Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ìsìn Ṣe Jàjàyè

Bí Ìsìn Ṣe Jàjàyè

Bí Ìsìn Ṣe Jàjàyè

NÍGBÀ tó máa fi tó àsìkò tí ìjọba Násì ti Jámánì gbógun ti Rọ́ṣíà ní June 1941, ńṣe ni ká kúkú sọ pé ìjọba Soviet ti pa Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà run ráúráú. Àmọ́ nígbà tó di pé ìjọba Násì gbógun dé, ni ìjọba Soviet bá bẹ̀rẹ̀ sí í yí bó ṣe ń ṣe sí ìsìn tẹ́lẹ̀ padà. Kí ló fà á?

Richard Overy tí í ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìtàn òde òní ti ilé ẹ̀kọ́ gíga King’s College nílùú London, sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Russia’s War—Blood Upon the Snow pé: “Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà, Sergei, tó jẹ́ olórí Ṣọ́ọ̀ṣì, bẹ àwọn onígbàgbọ́ lọ́jọ́ náà gan-an tí Jámánì gbógun dé pé, kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti ṣẹ́gun. Láàárín ọdún méjì tó tẹ̀ lé e, lẹ́tà tó kọ kò dín ní mẹ́tàlélógún, èyí tó fi ń pe àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ láti jà fún ìlú aláìlọ́lọ́run tí wọ́n ń gbé.” Gẹ́gẹ́ bí Overy ti ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, fún ìdí yìí, ‘Stalin fún ìsìn láyè kí ó tún gbèrú padà.’

Ní 1943, Stalin gbà níkẹyìn láti fara mọ́ ohun tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì fẹ́ nípa yíyan Sergius sípò gẹ́gẹ́ bíi bíṣọ́ọ̀bù tuntun fún ìjọ náà. Overy sọ pé: “Àwọn aláṣẹ Ṣọ́ọ̀ṣì dáhùn nípa gbígba owó jọ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ láti fi ti àwọn ọmọ ogun Soviet tó máa ń wà nídìí ọkọ̀ ogun lẹ́yìn. Àwọn àlùfáà àtàwọn bíṣọ́ọ̀bù gba àwọn ọmọ ìjọ wọn níyànjú láti má ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọ́run àti Stalin yẹ̀.”

Nígbà tí Sergei Ivanenko tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nídìí ọ̀ràn ẹ̀sìn ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń sọ bí nǹkan ti rí lásìkò yìí nínú ìtàn ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ó kọ̀wé pé: ‘Ìwé ìròyìn The Journal of the Moscow Patriarchate tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń tẹ̀ jáde, gbóríyìn fún Stalin gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àti olùkọ́ tí kò lẹ́lẹ́gbẹ́ ní orílẹ̀-èdè èyíkéyìí, ẹni tí Ọlọ́run rán láti gba orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́ ìnira, lọ́wọ́ àwọn onílẹ̀, àtàwọn olówò bòńbàtà. Ó wá rọ gbogbo àwọn onígbàgbọ́ pé ohun tí ìjà náà bá gbà ni kí wọ́n fún un kí wọ́n lè gba orílẹ̀-èdè USSR lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀, kí wọ́n má sì bojú wẹ̀yìn láti rí i pé ètò ìjọba Kọ́múníìsì gòkè àgbà.’

“KGB Kò Kóyán Wọn Kéré Rárá”

Kódà lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí ní 1945, Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ṣì wúlò fún ìjọba Kọ́múníìsì. Ìwé The Soviet Union: The Fifty Years, látọwọ́ Harrison Salisbury tú àṣírí yìí nígbà tó sọ pé: “Bógun ṣe parí báyìí, bẹ́ẹ̀ làwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì dara pọ̀ mọ́ Stalin nínú ohun tó ń béèrè nínú àkọsílẹ̀ ìlànà bíbá ilẹ̀ òkèèrè lò nígbà Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀.”

Ìwé The Sword and the Shield tí wọ́n ṣe jáde láìpẹ́ yìí sọ nípa bí àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ṣiṣẹ́ fún ire ilẹ̀ Soviet. Ó tún sọ pé Bíṣọ́ọ̀bù Alexis Kìíní, tó rọ́pò Sergius ní 1945, “dara pọ̀ mọ́ Àjọ Àlàáfíà Àgbáyé, ìyẹn àjọ bojúbojú kan tí ilẹ̀ Soviet dá sílẹ̀ lọ́dún 1949.” Ìwé ọ̀hún tún sọ pé: “KGB [Ìgbìmọ̀ Aláàbò Ìjọba Soviet] kò kóyán” òun àti Nikolai tí í ṣe Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà “kéré rárá gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ìjọba ń rí lò lábẹ́lẹ̀.”

Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ ní 1955 nígbà tí Bíṣọ́ọ̀bù Alexis Kìíní kéde pé: “Gbágbáágbá ni Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà wà lẹ́yìn àkọsílẹ̀ ìlànà alálàáfíà fún bíbá ilẹ̀ òkèèrè lò èyí tí ìjọba wa dágbá lé, kì í ṣe nítorí òmìnira tí wọ́n sọ pé Ṣọ́ọ̀ṣì kò ní, àmọ́ ó jẹ́ nítorí pé ìlànà ìjọba ilẹ̀ Soviet dára, ó si bára mu pẹ̀lú àwọn ìlànà Kristẹni èyí tí Ṣọ́ọ̀ṣì ń wàásù rẹ̀.”

Wọ́n fa ọ̀rọ̀ àlùfáà ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, Georgi Edelshtein tí kò fara mọ́ àwọn yòókù yọ nínú ìwé ìròyìn The Guardian tìlú London, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìtẹ̀jáde ti January 22, 2000 pé: “Ńṣe ni wọ́n fara balẹ̀ ṣa gbogbo àwọn bíṣọ́ọ̀bù náà kí wọ́n bàa lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìjọba soviet. Amí ni gbogbo wọn jẹ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ KGB. Kò sẹ́ni tí kò mọ̀ pé ìgbìmọ̀ KGB ló yan Bíṣọ́ọ̀bù Alexy sípò lábẹ́ orúkọ oyè Drozdov tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn nígbà kan. Lónìí, wọ́n ṣì wà nídìí òṣèlú tí wọ́n ṣagbátẹrù rẹ̀ ní ogún ọdún sí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn.”

Irinṣẹ́ Ìjọba Soviet

Nígbà tí ìwé ìròyìn Life ti September 14, 1959 ń sọ nípa àjọṣe tó wà láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì àti ìjọba Soviet, ó sọ pé: “Stalin fún ìsìn láwọn ẹ̀tọ́ kan, ni ṣọ́ọ̀ṣì bá ń gbé e gẹ̀gẹ̀ bíi pé olú ọba ni. Ẹ̀ka ìjọba kan tí òjíṣẹ́ kan ń darí ló ń rí sí i pé mìmì kò ní mi àjọṣe onísìn náà, àtìgbà náà sì ni ìjọba Kọ́múníìsì ti ń lo ṣọ́ọ̀ṣì gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ ìjọba Soviet.”

Matthew Spinka, tó mọnúmòde àwọn ọ̀ràn tó ní i ṣe pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Rọ́ṣíà jẹ́rìí sí àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba nínú ìwé The Church in Soviet Russia èyí tó ṣe jáde ní 1956. Ó kọ ọ́ pé: “Bíṣọ́ọ̀bù Alexei tó jẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ ti mọ̀ọ́mọ̀ sọ Ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ di irinṣẹ́ ìjọba.” Àní sẹ́, nítorí pé Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì sọ ara rẹ̀ di irinṣẹ́ Ìjọba ló mú kó jàjàyè. O lè wá béèrè pé, ‘Kí wá ló burú nínú ìyẹn?’ Ó dára, ronú ná nípa irú ojú tí Ọlọ́run àti Kristi fi wo ọ̀ràn náà.

Jésù Kristi sọ nípa àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn tòótọ́ pé: “Ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún ṣe ṣàkó nígbà tó béèrè pé: “Ẹ̀yin panṣágà obìnrin, ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run?” (Jòhánù 15:19; Jákọ́bù 4:4) Bí ṣọ́ọ̀ṣì ṣe sọ ara rẹ̀ di aṣẹ́wó gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe pè é nìyẹn, ẹni tí “àwọn ọba ilẹ̀ ayé bá ṣe àgbèrè.” Ó ti sọ ara rẹ̀ di apá kan ohun tí Bíbélì pè ní “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó àti ti àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 17:1-6.

Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣe Jàjàyè

Ní ìyàtọ̀ sí èyí, Jésù Kristi sọ ohun tí wọ́n máa fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́ mọ̀, ó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ìfẹ́ yìí ni ohun pàtàkì tó mú káwọn Ẹlẹ́rìí là á já lásìkò ìjọba Soviet Union àtijọ́, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ lé e yìí látinú ìwé The Sword and the Shield ṣe sọ. “Àwọn Oní-Jèhófà náà ṣe onírúurú ìrànwọ́ fún gbogbo àwọn mẹ́ńbà ìsìn wọn tó wà nínú àwọn àgọ́ [ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́] tàbí ní ìgbèkùn lórílẹ̀-èdè wọn, wọ́n ń fún wọn lówó, oúnjẹ àti aṣọ.”

Lára àwọn “oúnjẹ” tí wọ́n pèsè fáwọn tó wà lẹ́wọ̀n ni oúnjẹ tẹ̀mí—ìyẹn Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bíbélì ní ‘àwọn àsọjáde Ọlọ́run’ nínú, èyí tí Jésù sọ pé a nílò láti máa wà láàyè nípa tẹ̀mí. (Mátíù 4:4) Inú ewu ńláǹlà làwọn tó ń kó Bíbélì wọnú àwọn àgọ́ náà wà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìyà tó gbópọn ni wọ́n máa fi ń jẹ ẹnikẹ́ni tọ́wọ́ bá tẹ̀ pé ó ṣe bẹ́ẹ̀.

Wọ́n ju Helene Celmina, tó jẹ́ ará Latvia sẹ́wọ̀n nínú àgọ́ ìfìyàjẹni tó wà ní Potma ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà látọdún 1962 sí 1966. Ó kọ ìwé tó ń jẹ́ Women in Soviet Prisons, nínú èyí tó ti ṣàlàyé pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára fún kìkì nítorí pé wọ́n bá àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ bíi mélòó kan nínú ilé wọn. Ohun tó ń mú kí àwọn aláṣẹ máa ṣàníyàn kí agara sì máa dá wọn ni pé bí wọ́n ṣe ń kó àwọn tó ní ìwé yìí tó, bẹ́ẹ̀ ni ìwé náà ṣì ń rọ́nà wọnú àgọ́.”

Ó dájú hán-ún pé, fífi òmìnira àti ààbò ara ẹni sínú ewu nítorí àtipèsè ìrànwọ́ tẹ̀mí jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ Kristẹni! Àmọ́, bí èyí tilẹ̀ jẹ́ ohun pàtàkì tó mú káwọn Ẹlẹ́rìí jàjàyè, ohun kan tó tún ṣe pàtàkì jù yẹn lọ ṣì wà. Helene Celmina sọ pé: “Kò sẹ́ni tó yé bí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fòfin dè ṣe rọ́nà wọ ibi tó jẹ́ pé kìkìdá wáyà onírin ṣóńṣó ni wọ́n fi yí ibẹ̀ ká, tí wọ́n kì í fi bẹ́ẹ̀ fún èèyàn láyè láti bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀.” Ó dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo àwọn tí wọ́n bá wọnú ẹ̀wọ̀n náà ni wọ́n máa ń yẹ̀ wò fínnífínní. Òǹkọ̀wé yìí sọ pé: “Ńṣe ló dà bíi pé àwọn áńgẹ́lì máa ń fò wá lóru tí wọ́n á sì dà á sílẹ̀.”

Ní tòótọ́, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun kò ní fi àwọn èèyàn òun sílẹ̀, tàbí kí òun pa wọ́n tì. Nítorí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́ fi gbogbo ara gbà pẹ̀lú onísáàmù inú Bíbélì náà pé: “Wò ó! Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi.” (Sáàmù 54:4; Jóṣúà 1:5) Láìsí àní-àní, ìrànwọ́ rẹ̀ yìí ni pàtàkì ohun tó mú káwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́ jàjàyè!

Bí Ipò Nǹkan Ṣe Yí Padà

Ní March 27, 1991, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà di ètò àjọ tí ilẹ̀ Soviet Union kà sí èyí tó bófin mu nígbà tó fọwọ́ sí ìwé òfin ẹgbẹ́ wọn èyí tó ní ìkéde yìí nínú: “Ète tí Ètò Ẹ̀sìn yìí wà fún ni láti máa ṣe iṣẹ́ ẹ̀sìn wọn ti sísọ orúkọ Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ọ̀run ní ọwọ́ Jésù Kristi di mímọ̀ fún aráyé.”

Lára àwọn ọ̀nà tí wọ́n là lẹ́sẹẹsẹ sínú ìwé òfin náà fún ṣíṣe iṣẹ́ ẹ̀sìn náà nìṣó ni wíwàásù ní gbangba àti bíbẹ àwọn ènìyàn wò nínú ilé wọn, kíkọ́ àwọn tí wọ́n ṣe tán láti fetí sílẹ̀ ní àwọn òtítọ́ Bíbélì, ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ pẹ̀lú wọn nípa lílo àwọn ìtẹ̀jáde ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti pínpín Bíbélì kiri.

Látìgbà tí wọ́n ti buwọ́ lu ìwé yẹn ní ohun tó lé lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, Soviet Union ti tú ká, bẹ́ẹ̀ sì ni ipò nǹkan ti yí padà lọ́nà tó jọni lójú láwọn orílẹ̀-èdè olómìnira mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ti ilẹ̀ Soviet àtijọ́ yẹn. Kí lóhun táa lè sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí ìsìn lọ́jọ́ iwájú níbẹ̀ àti láwọn ibi yòókù lágbàáyé?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

Bí Ṣọ́ọ̀ṣì Ṣe Lẹ̀dí Àpò Pọ̀ Pẹ̀lú Ìjọba Soviet

Nínú ìwé rẹ̀, Russia Is No Riddle tó ṣe jáde lọ́dún 1945, Edmund Stevens kọ̀wé pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì rí i dájú pé òun ṣọ́ra gidigidi láti má fojú ẹni tó ń ṣe òun lóore gúngi. Ó mọ̀ dájú pé Ìjọba retí pé kí Ṣọ́ọ̀ṣì ti Ìjọba ilẹ̀ Soviet lẹ́yìn gbágbáágbá ní ìsanpadà fún oore tó ṣe é, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ààlà kan wà tí kò gbọ́dọ̀ ré kọjá.”

Stevens ń bá àlàyé rẹ̀ lọ pé: “Ohun tó ti máa ń ṣẹlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún nínú ẹ̀sìn Orílẹ̀-èdè ti rídìí múlẹ̀ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, ìdí sì rèé tó fi jẹ́ pé pẹ̀lú ìrọ̀rùn ló fi tẹ́wọ́ gba ipò tuntun ti lílẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Ìjọba ilẹ̀ Soviet.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣèwádìí ti Keston, ṣèwádìí kínníkínní nípa kùrùkẹrẹ tó wà láàárín Ìjọba Soviet àti Alexis Kejì, tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìròyìn rẹ̀ parí báyìí pé: “Bí Aleksi ṣe lẹ̀dí àpò pọ̀ kì í ṣe nǹkan tuntun o—ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí ìjọba fàṣẹ sí ìsìn wọn ni wọ́n jẹ́ amí fún àwọn KGB—títí kan àwọn Kátólíìkì, àwọn Onítẹ̀bọmi, àwọn Ẹlẹ́kọ̀ọ́ Ọjọ́ Ìsinmi, àwọn Mùsùlùmí àtàwọn ẹlẹ́sìn Búdà. Kódà, ìròyìn ọdọọdún tó ṣàlàyé bí wọ́n ṣe yan Aleksi tún mẹ́nu kan ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn mìíràn tí wọ́n yàn ṣe aṣojú, àwọn kan lára wọn wà nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Luther ti Estonia.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Bíbá Àwọn Tó Wà Nínú Àgọ́ Sọ̀rọ̀

Inú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Mordovian tó jẹ́ nǹkan bí irínwó kìlómítà lápá gúúsù ìlà oòrùn Moscow ni Viktors Kalnins, tó jẹ́ akọ̀ròyìn ọmọ ilẹ̀ Latvia ti ṣe èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá (1962 sí 1972) tí wọ́n dá fún un. Nínú ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò kan pẹ̀lú akọ̀ròyìn Jí! ní March 1979, wọ́n bi Kalnins léèrè pé: “Ǹjẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà láhàámọ́ tiẹ̀ mọ nǹkan tó ń lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà níbí àti láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn nípa ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ètò àjọ wọn?”

Kalnins fèsì pé: “Wọ́n mọ̀ ọ́n, ìyẹn sì jẹ́ nípasẹ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń rí gbà. . . . Wọ́n tiẹ̀ fi àwọn ìwé ìròyìn wọn hàn mí. Ibi tí wọ́n ń kó àwọn ìwé náà pa mọ́ sí kò yé mi; ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń yíwọ́ ẹ̀ padà. Àmọ́ kò sẹ́ni tí kò mọ̀ pé àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn wà nínú àgọ́. . . . Bí eku àti ológbò làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ṣe ń ṣe, bí wọ́n ti ń gbìyànjú láti fi àwọn ìwé náà pa mọ́ láwọn yẹn náà ń gbìyànjú láti wá a rí!”

Nígbà tí wọ́n bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tiẹ̀ gbìyànjú láti bá ẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́?” Kalnins dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni o! Gbogbo èèyàn ló mọ̀ wọ́n dáadáa. A mọ ohun tó ń jẹ́ Amágẹ́dọ́nì . . . Wọn ò yéé sọ pé àìsàn máa dópin.”

[Àwòrán]

Àwọn Ẹlẹ́rìí ní àwọn àgọ́ Mordovia fi tìgboyàtìgboyà ṣàjọpín àwọn òtítọ́ Bíbélì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Wọ́n kó ìdílé Vovchuks lọ sí Irkutsk, Siberia, ní 1951 wọ́n sì ń bá a lọ ní jíjẹ́ Kristẹni adúróṣinṣin títí dòní

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Nítorí ìtìlẹ́yìn tí ṣọ́ọ̀ṣì fún ìjọba lákòókò Ogun Àgbáyé Kejì, Stalin gba ìsìn láyè láti máa báṣẹ́ lọ fúngbà díẹ̀

[Credit Line]

U.S. Army photo

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Bíṣọ́ọ̀bù Alexis Kìíní (1945 sí 1970) sọ pé: ‘Èròǹgbà ìjọba Soviet ṣe gẹ́lẹ́ pẹ̀lú àwọn ìlànà Kristẹni tí Ṣọ́ọ̀ṣì ń wàásù rẹ̀’

[Credit Line]

Látinú Central State Archive nípa àkọsílẹ̀ fíìmù/fọ́tò/ẹ̀rọ giramafóònù ti Saint-Petersburg