Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ilẹ̀ Soviet Gbógun Ti Ìsìn

Ilẹ̀ Soviet Gbógun Ti Ìsìn

Ilẹ̀ Soviet Gbógun Ti Ìsìn

WỌ́N dá Orílẹ̀-èdè Olómìnira Àjùmọ̀ni Soviet sílẹ̀ ní 1922, tí Rọ́ṣíà sì jẹ́ èyí tó tóbi jù lọ tó sì tún tayọ jù lọ nínú àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira mẹ́rin àkọ́kọ́. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó gbòòrò di orílẹ̀-èdè olómìnira mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí wọ́n sì gba ojú ilẹ̀ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá kan nínú mẹ́fà àyè tí ilẹ̀ ayé ní. Ṣùgbọ́n lọ́dún 1991, wọ́n tú Soviet Union ká lójijì. a O gbani láfiyèsí pé, òun ni Ìjọba tó máa kọ́kọ́ gbìyànjú láti pa ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run rẹ́ lọ́kàn àwọn ènìyàn rẹ̀.

Ọmọ ẹ̀yìn Karl Marx, tó pe ìsìn Kristẹni ni nǹkan ìnira ni Vladimir Lenin, tó jẹ́ olórí àkọ́kọ́ fún Soviet Union. Marx pe ìsìn ní “ohun tó ń pa àwọn ènìyàn lọ́bọ̀ọ́lọ̀,” lẹ́yìn náà ni Lenin wá polongo pé: “Èrò èyíkéyìí tó ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn, tàbí tó ní í ṣe pẹ̀lú ọlọ́run èyíkéyìí, . . . jẹ́ ohun aláìníláárí tó kọjá àfẹnusọ.”

Nígbà tí Tikhon, Olórí Ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà kú ní 1925, wọn ò fún ṣọ́ọ̀ṣì náà láyè láti yan olórí mìíràn. Ṣíṣe àtakò sí ìsìn tó tẹ̀ lé e yọrí sí bíba èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ tàbí yíyí wọn padà fún ìlò iṣẹ́ ajé. Wọ́n rán àwọn àlùfáà lọ sáwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, níbi tí ọ̀pọ̀ wọn ṣègbé sí. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Lábẹ́ ìṣàkóso Joseph Stalin, nígbà tí ọdún 1920 àti ọdún 1930 ń parí lọ, wọ́n ṣe inúnibíni sí ṣọ́ọ̀ṣì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún fi gbẹ́mìí mì. Nígbà tó máa fi di 1939, kìkì bíṣọ́ọ̀bù Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì mẹ́ta tàbí mẹ́rin àti ọgọ́rùn ún kan ṣọ́ọ̀ṣì ló ṣẹ́ kù tí wọ́n láṣẹ láti máa báṣẹ́ lọ.”

Àmọ́, ọ̀sán-kan-òru-kan ni ìyípadà pípabanbarì kan ṣàdédé ṣẹlẹ̀.

Ogun Àgbáyé Kejì àti Ìsìn

Ní 1939, ìjọba Násì ti Jámánì tó jẹ́ alájọṣe Soviet Union nígbà náà kọ lu Poland, ni Ogun Àgbáyé Kejì bá bẹ̀rẹ̀. Láàárín ọdún kan péré, Soviet Union ti gba mẹ́rin tó kẹ́yìn lára orílẹ̀-èdè olómìnira mẹ́ẹ̀ẹ́dógún rẹ̀—ìyẹn Latvia, Lithuania, Estonia, àti Moldavia. Bó ti wù kó rí, ní June 1941, Jámánì gbógun gbígbóná janjan ti Soviet Union, èyí sì bá Stalin lábo pátápátá. Nígbà tọ́dún yẹn á fi parí, àwọn ọmọ ogun Jámánì ti dé ààlà Moscow, ó sì dà bí ẹni pé ìṣubú Soviet Union ti rọ̀ dẹ̀dẹ̀.

Ṣìbáṣìbo bá Stalin, ló bá wọ́nà láti múra orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ fún ogun, èyí táwọn ará Rọ́ṣíà pè ní Ogun Ìfọkànsìn Orílẹ̀-Èdè Ẹni Tó Hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀. Stalin rí i pé tóun bá máa rí ìtìlẹ́yìn àwọn èèyàn gbà fún akitiyan ogun náà, ó di dandan kóun dá àwọn ẹ̀tọ́ kan padà fún ṣọ́ọ̀ṣì, nítorí pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn ṣì fọwọ́ dan-in dan-in mú ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Kí ló jẹ́ àbájáde yíyí tí Stalin yí èrò rẹ̀ nípa ìsìn padà lọ́nà tó jọni lójú bẹ́ẹ̀?

Pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n múra àwọn èèyàn ilẹ̀ Rọ́ṣíà sílẹ̀ fún jíja ogun náà, nígbà tó sì máa fi di 1945, Soviet ṣẹ́gun àwọn ará Jámánì lọ́nà kíkàmàmà. Lẹ́yìn tí Soviet ti gbé ìgbógunti ìsìn tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, iye ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì lọ sókè sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000], tí iye àwọn àlùfáà sì ròkè dé ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33,000].

Ìgbóguntì Tún Bẹ̀rẹ̀ Lákọ̀tun

Àní sẹ́, góńgó àwọn aṣáájú Soviet láti pa èrò nípa Ọlọ́run rẹ́ kúrò lọ́kàn àwọn èèyàn wọn kò tíì yí padà o. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica sọ pé: “Nikita Khrushchev tó jẹ́ Olórí Ìjọba bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ tuntun ti títako ìsìn lọ́dún 1959 sí 1964, tí ìyẹn sì dín iye àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó lómìnira kù sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá. Ní 1971, wọ́n yan Pimen gẹ́gẹ́ bí olórí ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì lẹ́yìn ikú Alexis, àti pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló ṣì fi ìdúróṣinṣin wọn hàn fún ṣọ́ọ̀ṣì, ohun tó máa jẹ́ ọjọ́ iwájú rẹ̀ kò yé ẹnì kan.” b

A ṣì ń bọ̀ wá jíròrò bí ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe jàjàbọ́ lọ́wọ́ ìgbóguntì tuntun tí Soviet ṣe. Àmọ́ báwo ni nǹkan ti rí fáwọn ìsìn mìíràn ní Soviet Union? Èwo lára wọn ní wọ́n wá dájú sọ nínú ìgbóguntì náà, kí ló sì fà á? Èyí la ó jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún oníjọba-ara-ẹni tí wọ́n fìgbà kan jẹ́ ara orílẹ̀-èdè olómìnira Soviet nìwọ̀nyí: Armenia, Azerbaijan, Belarus, Estonia, Georgia, Kazakhstan, Kyrgyzstan, Latvia, Lithuania, Moldova, Russia, Tajikistan, Turkmenistan, Ukraine, àti Uzbekistan.

b Nígbà míì, wọ́n máa ń pe orúkọ àwọn olórí ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà, Alexis Kìíní tó jẹ́ olórí láti ọdún 1945 sí 1970 àti Alexis Kejì, tó jẹ́ olórí láti 1990 títí di àkókò yìí ní Alexy, Aleksi, Aleksei, àti Alexei.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Lenin pe ‘èrò èyíkéyìí nípa Ọlọ́run ní ohun aláìníláárí tó kọjá àfẹnusọ’

[Credit Line]

Musée d’Histoire Contemporaine—BDIC