Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Ẹ̀yà Júù Ni Jèhófà?

Ṣé Ọlọ́run Ẹ̀yà Júù Ni Jèhófà?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ọlọ́run Ẹ̀yà Júù Ni Jèhófà?

NÍ Ọ̀PỌ̀ orílẹ̀-èdè lónìí, ètò àjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tòde òní làwọn èèyàn mọ orúkọ náà Jèhófà mọ́. Síbẹ̀, orúkọ yìí fara hàn nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan táwọn ìsìn míràn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò. Àní, fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún làwọn èèyàn ti ń lo orúkọ náà, Jèhófà tí Tetragrammaton dúró fún, ìyẹn lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run.

Nígbà mìíràn, wọ́n máa ń pe Jèhófà ní “Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” (1 Kíróníkà 17:24) Gbólóhùn yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ rò pé ọlọ́run ẹ̀yà kan ló wulẹ̀ jẹ́, èyí táwọn Hébérù yá lò látinú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ mìíràn tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn hùmọ̀ ẹ̀ fúnra wọn. Karen Armstrong, ẹni tó kọ ìwé A History of God sọ pé: “Níbẹ̀rẹ̀, ọlọ́run oníjàgídíjàgan ti ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n gbà pé [Jèhófà] jẹ́. Nígbà tó yá, ní nǹkan bí ọ̀rúndún keje àti ìkẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn wòlíì Ísírẹ́lì lo orúkọ Ọlọ́run yìí láti dúró fún ẹni ẹ̀mí tí kò ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn láti ṣàpèjúwe rẹ̀.”

Àwọn apìtàn ẹ̀sìn bíi mélòó kan ti gbìyànjú láti tanlẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ orúkọ náà Jèhófà padà sọ́dọ̀ àwọn ará Kénáánì tàbí àwọn ará Íjíbítì. Àwọn mìíràn jiyàn pé “orúkọ ẹ̀yà kan ni tó sì ti pẹ́” kò sì ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú irú Ọlọ́run tí “Májẹ̀mú Tuntun” ṣàpèjúwe rẹ̀. Ṣé òótọ́ ni? Bí a bá fẹ̀sọ̀ ka Bíbélì, kí la máa rí?

Jèhófà—Ọlọ́run Gbogbo Èèyàn

Bíbélì jẹ́rìí sí i pé Jèhófà ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Àmọ́ èyí kì í wá ṣe ìdí láti máa rò pé ọlọ́run ẹ̀yà kan lásán ló wulẹ̀ jẹ́. Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Àbí Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ni òun í ṣe? Òun kì í ha ṣe Ọlọ́run àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú bí?” Kí ni ìdáhùn Pọ́ọ̀lù tó ṣe kedere? “Bẹ́ẹ̀ ni, ti àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú.” (Róòmù 3:29) Ta ni Ọlọ́run tí Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí? Ó dáa, nínú lẹ́tà kan náà yìí sáwọn ará Róòmù, orúkọ yẹn, Jèhófà, fara hàn nígbà mọ́kàndínlógún. Nígbà tí àpọ́sítélì yìí ń fa ọ̀rọ̀ wòlíì Hébérù ìgbàanì Jóẹ́lì yọ, ó sọ pé “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là” kì í ṣe àwọn Júù nìkan.—Róòmù 10:13; Jóẹ́lì 2:32.

Kì í ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló yan Jèhófà láti ṣe Ọlọ́run wọn; kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ló yàn wọ́n kí ó lè mú ète rẹ̀ ṣẹ—ìyẹn ni, láti tún ọ̀nà ṣe de Mèsáyà náà. Síwájú sí i, bọ́jọ́ iwájú ọlọ́run ẹ̀yà kan ṣe máa rí, ọjọ́ iwájú tàwọn èèyàn rẹ̀ ló máa sọ ọ́. Bí wọ́n bá sì ṣẹ́gun ẹ̀yà náà, ògo ọlọ́run yẹn á wọmi. Ọ̀rọ̀ ti Jèhófà kò rí bẹ́ẹ̀.

Májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá, èyí tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú sànmánì Kristẹni ní ìlérí ọ̀pọ̀ ìbùkún fún gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè, ìyẹn sì ń fi ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí ìran ènìyàn hàn. (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3; Ìṣe 10:34, 35; 11:18) Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì fi hàn pé kì í ṣe ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìkan ló jẹ́ ohun ìní Jèhófà: “Ti Jèhófà ni ilẹ̀ ayé àti ohun tí ó kún inú rẹ̀, ilẹ̀ eléso àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.”—Sáàmù 24:1.

Lẹ́yìn náà, nígbà tí Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ya tẹ́ńpìlì ìjọsìn kan sí mímọ́ fún Jèhófà, ó fi hàn pé ọ̀nà kan wà táwọn èèyàn onírẹ̀lẹ̀ láti orílẹ̀-èdè èyíkéyìí fi lè sún mọ́ Jèhófà. Nínú àdúrà ìyàsímímọ́ tí Sólómọ́nì gbà, ó sọ pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, tí kì í ṣe ara àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, tí ó sì ti ilẹ̀ jíjìnnà wá . . . tí ó sì gbàdúrà síhà ilé yìí, kí ìwọ alára fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ń gbé, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè náà ké pè ọ́ sí; kí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé lè wá mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì ti ń ṣe.”—1 Àwọn Ọba 8:41-43.

Ó Kọ Ísírẹ́lì Sílẹ̀

Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n C. J. Labuschagne ń sọ nípa àjọṣe tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní pẹ̀lú Jèhófà, ó kọ̀wé pé: “Jálẹ̀ gbogbo ìtàn Ísírẹ́lì, léraléra ni orílẹ̀-èdè náà rí i pé Ọlọ́run tí wọ́n pè ní ‘ti orílẹ̀-èdè’ náà lè hùwà lọ́nà tó fi hàn pé òun kò nínú dídùn sí wọn àní kí ó tiẹ̀ tún kẹ̀yìn sí wọn pàápàá nígbà míì.” Nígbà tí Ísírẹ́lì kọ Mèsáyà sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, Jèhófà kọ orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀.

Àmọ́, àwọn tó jẹ́ Kristẹni á ṣì máa bá a lọ ní lílo orúkọ Jèhófà. Bí ìjọ Kristẹni ti ń dàgbà, àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ wá ní àwọn ènìyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè nínú. Nígbà tí Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ Júù ń darí ìpàdé Kristẹni kan ní Jerúsálẹ́mù, ó sọ pé: ‘[Ọlọ́run] ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè [tí kì í ṣe Júù] láti mú àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde láti inú wọn.’ Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí láti fi hàn pé a ti sàsọtẹ́lẹ̀ èyí, Jákọ́bù fa àsọtẹ́lẹ̀ kan yọ látinú ìwé Ámósì níbi tí orúkọ Jèhófà ti fara hàn.—Ìṣe 15:2, 12-18; Ámósì 9:11, 12.

Ó Bìkítà Nípa Gbogbo Èèyàn, Ó Ń Bù Kún Wọn

Láti túbọ̀ jẹ́rìí sí i pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run lórí gbogbo ayé, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò sí ìyàtọ̀ láàárín Júù àti Gíríìkì, nítorí Olúwa kan náà ní ń bẹ lórí gbogbo wọn, ẹni tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.” (Róòmù 10:12) Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ìran ènìyàn tó bá ṣègbọràn ló lè rí ìbùkún Jèhófà gbà.

Jèhófà ṣèlérí ọjọ́ ọ̀la ológo fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ọmọ rẹ̀ tó bá ṣe olóòótọ́ àti onígbọràn, láìka orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà wọn sí. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pe irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ní “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Hágáì 2:7) Àwọn ènìyàn wọ̀nyí mọ̀ nípa Jèhófà wọ́n sì wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì sọ nípa wọn pé: “Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì jọ́sìn níwájú rẹ [Jèhófà], nítorí a ti fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ rẹ tí ó jẹ́ òdodo hàn kedere.”—Ìṣípayá 15:4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Mósè níbi tó ti mú Òfin Mẹ́wàá dáni