Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ó Ń kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́, Ó Ń pèsè Ìsọfúnni’

‘Ó Ń kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́, Ó Ń pèsè Ìsọfúnni’

‘Ó Ń kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́, Ó Ń pèsè Ìsọfúnni’

Ọ̀rọ̀ òkè yìí ni ọkùnrin ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n kan tó ń gbé Ilẹ̀ Olókè ní Papua New Guinea fi ṣàpèjúwe Jí!

Nínú lẹ́tà tó kọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àdúgbò náà, ó sọ pé: “Mo yìn yín fún títẹ àwọn àpilẹ̀kọ tó péye, tó ń sọ òkodoro òtítọ́, tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, tó sì kún fún ìsọfúnni nípa àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé ìròyìn Jí! yín tó gbajúmọ̀.” Ọkùnrin náà ṣàlàyé pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé n kì í ṣe mẹ́ńbà ìsìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mó máa ń gbádùn kíka àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn Jí! gan an ni, èyí tí mó máa ń yá lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́. . . . Kò sígbà tí mo bá ka ẹ̀dà kan tí kì í ṣe mí bíi ki ń kọ̀wé sí i yín láti gbóríyìn fún iṣẹ́ takuntakun yín. Àmọ́ bí mo bá ti fẹ́ kọ ọ́ báyìí, ni òmíràn á tún dé tí kò sì ní jẹ́ kí n ráyè mọ́.”

Òǹkàwé tó fi ìmọrírì hàn yìí parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Lójú tèmi o, kòṣeémáàní ni Jí! jẹ́ ní ti gidi fún ẹnikẹ́ni tó bá mọ̀wéé kà. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.”

Jí! ń pèsè ìlàlóye lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kókó ẹ̀kọ́. Àmọ́ ní pàtàkì jù lọ, ó ń gbé ìgbọ́kànlé ró nínú ìlérí Ẹlẹ́dàá náà nípa ayé tuntun alálàáfíà kan tó máa rọ́pò ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.

Ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n náà Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tẹnu mọ́ ète Ọlọ́run, nípa pípèsè ìsọfúnni látinú Bíbélì láti fi ohun táa gbọ́dọ̀ ṣe hàn wá báa bá fẹ́ rí ojú rere rẹ̀. O lè béèrè fún ẹ̀dà kan nípa kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tí a tò sí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.