Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Ń Lo Abala “Wíwo Ayé” Ní Ilé Ẹ̀kọ́

Wọ́n Ń Lo Abala “Wíwo Ayé” Ní Ilé Ẹ̀kọ́

Wọ́n Ń Lo Abala “Wíwo Ayé” Ní Ilé Ẹ̀kọ́

EDELMIRA, ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lo ìwé ìròyìn Jí! lọ́nà tó gbéṣẹ́ nílé ẹ̀kọ́. Nínú lẹ́tà rẹ̀ sáwọn òǹṣèwé, ó kọ ọ́ pé:

“Gbogbo ọjọ́ Friday la máa ń kọ ọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́. Mo ka Jí! May 8, 2000 mo sì sọ pé màá gbé ọ̀rọ̀ tèmi karí àkòrí náà, ‘Ilé Iṣẹ́ Tábà Jẹ́wọ́ Pé Sìgá Mímu Ń Fa Àrùn Jẹjẹrẹ,’ èyí tó jáde nínú abala ‘Wíwo Ayé.’ Mo kọ ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mo sì kà á fáwọn ọmọ kíláàsì. Olùkọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́. Nígbà tí mo kà á tán, akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ mi kan wá béèrè lọ́wọ́ mi níṣojú gbogbo ọmọ kíláàsì bóyá ó gbà mí lákòókò púpọ̀ láti kó àwọn ọ̀rọ̀ tí mo kọ jọ. Mo fún un ní Jí! náà. Pẹ̀lú ìháragàgà ló fi bẹ̀rẹ̀ sí kà á, ọmọkùnrin kan tó wà ní ìjọ wa sọ pé nígbà tóun rí ọmọbìnrin yìí ní kíláàsì mìíràn, ó ṣì ń ka ìwé náà. Ní báyìí ọmọbìnrin náà sọ pé òun fẹ́ máa gba ìtẹ̀jáde Jí! àti èkejì rẹ̀ Ilé Ìṣọ́ déédéé.

“Ìrírí yìí jẹ́ kí ń máa yangàn pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó kọ́ mi pé a ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní láti sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà.” Edelmira parí lẹ́tà rẹ̀ báyìí: “Mo kí i yín fún iṣẹ́ ribiribi tí ẹ ń ṣe láti pèsè àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe dáwọ́ títẹ abala ‘Wíwo Ayé’ dúró o!”