Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àbí Ohun Táa Pè Lójútùú Ló Ń Dá Kún Ìṣòro?

Àbí Ohun Táa Pè Lójútùú Ló Ń Dá Kún Ìṣòro?

Àbí Ohun Táa Pè Lójútùú Ló Ń Dá Kún Ìṣòro?

“Títàbùkù àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ṣíṣe wọ́n níṣekúṣe kọ́ ló máa mú kí wọ́n di ọmọlúwàbí bí wọ́n bá jáde lẹ́wọ̀n.”—Ọ̀RỌ̀ OLÓÒTÚ NÍNÚ ÌWÉ ÌRÒYÌN THE ATLANTA CONSTITUTION.

ÌKÁLỌ́WỌ́KÒ ni ọgbà ẹ̀wọ̀n wà fún—fúngbà díẹ̀ sì ni. Bí wọ́n bá dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀, ṣé lóòótọ́ ló ti jìyà ìwà ọ̀daràn tó hù? Àwọn tó ṣe lọ́ṣẹ́ tàbí àwọn èèyàn wọn ńkọ́? Nígbà tí wọ́n dá ẹni tó pa ọmọ rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́rìndínlógún sílẹ̀ lẹ́yìn tó ṣẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta péré, Rita, ìyá ọmọ náà sọ fún tẹ̀wọ̀ndé náà pé, “Èmi ni ìyá ọmọ tóo pa. Jọ̀ọ́ fara balẹ̀ kóo sì rò ó wò ná. Ṣóo mọ bọ́ràn ọ̀hún ṣe rí lára mi?” Bí ọ̀ràn Rita ṣe fi hàn, ìbànújẹ́ ṣì máa ń wà lọ́kàn àwọn èèyàn fún ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ti parí ẹjọ́ táwọn ìwé ìròyìn sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ náà.

Kì í ṣe kìkì àwọn tí ìwà ọ̀daràn ti pa lára nìkan lọ̀ràn yìí kàn o, ó tún kan gbogbo èèyàn. Ó ṣe tán, yálà ẹlẹ́wọ̀n kan ti yí padà tàbí pé ńṣe ló túbọ̀ dìdàkudà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lè nípa lórí ìbàlẹ̀ ọkàn rẹ kódà ó lè nípa lórí ààbò rẹ pàápàá.

Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Di Ibi Táwọn Ọ̀daràn Ti Ń Gbokùn

Ọgbà ẹ̀wọ̀n kì í fìgbà gbogbo yí ìwà àwọn ọ̀daràn padà pátápátá. Jill Smolowe kọ ọ́ nínú ìwé ìròyìn Time pé: “Bí wọ́n bá ń run owó lórí kíkọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n púpọ̀ sí i dípò tí wọn ì bá fi tún orúkọ búburú tí ẹlẹ́wọ̀n ti ṣe fún ara rẹ̀ ṣe, ọ̀pọ̀ ìgbà lèyí máa yọrí sí ìwà ipá púpọ̀ sí i—tó tiẹ̀ tún burú jáì pàápàá.” Peter, a tó ti lo ọdún mẹ́rìnlá lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kín ọ̀rọ̀ yẹn lẹ́yìn. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹgbẹ́ mi ló jẹ́ pé ìwà ọ̀daràn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ni wọ́n fi bẹ̀rẹ̀, wọ́n wá jingíri dórí kí wọ́n máa jí ohun ìní, tí wọ́n sì wá gboyè nínú híhu àwọn ìwà ọ̀daràn tó burú jáì sáwọn èèyàn. Lójú wọn, ńṣe ni ọgbà ẹ̀wọ̀n dà bí ilé ẹ̀kọ́ òwò. Tí wọ́n bá fi máa jáde, wọ́n á ti di ògbóǹkangí nínú ìwà búburú.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n lè mú àwọn ọ̀daràn kúrò ládùúgbò fúngbà díẹ̀, ó dà bí pé kò sí ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú ìwà ọ̀daràn kúrò fún ìgbà pípẹ́. Àwọn ọmọdékùnrin àtàwọn tó ti dàgbà díẹ̀ nígboro ìlú ńlá máa ń wo lílọ sẹ́wọ̀n bí ohun kan tó ń sọ èèyàn di ọkùnrin. Lọ́pọ̀ ìgbà ni wọ́n á wá di kúrá nínú ìwà ọ̀daràn. Larry tó jẹ́ pé bí wọ́n ti ń tú u sílẹ̀ ni wọ́n tún ń gbé e jù sẹ́wọ̀n fún ìgbà púpọ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ̀ sọ pé: “Ọgbà ẹ̀wọ̀n kò yí èèyàn padà rárá. Báwọn èèyàn yìí bá kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ohun kan náà tí wọ́n torí ẹ̀ dèrò ẹ̀wọ̀n ni wọ́n á tún mú ṣe.”

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ìwà ọ̀daràn tó burú gan an ló jẹ́ nǹkan bí ìdá márùn ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀daràn tó ti fẹ̀wọ̀n jura rí ló hù wọ́n tí wọ́n á sì tún padà sẹ́wọ̀n. Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Nígbà tọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n bá dilẹ̀, wọ́n á máa ronú bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ jáfáfá sí i nínú ìwà ibi, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á tún kọ́ oríṣiríṣi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí wọ́n á máa lò láti hùwà ọ̀daràn nígbà tí wọ́n bá jáde lẹ́wọ̀n.”

Kì í ṣe Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan lọ́ràn ti rí bẹ́ẹ̀ o. John Vatis, tó jẹ́ oníṣègùn ní ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ológun ní Gíríìsì sọ pé: “Àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n wa ti dọ̀gá nínú kíkọ́ àwọn èèyàn láti di eléwu, oníwà ipá, àti ẹni tó ń mú àwọn èèyàn bínú. Nígbà tí wọ́n bá dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló máa ń fẹ́ ‘gbẹ̀san’ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn lára àwọn èèyàn.”

Iye Tó Ń Ná Àwùjọ

Ìṣòro ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ìṣúnná owó tìẹ náà. Wọ́n fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń sanwó orí ń ná nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógún dọ́là sórí ẹlẹ́wọ̀n kọ̀ọ̀kan lọ́dọọdún. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ti lé lọ́gọ́ta ọdún lè ná ìlọ́po mẹ́ta iye yẹn. Àwọn ohun mìíràn wà tí kò jẹ́ káwọn èèyàn tún fi bẹ́ẹ̀ fọkàn tán ọ̀nà ìfìyà jẹ àwọn ọ̀daràn mọ́ lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè. Àwọn èèyàn ń ṣàníyàn nípa bí wọ́n ṣe máa ń dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀ láìtọ́jọ́ táwọn ọ̀daràn mìíràn kò tiẹ̀ ní lọ sẹ́wọ̀n rárá bí amòfin kan bá ti lè fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí dojú ọ̀rọ̀ náà dé. Àwọn ọ̀daràn tí wọ́n dá sílẹ̀ yìí tún lè lọ ṣe àwọn èèyàn kan náà lọ́ṣẹ́ táwọn yẹn sì lè máà láǹfààní láti pẹjọ́.

Àwọn Èèyàn Túbọ̀ Ń Ṣàníyàn

Àwọn kan kò tún fi bẹ́ẹ̀ nígbẹkẹ̀lẹ́ nínú ètò ọgbà ẹ̀wọ̀n mọ́ nítorí ìwà tí kò yẹ ọmọ èèyàn tí wọ́n ń hù sáwọn ẹlẹ́wọ̀n, gẹ́gẹ́ bí àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ́ yìí ti ṣàlàyé. Ó ṣòro fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ti hùwà àìdáa sí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n láti yí ìwà wọn padà. Láfikún sí i, ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ló ti ń kọminú nípa bí iye mẹ́ńbà àwọn àwùjọ tí kò gbajúmọ̀ tí wọ́n rí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ṣe pọ̀ tó. Wọ́n béèrè bóyá ó kàn ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni tàbí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ló fà á.

Ìròyìn kan tí àjọ akọ̀rọ̀yìn Associated Press kọ lọ́dún 1998 pe àfiyèsí sí ìṣòro àwọn ẹlẹ́wọ̀n tẹ́lẹ̀rí kan ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Holmesburg tó wà ní Pennsylvania, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, pé kí wọ́n fún àwọn ní owó gbà-máà-bínú nítorí pé wọ́n ti lo àwọn nílò ẹranko, tí wọ́n fi àwọn ṣe ìwádìí oníkẹ́míkà nígbà táwọn wà lẹ́wọ̀n. Dídè tí wọ́n ń dè àwọn ẹlẹ́wọ̀n mọ́ra wọn tí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà yìí ńkọ́ o? Àjọ Adáríjini Lágbàáyé sọ pé: “Àwọn tí wọ́n ń dè pa pọ̀ náà ní láti ṣiṣẹ́, lọ́pọ̀ ìgbà fún wákàtí mẹ́wàá sí méjìlá nínú oòrùn ganrín-ganrín, tí wọ́n á kàn fún wọn láyè díẹ̀ láti mu omi, àti wákàtí kan fún oúnjẹ ọ̀sán. . . . Ohun kan ṣoṣo tí wọ́n ń lò bí ilé ìyàgbẹ́ ni póò kékeré kan tí wọ́n gbé sẹ́gbẹ̀ẹ́ pákó tí wọ́n fi dí gàgá iyàrá náà. Orí ìdè làwọn ẹlẹ́wọ̀n yìí máa wà nígbà tí wọ́n bá ń lò ó. Bí póò kékeré yìí kò bá sì sí lárọ̀ọ́wọ́tó, wọ́n á ní kí wọ́n lóṣòó sí gbangba ìta.” Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo ọgbà ẹ̀wọ̀n lọ̀ràn ti rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá, àtúbọ̀tán ṣíṣe wọ́n níṣekúṣe yìí kì í dára, àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n, àtàwọn tó ṣe wọ́n níṣekúṣe ló máa fara kááṣá rẹ̀.

Ṣé Ó Tiẹ̀ Ń Ṣe Àwùjọ Láǹfààní?

Ọkàn àwọn èèyàn máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá ti ju àwọn ọ̀daràn paraku sẹ́wọ̀n. Ọ̀tọ̀ sì lohun tó mú káwọn mìíràn nífẹ̀ẹ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n. Nígbà tí wọ́n fẹ́ ti ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tó wà ní ìlú Cooma ní Ọsirélíà pa, àwọn èèyàn fárí gá. Kí ló dé? Ìdí ni pé ọgbà ẹ̀wọ̀n náà jẹ́ káwọn ará àdúgbò náà tí ètò ọrọ̀ ajé wọn ò ṣe dáadáa ríṣẹ́ ṣe.

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ìjọba kan ti ta àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n wọn fún ilé iṣẹ́ aládàáni láti dín ìnáwó kù. Ó ṣeni láàánú pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n púpọ̀ sí i àti iye ọdún púpọ̀ sí i tí wọ́n fi ń ṣẹ̀wọ̀n ti wá di ọ̀ràn ìṣòwò. Nípa báyìí, ìdájọ́ ti dàpọ̀ mọ́ ìṣòwò.

Bí a bá sọ ọ́ lọ, táa sọ ọ́ bọ̀, ògidì ìbéèrè náà ṣì wà níbẹ̀ pé: Ṣé ọgbà ẹ̀wọ̀n máa ń yí àwọn ọ̀daràn padà? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé rárá o ni ìdáhùn sábàá máa ń jẹ́, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé a ti ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan lọ́wọ́ wọ́n sì ti yí padà. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe rí bẹ́ẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ àwọn kan nínú àpilẹ̀kọ yìí padà.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

Wíwo Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n Ní Ṣókí

ÀPỌ̀JÙ ÈRÒ: Ìṣòro àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni àpọ̀jù èrò to ré kọjá ààlà, èyí kò sì kúkú yani lẹ́nu! Orílẹ̀-èdè yẹn ló wà ní ipò kejì nínú àwọn tí wọ́n ní ìpín ẹlẹ́wọ̀n tó pọ̀ jù lọ ní gbogbo Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù. Nínú ọ̀kẹ́ márùn-ún [100, 000] àwọn èèyàn ibẹ̀, márùnlélọ́gọ́fà [125] jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n. Ní Brazil, wọ́n kọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tó tóbi jù lọ ní São Paulo láti gba ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ẹlẹ́wọ̀n. Dípò iye yìí, ẹgbàata ẹlẹ́wọ̀n ló wà nínú rẹ̀. Ní Rọ́ṣíà, àádọ́rùn-ún sí àádọ́fà ẹlẹ́wọ̀n ló ń wà nibi tó yẹ kí ẹlẹ́wọ̀n méjìdínlọ́gbọ̀n wà. Ìṣòro yìí ti wá le débi pé ńṣe làwọn ẹlẹ́wọ̀n ń pín oorun sùn. Ní orílẹ̀-èdè Éṣíà kan, wọ́n há àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́tàlá tàbí mẹ́rìnlá mọ́ inú iyàrá kan tí kò ju ṣókótó lọ. Ní báyìí ná, ohun táwọn aláṣẹ ṣe ní Ìwọ̀ Oòrùn Ọsirélíà láti kápá àìsí àyè tó fẹ̀ tó ni fífi àwọn ẹlẹ́wọ̀n sínú àpótí ìkẹ́rùránṣẹ́ onírin.

ÌWÀ IPÁ: Ìwé ìròyìn èdè Jámánì náà, Der Spiegel, sọ pé láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n Jámánì, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n rorò máa ń para wọn, wọ́n sì tún máa ń fìyà jẹ ara wọn nítorí “ogun táwọn tó ń figa-gbága nítorí òwò ọtí líle, oògùn apanilọ́bọlọ̀, ìbálòpọ̀, àti ìyánilówó èlé” ń jà. Wàhálà ẹ̀yà tún ń súnná sí ìwà ipá lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Ìwé ìròyìn Der Spiegel sọ pé: “Èdè àìyedè àti àìgbọ́ra ẹni yé tó ń yọrí sí ìwà ipá kò lè ṣe kó máà wáyé nítorí pé orílẹ̀-èdè méjìléláàádọ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn ẹlẹ́wọ̀n yìí ti wá.” Ní ọgbà ẹ̀wọ̀n kan níhà Gúúsù Amẹ́ríkà, àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ sọ pé ní ìpíndọ́gba, ẹlẹ́wọ̀n méjìlá ló ń ríkú he lóṣooṣù. Ìwé ìròyìn Financial Times ti London sọ pé: “Àwọn ẹlẹ́wọ̀n sọ pé iye náà fi ìlọ́po méjì jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

FÍFIPÁBÁNI-LÒPỌ̀: Ìwé ìròyìn The New York Times sọ nínú àpilẹ̀kọ náà “Wàhálà Ìfipábáni-Lòpọ̀ Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n” pé, wọ́n fojú díwọ̀n ẹ̀ pé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, “ohun tó lé ní ẹgbàá márùnlélógóje [290,000] ọkùnrin ni wọ́n ń fipá bá lòpọ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lọ́dọọdún.” Ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Ìrírí ajámọláyà ti ìbálòpọ̀ oníwà ipá yìí kọjá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan péré, ó ti di ojoojúmọ́.” Ètò àjọ kan díwọ̀n rẹ̀ pé ní àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000] ìfipábáni-lòpọ̀ ló ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́.

ÌLERA ÀTI ÌMỌ́TÓTÓ: Àkọsílẹ̀ wà fún títàn tí àwọn àrùn tí ń ranni nípasẹ̀ ìbálòpọ̀ ń tàn kálẹ̀ láàárín àwọn tó wà lẹ́wọ̀n. Ikọ́ ẹ̀gbẹ láàárín àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní Rọ́ṣíà àtàwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà ti di èyí tí gbogbo ayé mọ̀ àti bí wọn kò ṣe kọbi ara sí ìtọ́jú ìṣègùn, ìmọ́tótó, àti oúnjẹ ní ọ̀pọ̀ ọgbà ẹ̀wọ̀n káàkiri ayé.

[Àwòrán]

Ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tó kún àkúnya ní São Paulo, Brazil

[Credit Line]

Fọ́tò AP/Dario Lopez-Mills

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Ọgbà ẹ̀wọ̀n ńlá La Santé ní Paris, ilẹ̀ Faransé

[Credit Line]

Fọ́tò AP/Francois Mori

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn obìnrin lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ní Managua, Nicaragua

[Credit Line]

Fọ́tò AP/Javier Galeano