Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Máa Dáhùn Àdúrà Mi?

Ṣé Ọlọ́run Máa Dáhùn Àdúrà Mi?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ṣé Ọlọ́run Máa Dáhùn Àdúrà Mi?

“Kò sóhun tí n kì í gbàdúrà nípa rẹ̀ sí Jèhófà nítorí pé ọ̀rẹ́ mi ni, mo sì mọ̀ pé á ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá níṣòro.”—Andrea.

Ó DÁ Andrea tó jẹ́ èwe lójú gan-an pé Ọlọ́run ń gbọ́ àwọn àdúrà rẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ọ̀dọ́ ló ní irú ìdánilójú yẹn. Àwọn kan rò pé àwọn ti jìnnà sí Ọlọ́run jù, pé àwọn ò lè bá a sọ̀rọ̀. Wọ́n tiẹ̀ lè máa ronú pé Ọlọ́run kò bìkítà nípa wọn débi káwọn gbàdúrà sí i.

Kí tiẹ̀ làṣírí àdúrà gan-an? Láìdéènà pẹnu, ó jẹ́ níní ojúlówó ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Onísáàmù náà gbàdúrà pé: “Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ.” (Sáàmù 9:10) Ìwọ náà ń kọ́? Ṣé o mọ Ọlọ́run débi tóo fi lè gbàdúrà sí i pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé yóò gbọ́ ọ? Kóo tó máa bá kíka ọ̀rọ̀ yìí lọ, jọ̀wọ́ gbìyànjú láti dáhùn àwọn ìbéèrè inú àpótí tó ní àkọlé náà “Báwo Lo Ṣe Mọ Ọlọ́run Dáadáa Tó?” Mélòó nínú wọn lo lè dáhùn?

BÁWO LO ṢE MỌ ỌLỌ́RUN DÁADÁA TÓ? Ìdáhùn wà lójú ewé 31.

1. Kí lorúkọ Ọlọ́run, kí sì ni ìtumọ̀ rẹ̀?

2. Kí ni Bíbélì fi hàn pé ó jẹ́ ànímọ́ mẹ́rin pàtàkì tí Ọlọ́run ní?

3. Kí ni ìfẹ́ títóbi jù lọ tí Ọlọ́run fi hàn sí aráyé?

4. Báwo la ṣe lè gbádùn bíbá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́?

5. Báwo ló ṣe yẹ ká ṣe táa bá ń gbàdúrà?

Ṣé o lè dáhùn díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè náà nísinsìnyí, àní kí ó tiẹ̀ tó di pé o ka ìyókù àpilẹ̀kọ yìí? A jẹ́ pé o ti mọ díẹ̀ nípa Ọlọ́run ju ọ̀pọ̀ èèyàn lọ nìyẹn. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe làwọn ìdáhùn rẹ fi hàn pé o ṣì ní láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa rẹ̀ kóo baà lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n dunjú-dunjú. (Jòhánù 17:3) Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ohun tí Bíbélì fi kọ́ wa nípa “Olùgbọ́ àdúrà” náà.—Sáàmù 65:2.

Ẹni Gidi Ni Ọlọ́run

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Ọlọ́run kì í ṣe agbára kan lásán tí kò sí níbì kankan. Ó jẹ́ ẹnì kan, ó sì ní orúkọ kan, Jèhófà ni. (Sáàmù 83:18) “Alèwílèṣe” ni orúkọ yìí túmọ̀ sí lédè Hébérù. Ó lè ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ láti mú ète rẹ̀ ṣẹ. Agbára kan lásánlàsàn kò lè ṣe ìyẹn láé! Nítorí náà, nígbà tóo bá ń gbàdúrà, jẹ́ kó dá ọ lójú pé kì í ṣe agbára kan tó ṣòro ó lóye lo ń gbàdúrà sí tàbí pé ńṣe lo kàn ń sọ̀rọ̀ dà sínú afẹ́fẹ́. Ẹnì kan lo ń bá sọ̀rọ̀, ẹni tó lè gbọ́ àdúrà rẹ tí á sì tún dáhùn rẹ̀.—Éfésù 3:20.

Èyí ló mú ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Diana sọ pé: “Mo mọ̀ pé ibikíbi tó wù kí n wà, Jèhófà á tẹ́tí gbọ́ mi.” Kóo tó lè ní irú ìdánilójú yẹn, Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ ni gidi sí ọ! Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ.”—Hébérù 11:6.

Orísun Ọgbọ́n àti Agbára

Ní tòótọ́, Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ nítorí àgbàyanu ni agbára rẹ̀. Agbára yẹn kò ní ààlà, gẹ́gẹ́ bí a ti rí ẹ̀rí èyí nínú bí àgbáálá ayé tó ṣeé fojú rí ti fẹ̀ tó tó sì tún díjú tó. Bíbélì sọ pé Jèhófà mọ orúkọ ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìlóǹkà bílíọ̀nù ló wà! Yàtọ̀ síyẹn, òun náà tún ni orísun gbogbo agbára tó wà nínú àwọn ìràwọ̀ yẹn. (Aísáyà 40:25, 26) Ǹjẹ́ àgbàyanu gbáà kọ́ lèyí? Síbẹ̀, bó ti wù káwọn òtítọ́ yìí yà wá lẹ́nu tó, Bíbélì sọ pé “eyi ni diẹ ninu ọnà rẹ̀”!—Jóòbù 26:14, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

Tún gbé ọgbọ́n Jèhófà tí kò láàlà yẹ̀ wò. Bíbélì sọ pé àwọn ìrònú rẹ̀ “jinlẹ̀ gidigidi.” (Sáàmù 92:5) Òun ló dá ìran ènìyàn, nítorí náà ó mọ̀ wá gan an ju bí a ṣe mọ ara wa lọ. (Sáàmù 100:3) Nítorí pé ó ti wà “láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin,” ìrírí rẹ̀ kò láàlà. (Sáàmù 90:1, 2) Kò sóhun tó ṣòro fún un láti lóye.—Aísáyà 40:13, 14.

Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo gbogbo agbára àti ọgbọ́n yẹn? Ìwé 2 Kíróníkà 16:9 sọ pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Kò sí irú ìṣòro náà tí o lè ní tí Ọlọ́run kò lè yanjú rẹ̀ tàbí kó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú rẹ̀. Kayla tó jẹ́ ọ̀dọ́ sọ pé: “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, nígbà témi àti ìdílé mi wà nínú ìṣòro lílekoko kan, mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì rí i pé ó ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á àti láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ipò ìṣòro, àtàwọn èrò tíì bá ti kọjá agbára wa.” Nígbà tóo bá bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, ọ̀dọ̀ ẹni tó jẹ́ orísun ọgbọ́n lo lọ yẹn. Kò sóhun tó lè ṣàǹfààní fún ẹ jùyẹn lọ!

Ọlọ́run Ìdájọ́ Òdodo àti Ìfẹ́

Àmọ́ báwo lo ṣe lè mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ìdí ni pé kì í ṣe nípasẹ̀ agbára rẹ̀ kíkàmàmà tàbí ọgbọ́n rẹ̀ àwámáridìí tàbí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ni Jèhófà fi fara rẹ̀ hàn wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun pàtàkì táa fi mọ Jèhófà ni ànímọ́ rẹ̀ ti ìfẹ́. Ìwé 1 Jòhánù 4:8 sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Ìfẹ́ ńlá tó ní yẹn ló fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé yóò dáhùn àwọn àdúrà wa. Ọ̀nà tó ga jù lọ tó gbà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí wa ni fífi tó fi Ọmọ rẹ̀ fún wa ní ẹbọ ìràpadà ká lè gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 4:9, 10.

Nítorí pé Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́, kò yẹ kóo bẹ̀rù rárá pé kò ní dá ẹ lóhùn tàbí pé kò ní ṣe dáadáa sí ẹ. Diutarónómì 32:4 sọ pé, “gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.” Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí ẹ ló máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé á tẹ́tí gbọ́ ẹ dáadáa. Èyí jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ láti sọ èrò wa àtàwọn ohun tó ń dùn wá tá ò lè sọ fún àwọn ẹlòmíràn fún un.—Fílípì 4:6, 7.

Bíbá Ọlọ́run Ṣọ̀rẹ́

Ní ti gidi, Jèhófà ń ké sí wa láti bá òun sọ̀rọ̀. Kò fẹ́ kóun jẹ́ àjèjì sí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, jálẹ̀ gbogbo ìtàn aráyé ni Jèhófà ti ń ké sáwọn èèyàn láti jẹ́ ọ̀rẹ́ òun. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti àgbà wà lára àwọn tó gbádùn bíbá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́, tí wọ́n tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn. Ábúráhámù, Dáfídì Ọba, àti Màríà tó jẹ́ ìyá Jésù wà lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.—Aísáyà 41:8; Lúùkù 1:26-38; Ìṣe 13:22.

Ìwọ náà lè di ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà. Ó dájú pé irú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ kò túmọ̀ sí pé wàá wá sọ Ọlọ́run di iwin kan tó jẹ́ pé ìgbà tóo bá fẹ́ nǹkan kan tàbí tóo bá níṣòro nìkan ni wàá máa pè é. Àdúrà wa kò gbọ́dọ̀ dá lórí ohun táa nílò nìkan. Táa bá fẹ́ kí Ọlọ́run bá wa dọ́rẹ̀ẹ́, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀, kó máà jẹ́ tiwa nìkan, a sì gbọ́dọ̀ e ìfẹ́ Ọlọ́run ní ti gidi. (Mátíù 7:21) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn láti jẹ́ kí àdúrà wọ́n dá lórí àwọn ohun tó jẹ́ pàtàkì lójú Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’” (Mátíù 6:9, 10) Àwọn àdúrà wa tún gbọ́dọ̀ kún fún ìyìn àti ìdúpẹ́ sí Ọlọ́run!—Sáàmù 56:12; 150:6.

Síbẹ̀, kò yẹ ká ronú pé àwọn ohun táa nílò tàbí àwọn ohun tó ń dà wá láàmú ti kéré jù, pé wọn ò tó ohun táa lè máa torí ẹ̀ gbàdúrà. Steve sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń gbìyànjú láti sọ bí nǹkan bá ṣe rí lọ́kàn mi fún Ọlọ́run, àwọn ìgbà míì wà tí màá rò pé kó yẹ kí n da Ọlọ́run láàmú lórí àwọn ohun kan tó jẹ́ tara.” Nígbàkigbà tí irú èrò yẹn bá ti bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ẹ lọ́kàn, gbìyànjú láti rántí ohun tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ológoṣẹ́ márùn-ún ni a ń tà ní ẹyọ owó méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run. . . . Ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́.” (Lúùkù 12:6, 7) Ǹjẹ́ ìyẹn kò túbọ̀ fini lọ́kàn balẹ̀?

Ó rọrùn nígbà náà láti mọ̀ pé, bóo bá ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà sí i tó, bẹ́ẹ̀ nìyẹn á ṣe máa sún ọ láti máa tọ̀ ọ́ lọ nínú àdúrà tó, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọkàn rẹ̀ á ṣe túbọ̀ balẹ̀ tó pé Jèhófà lè ràn ọ́ lọ́wọ́ àti pé yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, báwo ló ṣe yẹ kóo ṣe tóo bá fẹ́ bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nínú àdúrà? Ó yẹ kóo fi ọ̀wọ̀ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn, kóo sì jẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan. Ṣé o rò pé aláṣẹ kan tó wà ní ipò gíga nínú ayé á tẹ́tí gbọ́ ẹ tóo bá béèrè nǹkan kan lọ́wọ́ ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbéraga tàbí lọ́nà tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn? Kò yẹ kó yà ọ́ lẹ́nu nígbà náà pé, Jèhófà náà retí pé kóo bọ̀wọ̀ fún òun àti àwọn ìlànà òun kó tó lè dáhùn àwọn àdúrà rẹ.—Òwe 15:29.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èwe tó níbẹ̀rù Ọlọ́run ti kọ́ láti sọ gbogbo nǹkan tó wà lọ́kàn wọn fún Ọlọ́run. (Sáàmù 62:8) Brett sọ pé: “Nígbà tí Jèhófà bá dáhùn àwọn àdúrà mi, ìyẹn máa ń fún mi níṣìírí pé ó ṣì jẹ́ ọ̀rẹ́ mi síbẹ̀.” Ìwọ náà ńkọ́? Báwo lo ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn irú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ yẹn pẹ̀lú Ọlọ́run? Àwọn ọ̀dọ́ méjì tó jẹ́ Kristẹni sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí:

Rachel: “Mo mọ̀ pé tí mo bá fẹ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, mo gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jinlẹ̀jinlẹ̀, mo sì ń gbìyànjú láti kọ́ bí màá ṣe ní ìyánhànhàn fún irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀.”—1 Pétérù 2:2.

Jenny: Mo gbà pé bóo bá ṣe fi ara rẹ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tó, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe rí i pé o túbọ̀ ń sún mọ́ ọn tó.”—Jákọ́bù 4:8.

Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì rí pé bóyá àdúrà gbígbà tiẹ̀ làǹfààní tó ń ṣe? Ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Kristẹni sọ pé: “Mo mọ̀ pé màá túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run ká ní ó lè bá mi sọ̀rọ̀ tàbí kó fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí mi.” Àmọ́ nígbà tí a kì í gbóhùn Jèhófà tó bá ń dáhùn àdúrà wa, báwo gan an làdúrà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́? Èyí la máa jíròrò nínú ìtẹ̀jáde tó ń bọ̀ níwájú.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]

Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó wà ní ojú ewé 29

1. Jèhófà. Ó túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.”

2. Ìfẹ́, agbára, ìdájọ́ òdodo, àti ọgbọ́n.

3. Ó rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, Jésù, láti wá kú nítorí wa.

4. Nípa ṣíṣàìjẹ́ kí àwọn ohun tó jẹ́ àìní wa jẹ wá lọ́kàn jù, àmọ́ kí á nífẹ̀ẹ́ nínú ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àti ṣíṣe é.

5. A gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká fi ọ̀wọ̀ hàn, ká má sì jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì àti lára ìṣẹ̀dá á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ Ọlọ́run dáadáa