Ó Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Kojú Ìpèníjà
Ó Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Kojú Ìpèníjà
Ọ́FÍÌSÌ ẹ̀ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Sri Lanka rí lẹ́tà kan gbà látọ̀dọ̀ akọ̀wé Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí sí Ìdàgbàsókè Ọ̀dọ́ àti Ipa Tí Ẹ̀dá Ń Kó Láwùjọ ní Ẹkùn Ìlà Oòrùn. Akọ̀wé ọ̀hún béèrè fún àwọn ìtẹ̀jáde Jí! kan tó ti kọjá ó sì sọ pé:
“Èmi àtàwọn táa jọ ń ṣiṣẹ́ ti rí i pé àwọn ìwé ìròyìn tẹ́ẹ fi ránṣẹ́ sí mi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ìsọfúnni kúnnú wọn, wọ́n ń tani jí, wọ́n bọ́gbọ́n mu bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń yíni lérò padà. Àwọn ìwé ìròyìn náà kò fi èrò òdì tan ẹ̀kọ́ Kristẹni kálẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan tí kò lóye ṣe máa ń sọ. Àwọn ìwé ọ̀hún kò lẹ́gbẹ́.
“Ńṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń béèrè fún àwọn ẹ̀dà Jí! (àti tuntun àtèyí tó ti pẹ́), ó sì hàn gbangba pé àwọn èèyàn á ṣì tún máa béèrè sí i láwọn oṣù tó ń bọ̀ níwájú. Àwọn àpilẹ̀kọ inú àwọn ìwé ìròyìn yín máa ń fún àwọn àgbàlagbà, àwọn ọ̀dọ́, àtàwọn ọmọdé ní ìmọ̀. Wọ́n ń ṣèrànwọ́ fún gbogbo èèyàn láti ṣẹ́pá àwọn ìpèníjà òde òní àtèyí tó ṣì ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, tó ń jẹ yọ látinú báwọn èèyàn ò ṣe kọbi ara sí ìsìn.”
Kò tíì sígbà kankan rí nínú ìtàn tí tọmọdétàgbà dojú kọ ìṣòro bíi ti ọjọ́ òní. Ohun tó tiẹ̀ wá rú àwọn kan lójú ni bí ọjọ́ ọ̀la yóò ti rí àti pé bóyá Ọlọ́run kan tiẹ̀ wà tó bìkítà nípa wọn. A dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí ń tẹni lọ́rùn nínú ìwé pẹlẹbẹ, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? O lè rí ẹ̀dà kan gbà tóo bá kàn sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí táa tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.