Ibo Ni Gbogbo Omi Ọ̀hún lọ?
Ibo Ni Gbogbo Omi Ọ̀hún lọ?
ÌLÚ Cherrapunji ní Íńdíà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi ti òjò ti máa ń rọ̀ jù lọ lágbàáyé. Nígbà òjò, gbingbin lomi máa ń rin àwọn òkè rẹ̀, èyí tó wà lápá ìsàlẹ̀ Òkè Himalaya. Àmọ́ o, bó ṣe lè yani lẹ́nu tó, ìyà omi mà tún ń jẹ ìlú Cherrapunji.
NÍTORÍ pé igbó tó wà níbẹ̀ kò tó láti gba omi dúró mọ́, kíá lomi máa ń ṣàn lọ bó bá ti ń dà látojú sánmà. Oṣù méjì lẹ́yìn tí ìgbà òjò bá sì ti kọjá lomi á ti bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́n. Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Water: The International Crisis, Robin Clarke pe ìlú Cherrapunji ní “aṣálẹ̀ tí òjò ti ń rọ̀ jù lọ lágbàáyé.”
Apá ìsàlẹ̀ ibi tí omi tó ń bọ̀ láti Cherrapunji ń ṣàn gbà ni Bangladesh wà, orílẹ̀-èdè elérò púpọ̀ kan tó wà lọ́wọ́ ìsàlẹ̀, tó sì ń forí fá èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wàhálà omi ìgbà òjò tó ń ṣàn wálẹ̀ láti apá òkè ilẹ̀ Íńdíà àti Nepal tí gbogbo igbó wọn ti parẹ́. Ní àwọn ọdún mìíràn, ìdá méjì nínú mẹ́ta ìlú Bangladesh lomi ń bò mọ́lẹ̀. Àmọ́ tí kíkún omi náà bá ti lè rọlẹ̀, ńṣe lomi Odò Ganges máa fà, ilẹ̀ náà á sì gbẹ táú. Ó ju ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù èèyàn lọ tó ń ko ìṣòro ìkún omi òun ọ̀dá tí ń hanni léèmọ̀ yìí ní Bangladesh lọ́dọọdún. Ohun tó tún wá mú ọ̀rọ̀ ọ̀hún burú sí i ni pé, oògùn apakòkòrò arsenic ti kó èérí bá omi kànga wọn, àfàìmọ̀ kó má sì ti kó májèlé ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn.
Ní Nukus, Uzbekistan, èyí tí kò jìnnà sí Okun Aral, ìṣòro tiwọn kìí ṣe ti oògùn apakòkòrò arsenic, bí kò ṣe iyọ̀. Ńṣe làwọn gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ funfun gígan paali bo igi òwú wọn ṣíbáṣíbá tí kò sì jẹ́ kí wọ́n ráyè dàgbà dáadáa. Àtinú yanrìn abẹ́lẹ̀ tomi ti rin gbingbin ni iyọ̀ ọ̀hún ti wá sókè. Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí ìṣòro yìí máa ṣẹlẹ̀ nìyí. Irú ìṣòro yìí gan an ló mú iṣẹ́ àgbẹ̀ àwọn ará Mesopotámíà jó rẹ̀yìn ní ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rin sẹ́yìn. Bíbomirinlẹ̀ kọjá ààlà àti kí omi má rí ọ̀nà jáde ló ń mú kí iyọ̀ gbára jọ sókè eèpẹ̀. Láti rí ohun gidi kórè lóko, omi tí kò níyọ̀ ni wọ́n nílò. Àmọ́ síbẹ̀ náà, bópẹ́ bóyá, iyẹ̀pẹ̀
yẹn kò ní wúlò mọ́ fáwọn ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìn.Ibo Ni Gbogbo Omi Ọ̀hún Lọ?
Ohun tó dunni ni pé, lọ́pọ̀ ìgbà, yàà ni òjò máa ń da omi sílẹ̀. Kì í ṣe pé èyí máa ń fa omíyalé nìkan ni o, àmọ́ ńṣe ló tún máa ń jẹ́ kí omi ṣàn kúrò lórí ilẹ̀ ní kíákíá lọ sínú òkun. Bẹ́ẹ̀ lòjò máa ń rọ̀ ṣáá láwọn ibì kan tí kì í sì í tó láwọn ibòmíì. Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti mọ Cherrapunji fún níní àkọsílẹ̀ tó ju ẹgbàá mẹ́tàlá [26,000] mìlímítà òjò lọ lọ́dún, bẹ́ẹ̀ sì rèé eku káká lòjò fi máa ń rọ̀ lọ́dún míì ní Aṣálẹ̀ Atacama tó wà ní àríwá Chile.
Láfikún sí i, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé wa yìí ló jẹ́ pé ibi tomi ò pọ̀ tó ni wọ́n ń gbé. Fún àpẹẹrẹ, èèyàn díẹ̀ ló ń gbé láwọn àgbègbè tójò ti máa ń rọ̀ gan an nílẹ̀ olóoru Áfíríkà àti ní Gúúsù Amẹ́ríkà. Ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún ọ̀gbàrá òjò tó ń ṣàn ní gbogbo ayé lọ́dọọdún ni Odò Amazon nìkan ń tú dà sínú Òkun Àtìláńtíìkì, àwọn èèyàn tó ń gbé lágbègbè náà ò kúkú pọ̀, ìwọ̀nba omi díẹ̀ ni wọ́n sì nílò. Àmọ́ òdìkejì èyí ni ti ilẹ̀ Íjíbítì níbi tójò kì í fi bẹ́ẹ̀ rọ̀, àwọn èèyàn tó ń lọ sí bí ọgọ́ta mílíọ̀nù ló ń gbébẹ̀, Odò Náílì tó ń gbẹ lọ nìkan ló sì ń pèsè omi fún wọn láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́ fomi ṣe.
Láwọn ọdún tó kọjá, irú àìbáradọ́gba báyìí nínú ìpèsè omi kì í fa ìṣòro kan lọ títí. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ṣe sọ, lọ́dún 1950, kò sí àgbègbè kankan láyé tí ìyà omi ń jẹ́ bóyá níwọ̀nba tàbí lójú méjèèjì. Àmọ́ àkókò tí omi wà yámuyàmu bẹ́ẹ̀ ti yí padà o. Láwọn àgbègbè tó gbẹ táútáú ní Àríwá Áfíríkà àti Àárín Gbùngbùn Éṣíà, ìwọ̀n omi tó wà fún ènìyàn kan ti wá sílẹ̀ sí ìdá kan nínú mẹ́wàá ohun tó jẹ́ lọ́dún 1950.
Yàtọ̀ sí pé àwọn èèyàn pọ̀ sí i, tí òjò kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ láwọn àgbègbè téèyàn pọ̀ sí jù lọ, àwọn ìdí mìí tún wà tó sọ omi di ọ̀wọ́n. Nínú ayé lónìí, láti lè ní ìtẹ̀síwájú àti aásìkí, omi gbọ́dọ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó.
Àwọn Èèyàn Ń Fẹ́ Omi Púpọ̀ Sí i
Bó bá jẹ́ orílẹ̀-èdè onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lò ń gbé, kò sí àní-àní pé wàá ti ṣàkíyèsí pé ibi táwọn odò ńlá bá wà làwọn iléeṣẹ́ máa ń ṣù jọ sí. Ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ kò ṣòroó mọ̀ o. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tí iléeṣẹ́ kan máa mú jáde tí kò ní la lílo omi lọ, látorí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà títí dórí pín-ìn-nì tí wọ́n fi ń mú bébà pọ̀. Omi táwọn iléeṣẹ́ tí ń ṣe oúnjẹ ń lò kì í ṣe kékeré. Omi díẹ̀ kì í tó àwọn iléeṣẹ́ amúnáwá ní
tiwọn, ibi tí adágún tàbí odò bá sì wà ni wọ́n máa ń tẹ̀dó sí.Omi tí iṣẹ́ àgbẹ̀ nílò tiẹ̀ tún wá kọjá ìyẹn. Ọ̀pọ̀ ibi ló jẹ́ pé òjò kì í fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ tàbí kó máà tóo gbára lé débi téèyàn lè máa retí irè oko tó dára, ìdí rèé tó jẹ́ pé bíbomirin oko ló dà bí ojútùú tó kù láti bọ́ aráyé tébi ń pa. Nítorí pé bíbomirin oko làwọn èèyàn gbára lé fún iṣẹ́ ọ̀gbìn, èyí tí iṣẹ́ àgbẹ̀ ń gbà nínú omi ilẹ̀ ayé ló pọ̀ jù lọ.
Láfikún sí i, omi téèyàn ń lò nínú ilé tún ti pọ̀ sí i. Láàárín àwọn ọdún 1990, òbítíbitì àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] mílíọ̀nù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lọ gbé ní àwọn ìlú ńlá ló nílò ìmọ́tótó tó péye àti rírí omi tó dára lò. Ibi táwọn èèyàn ti ń rí omi látayébáyé, ìyẹn àwọn òdo àti kànga kò tún tó fún àwọn aráàlú mọ́. Fún àpẹẹrẹ, Ìlú Mẹ́síkò ní láti lọ máà fa omi wá báyìí láti ibi tó ju kìlómítà márùnlélọ́gọ́fà [125] lọ, kí wọ́n sì fà á gba orí àwọn òkè ńlá tó fi ẹgbẹ̀fà [1,200] mítà ga ju ìlú náà lọ. Dieter Kraemer sọ nínú ìròyìn rẹ̀ tó pè ní Water: The Life-Giving Source, pé “gátagàta làwọn páìpù omi ọ̀hún rí káàkiri.”
Bọ́rọ̀ ṣe dà nìyẹn o, tí iléeṣẹ́, iṣẹ́ àgbẹ̀, àtàwọn ará ìgboro bẹ̀rẹ̀ sí wá omi lójú méjèèjì. Ní báyìí ná, omi tí ilẹ̀ ayé ní nípamọ́, ìyẹn omi abẹ́lẹ̀, ni wọ́n ń lọ fà láti mú wàhálà yìí rọjú. Inú ilẹ̀ nísàlẹ̀ lọ́hùn-ún jẹ́ ọ̀kan lára ibi pàtàkì tí ilẹ̀ ayé fi omi aláìníyọ̀ pamọ́ sí. Àmọ́ kò túmọ̀ sí pé kò lè tán o. Ńṣe làwọn omi tó wà nípamọ́ yẹn dà bí owó tóo fi pa mọ́ sí báńkì. Ó ò kàn lè máa lọ gba owó ṣáá tí èyí tóo fi síbẹ̀ kò bá pọ̀. Ọjọ́ kan á jọ́kan tí ìwọ náà á fojú ara rẹ ri i pé o ti gbowó kan ìsàlẹ̀ àpò.
Ìwúlò Omi Abẹ́lẹ̀ àti Bí Wọ́n Ṣe Ń Ṣì Í Lò
Omi abẹ́lẹ̀ la máa ń fà nígbà táa bá gbẹ́ kànga. Ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé tí wọ́n pè ní Groundwater: The Invisible and Endangered Resource ṣírò rẹ̀ pé, ìdajì omi táa ń lò nínú ilé àtèyí táa fi ń bomi rin oko ló wá láti ibẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tó sì jẹ́ pé omi abẹ́lẹ̀ kì í fi bẹ́ẹ̀ lẹ́gbin bíi tòkè, òun náà ló ń pèsè púpọ̀ lára omi táa ń mu, láàárín ìlú àti ní àrọko. Tí wọn ò bá ki àṣejù bọ̀ ọ́, yámuyàmu lomi yìí á ṣì wà níbẹ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìgbà gbogbo lomi òjò tó máa ń ro síbẹ̀ máa ń ṣàlékún rẹ̀. Àmọ́ fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún báyìí làwọn ọmọ aráyé ti ń lọ gbọ́n omi yìí lọ́nà tó kọjá
ohun tí agbára rẹ̀ gbé láti dá padà.Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé téèyàn bá gbẹ́ kànga kì í tètè kan omi, téèyàn bá sì fẹ́ẹ́ gbẹ́ ẹ kan omi ìfowóṣòfò àti lílo agbára dànù lásán ló máa jẹ́. Nígbà tómi kànga bá gbẹ, àdánwò ńlá ló máa ń dá sílẹ̀, ní ti ọ̀ràn ìnáwó àti fún àwọn èèyàn. Irú àjálù yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Íńdíà o. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé omi abẹ́lẹ̀ ni wọ́n gbára lé fún mímú oúnjẹ jáde fún bílíọ̀nù kan èèyàn tó ń gbé láwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ China àti Íńdíà, kò dà bí ẹni pé ọjọ́ iwájú á dára.
Sísọ omi yìí di eléèérí ló tún ń mú kó máa dínkù sí i. Àwọn ajílẹ̀ tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ọ̀gbìn, ìgbẹ́ ẹran àti tèèyàn, àti àwọn kẹ́míkà tí wọ́n ń lò ní iléeṣẹ́, gbogbo wọn pátá ló ń lọ sínú omi abẹ́lẹ̀ náà. Ìròyìn kan tí Àjọ Àgbáyé Tí Ń Wo Ojú Ọjọ́ Sàsọtẹ́lẹ̀ tẹ̀ jáde sọ pé: “Tí omi inú ilẹ̀ lọ́hùn-ún bá ti lè di èyí táa kó èérí bá, àtitún un ṣe lè máà yá bọ̀rọ̀, ó sì lè ná ni lówó gegere, ó tiẹ̀ lè má ṣe é tún ṣe rárá. ‘Ẹ̀bìtì gbáà’ ni bí omi abẹ́lẹ̀ ṣe ń di eléèérí díẹ̀díẹ̀ yìí jẹ́. Ìgbàkigbà lẹ̀bìtì ọ̀hún lè ré mọ́ ìran ènìyàn.”
Ohun tí ò wá dáa níbẹ̀ ni pé, omi tí wọ́n fà jáde láti abẹ́ ilẹ̀ tún lè padà wá ṣe ilẹ̀ tí wọ́n fi ń bomi rin ní jàǹbá. Ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tí wọ́n ń bomi rin láwọn orílẹ̀-èdè tó gbẹ táútáú tàbí tí òjò kì í ti í dunlẹ̀ ni àpọ̀jù iyọ̀ ń dà láàmú báyìí. Ní Íńdíà àti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tí wọ́n jẹ́ méjì lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ń pèsè oúnjẹ jù lọ lágbàáyé, ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún ilẹ̀ tí wọ́n ń bomi rin ló ti bàjẹ́ gan-an.
Má Fi Ṣòfò, Kóo Má Bàa Jìyà Rẹ̀
Pẹ̀lú gbogbo ìṣòro yìí náà, ipò ọ̀hún kì bá tí burú tó bẹ́ẹ̀ ká ní wọn ń ṣọ́ omi tó wà ní ilẹ̀ ayé lò. Àìbomi rinlẹ̀ lọ́nà tó tọ́ sábàá máa ń fi ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún omi ọ̀hún ṣòfò kó tó dé ibi táwọn nǹkan ọ̀gbìn wà. Àmọ́ bí wọ́n bá túbọ̀ ń ṣe é lọ́nà tó dára, tí wọ́n ń lo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní, ìyẹn lè dín omi táwọn iléeṣẹ́ ń lò kù sí ìdajì. Kódà wọ́n lè dín omi tí wọ́n ń lò ní ìgboro kù pẹ̀lú ìpín ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún ká ní lẹ́yẹ-ò-sọkà ni wọ́n máa ń tún àwọn páìpù tó bá fọ́ ṣe.
Bí omi bá máa di èyí táa ṣọ́ lò, àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ a sì tún gbọ́dọ̀ ṣàwárí ọ̀nà tí a ó gbà ṣe é. Ṣé àwọn ìdí gidi wà táa fi lè gbà pé a lè ṣọ́ omi tó wà nínú ilẹ̀ ayé wa lò débi táwọn ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìn á fi rí i lò? Àpilẹ̀kọ wa tó kẹ́yìn ló máa bójú tó ìbéèrè yìí.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
KÒ SÓHUN TÁA LÈ ṢE LÁÌLO OMI
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tí wọ́n ń mú jáde láwọn iléeṣẹ́ ló ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
◼ Ó lè gbà tó ọ̀rìnlélúgba [280] tọ́ọ̀nù omi láti mú tọ́ọ̀nù irin kan ṣoṣo jáde.
◼ Pípèsè bébà kìlógíráàmù kan ṣoṣo lè gbà tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] kìlógíráàmù omi (ìyẹn bí iléeṣẹ́ náà kò bá ń ṣàtúnlò omi wọn).
◼ Láti ṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan jáde, wọ́n á lo omi tó jẹ́ ìwọ̀n ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà ní ìlọ́po àádọ́ta.
Iṣẹ́ àgbẹ̀ lè gba omi tó tóyẹn, àgàgà tí wọ́n bá ń sin ohun ọ̀sìn láwọn àgbègbè tí òjò kì í ti í dunlẹ̀.
◼ Láti lè mú ègé ẹran tó wọn kìlógíráàmù kan jáde ní ilé ẹran ní California, á gba lítà omi ẹgbàáwàá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [20,500].
◼ Á gbà tó omi lítà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n láti lè fọ adìyẹ kan ṣoṣo mọ́ kí a tó gbé e sínú ẹ̀rọ tó ń mú nǹkan dì.
[Graph/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÀWỌN IBO LA TI Ń LO OMI?
Ibi iṣẹ́ àgbẹ̀ 65%
Iléeṣẹ́ 25%
Inú ilé 10%
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ọ̀kẹ́ àìmọye lítà omi ló ń ṣòfò nítorí àwọn páìpù omi tó ti fọ́ àtàwọn ẹ̀rọ omi tí wọ́n ń ṣí dà sílẹ̀
[Credit Line]
Fọ́tò AP/Richard Drew