹ túbọ̀ pọ̀ sí i. Fún ìtọ́jú kíákíá tó jẹ́ fún àkókò díẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́nu wọn ń rùn lè máa fi oògùn apakòkòrò tí wọ́n fi omi lú yọnu ṣùkùṣùkù kí wọ́n sì dì í sẹ́nu fúngbà díẹ̀.

Iye Èèyàn Tó Ń Sọ̀rètí Nù Ń Pọ̀ Sí I

Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Faransé náà, Le Monde sọ pé, láàárín ọdún 1950 sí 1995, níbàámu pẹ̀lú ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè márùnlélọ́gọ́rùn-ún, ìpíndọ́gba ìpara-ẹni láwọn orílẹ̀-èdè náà ti fi ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ròkè láàárín ọdún 1950 sí 1995. Dókítà José-Maria Bertolote tó jẹ́ olùṣekòkárí ní ẹ̀ka ìlera ọpọlọ ti Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, mílíọ̀nù kan àwọn èèyàn ló máa fọwọ́ ara wọn pa ara wọn lọ́dún 2000 tí àwọn bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá sí ogún á sì gbìyànjú rẹ̀. Àmọ́ o, iye tó jẹ́ lóòótọ́ lè jù bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa. Níbàámu pẹ̀lú ìròyìn náà, àwọn tó ń fi ọwọ́ ara wọn para wọn lọ́dọọdún pọ̀ ju àwọn tó kú nínú gbogbo ogun tó ti jà lágbàáyé lọ. Ìfọwọ́-ẹni-para-ẹni láàárín àwọn tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí márùndínlógójì “ti wá di ọ̀kan lára ohun mẹ́ta pàtàkì tó ń fa ikú,” gẹ́gẹ́ bí Dókítà Bertolote ti sọ.

Àwọn Tí Wọ́n Fipá Bá Lòpọ̀ Ní Gúúsù Áfíríkà

Ìwé ìròyìn World Press Review sọ pé: “Lọ́dọọdún, ìfipábánilòpọ̀ tó tó mílíọ̀nù kan ló ń ṣẹlẹ̀ ní Gúúsù Áfíríkà. Èyí túmọ̀ sí pé ìfipábánilòpọ̀ kan máa ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ààbọ̀ ìṣẹ́jú. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé “Gúúsù Áfíríkà ni ìfipábánilòpọ̀ tó ga jù lọ lágbàáyé ti ń ṣẹlẹ̀ tó tún jẹ́ pé pípa ni wọ́n ń pa àwọn tí wọ́n bá bá lòpọ̀ náà.” Ìlọ́po méjìlá ni iye yẹn fi ga ju ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tó pọwọ́ lé e lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó ń gbé ní Gúúsù Áfíríkà yìí kò ju ogójì mílíọ̀nù lọ. Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé: “Láwọn orílẹ̀-èdè míì, àwọn èèyàn lè fipá báni lòpọ̀, kí wọ́n fipá gba nǹkan, tàbí kí wọ́n pààyàn. Àmọ́ ní Gúúsù Áfíríkà, ńṣe làwọn èèyàn máa kọ́kọ́ fipá báni lòpọ̀ kí wọ́n tó pa ẹni náà, kìkì nítorí pé ọwọ́ ba ẹni ọ̀hún. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ńṣe ni ìfipábánilòpọ̀ àtàwọn ìwà ọ̀daràn míì jọ máa ń rìn pọ̀.” Bákan náà, “fífipá báni lòpọ̀ ti wá di ara ààtò fáwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ìta,” tí wọ́n á sì wá pa àwọn tó bá kó sí wọn lọ́wọ́. Ara àwọn ohun tó ń fà á tí àpilẹ̀kọ náà mẹ́nu kan ni híhùwà àìdáa sọ́mọdé tó ti wá gogò àti èrò náà tó gbòde kan pé ìwàláàyè kò jẹ́ nǹkankan. Ní àfikún sí i, nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ìlú Johannesburg ní 1998, àpilẹ̀kọ náà sọ pé ìwádìí náà “fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́kùnrin gbà pé àwọn obìnrin máa ń gbádùn kí wọ́n fipá bá wọn lòpọ̀ àmọ́ wọn kì í fẹ́ sọ ọ́ jáde, àti pé tóo bá gbé ọmọbìnrin kan ròde, o lẹ́tọ̀ọ́ àti bá a sùn.”

Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀ Ní Gúúsù Áfíríkà

Ìwé ìròyìn The Mercury ti Gúúsù Áfíríkà sọ pé: “Àkọsílẹ̀ tó ń ròkè lọ́nà bíbanilẹ́rù nípa àrùn Éèdì ti mú kí ọ̀kan lára àwùjọ ilé ìwòsàn àdáni pàtàkì ní Gúúsù Áfíríkà yàn láti yíjú sí ‘ìtọ́jú àti iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀.’” Dókítà Efraim Kramer tó jẹ́ olùdarí ìṣègùn fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sọ pé: “Èròǹgbà wa ni láti fún ẹgbẹ́ oníṣègùn lápapọ̀ níṣìírí láti máa fún àwọn aláìsàn nítọ̀ọ́jú àti iṣẹ́ abẹ tí kò la lílo ẹ̀jẹ̀ táa fi tọrẹ lọ.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ̀rin dókítà ó kéré tán ní Gúúsù Áfíríkà ló ti ń fúnni ní ìtọ́jú tí wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀, ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwùjọ ilé ìwòsàn kan máa pinnu láti máa lo irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ bẹ́ẹ̀ tí odindi orílẹ̀-èdè pawọ́ pọ̀ ṣe. Dókítà Kramer sọ pé àwọn dókítà dáhùn padà lọ́nà “tó wúni lórí gan an” ni. Ìwé ìròyìn The Mercury wá sọ pé: “Ní pàtàkì, nítorí ohun táwọn àjọ ẹlẹ́sìn bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń béèrè, tí wọ́n kì í gbà ìtọ́jú tó la lílo ẹ̀jẹ̀ ẹlòmíì lọ, a ti ṣàwárí àwọn ọ̀nà ìtọ́jú gbígbéṣẹ́ tí kò ní lílo ẹ̀jẹ̀ nínú.”

Kápúsù Fitami C Àdánidá

Fífẹ̀ azarole, tí a tún mọ̀ sí àgbálùmọ́ ẹgàn kò ju sẹ̀ǹtímítà méjì lọ. Síbẹ̀, èso tó ládùn tó sì tún korò yìí ní fitami C tó ju ti ọsàn lọ ní ìlọ́po àádọ́ta tó sì ju ti ọsàn wẹ́wẹ́ lọ ní ọgọ́rùn ún ìgbà. Ìwádìí tí wọ́n ṣe ní San Martín State University ti Tarapoto ní Peru fi hàn pé, ọgọ́rùn-ún gíráàmù ṣákítí tó wà nínú ọsàn wẹ́wẹ́ tó kan jù lọ ní fitami C mílígíráàmù mẹ́rìnlélógójì nínú, nígbà tí azarole tó jẹ́ iye kan náà ní ẹgbẹ̀tàlélógún [4,600] mílígíráàmù fitami C nínú. Kìkì “kápúsù” àdánidá mẹ́rin yìí ti tó láti pèsè fitami C tí ara àgbàlagbà kan nílò lójúmọ́. Níbàámu pẹ̀lú ohun tí ìwé ìròyìn El Comercio sọ, akitiyan ti ń lọ lọ́wọ́ láti rí i bóyá wọ́n lè máa gbin azarole tó jẹ́ “èso tó tètè máa ń bàjẹ́” láti máa tà á láti fi rọ́pò coca.

Ìmọ̀ràn Tó Léwu

Ìwé ìròyìn Psychology Today sọ pé: “Ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde àtàwọn afìṣemọ̀rònú ń gbé èrò ‘títú’ [ìbínú] jáde lárugẹ. Àmọ́ ewu tó wà nínú ìmọ̀ràn yìí pọ̀ ju ìwúlò rẹ̀ lọ.” Níbàámu pẹ̀lú ohun tí Brad Bushman tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú ní Yunifásítì ti Ìpínlẹ̀ Iowa sọ, “títú ìbínú jáde máa ń mú kéèyàn túbọ̀ fínràn sí i ní ti gidi.” Àwọn tí wọ́n lò fún ìwádìí, tí “wọ́n tú ìbínú wọn jáde” nípa kíkan àpò tí wọ́n fi ń ṣeré ìmárale lẹ́ṣẹ̀ẹ́ fi ìwà ìfínràn àti ìwà òǹrorò hàn ní ìlọ́po méjì ju àwọn tí kò tú ìbínú wọn jáde lọ. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé kódà “àwọn èèyàn tí wọ́n ka ìwé nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú títú ìbínú ẹni jáde kí wọ́n tó lọ kan àpò náà lẹ́ṣẹ̀ẹ́ ló ṣeé ṣe pé kí wọ́n tún fẹ́ láti kan èèyàn lẹ́ṣẹ̀ẹ́ ju àwọn mìíràn lọ.” Bushman wá sọ pé: “Dípò gbígbìyànjú láti sinmẹ̀dọ̀, kúkú jáwọ́ nínú ìbínú náà pátápátá. Ka ení, èjì dórí ẹẹ́wàá, tàbí dórí ọgọ́rùn ún tó bá gbà bẹ́ẹ̀—ìbínú náà á sì wábi gbà.”

Ihò Ozone Tó Tíì Tóbi Jù Lọ

Ní September ọdún 2000, sátẹ́láìtì àjọ NASA tó ń yẹ ozone wò ti fi ihò tó tíì tóbi jù lọ nínú ìpele ozone hàn lágbègbè Antarctic. Ohun tí ìwé ìròyìn Clarín ti Buenos Aires ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà sọ nìyẹn. Ihò yìí fara hàn lágbègbè tó tó nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [28,300,000] kìlómítà, èyí fi ohun tó lé ní mílíọ̀nù kan kìlómítà ju èyí tí wọ́n kọ́kọ́ ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ lọ. Ìyàlẹ́nu ni ihò tó gbòòrò lọ́nà kíkàmàmà yìí jẹ́ fáwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì o. Ọ̀mọ̀wé Michael Kurylo tó ń ṣiṣẹ́ ní NASA yìí sọ pé àwọn àkíyèsí wọ̀nyí “túbọ̀ dá kún àníyàn nípa ipò ẹlẹgẹ́ tí ayé wà nínú ìpele ozone.” Rubén Piacentini tó jẹ́ onímọ̀ físíìsì tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ìgbòkègbodò Gbalasa Òfuurufú ní Ajẹntínà ṣàlàyé pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé lókè Antarctica, níbi tẹ́nì kankan kì í gbé ni ihò náà ṣì wà báyìí, “ó ṣeé ṣe kó kọjá lọ sí àgbègbè ìhà gúúsù [Ajẹntínà].” Ìwé ìròyìn Clarín sọ pé ozone máa ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ààbò kan nípa dídín ipa búburú tó ṣeé ṣe kó wá látinú ìtànṣán olóró gíga tó ń wá látinú oòrùn kù.