Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìṣòro Dé Bá Àwọn Ọgbà Ẹ̀wọ̀n

Ìṣòro Dé Bá Àwọn Ọgbà Ẹ̀wọ̀n

Ìṣòro Dé Bá Àwọn Ọgbà Ẹ̀wọ̀n

“Kíkọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n sí i láti yanjú ìṣòro ìwà ọ̀daràn wulẹ̀ dà bíi kíkọ́ itẹ́ òkú sí i láti kápá àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí.”—ROBERT GANGI, ÒGBÓǸKANGÍ NÍNÚ ÈTÒ ÌYÍWÀPADÀ.

NÍNÚ ayé kan tí a ti máa ń fi àdàpè ọ̀rọ̀ bàṣírí àwọn nǹkan tá ò nífẹ̀ẹ́ sí yìí, ńṣe làwọn èèyàn máa ń lo àdàpè ọ̀rọ̀ fún “ọgbà ẹ̀wọ̀n” nítorí pé nǹkan ìtìjú ni. Ó tẹ́ àwọn èèyàn kan lọ́rùn láti pè é ní “ọgbà ìyínipadà” níbi tí wọ́n ti ń “kọ́ni ní iṣẹ́ ọwọ́” àti “iṣẹ́ tó lè ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní.” Orúkọ àdàpè tẹ́ àwọn kan lọ́rùn ju kí wọ́n pè é ní “ẹlẹ́wọ̀n” lọ. Àmọ́ bóo bá baralẹ̀ wò ó dáadáa, wàá rí i pé ìṣòro ńlá ti dé bá àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n báyìí, irú bí ìgasókè nínú owó tí wọ́n fi ń bójú tó àwọn ọ̀daràn àti àbájáde ìfinisẹ́wọ̀n èyí tó ti wá yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí wọ́n torí ẹ̀ fi àwọn èèyàn sẹ́wọ̀n.

Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n kò múná dóko mọ́. Wọ́n kíyè sí i pé pẹ̀lú bí iye àwọn ẹlẹ́wọ̀n kárí ayé ṣe ròkè kọjá mílíọ̀nù mẹ́jọ, ìwà ọ̀daràn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kò torí ẹ̀ lọọlẹ̀. Kò tán síbẹ̀ o, pẹ̀lú pé àwọn oògùn tí kò bófin mu ló sọ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n dèrò ẹ̀wọ̀n, oògùn olóró ṣì pọ̀ bí eléèmọ̀ káàkiri, èyí sì ń kópayà báni.

Síbẹ̀síbẹ̀, tàgbà tèwe ló gbà pé ìfinisẹ́wọ̀n ni ọ̀nà ìfìyà jẹni tó tọ́. Bí wọ́n bá ju ọ̀daràn kan sẹ́wọ̀n, wọ́n ti gbà pé ìyà tó tọ́ sí i ló ń jẹ yẹn. Akọ̀ròyìn kan ṣàpèjúwe ìtara fífi àwọn ọ̀daràn sẹ́wọ̀n, ó pè é ní “ẹ̀mí ẹ-gbé-wọn-jù-sẹ́wọ̀n.”

Ìdí mẹ́rin pàtàkì ni wọ́n fi ń kó àwọn arúfin sẹ́wọ̀n: (1) láti fìyà jẹ àwọn ọ̀daràn, (2) láti dáàbò bo àwùjọ, (3) láti má ṣe jẹ́ kí ìwà ọ̀daràn ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àti (4) láti yí àwọn ọ̀daràn padà, ní kíkọ́ wọn láti ṣègbọràn sófin kí wọ́n sì tẹpá mọ́ṣẹ́ bí wọ́n bá jáde lẹ́wọ̀n. Ẹ jẹ́ ká wò ó bóyá àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n ń kẹ́sẹ járí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí.