Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìsìn Tí Ilẹ̀ Soviet Dojú Àtakò Kọ

Ìsìn Tí Ilẹ̀ Soviet Dojú Àtakò Kọ

Ìsìn Tí Ilẹ̀ Soviet Dojú Àtakò Kọ

ILẸ̀ Soviet kò jẹ́ kí ṣọ́ọ̀ṣì rímú mí láìfi àwọn ẹ̀tọ́ náà pè, èyí tó ní òun fún Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà nítorí àtiṣẹ́gun nínú Ogun Àgbáyé Kejì. Nípa bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìwé The Sword and the Shield tí wọ́n kọ ní 1999, tó dá lórí ìtàn KGB (Ìgbìmọ̀ Aláàbò fún Ìjọba Soviet) ṣe sọ, “‘ìgbòkègbodò tó lè dojú ìjọba dé’ táwọn Kristẹni tí KGB ò lágbára láti darí ní tààràtà ń ṣe kó ìdààmú bá a lọ́pọ̀lọpọ̀.” Àwùjọ àwọn ẹlẹ́sìn wo làwọn wọ̀nyí?

Ìjọ Kátólíìkì Gíríìkì ti Ukraine ló tóbi jù lọ nínú wọn, èyí tó ti wá di Ìjọ Kátólíìkì àwọn ará Ukraine báyìí. Ó ní àwọn mẹ́ńbà tó tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rin. Gẹ́gẹ́ bí The Sword and the Shield ṣe sọ, “gbogbo àwọn bíṣọ́ọ̀bù rẹ̀ mẹ́wàá, yàtọ̀ sáwọn méjì kan, pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àlùfáà àtàwọn onígbàgbọ́ ni wọ́n kú sínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ní Siberia nítorí ìgbàgbọ́ wọn.” Àwọn mìíràn tí ìgbìmọ̀ KGB tún halẹ̀ mọ́ ni àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọn ò lórúkọ lábẹ́ òfin, tó jẹ́ pé kì í ṣe Ìjọba ló ń darí àwọn náà ní tààràtà. Bí àwọn ọdún 1950 ti ń parí lọ, ìgbìmọ̀ KGB ọ̀hún fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, àwọn àwùjọ Pùròtẹ́sítáǹtì lápapọ̀ ní tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn ún [100,000] mẹ́ńbà.

Ara àwùjọ Pùròtẹ́sítáǹtì ni ìgbìmọ̀ KGB ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, tí wọ́n fojú bu iye wọn ní 1968 pé wọ́n á máa lọ sí bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún [20,000] ní Soviet Union. Títí di ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ Ogun Àgbáyé Kejì ní 1939, iye àwọn Ẹlẹ́rìí kéré gan an. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ pe àfiyèsí sí wọn. Àmọ́ bìrí ni ipò nǹkan yí nígbà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ṣàdédé fojú hàn ní Soviet Union. Báwo ni èyí ṣe ṣẹlẹ̀?

Ìbísí Pípabanbarì Bẹ̀rẹ̀

Walter Kolarz, nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Religion in the Soviet Union tó ṣe jáde ní 1961 sọ ohun méjì pàtàkì tó fa ìbísí pípabanbarì yìí. Ọ̀kan lára rẹ̀, gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ ni, “àwọn ìpínlẹ̀ tuntun tí Soviet Union sọ di apá kan ara rẹ̀ ní ọdún 1939 sí 1940”—àwọn ni Latvia, Lithuania, Estonia, àti Moldavia—tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ “àwùjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà onítara.” Láfikún sí i, àwọn apá ibì kan lára ìlà oòrùn Poland àti Czechoslovakia tó ní àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé lẹ́gbẹ̀rún kan tún wà lára àwọn tí Soviet Union gbà mọ́ra, tí wọ́n sì di apá kan Ukraine. Bẹ́ẹ̀ ló di pé, ọ̀sán-kan-òru-kan ni gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí rí ara wọn tí wọ́n dẹni tó ń gbé ní Soviet Union.

Kolarz kọ̀wé pé, “bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè dún létí bí ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́” ìbísí tún wá látinú “àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Jámánì.” Ìjọba Násì ti kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí dà sẹ́wọ̀n fún kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti ti Hitler àti ogun tó fọwọ́ ara rẹ̀ fà lẹ́yìn. Kolarz ṣàlàyé pé àwọn ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n nínú àwọn àgọ́ yìí “ti kíyè sí ìgboyà àti ìdúróṣinṣin àwọn ‘Ẹlẹ́rìí’ náà, ó sì wú wọn lórí, ó lè jẹ́ ìyẹn ló wá mú kí ìlànà ìsìn wọn fà wọ́n mọ́ra.” Àbájáde rẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà tó jáde látinú àwọn àgọ́ náà ló padà sí Soviet Union pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tuntun nínú Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn àgbàyanu ète rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé.—Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4.

Nítorí irú àwọn kókó bẹ́ẹ̀, kíá làwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Soviet Union ti di ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Nígbà tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1946, ó kéré tán, wọ́n ti di ẹgbẹ̀jọ, nígbà tó sì máa fi di ìparí ẹ̀wádún náà, wọ́n ti lé lẹ́gbẹ̀rún mẹ́jọ dáadáa. Ìbísí yìí kó ìdágìrì bá ìgbìmọ̀ KGB, torí pé, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ níṣàájú, wọ́n ń ṣàníyàn gidigidi nípa “ìgbòkègbodò àwọn Kristẹni tí wọn ò lágbára láti darí ní tààràtà.”

Àtakò Bẹ̀rẹ̀

Láìka ti pé iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Soviet Union kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí, kò pẹ́ rárá tí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù onítara wọn fi dojú kọ àtakò àwọn aláṣẹ Soviet. Ní Estonia, àtakò náà bẹ̀rẹ̀ ní August 1948 nígbà tí wọ́n fàṣẹ ọba mú àwọn márùn-ún tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ náà tí wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Lembit Toom tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ará Estonia sọ pé: “Kò pẹ́ tó fi hàn gbangba sí wa pé gbogbo wa pátá làwọn ìgbìmọ̀ KGB yìí fẹ́ fàṣẹ ọba mú.” Bọ́rọ̀ ti jẹ́ nìyẹn níbikíbi tí wọ́n bá ti rí àwọn Ẹlẹ́rìí ní ilẹ̀ Soviet Union.

Soviet ṣàpèjúwe àwọn Ẹlẹ́rìí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀daràn tó burú jù lọ àti pé wọ́n jẹ́ ewú ńlá fún Ìjọba ilẹ̀ Soviet tí kò gbà pé Ọlọ́run wà. Nítorí náà, wíwá ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá wọn kiri, tí wọ́n ń fàṣẹ ọba mú wọn, tí wọ́n sì ń sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. Ìwé The Sword and the Shield sọ pé: “Ó dà bí pé dídájú tí àwọn aṣáájú ìgbìmọ̀ KGB dájú sọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ àpẹẹrẹ gígajù tó ń fi hàn pé wọn kò mọ ohun tó ṣe pàtàkì nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó ohun tí kò ṣeé fúnka mọ́.”

Dídájú tí wọ́n dájú sọ wọ́n yìí túbọ̀ wá hàn gbangba nínú àtakò kan tí wọ́n wéwèé rẹ̀ mọ́ránmọ́rán tí wọ́n sì gbé jáde sáwọn Ẹlẹ́rìí ní April 1951. Lẹ́nu bí ọdún méjì sẹ́yìn, ìyẹn ní 1999, Ọ̀jọ̀gbọ́n Sergei Ivanenko, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan táa bọ̀wọ̀ fún, sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The People Who Are Never Without Their Bibles pé níbẹ̀rẹ̀ oṣù April ọdún 1951, “ó lé lẹ́gbẹ̀rún márùn-ún ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti Ukraine, Byelorussia, Moldavia, àtàwọn orílẹ̀-èdè olómìnira ti Baltic Soviet tí wọ́n kó lọ sí ‘ibùgbé àrèmábọ̀’ ní Siberia, Ìlà Oòrùn Siberia Jíjìnnà, àti Kazakhstan.”

Ohun Tó Yẹ Ká Máa Rántí Ni

Ṣé o lè fojú inú wo òpò tí wọ́n ṣe nítorí àtakò náà—tí wọ́n fi ọjọ́ kan palẹ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́ ráúráú kúrò ní gbogbo àgbègbè tó fẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ yẹn? Ronú ohun tó ná wọn láti kó ọgọ́rọ̀ọ̀rún, bí kì í bá ṣe ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn jọ fún iṣẹ́ ọ̀hún, àkọ́kọ́, wọ́n ní láti dá àwọn Ẹlẹ́rìí náà mọ̀, lẹ́yìn náà, wọ́n á wá fòru dúdú bojú lọ sílé wọn, wọ́n á sì kó gbogbo wọn lójijì nínú ilé wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n á tún kó àwọn èèyàn náà sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin, ọkọ̀ akẹ́rù, àtàwọn ọkọ̀ míì; tí wọ́n á kó wọn lọ sáwọn ibùdó ọkọ̀ ojú irin; ibẹ̀ ni wọ́n á sì ti kó wọn dà sínú ọkọ̀ ojú irin.

Tún wá ronú ìyà tó jẹ àwọn tí wọ́n kó náà. Ǹjẹ́ o lè ronú bó ṣe máa rí láti fipá mú èèyàn rìnrìn àjò ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà—fún bí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, nínú ọkọ̀ ojú irin tó kún àkúnya, tí kò dára fún ìlera, tó jẹ́ pé korobá kan ni wọ́n ní gẹ́gẹ́ bí ilé ìyàgbẹ́? Tún ronú nípa kí wọ́n kàn já èèyàn sílẹ̀ nínú aginjù Siberia, ní mímọ̀ pé béèyàn ò bá sán ṣòkòtò ẹ̀ dáadáa láti wá nǹkan tó máa jẹ lágbègbè tó gbẹ táútáú yẹn, ikú yá nìyẹn.

Oṣù táa wà yìí ni àyájọ́ àádọ́ta ọdún tí wọ́n kó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sígbèkùn, ìyẹn ní April 1951. Káwọn tó làá já lè sọ ìtàn nípa bí wọ́n ṣe dúró ṣinṣin láìka àwọn ẹ̀wádún tí wọn fi ṣe inúnibíni sí wọn sí, àwọn ìrírí wọn ní a ti gbà sílẹ̀ sínú fídíò. Àwọn ìrírí yìí fi hàn pé—àní gẹ́gẹ́ bó ṣe rí pẹ̀lú àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní—ó dájú pé pàbó ni gbogbo ìgbìdánwò láti dí àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run yóò máa já sí.

Ohun Tí Ìkólọsígbèkùn Náà Mú Jáde

Kò pẹ́ táwọn ará Soviet fi mọ̀ pé yóò ṣòro kọjá báwọn ṣe rò láti dí àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ láti sin Jèhófà. Láìkọbi ara sí àtakò tí àwọn tó kó wọn ń ṣe, ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí náà ń kọrin ìyìn sí Jèhófà bí wọ́n ti ń fipá kó wọn lọ sígbèkùn tí wọ́n sì gbé àmì kan kọ́ sára àwọn ọkọ̀ ojú irin náà tó sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ló Wà Nínú Ọkọ̀ Ojú Irin Yìí.” Ẹlẹ́rìí kan ṣàlàyé pé: “Báa ti ń dé àwọn ibùdó ojú irin tó wà lọ́nà, bẹ́ẹ̀ la ń pàdé àwọn mìíràn tí wọ́n ń kó lọ sígbèkùn táa sì rí àwọn àmì táwọn náà gbé kọ́ sára àwọn ọkọ̀ ojú irin wọn.” Ìṣírí ńlá gbáà lèyí jẹ́ fún wa!

Nítorí náà, dípò tínú àwọn tí wọ́n ń kó lọ sígbèkùn náà ì bá fi máa bàjẹ́, irú ẹ̀mí táwọn àpọ́sítélì Jésù ní ni wọ́n gbé yọ. Bíbélì sọ pé lẹ́yìn tí wọ́n ti nà wọ́n tí wọ́n sì pàṣẹ fún wọn láti dáwọ́ wíwàásù dúró, “wọ́n . . ń báa lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà.” (Ìṣe 5:40-42) Àní sẹ́, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Kolarz sọ nípa ìkólọsígbèkùn náà, “èyí kọ́ lòpin àwọn ‘Ẹlẹ́rìí’ ní Rọ́ṣíà o, àmọ́ ó wulẹ̀ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ tuntun míì ni nínú ìgbòkègbodò wọn ti yíyí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà. Àní wọ́n tiẹ̀ tún gbìyànjú láti tan ìgbàgbọ́ wọn kálẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dúró láwọn ibùdó ojú irin lójú ọ̀nà wọn lọ sí ìgbèkùn.”

Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí náà dé ibi tí wọ́n ń lọ tí wọ́n sì já wọn jù sílẹ̀, wọ́n mọ̀ wọ́n fún ìwà rere wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn tó jẹ́ onígbọràn àti òṣìṣẹ́ kára. Síbẹ̀, ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì Kristi, ohun tí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ sọ fún àwọn aninilára wọn ni pé: ‘Àwa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run wa.’ (Ìṣe 4:20) Ọ̀pọ̀ fetí sóhun táwọn Ẹlẹ́rìí ń kọ́ni wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ wọn nínú sísin Ọlọ́run.

Àbájáde rẹ̀ kò yàtọ̀ rárá sí ohun tí Kolarz sọ, pé: “Ńṣe ni Ìjọba Soviet wulẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tan ìgbàgbọ́ wọn kálẹ̀ nípa lílé wọn kúrò nílùú. Ńṣe ni kíkó tí wọ́n kó àwọn ‘Ẹlẹ́rìí’ kúrò lábúlé àdádó wọn tẹ́lẹ̀ rí [ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè olómìnira Soviet] mú wọn wá sójútáyé, kódà ká tiẹ̀ ní ibẹ̀ jẹ́ àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti àgọ́ ìsìnrú tó tíì burú jù lọ.”

Àwọn Ìsapá Láti Dí Ìdàgbàsókè Wọn Lọ́wọ́

Bí àkókò ti ń lọ, àwọn ará Soviet tún gbìyànjú oríṣiríṣi ọ̀nà mìíràn láti pa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu mọ́. Níwọ̀n bí inúnibíni rírorò kò ti ṣàṣeyọrí ohun tí wọ́n ń fẹ́, ni wọ́n bá dágbá lé ìpolongo èké ti irọ́ pípa tí wọ́n wéwèé rẹ̀ mọ̀ràn-ìn-mọran-in. Kò sóhun tí wọn ò gbìyànjú ẹ̀—wọn lo ìwé, wọ́n lo fíìmù, wọ́n tún lo ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí rédíò—títí kan àwọn amí tí wọ́n ti dá lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa nínú ìgbìmọ̀ KGB láti yọ́ wọ àárín ìjọ.

Ọ̀rọ̀ ìbanilórúkọjẹ́ tí wọ́n tàn kálẹ̀ yìí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa fi àṣìṣe wo àwọn Ẹlẹ́rìí bí àwọn ẹni téèyàn ń bẹ̀rù àti bí àwọn tí kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, gẹ́gẹ́ bí èyí ti fara hàn nínú àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Reader’s Digest ti August 1982, ìtẹ̀jáde ti Kánádà. Ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan tó ń jẹ́ Vladimir Bukovsky tí wọ́n yọ̀ǹda fún láti wá máa gbé ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní 1976 ló kọ ọ́. Ó kọ ọ́ pé: “Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan ní London, mo bá rí pákó ìsọfúnni kan lára ilé kan, ohun tí wọ́n kọ́ sára ẹ̀ ni: ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ . . . Mí ò lè kà jùyẹn lọ, ẹ̀rù bà mí débi pé jìnnìjìnnì fẹ́rẹ̀ẹ́ mú mi.”

Vladimir ṣàlàyé ìdí tí ìbẹ̀rù tí kò nídìí fi mú òun, ó ní: “Àwọn wọ̀nyí ni ẹgbẹ́ òkùnkùn táwọn aláṣẹ ní orílẹ̀-èdè wa máa ń lò láti fi dún kùkùlajà mọ́ àwọn ọmọdé . . . Ní U.S.S.R., kìkì inú ẹ̀wọ̀n àtàwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lẹ ti lè rí àwọn ògidì ‘Ẹlẹ́rìí.’ Òun ni mó wá bára mi níwájú ilé kan yìí tí ohun tí wọ́n kọ sí i fi hàn pé àwọn ló wà níbẹ̀. Ó wá béèrè pé: ‘Ṣé wọ́n á dẹ̀ rẹ́nì kankan tó máa wọbẹ̀ láti yọjú sí wọn báyìí?’” Láti lè tẹnu mọ́ ìdí fún igbe ìbòòsí tó fi bọnu, Vladimir kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Tìbínú-tìbínú ni wọ́n fi máa ń lé àwọn ‘Ẹlẹ́rìí’ dà nù lórílẹ̀-èdè wa bí wọ́n ṣe máa ń lé àwọn Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn lórílẹ̀-èdè tí wọ́n bá wà, àwọn èèyàn ò sì lóye àwọn méjèèjì.”

Síbẹ̀, láìka inúnibíni rírorò àti ìpolongo èké yìí sí, àwọn Ẹlẹ́rìí ń bá a nìṣó, bẹ́ẹ̀ ni iye wọn sì ń pọ̀ sí i. Àwọn ìwé ilẹ̀ Soviet irú bíi The Truths About Jehovah’s Witnesses, tí iye tí wọ́n tẹ̀ jáde lédè Rọ́ṣíà lọ́dún 1978 ń lọ sí bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ẹ̀dà, dámọ̀ràn pé ó yẹ kí wọ́n jára mọ́ ìpolongo èké lòdì sí àwọn Ẹlẹ́rìí. V. V. Konik tó jẹ́ òǹkọ̀wé náà, ẹni tó ṣàpèjúwe bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ń bá ìwàásù wọn lọ lójú ìkálọ́wọ́kò lílekoko, dámọ̀ràn pé: “Ó yẹ káwọn tó ń ṣèwádìí nípa ìsìn ní ilẹ̀ Soviet túbọ̀ lọ kọ́ nípa ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tí wọ́n lè fi ṣẹ́pá ẹ̀kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

Kí Ló Mú Kí Wọ́n Dájú Sọ Wọ́n?

Láìdéènà pẹnu, nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣàfarawé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ìjímìjí ló mú kí ilẹ̀ Soviet dìídì dojú àtakò kọ wọ́n. Ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n pa á láṣẹ fáwọn àpọ́sítélì “láti má ṣe máa kọ́ni nípa orúkọ [Jésù].” Síbẹ̀, àwọn tó ṣe inúnibíni sí wọn tún ráhùn lẹ́yìn náà pé: “Wò ó! ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù.” Àwọn àpọ́sítélì náà kò sẹ́ pé àwọn ti ń bá a lọ láti máa wàásù láìka àṣẹ tí wọ́n fún wọn láti má ṣe bẹ́ẹ̀ sí, àmọ́, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n dáhùn pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:27-29.

Bákan náà lónìí, ọwọ́ dan-in-dan-in làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú àṣẹ tí Jésù pa fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ “láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná.” (Ìṣe 10:42) Maurice Hindus, nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The Kremlin’s Human Dilemma sọ pé “ìtara tí kò ṣeé paná ẹ̀” táwọn Ẹlẹ́rìí ní “fún ìwàásù” ló sọ wọ́n di “oníjọ̀ngbọ̀n lọ́dọ̀ ìjọba Moscow tó sì [ń mú] wọn forí gbárí pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Soviet nígbà gbogbo.” Ó fi kún un pé: “Kò sóhun tó lè pa wọ́n lẹ́nu mọ́. Bí wọ́n bá tẹ̀ wọ́n rì níbì kan, wọ́n á tún rú yọ níbòmíì.”

Sergei Ivanenko, òpìtàn ilẹ̀ Rọ́ṣíà kọ̀wé pé: “Níbi tó yé mi dé o, ètò àjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni ẹgbẹ́ onísìn tí iye wọn ń pọ̀ sí i ní USSR láìka ìfòfindè àti inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wọ́n sí.” Lóòótọ́, àwọn ìsìn mìíràn náà kò jáwọ́, títí kan èyí tó jẹ́ òléwájú nínú gbogbo wọn, ìyẹn Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Yóò gbádùn mọ́ ọ láti mọ̀ nípa bí ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe bọ́ lọ́wọ́ àtakò ìjọba ilẹ̀ Soviet.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

“Ẹgbẹ́ Onísìn   Tí Wọ́n Ṣe Inúnibíni Rírorò sí Jù Lọ”

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, A Concise Encyclopædia of Russia ti 1964 sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “kò kẹ̀rẹ̀ rárá nínú iṣẹ́ ká yíni lọ́kàn padà” àwọn náà sì tún ni “ẹgbẹ́ onísìn tí wọ́n ṣe inúnibíni rírorò sí jù lọ ní ilẹ̀ Soviet Union.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ó JẸ́ Ọ̀KAN LÁRA ẸGBẸẸGBẸ̀RÚN WỌN—Fyodor Kalin Ṣàpèjúwe Ìkólọsígbèkùn Ìdílé Rẹ̀

Abúlé Vilshanitsa lápá ìwọ̀ oòrùn Ukraine ni ìdílé wa ń gbé. Ilẹ̀ kò tíì mọ́ rárá lówùúrọ̀ April 8, 1951 nígbà táwọn ọlọ́pàá tó kó ajá dání dé, wọ́n jí wa, wọ́n sì sọ fún wa pé àwọ́n ń kó wa lọ sí Siberia níbàámu pẹ̀lú àṣẹ tó wá látọ̀dọ̀ ìjọba ní Moscow. Àmọ́ táa bá lè fọwọ́ sí ìwé kan tó sọ pé a kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, ó ṣeé ṣe fún wa láti dúró. Ìdílé wa ẹlẹ́ni méje, ìyẹn àwọn òbí mi àtàwa ọmọ wọn pinnu láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni mí nígbà yẹn.

Ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá náà sọ fún wa pé: “Ẹ jẹ́ kó ẹ̀wà, ọkà, ìyẹ̀fun, oúnjẹ tó ṣeé fi pa mọ́, àti cabbage dání—àbí báwo lẹ ṣe máa rí oúnjẹ fún àwọn ọmọ yín?” Wọ́n tún fún wa láyè kí á pa àwọn adìyẹ díẹ̀ àti ẹlẹ́dẹ̀ kan ká sì kó wọn dání. Wọ́n kó àwọn ọkọ̀ ẹrù méjì tí ẹṣin ń fà wá, wọ́n di gbogbo ẹrù wa sínú wọn, wọ́n sì kó wa lọ sí ìlú Hriplin. Níbẹ̀, wọ́n fún àwa bí ogójì sí àádọ́ta pọ̀ sínú ọkọ̀ ojú irin akẹ́rù kan, wọ́n sì tilẹ̀kùn pa.

Ọkọ̀ náà ní àwọn pákó bíi mélòó kan táa lè sùn lé àmọ́ kò tó fún gbogbo wa—ó tún ní sítóòfù kan àti èédú tòun ti igi díẹ̀. Sítóòfù yẹn la fi ń dáná, táa sì ń lo àwọn nǹkan ìgbọ́únjẹ táa kó dání. Àmọ́ kò sílé ìyàgbẹ́—korobá kan la kàn ń lò. Nígbà tó yá, a gbẹ́ ihò róbótó kan sílẹ̀ ọkọ̀ náà, a ki korobá náà bọ̀ ọ́, a sì fi àwọn aṣọ ìbora bò ó yíká kó lè bo ẹni tó bá wà níbẹ̀.

Gádígádí la há mọ́ inú ọkọ̀ ojú irin náà bí a ti ń rìnrìn àjò ẹlẹ́gbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà náà lọ díẹ̀díẹ̀ síbi tí a kò mọ̀. Níbẹ̀rẹ̀, ìbànújẹ́ fẹ́ dorí wa kodò. Àmọ́ báa ti ń kọ àwọn orin Ìjọba pa pọ̀ pẹ̀lú ìtara, débi pé a fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè sọ̀rọ̀ mọ́ lẹ́yìn náà—ńṣe layọ̀ kún ọkàn wa. Ọ̀gá tó wà níbẹ̀ á ṣí ilẹ̀kùn á sì sọ fún wa pé ká dákẹ́, àmọ́ bí a ò kọ orin náà tán, a ò ní panu mọ́. Nígbà táa bá dúró láwọn ibùdó ọkọ̀ ojú irin, ọ̀pọ̀ ló ń mọ̀ pé wọ́n ń kó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sígbèkùn. Níkẹyìn, lẹ́yìn táa ti lo bí ọjọ́ mẹ́tàdínlógún sí méjìdínlógún nínú ọkọ̀ ojú irin yẹn, wọ́n já wa dà sílẹ̀ ní Siberia nítòsí Adágún Baikal.

[Àwòrán]

Èmi ni mo dúró nílà ẹ̀yìn yẹn, lápá ọ̀tún

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

ARMAGEDDON—Fíìmù Tí Ilẹ̀ Soviet Fi Ṣe Ìpolongo Èké

Ilẹ̀ Soviet ṣe fíìmù kan jáde tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Armageddon nínú akitiyan wọn láti bẹ̀tẹ́ lu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó jẹ́ ìtàn àròsọ tó dá lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ láàárín ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó wà nínú ẹgbẹ́ ológun ilẹ̀ Soviet àti ọ̀dọ́mọbìnrin kan táwọn Ẹlẹ́rìí tàn jẹ láti di ara wọn. Ní ìparí fíìmù ọ̀hún, ọmọdébìnrin kékeré kan tó jẹ́ àbúrò ọ̀dọ́mọbìnrin náà kú nínú jàǹbá kan tí alábòójútó kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí fà, ẹni tí wọ́n ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ilẹ̀ Amẹ́ríkà ń lò láti ṣe amí.

Nígbà tí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Ukraine The Red Flag ti May 14, 1963 ń sọ nípa fíìmù náà, èyí tó ru ìmọ̀lára gbogbo àwọn tó wò ó sókè, ó sọ pé: “Ní irú ọ̀nà yẹn, ìpolongo èké àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà máa ń gbéṣẹ́, ó ń yíni lérò padà, wọ́n sì tún lè lò ó láwọn abúlé míì lórílẹ̀-èdè yìí níbi tí wọ́n bá ti ṣàfihàn irú fíìmù náà.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Wọ́n fi ọkọ̀ ojú irin kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ sí Siberia