Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Ń pèsè Ìtùnú Nígbà Téèyàn Ẹni Bá Kú

Ó Ń pèsè Ìtùnú Nígbà Téèyàn Ẹni Bá Kú

Ó Ń pèsè Ìtùnú Nígbà Téèyàn Ẹni Bá Kú

Ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ ìwé pẹlẹbẹ kan jáde tó sọ̀rọ̀ lórí bó ṣe máa ń ṣòro tó láti kojú àdánù èèyàn wa tó kú. Láìpẹ́ yìí, a gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ obìnrin kan tó mọrírì kíkà á ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Yugoslavia, ohun tó kọ rèé: “Gbogbo ọkàn mi ni mo fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìwé pẹlẹbẹ náà Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. Gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa béèyàn ẹni bá kú ló tú yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́.”

Obìnrin náà sọ pé: “Nígbà tí ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin kú nínú jàǹbá ọkọ̀, ìwé pẹlẹbẹ náà fún mi ní ‘ìrànlọ́wọ́ tí mo nílò lójú méjèèjì.’ Abala ‘Àwọn Àbá Gbígbéṣẹ́ Mélòókan,’ lójú ìwé 18 tù mí nínú púpọ̀púpọ̀. Àmọ́ lẹ́yìn oṣù mẹ́rin, gbogbo ara bẹ̀rẹ̀ sí dùn mí ọkàn mi sì ń fà sẹ́ni tó kú náà lójú méjèèjì. Ẹ̀rú bà mí pé ìbànújẹ́ yìí lè sọ mí dolókùnrùn.

“Ni mo bá tún mú ìwé pẹlẹbẹ náà kà, mo sì rí i lábẹ́ àkòrí náà ‘Ọ̀nà Ìgbà Kẹ́dùn,’ nínú àpótí tó wà lójú ìwé 9 pé béèyàn bá fẹ́ mọ́kàn kúrò níbi àdánù náà, èèyàn á máa nímọ̀lára ìbànújẹ́, àárò ẹni náà á sì máa sọ ọ́. Ó tù mí nínú gan-an ni. Ẹ ṣeun fún àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí ẹ fi hàn nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí.”

Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà tàbí ẹnì kan tóo mọ̀ rí ìtùnú nínú kíka ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí. Bí ìwọ náà bá fẹ́ ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ yìí, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kóo sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ sínú fọ́ọ̀mù náà, tàbí kí o fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí táa tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.