Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Lè Jí Ohun Ìdánimọ̀ Rẹ Lọ!

Wọ́n Lè Jí Ohun Ìdánimọ̀ Rẹ Lọ!

Wọ́n Lè Jí Ohun Ìdánimọ̀ Rẹ Lọ!

Ọ̀DỌ́BÌNRIN náà bẹ̀rẹ̀ sí í gba àwọn ìsọfúnni kòbákùngbé látọ̀dọ̀ oríṣiríṣi ọkùnrin lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù rẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni ọkùnrin kan tún bá a sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù pé, nítorí àwọn ìkéde pálapàla tó ṣe sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lòún ṣe tẹ̀ ẹ́ láago. Àmọ́ obìnrin yìí ò tiẹ̀ lóhun tó ń jẹ́ kọ̀ǹpútà. Ó ṣe díẹ̀ kó tó mọ̀ pé ẹnì kan ló ń lo orúkọ òun lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó sì wá ń fi àwọn ìkéde náà sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kì í ṣe ìyẹn nìkan o, ńṣe ni afàwọ̀rajà náà tún ń sọ àdírẹ́sì obìnrin náà, béèyàn ṣe lè dé ilé rẹ̀, àní ó tiẹ̀ tún pèsè ìmọ̀ràn lórí béèyàn ṣe lè fọgbọ́n wọlé obìnrin náà kí aago tó máa ń dún tí jàǹdùkú bá wọlé má sì pariwo!

Ọ̀pọ̀ jù lọ wa ni kì í fọwọ́ gidi mú àwọn ohun ìdánimọ̀ wa. A mọ ẹni tí a jẹ́, tẹ́nì kan bá sì bi wá lẹ́jọ́, a lè ṣàlàyé ara wa. Àmọ́, àwọn ohun táa máa ń lò bí ẹ̀rí ìdánimọ̀ wa—àwọn bí ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí, nọ́ńbà ìdánimọ̀, a ìwé ìwakọ̀, ìwé àṣẹ ìrìn àjò, káàdì ìdánimọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ti túbọ̀ ń di ohun tó rọrùn láti ṣe ayédèrú wọn tàbí kí wọ́n jí wọn, débi pé ìwà ọ̀daràn tuntun kan ti ṣẹ̀ṣẹ̀ yọjú tí wọ́n ń pè ní “jíjí ohun ìdánimọ̀.”

Jìbìtì Tó Gbalẹ̀ Kan

Irú ìwà ọ̀daràn táa ń sọ yìí díjú o, ó kún fún àyínìke, ó sì ṣeé ṣe kó ba tèèyàn jẹ́. Àwọn tó bá kó sí wọn lọ́wọ́ á kàn ṣàdédé rí i pé ẹnì kan ti ń gba owó rẹpẹtẹ nínú àkáǹtì wọn, tí wọ́n á jẹ gbèsè gọbọi sí wọn lọ́rùn, tí wọ́n á sì ṣe àwọn jàǹbá mìí lórúkọ wọn. Àwọn ilẹ̀ kan wà níbi tí òfin ti dáàbò bo irú àwọn tó kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí pé kí wọ́n má san nǹkan kan padà, àmọ́ orúkọ wọn lè ti bà jẹ́ kí gbèsè sì ti di gọbọi sí wọn lọ́rùn.

Àwọn agbófinró, àwọn iléeṣẹ́ tó ń rí sí káàdì ìrajà àwìn, àtàwọn ẹgbẹ́ alájẹṣẹ́kù ti jẹ́rìí sí i gbangba-gbàǹgbà pé jíjí ohun ìdánimọ̀ máa ń fa àdánù ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún. Kò sí báa ṣe lè mọ̀ ní pàtó báwọn èèyàn tí wọ́n ń lù ní jìbìtì nípa jíjí ohun ìdánimọ̀ wọn ṣe pọ̀ tó. Èyí tó burú jù lọ nínú ìṣòro ọ̀hún ni pé, ọ̀pọ̀ oṣù lè ti kọjá kéèyàn tó mọ̀ pé wọ́n ti jí ohun ìdánimọ̀ òun. Àwọn agbèfọ́ba kan pe jíjí ohun ìdánimọ̀ ní ìwà ọ̀daràn tó ń yara gbilẹ̀ jù lọ ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwọn orílẹ̀-èdè míì náà sọ irú nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀.

Ohun tó túbọ̀ mú kí ọ̀rọ̀ náà burú sí i ni pé, àwọn olè mọ̀ pé lílu jìbìtì ohun ìdánimọ̀ ṣòro láti wádìí ẹ̀, òfin kì í sì í sábàá ṣe nǹkan kan sí i. Akíkanjú aṣèwádìí kan, Cheryl Smith sọ pé: “Àwọn ọ̀daràn ka jíjí ohun ìdánimọ̀ sí ìwà ọ̀daràn tí kò pa ẹnì kan lára ní pàtàkì. Àwọn tó ń kó sí wọn lọ́wọ́ lè jẹ́ báńkì tàbí ilé ìtajà. Wọ́n kì í ronú pé ẹnì kan wà tí àwọ́n ń fi kó bá.”

Fífi Orúkọ Rẹ Lu Jìbìtì

Àwọn olè tó ń jí ohun ìdánimọ̀ sábàá máa ń jí ohun kan tàbí àwọn nǹkan pàtàkì míì tó ní í ṣe pẹ̀lú ìsọfúnni rẹ, irú bíi nọ́ńbà ìdánimọ̀ tàbí ìwé ìwakọ̀. Wọ́n á wá lọ lò ó bí ẹni pé àwọn gangan ni ọ́ tí wọ́n á sì forúkọ rẹ ṣí ìwé gbèsè. Síbẹ̀, inú àdírẹ́sì tiwọn ni wọ́n máa ní kí wọ́n darí àwọn ìwé tó ní í ṣe pẹ̀lú rẹ̀ sí. Wọ́n á ná owó rẹ bí wọ́n bá ṣe lè ná an tó àti ní kíákíá. Ìwọ ò ní mọ̀ pé nǹkan kan ń ṣẹlẹ̀ àfìgbà táwọn àjọ tó ń gba owó padà bá bẹ̀rẹ̀ sí í pè ọ́.

Báwo làwọn oníwàkiwà ẹ̀dá yìí ṣe ń rí irú àwọn ìsọfúnni àdáni bẹ́ẹ̀ jí? Kò ṣòro rárá. Ó sábàá máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kíkó àwọn ìsọfúnni táwọn èèyàn máa ń kọ sínú ìwé tí wọ́n fi ń gba káàdì ìrajà àwìn jọ tàbí tí wọ́n fún àwọn tó ń tajà lórí tẹlifóònù. ‘Títú ibi ìdalẹ̀sí’ ni iṣẹ́ àwọn kan lára àwọn ọ̀daràn yìí—wọ́n á máa tú ibi tóò ń kó ìdọ̀tí sí láti wá ìwé ìfowópamọ́, ìwé owó èlé, tàbí àwọn ìwé ìrajà àwìn rẹ. Ńṣe làwọn kan á sì lọ dábùú àwọn lẹ́tà rẹ tó ní í ṣe pẹ̀lú owó kí wọ́n tó dé inú àpótí ìfìwéránṣẹ́ rẹ. ‘Àwọn agbéjìká-garùn’ làwọn olè tó ń lo kámẹ́rà tàbí awò-awọ̀nàjíjìn láti fi wo nọ́ńbà táwọn tí wọ́n fẹ́ lù ní jìbìtì ń tẹ̀ sórí ẹ̀rọ tó ń gbowó tó sì ń sanwó ní báńkì (ATMs) tàbí láwọn ìdí tẹlifóònù àdúgbò. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ó rọrùn púpọ̀ láti rí ọ̀pọ̀ ìsọfúnni nípa àwọn èèyàn ní ilé ẹjọ́, nínú àwọn àkọsílẹ̀ gbogbo gbòò, tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Jíjí Orúkọ Rere Rẹ

Tọ́wọ́ ọ̀daràn náà bá ti lè tẹ nọ́ńbà ìdánimọ̀ rẹ, ó tún lè nílò àwọn ìsọfúnni mìíràn fún ìdánimọ̀, irú bí ọjọ́ ìbí rẹ àti àdírẹ́sì rẹ àti nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ. Pẹ̀lú àwọn ìsọfúnni yìí, bóyá pẹ̀lú ìwé ìwakọ̀ kan tí kì í ṣe ojúlówó tí fọ́tò rẹ̀ wà lára rẹ̀, olè yìí lè bẹ̀rẹ̀ ìwà ọ̀daràn rẹ̀. Kíákíá ni olè yìí máa béèrè fún ọjà àwìn, ó lè lọ fúnra rẹ̀ tàbí kó kọ̀wé ránṣẹ́ sí wọn, tí á sì ṣe bí ẹni pé ìwọ ni. Lọ́pọ̀ ìgbà, àdírẹ́sì tiẹ̀ ló máa fi sílẹ̀, á ní òun ti kó kúrò níbi tí òun ń gbé tẹ́lẹ̀. Níbi táwọn tó ń ṣàyẹ̀wò rírajà àwìn sì ti ń kánjú, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń wò ó bóyá àwọn ìsọfúnni tàbí àwọn àdírẹ́sì yẹn jẹ́ òótọ́.

Nítorí náà, tí afàwọ̀rajà náà bá ti lè ṣí àkáǹtì àkọ́kọ́, ó lè wá máa lo àkáǹtì tuntun yìí pẹ̀lú àwọn ìsọfúnni pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ fún ìdánimọ̀ tó ní láti túbọ̀ fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Èyí á wá túbọ̀ mú kó rọrùn fun un láti máa bá lílu jìbìtì náà lọ ràì. Ọ̀nà ti ṣí sílẹ̀ fún ọ̀daràn náà báyìí láti di ọlọ́rọ̀ o, bó sì ti ń ṣe èyí ló ń ba iyì àti orúkọ rere tiẹ̀ jẹ́.

Kì í rọrùn láti tún àwọn ohun tó ti bà jẹ́ ṣe, ó máa ń gba àkókò, ó tún máa ń múnú bíni. Mari Frank tó jẹ́ agbẹjọ́rò kan láti California mọ bí ọ̀ràn yìí ṣe nira tó nígbà tí afàwọ̀rajà kan kó o sí gbèsè tó ń lọ sí bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn ún dọ́là nípa lílo orúkọ rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo ní láti kọ àádọ́rùn ún lẹ́tà tí mo sì lo ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] wákàtí láti lè fọ orúkọ mi mọ́. Ó jẹ́ ìjàkadì kan láti tún orúkọ rẹ ṣe kó má sì dà ọ́ lórí rú . . . . Lọ́pọ̀ ìgbà, o ò ní mọ ẹni tó ń ṣe é, bẹ́ẹ̀ sì ni ọwọ́ kì í tẹ àwọn ọ̀daràn náà.”

Ohun Tóo Lè Ṣe

Ká ní ìwọ lo bọ́ sọ́wọ́ àwọn olè tí ń jí ohun ìdánimọ̀, àwọn ìgbésẹ̀ díẹ̀ wà tóo lè gbé. Àkọ́kọ́ pàá, a dáa lábàá pé kóo kàn sí ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí jìbìtì lílù tó wà ládùúgbò rẹ láti fi tó wọn létí. Lẹ́yìn náà kọ ọ́ sí ìwé, kóo sì bẹ̀ wọ́n pé wàá fẹ́ kí wọ́n fojú kàn ọ́ kí wọ́n tó ṣí àkáǹtì ìrajà àwìn tuntun fún ọ.

Lẹ́yìn èyí, lọ fi tó àwọn ọlọ́pàá létí. Rí i dájú pé o ní ẹ̀dà àkọsílẹ̀ àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ nítorí o lè lọ nílò rẹ̀ láti jẹ́ káwọn tó ń tajà àwìn fún ọ mọ̀ nípa rẹ̀.

O tún gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn báńkì àti iléeṣẹ́ ìrajà àwìn tí ò ń bá ṣòwò pọ̀ gbọ́ nípa rẹ̀. Kódà, ká tiẹ̀ ní olè náà lo àwọn ìsọfúnni tó jí láti fi gba káàdì ìrajà tuntun, yóò jẹ́ ààbò gidi fún ọ bóo bá tún gbogbo káàdì ìrajà àwìn rẹ gbà padà. Bákan náà, táwọn olè bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé tóo fi ń gbowó àtèyí tóo fi ń sanwó, ó lè pọndandan pé kóo ṣí àwọn tuntun míì. Láfikún sí i, ó tún lè pọndandan pé kóo gba káàdì tuntun fún ATM àti nọ́ńbà ìdánimọ̀ tuntun.

Ǹjẹ́ Ojútùú Kan Yóò Wà Láìpẹ́?

Àwọn ìjọba, àwọn agbófinró, àtàwọn àjọ ayánilówó ti ń sá sókè-sódò láti wá ọ̀nà láti dáwọ́ jíjí ohun ìdánimọ̀ dúró. Láwọn àdúgbò kan, wọ́n ṣe àwọn òfin kan síta tó sọ ìwà yìí di ìwà ọ̀daràn ńlá, wọ́n sì tún ṣe àwọn kan tó túbọ̀ dáàbò bo ìsọfúnni àwọn èèyàn. Àwọn ìgbésẹ̀ ọlọ́gbọ́n iṣẹ́-ẹ̀rọ gíga míì wà tí wọ́n tún gbé. Èyí kan àwọn káàdì tó dá òǹtẹ̀ ìka ọwọ́ mọ̀, káàdì ATM tó ń dá ìlà àtẹ́lẹwọ́ tàbí ohùn ẹni mọ̀, àwọn káàdì oníkọ̀ǹpútà tó lè gba àwọn ohun ìdánimọ̀ bí irú ẹ̀jẹ̀ ẹnì kan àti ìlà ọwọ́ sílẹ̀, àtàwọn káàdì tó ní ibi ìbuwọ́lù tí kò ṣeé parẹ́.

Yàtọ̀ fún àwọn ọ̀nà dídíjú yìí láti ṣèdíwọ́ ìwà yìí, àwọn ohun gbígbéṣẹ́ kan wà tóo lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ. (Wo àpótí náà, “Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Olè Tí Ń Jí Ohun Ìdánimọ̀.”) Nípa ríronú ṣáájú àti mímúrasílẹ̀ dáadáa, ó lè dín ewu àwọn olè tó ń jí ohun ìdánimọ̀ kù!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wọ́n máa ń fún àwọn ọmọ onílẹ̀ àtàwọn tó bá wá gbé ibẹ̀ láwọn nọ́ńbà kan fún ìdánimọ̀. Kì í ṣe ìdánimọ̀ nìkan ni wọ́n lè lò ó fún àmọ́ wọ́n tún ń lò ó fún sísan owó orí àti gbígba ìtọ́jú ìṣègùn. Ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n máa ń fún àwọn aráàlú ní ohun tí wọ́n ń pè ní nọ́ńbà Jíjẹ́ Oníǹkan. Bí wọ́n ṣe ń pe àwọn nọ́ńbà ìdánimọ̀ yìí yàtọ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]

Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Olè Tí Ń Jí Ohun Ìdánimọ̀

● Ìgbà tó bá pọndandan nìkan ni kóo sọ nọ́ńbà ìdánimọ̀ rẹ.

● Má ṣe kó káàdì ìrajà àwìn, nọ́ńbà ìdánimọ̀ rẹ, ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí, tàbí ìwé àṣẹ ìrìn àjò sínú àpamọ́wọ́ tàbí àpò rẹ, àyàfi tó bá pọndandan.

● Ya àwọn fọ́ọ̀mù tóo fi gba káàdì ìrajà àwìn tóo ti lò tàn tí wọ́n sì ti buwọ́ lù sí wẹ́wẹ́ kóo tó kó wọn dà nù. Tún ya àwọn ìwé báńkì tí o kò lò mọ́, ìwé tóo fi sanwó fóònù, àwọn ìwé tóo fi sanwó káàdì ìrajà àwìn rẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú.

● Tóo bá ń lo ẹ̀rọ ìsanwó ní báńkì tàbí tóo ń lo káàdì tẹlifóònù láti fi pe ọ̀nà jíjìn, lo ọwọ́ rẹ láti fi bò wọ́n. Àwọn ‘agbéjìká-garùn’ lè wà nítòsí pẹ̀lú awò-awọ̀nàjíjìn tàbí kámẹ́rà.

● Máa lo àpótí lẹ́tà tó ṣeé tì láti dín jíjí lẹ́tà kù.

● Lọ fọwọ́ ara rẹ gba ìwé sọ̀wédowó ní báńkì dípò tí wàá fi ní kí wọ́n fi ránṣẹ́ sí ọ.

● Máa ṣàkọsílẹ̀ tàbí kí o ní ẹ̀dà gbogbo nọ́ńbà àkáǹtì ọjà tóo rà láwìn lọ́wọ́, kóo sì fi wọ́n pa mọ́ síbi tí kò séwu.

● Má ṣèèṣì sọ nọ́ńbà káàdì ìrajà àwìn rẹ tàbí àwọn ìsọfúnni mìíràn nípa ara rẹ lórí tẹlifóònù àyàfi tí iléeṣẹ́ náà bá jẹ́ èyí tóo fọkàn tán tàbí pé ìwọ lo pè wọ́n lórí tẹlifóònù.

● Mọ ọ̀rọ̀ tóo fi ń ṣí kọ̀ǹpútà rẹ sórí. Má ṣe fi ibi tóo kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó fi ń ṣí kọ̀ǹpútà sí sínú àpamọ́wọ́ tàbí àpò rẹ.

● Rí i pé o ń gba ẹ̀dà èsì àwìn ọjà tóo rà déédéé tó bá ṣeé ṣe.

● Ní kí wọ́n yọ orúkọ rẹ kúrò níbi tí wọ́n to orúkọ àti àdírẹ́sì àwọn tó ń ra káàdì ìrajà àwìn sí èyí táwọn iléeṣẹ́ náà àtàwọn tó fàyè tó gùn sílẹ̀ fún ọjà àwìn máa ń gbé jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

‘Àwọn agbéjìká-garùn’ máa ń ṣọ́ àwọn tí wọ́n fẹ́ lù ní jìbìtì bí wọ́n ti ń tẹ àwọn nọ́ńbà níbi tẹlifóònù àdúgbò tàbí nídìí ẹ̀rọ tó ń gbowó tó sì ń sanwó ní báńkì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

‘Àwọn tó ń tú ibi ìdalẹ̀sí’ máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti jí ìsọfúnni àwọn èèyàn