Kòkòrò Ìrẹ̀, Olórin Ìfẹ́
Kòkòrò Ìrẹ̀, Olórin Ìfẹ́
NÍTORÍ kíkéré ti kòkòrò ìrẹ̀ kéré, ó lè dà bíi pé kò tó nǹkan téèyàn ń dúró wò. Síbẹ̀, àgbọ́málèlọ ni híhan ìrẹ̀ jẹ́ fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn káàkiri ayé. Báwo ni ẹ̀dá kékeré yìí ṣe ń han, kí sì ni ète tó fi ń han?
Ohun tó jọni lójú ni pé, nínú nǹkan bíi egbèjìlá [2,400] irú ọ̀wọ́ ìrẹ̀ tó wà, kìkìdá akọ inú wọn nìkan ló ń han. Dípò tí wọn ì bá máa fi ẹnu han, ìyẹ́ apá wọn ni àwọn akọ ìrẹ̀ yìí ń lò. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé bí àwọn akọ ìrẹ̀ ṣe máa ń han ni pé, wọ́n á fi ìyẹ́ ọwọ́ iwájú wọn kan ha àwọn ibi gọngọ tí ó tó bí àádọ́ta sí àádọ́talérúgba tó wà lára ìyẹ́ ọwọ́ iwájú kejì. Bí híhan náà ṣe máa gùn tó sinmi lórí iye ìgbà tó bá fi àwọn ìyẹ́ náà ha àwọn ibi títa gọngọ yẹn láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan. Gbígbọ̀n yìí ló máa wá mú kí híhan ìrẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ náà gba gbogbo àyíká kan.
Àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé, kì í ṣe torí àtidá àwọn èèyàn tó ń tẹ́tí sí i lárayá ló ń mú kí akọ ìrẹ̀ han! Nítorí ìyẹn kọ́ o! Ẹni tí ìrẹ̀ yìí ń torí ẹ̀ kọrin ni ẹni tó ṣeé ṣe kó di olólùfẹ́ rẹ̀. Ìwé Exploring the Secrets of Nature sọ pé: “Oríṣi híhan mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni akọ ìrẹ̀ tó jẹ́ aláròyé yìí máa ń han bó ṣe ń wá ẹni tó máa fẹ́ kiri: ọ̀kan jẹ́ láti polongo pé òun ti dé o, òmíràn jẹ́ fún ìfẹ́rasọ́nà àti ọ̀kan yòókù fún lílé àwọn tó bá fẹ́ bá a du ìyàwó wọgbó.” Àwọn ìrẹ̀ kan kì í dákẹ́ híhan láti polongo pé àwọn ti dé títí dìgbà tí wọ́n bá rí abo ìrẹ̀ tó gba tiwọn. Bí èyí abo bá sì ti lè fetí ba orin ọ̀hún nípasẹ̀ “àwọn etí” tó wà lẹ́sẹ̀ rẹ̀ iwájú, kò ní dúró sọ́nà jíjìn mọ́ láti máa bá ìfẹ́sọ́nà náà lọ. Bó ṣe ń sún mọ́ tòsí ibi tí orin náà ti ń wá, ni akọ ìrẹ̀ náà á bá pohùn dà táá bẹ̀rẹ̀ kíkọ orin ìfẹ́ láìdáwọ́dúró. Orin ìfẹ́ yìí ló máa fa abo náà mọ́ olólùfẹ́ rẹ̀, àwọn ìrẹ̀ méjèèjì náà á sì bára wọn lòpọ̀.
Ní Ìlà Oòrùn Éṣíà, àwọn èèyàn kan máa ń sin akọ ìrẹ̀ nítorí híhan rẹ̀ tó máa ń fi dá wọn lára yá. Àwọn kan sì yàn láti lọ máa gbádùn híhan yìí níbi tí ìrẹ̀ sábàá máa ń gbé. Ibi yòówù kó jẹ́, káàkiri àgbáyé ni orin ìrẹ̀ ti máa ń fa àwọn èèyàn tó ń fetí sí i mọ́ra tó sì ń fi ìyìn fún Ẹlẹ́dàá rẹ̀.