Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Tó Wáyé Nígbà Ìjọba Násì Ṣé Ó Ṣì Tún Lè Ṣẹlẹ̀?

Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Tó Wáyé Nígbà Ìjọba Násì Ṣé Ó Ṣì Tún Lè Ṣẹlẹ̀?

Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Tó Wáyé Nígbà Ìjọba Násì Ṣé Ó Ṣì Tún Lè Ṣẹlẹ̀?

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ SWEDEN

NÍ January 26 sí 28, 2000, àwọn olórí Orílẹ̀-èdè àtàwọn aṣojú ìjọba méjìdínláàádọ́ta kárí ayé kóra jọ sí olú ìlú ilẹ̀ Sweden fún Àpérò Àgbáyé ti Stockholm Nípa Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Náà. Àwọn ọ̀rọ̀ táwọn kan sọ látorí pèpéle fi hàn pé ẹ̀rù ń ba àwọn aṣáájú ayé pé ètò ìjọba Nazi tún fẹ́ rú yọ. Ehud Barak tó jẹ́ Olórí Ìjọba Ísírẹ́lì tẹ́lẹ̀rí sọ pé: “Gbogbo ayé ni àpérò yìí ń bá sọ̀rọ̀ o, pé: Kò gbọ́dọ̀ tún ṣẹlẹ̀ mọ́ láé pé kí ẹnì kan, ní ibi yòówù kó wà lórí ilẹ̀ ayé fàyè gba ìjọba láabi, ìṣìkàpànìyàn, àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà láàárín àwọn ènìyàn nítorí ẹ̀sìn, ẹ̀yà tàbí àwọ̀.”

Kì Í Ṣàwọn Júù Nìkan Ló Ká Lára

Ọ̀pọ̀ èèyàn lágbàáyé ronú pé àwọn Júù nìkan ni “Ìpakúpa Rẹpẹtẹ” náà kàn. Àmọ́, ó tún kan àwọn mìíràn pẹ̀lú. Níbi ayẹyẹ ìrántí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ àwọn Júù tí wọ́n kéde nílé lóko, èyí tó wáyé ní Sínágọ́gù Ńlá ti Stockholm nígbà àpérò náà, olórí ìjọba Sweden dábàá pé kí gbogbo wọn ṣèlérí pé wọ́n máa pèsè ìlàlóye nípa Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà fún gbogbo èèyàn láwọn ibi ìkówèésí káàkiri ayé. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe pa ẹ̀yà Roma [àwọn Gypsy] run, bí wọ́n ṣe pa àwọn aláàbọ̀ ara lọ ràì àti bí wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sáwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, àwọn tó yapa àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n sì ṣìkà pa wọ́n.”

Ìjọba ilẹ̀ Sweden ti ṣe ìwé kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Tell Ye Your Children lórí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà, ọ̀fẹ́ ni wọ́n pín in fún gbogbo agboolé táwọn ọmọ wà káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Ìtẹ̀jáde yìí sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “kọ̀ láti búra pé àwọn máa ti Hitler àti ìjọba Násì ti Jámánì lẹ́yìn. Irú kíkọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀ nítorí ká ní wọ́n kàn fọwọ́ sí ìwé tó fi hàn pé wọ́n ti ìjọba yẹn lẹ́yìn ni, inúnibíni ọ̀hún ì bá dópin—síbẹ̀ ìwọ̀nba díẹ̀ ló ṣe bẹ́ẹ̀.”

Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Náà àti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ní 1933, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà ní Jámánì. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára wọn wà lára àwọn èèyàn tí wọ́n kọ́kọ́ jù sáwọn àgọ́ Násì àti ọgbà ẹ̀wọ̀n. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, wọ́n jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé kò sóhun tó kàn wọ́n kan oríṣiríṣi ìgbòkègbodò ìṣèlú àti ti ológun. Wọn kò kókìkí Hitler. Wọ́n kọ̀ láti fara mọ́ èròǹgbà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ìjọba Násì wọn ò sì dára pọ̀ mọ́ ètò òṣèlú àti ẹgbẹ́ ológun Hitler. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ló kú, nǹkan bí àádọ́ta dín nírínwó lára àwọn wọ̀nyí ni wọ́n yẹgi fún.

Kò tán síbẹ̀ o, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lẹ́wọ̀n ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n bí i tiwọn lọ́wọ́ láti fara dà á, títí kan àwọn Júù àtàwọn mìíràn. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ nípa gbígbin ìrètí tó wà nínú Bíbélì sí wọn lọ́kàn àti ṣíṣàjọpín ohunkóhun tí wọ́n bá ní pẹ̀lú àwọn tára wọn ò yá àtàwọn tára wọn ò ṣe ṣámúṣámú, lọ́pọ̀ ìgbà ni wọ́n ń fi gbogbo oúnjẹ tó kù lọ́wọ́ wọn tọrẹ. Láàárín àwọn ọdún tí inúnibíni ìjọba Násì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, wọ́n dọ́gbọ́n fi àwọn ìsọfúnni ránṣẹ́ sáwọn àgbègbè tí kò sí lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba Násì pé, àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ wà o, àwọn nǹkan báyìí-báyìí ló sì ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Látìgbà yẹn, wọ́n ti tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpilẹ̀kọ lórí ìwà ìkà ìjọba Násì àti ìrírí àwọn tó là á já jáde nínú ìwé ìròyìn wọn Ilé Ìṣọ́  àti Jí! tí wọ́n ń pín kárí ayé.

Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi Àpérò Àgbáyé ti Stockholm nípa Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Náà ń kọminú pé ètò ìjọba Násì tún lè rú yọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n Yehuda Bauer tó jẹ́ olùdarí Ibùdó Ìwádìí Nípa Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Náà Lágbàáyé, èyí tó wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Júù Òde Òní ní Ísírẹ́lì sọ ọ́ báyìí pé: “Nítorí pé ó ti ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan rí, ó tún lè ṣẹlẹ̀, kì í ṣe lọ́nà tó gbà ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó sì lè máà jẹ́ sáwọn èèyàn ti tẹ́lẹ̀, kì í ṣe àwọn tó fa ti tẹ́lẹ̀ ló máa fà á, àmọ́ ó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni, ẹnikẹ́ni sì lè dá a sílẹ̀. Irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, àmọ́ èyí tó ṣẹlẹ̀ ti wá di àpẹẹrẹ.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò ló fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà hàn yàtọ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30, 31]

1. Ìjọba Násì ló pa Julius Engelhardt, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brandenburg ní August 14, 1944

2. Mẹ́ta lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbọ̀nà ilé lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀ Sachsenhause lọ́dún 1945

3. Elsa Abt, Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n mú kúrò lọ́dọ̀ ọmọ rẹ̀ obìnrin kékeré tí wọ́n sì fi sẹ́wọ̀n fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta

[Credit Line]

Nordrhein-West fälisches Hauptstaatsarchiv, Düsseldorf

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn Elẹ́rìí tí wọ́n rù ú là sọ ìtàn wọn sínú àwọn fídíò wọ̀nyí