Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé ó Ṣeé Ṣe—Lóòótọ́ Láti Yí Àwọn Ọ̀daràn Padà?

Ṣé ó Ṣeé Ṣe—Lóòótọ́ Láti Yí Àwọn Ọ̀daràn Padà?

Ṣé ó Ṣeé Ṣe—Lóòótọ́ Láti Yí Àwọn Ọ̀daràn Padà?

“Kò sẹ́ni tó lè fi ọ̀ranyàn mú ẹlòmíràn yí padà. Ó gbọ́dọ̀ wá látinú onítọ̀hún fúnra rẹ̀ kí ó sì fẹ́ yí padà.”—VIVIEN STERN, A SIN AGAINST THE FUTURE—IMPRISONMENT IN THE WORLD.

KÓKÓ pàtàkì kan tó lè mú káwọn ẹlẹ́wọ̀n yí padà lóòótọ́ dá lórí ẹ̀kọ́ àti yíyí ìwà òun èrò padà. Ó dájú hán-ún pé àwọn kan wà tí wọ́n ń ṣakitiyan tọkàntọkàn láti kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì tún ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ẹlẹ́wọ̀n ló mọrírì iṣẹ́ aláǹfààní táwọn èèyàn náà ń ṣe.

Àwọn èèyàn kan á sọ pé ọgbà ẹ̀wọ̀n látòkèdélẹ̀ ti kọjá àtúnṣe pé kò fi bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n láti yí padà nírú àyíká bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ ni pé ìfinisẹ́wọ̀n nìkan kò ní kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí hùwà tó dáa, àwọn ìtọ́ni Bíbélì ti ran àwọn kan lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé wọn padà. Èyí fi hàn pé ó ṣeé ṣe káwọn kan yí ìwà wọn padà.

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Bíbélì, àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan lónìí ń ṣe àwọn ìyípadà tó ń mú kí wọ́n ronú kí wọ́n sì hùwà lọ́nà tó dáa. Báwo? Nípa ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe èyí?

Ipa Tí Bíbélì Ń Kó

Ọ̀pọ̀ èèyàn ronú pé ìsìn lè kó ipa ribiribi nínú ríran àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe. Lóòótọ́, ìṣòro kan tó wà níbẹ̀ ni pé ìyípadà èyíkéyìí tí ẹlẹ́wọ̀n kan bá ṣe lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lè pòórá ní gbàrà tí wọ́n bá dá a sílẹ̀. Ẹlẹ́wọ̀n kan sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé àwọn ti gba Kristi sáyé àwọn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àmọ́ bí wọ́n bá ti dá wọn sílẹ̀ báyìí, kò sóhun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́!”

Ìrírí ti fi hàn pé inú lọ́hùn-ún ni ojúlówó ìyípadà ti gbọ́dọ̀ wá—látinú èrò àti ọkàn ẹlẹ́wọ̀n náà ni ìyípadà tòótọ́ ti gbọ́dọ̀ wá, ó sì gbọ́dọ̀ jẹ́ lórí ìpìlẹ̀ ìfitọkàntọkàn ronú pìwà dà. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ Bíbélì lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti kọ́ nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwà ibi àti ìdí tí kò fi dára. Èyí lè fún un ní ìdí lílágbára tí kò fi ní í fẹ́ máa bá híhu irú ìwà bẹ́ẹ̀ nìṣó.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ Bíbélì bẹ́ẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọgbà ẹ̀wọ̀n káàkiri ayé, àbájáde rẹ̀ sì ń yani lẹ́nu. (Wo ojú ìwé kẹwàá) Ẹlẹ́wọ̀n kan sọ pé: “Wọ́n ti ràn wá lọ́wọ́ láti rí ohun tí Bíbélì sọ nípa ète ìgbésí ayé àti àwọn ìbùkún tó wà fún ìran ènìyàn lọ́jọ́ ọ̀la.” Ó fi kún un pé: “Ẹ̀kọ́ ọ̀hún kẹjẹgbẹ!” Ẹlẹ́wọ̀n mìíràn sọ pé: “Orí ìmọ̀ràn Ọlọ́run là ń gbé ìpinnu táa bá ṣe kà. . . . Àwa náà rí i pé a ti yí padà. A mọ àwọn nǹkan tó yẹ kó ṣáájú nínú ìgbésí ayé.”

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe inú ọgbà ẹ̀wọ̀n nìkan ni ìyípadà yẹn mọ sí. Mímú àwọn nǹkan tó ń mú kí ọgbà ẹ̀wọ̀n di kòṣeémáàní kúrò ni ojútùú tòótọ́ sí àwọn ìṣòro ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ọ̀kan lára àwọn òtítọ́ inú Bíbélì tó ti mú kí ọ̀pọ̀ ẹlẹ́wọ̀n ronú wà nínú ìlérí Ọlọ́run tó sọ pé: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò . . . Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:9, 29.

Nígbà tíyẹn bá rí bẹ́ẹ̀, ìjọba kan tí kò lábàwọ́n, tó nífẹ̀ẹ́ tí kò sì gba gbẹ̀rẹ́, ìyẹn Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run lábẹ́ Kristi—ìjọba tí a kọ́ àwọn Kristẹni láti gbàdúrà fún ni yóò mú kí ìlànà Ọlọ́run tó dára jù lọ fẹsẹ̀ múlẹ̀. (Mátíù 6:10) Nínú ayé tuntun yẹn, gbogbo àwọn tó bá wà níbẹ̀ ló máa yí padà nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn òfin Ọlọ́run tó dára jù lọ. Nígbà náà ni ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí náà pé “ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun,” yóò ní ìmúṣẹ. (Aísáyà 11:9) Kí ni yóò wá tibẹ̀ jáde? Àwọn olùgbé inú ayé tuntun náà tí wọ́n jẹ́ olùpa òfin mọ́ á wá “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Jíjẹ́ Kí Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Rí Ìmọ́lẹ̀ Ayọ̀

Ó ti lé lógún ọdún táwọn òjíṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ tó kẹ́sẹ járí tí a gbé karí Bíbélì ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba àpapọ̀ ní Atlanta, Georgia, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó lé ní ogójì ni a ti ràn lọ́wọ́ láti di òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi láàárín àkókò náà, àwọn tó sì ti jàǹfààní látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé lé ní àádọ́rùn-ún.

Láìpẹ́ yìí ni Jí! bá àwọn olùkọ́ bíi mélòó kan tí wọ́n ti yọ̀ọ̀da ara wọn láti fi Bíbélì kọ́ni nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn sọ̀rọ̀.

Èé ṣe tí ẹ̀kọ́ Bíbélì fi gbéṣẹ́ gan an ní mímú kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan yí ìgbésí ayé wọn padà?

David: Wọn kò fi ìfẹ́ hàn sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n rí, kódà nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé. Nígbà tí wọ́n wá mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n sì sọ gbogbo nǹkan tó wà lọ́kàn wọn jáde fún un nínú àdúrà tí ó sì dáhùn àwọn àdúrà wọn, ó wá di ẹni gidi kan sí wọn. Ọkàn wọn sún wọn láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Ray: Wọ́n bá ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí mo bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣèṣekúṣe nígbà tó wà lọ́mọdé. Nígbà tí mo béèrè pé kí ló mú un nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó dáhùn pé béèyàn bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì, onítọ̀hún á rí i pé Jèhófà lóye òun gidigidi. Èyí ló mú kó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àkópọ̀ ìwà Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ náà.

Àwọn kan sọ pé kí àkókò táwọn ẹlẹ́wọ̀n máa lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lè dín kù tàbí kí àkókò lè fi tètè kọjá lọ ni wọ́n ṣe máa ń jára mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Kí ni ìrírí rẹ ti fi hàn?

Fred: Bí àwọn ẹlẹ́wọ̀n bá wá sí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, a kì í gbìyànjú láti kó sí wọn lórí. Ká kàn ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn ni. Kò sì pẹ́ táwọn náà fi mọ̀ pé ẹ̀kọ́ nípa Bíbélì la wá kọ́ wọn, pé gbogbo ohun táa ń ṣe kò jùyẹn lọ. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan ti wá bá mi pé kí n ran àwọn lọ́wọ́ nípa ẹjọ́ wọn ní kóòtù. N kì í bá wọn sọ̀rọ̀ nípa èyí. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn tó bá ń pésẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ tó ń kẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì ń wá déédéé fún sáà kan fi hàn pé lóòótọ́ làwọ́n fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì wí.

Nick: Ohun kan tí mo kíyè sí ni àwọn ìyípadà táwọn ẹlẹ́wọ̀n kan ṣe nígbà tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n. Lára wọn ti di òjíṣẹ́ tó tí ṣèrìbọmi, ojú wọn sì ti rí màbo lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù. Ó ni wọ́n lára gidigidi. Ká sọ pé Bíbélì kò tí ì yí ọkàn wọn padà ni, wọ̀n kò ní lè jẹ́ olóòótọ́ lábẹ́ àwọn ipò wọ̀nyẹn.

Israel: Táa bá wò wọ́n lápapọ̀, èèyàn tó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ni wọ́n, ọ̀nà tí wọ́n sì ń gbà fi hàn ń wúni lórí. O lè rí i pé ó tọkàn wọn wá.

Joe: Àwọn tó di Kristẹni tòótọ́ ti wá lóye ohun tó mú kí ìgbésí ayé wọn wọ́. Wọ́n sì ti tún mọ̀ pé ìrètí wà láti ṣàtúnṣe, ìyẹn ni pé ìrètí ń bẹ fún wọn. Ní báyìí wọ́n lè fi tọkàntọkàn wọ̀nà fún ìmúṣẹ ìlérí Jèhófà fún ọjọ́ iwájú.

Kí ló dé tí ọgbà ẹ̀wọ̀n nìkan kò fi lè yí àwọn ọ̀daràn padà?

Joe: Ète ọgbà ẹ̀wọ̀n kì í ṣe láti yí àwọn ọ̀daràn padà bí kò ṣe láti kó wọn kúrò láàárín àwùjọ. Bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́gbà ẹ̀wọ̀n gan an ni olórí ìṣòro ọ̀hún.

Henry: Kò ṣeé ṣe fún ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n láti yí ọkàn àwọn ọ̀daràn padà. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn yìí ló tún máa hùwà ọ̀daràn bí wọ́n bá kúrò lẹ́wọ̀n.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n la ti ràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì