Lílo Oògùn Olóró—O Lè Jáwọ́ Ńbẹ̀!
Lílo Oògùn Olóró—O Lè Jáwọ́ Ńbẹ̀!
“ỌWỌ́ Àwọn Agbófinró Tẹ Kokéènì Rẹpẹtẹ Nínú Àwọn Ìgò Wáìnì.” Ohun tí wọ́n kọ sábẹ́ àkọlé yẹn nínú ìwé ìròyìn kan ṣàlàyé bí ọwọ́ ṣìkún àwọn ọlọ́pàá ní Johannesburg, ní Gúúsù Áfíríkà, ṣe tẹ àpótí ìkẹ́rùránṣẹ́ ńlá kan tí irínwó dín lẹ́gbàafà [11,600] ìgò ọtí wáìnì Gúúsù Amẹ́ríkà wà nínú rẹ̀. Wọ́n da nǹkan bíi àádọ́jọ sí ọgọ́sàn-án kìlógíráàmù kokéènì mọ́ wáìnì náà. Wọ́n gbà pé èyí ni fàyàwọ́ oògùn olóró kokéènì tó tóbi jù lọ tó tíì wọ orílẹ̀-èdè ọ̀hún.
Bí àwọn ọlọ́pàá ṣe rí oògùn olóró yìí gbà lè jẹ́ kéèyàn rò pé àjàyè logun tí wọ́n ń bá oògùn olóró jà, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé kìkì ìpín mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún oògùn olóró lágbàáyé làwọn ọlọ́pàá máa ń rí gbà. Ó mà ṣe o, ńṣe ló dà bí ìgbà tí àgbẹ̀ kan kàn ń géko lórí.
Èrè tàbùà-tabua tí wọ́n ń rí nínú oògùn olóró kò jẹ́ kí ìjọba lè fòpin sí ṣíṣe táwọn èèyàn ń ṣe é tí wọ́n sì ń tà á. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan, àìmọye bílíọ̀nù dọ́là ni iye oògùn olóró tí wọ́n fojú díwọ̀n rẹ̀ pé wọ́n ń tà tí wọ́n sì ń rà níbẹ̀ lọ́dọọdún. Pẹ̀lú owó tùùlù-tuulu tó wà nídìí rẹ̀ yí, kò yani lẹ́nu pé àwọn agbófinró àtàwọn aláṣẹ ìjọba, àtàwọn mìíràn nípò jàǹkànjàǹkàn ń hùwà ìbàjẹ́.
Alex Bellos ti iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn náà, The
Guardian Weekly ròyìn láti Brazil pé, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti fi hàn, “àwọn aṣòfin mẹ́ta, àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin méjìlá àtàwọn olórí ìlú mẹ́ta ni a to orúkọ wọn . . . nínú ìwé kan tó ní orúkọ àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rin tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n wà lára ẹgbẹ́ tó ń ṣètò ìwà ọ̀daràn tí wọ́n sì ń ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró ní orílẹ̀-èdè Brazil.” Orúkọ “àwọn agbófinró, àwọn amòfin, àwọn oníṣòwò àtàwọn àgbẹ̀ láti ìpínlẹ̀ mẹ́tàdínlógún lára ìpínlẹ̀ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tó wà níbẹ̀” tún wà nínú ìwé ọ̀hún. Ohun tí wọ́n rí yìí ló mú kí ọ̀jọ̀gbọ́n kan nípa òṣèlú ní Yunifásítì Brasília sọ pé: “Gbogbo ọ̀wọ́ àwọn èèyàn tó wà ní Brazil pátá lohun tó ṣẹlẹ̀ yìí nàka àbùkù sí.” A lè sọ ohun kan náà nípa àwọn àwùjọ tí oògùn olóró ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. Báwọn èèyàn púpọ̀ ṣe ń fẹ́ láti ta oògùn olóró táwọn púpọ̀ sì múra tán láti rà á ló tún bu epo síná ìṣòro ọ̀hún.Nígbà táwọn òfin tí wọ́n ṣe láti fi dè é kò gbéṣẹ́, làwọn kan bá sọ pé kí wọ́n ṣòfin tó máa fàyè gba àwọn oríṣi oògùn olóró kan. Èròǹgbà gbogbo gbòò ni pé kí wọ́n fàyè gba olúkúlùkù láti ní díẹ̀ táá máa lò lọ́wọ́. Wọ́n rò pé èyí á mú kí ìjọba lè káwọ́ rẹ̀ táa sì dín èrè tabua àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ nídìí oògùn olóró kù.
Àwọn Kan Ti Jáwọ́ Lílo Oògùn Olóró
Ìtọ́jú mímú májèlé oògùn olóró kúrò nínú ara lè kọ́kọ́ jẹ́ kí ẹnì kan fi oògùn olóró sílẹ̀ kí ìlera rẹ̀ sì gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Èyí tó wá dunni níbẹ̀ ni pé, bónítọ̀hún bá ti padà síbi tóògùn olóró wà, ó ṣeé ṣe kó tún bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó. Òǹkọ̀wé Luigi Zoja sọ ohun tó ń fà á, ó ní: “Ẹnì kan kò kàn lè fi ìwà rẹ̀ sílẹ̀ báyẹn láìjẹ́ pé èèyàn kọ́ ọ láti máa ronú lọ́nà mìíràn tó yàtọ̀ pátápátá sí ti tẹ́lẹ̀”
“Èrò tuntun” tí Darren, táa mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ní ló yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà. Ó ní: “Aláìgbà-pọ́lọ́run-wà ni mí tẹ́lẹ̀, àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mo sì fi máa ń joògùn yó kẹ́ri, àmọ́ nígbà tó yá, mo wá ronú pé Ọlọ́run gbọ́dọ̀ wà. Láàárín oṣù méjì sí mẹ́ta, mo gbìyànjú láti jáwọ́ nínú oògùn olóró, àmọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi kò jẹ́ kí n lè jáwọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì ń lo oògùn olóró, mo bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì ní alaalẹ́ kí n tó sùn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí yẹra fáwọn ọ̀rẹ́ mi wọ̀nyí. Lálẹ́ ọjọ́ kan èmi àtẹni táa jọ ń gbé yàrá ti joògùn yó kẹ́ri. Mo sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì fún un. Ló bá tẹ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láago láàárọ̀ ọjọ́ kejì. Nìyẹn bá júwe Ẹlẹ́rìí kan tó ń gbé nílùú táa wà fún wa, mo sì forí lé ibẹ̀.
“A sọ̀rọ̀ títí di aago mọ́kànlá òru, nǹkan bí oríṣi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjìlá ni mo kó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ rẹ̀ mo sì jáwọ́ lílo oògùn olóró àti mímu sìgá. Ní nǹkan bí oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn náà, mo ṣèrìbọmi láti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Kò rọrùn láti jáwọ́ lílo oògùn olóró. Michael, táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tó jáwọ́ lílo oògùn olóró lẹ́yìn ọdún mọ́kànlá tó ti ń lò ó, ó ní: “Mi ò lè jẹun, mo wá rù hangogo. Ńṣe lára á máa já mi jẹ, òógùn á bò mí, ojú mi á sì máa ṣe bàìbàì bí mo bá wà láàárín àwọn èèyàn. Ńṣe lọ̀fun mi ń dá tòótòó láti tún lo oògùn olóró, àmọ́ sísún mọ́ Jèhófà nípa àdúrà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò jẹ́ kí n padà sídìí rẹ̀ mọ́.” Àwọn tó ti ń lo oògùn olóró tẹ́lẹ̀ rí yìí gbà pé ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn yẹra fún ẹgbẹ́ tí wọ́n ń kó tẹ́lẹ̀.
Ohun Tó Mú Kí Akitiyan Ẹ̀dá Ènìyàn Já Sófo
Lílo oògùn olóró kàn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tó wà kárí ayé. Gbogbo ayé ló wà lábẹ́ agbára tó ń súnni láti hùwà búburú, láti hùwà ipá àti ìwà òǹrorò. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Àpọ́sítélì Jòhánù tọ́ka sí “ẹni burúkú náà” nínú Ìṣípayá 12:9, tó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”
Yàtọ̀ fún kùdìẹ̀-kudiẹ táwọn èèyàn ní, wọ́n tún ní láti máa bá ọ̀tá tó lágbára yìí wọ̀yá ìjà. Sátánì ló kó bọwọ́bọwọ́ bọ ẹ̀dá èèyàn lọ́wọ́ níbẹ̀rẹ̀ pàá. Ó ń forí ṣe fọrùn ṣe láti túbọ̀ sọ ìran ènìyàn dìdàkudà kó sì mú wọn fi Ọlọ́run sílẹ̀. Oògùn olóró táwọn èèyàn ń lò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń lò. Tìbínú-tìbínú ló fi ń ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe torí ó mọ̀ pé “sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣípayá 12:12.
Ojútùú Wo Ni Ọlọ́run Pèsè?
Bíbélì jẹ́ ká mọ ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Ẹlẹ́dàá ti ṣe láti mú ìran ènìyàn kúrò nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nínú ìwé 1 Kọ́ríńtì 15:22, a sọ fún wa pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.” Jésù fínnúfíndọ̀ wá sáyé ní ẹ̀dá èèyàn tó pé, ó sì fi ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé rúbọ láti gba ìran ènìyàn kúrò lọ́wọ́ àtúbọ̀tán ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.
Mímọ̀ táwọn kan mọ ohun tó ń fa ikú àti ojútùú sí ìṣòro ẹ̀dá ènìyàn ti fún wọn ní ìgboyà, ó sì ti sún wọn láti jáwọ́ nínú oògùn olóró. Ṣùgbọ́n ohun tí Bíbélì ṣe fún wa ju ríràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro oògùn olóró nísinsìnyí lọ. Ó sọ fún wa nípa àkókò tí gbogbo ìṣòro aráyé, tó fi dórí lílo oògùn olóró máa kúrò láú, ìyẹn nígbà tí Èṣù kò bá sí mọ́.
Ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe “odò omi ìyè kan, tí ń ṣàn jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣípayá 22:1) Odò ìṣàpẹẹrẹ yìí dúró fún ohun tí Ọlọ́run ti pèsè nípasẹ̀ Jésù Kristi láti mú ẹ̀dá èèyàn padà sí ìwàláàyè pípé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. Ìṣípayá ṣàpèjúwe àwọn igi ìyè tí wọ́n ń jà yọ̀yọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò náà, ó wá sọ pé: “Ewé àwọn igi náà sì wà fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.” (Ìṣípayá 22:2) Àwọn ewé ìṣàpẹẹrẹ wọ̀nyẹn ṣàpèjúwe àwọn ìpèsè fún ìmúláradá tí Jèhófà ti ṣe láti mú kí ìran ènìyàn ní ìlera tó jí pépé nípa tara àti tẹ̀mí.
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ẹ̀dá èèyàn á wá bọ́ lọ́wọ́ oògùn olóró àti gbogbo wàhálà, àtàwọn ìṣòro mìíràn tó ń bá wọn fínra nínú ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí!
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ṣé Ó Léwu Kéèyàn Lo Igbó fún Ìtọ́jú?
Àwọn orílẹ̀-èdè kan ń gbèrò láti gba igbó [marijuana] láyè lábẹ́ òfin, nítorí lílò ó fún egbòogi. Wọ́n ní ó máa ń dín ìrìndọ̀ tí ìtọ́jú oníkẹ́míkà ń fà kù, ẹ̀rí sì tún fi hàn pé ó máa ń mú káwọn tó ní àrùn éèdì lè jẹun. Wọ́n tún ti fi ṣe oògùn apàrora.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àbájáde ìwádìí tí wọ́n ṣe ṣì ń fa awuyewuye, àwọn àyẹ̀wò tí ìwé ìròyìn New Scientist sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fi hàn pé àwọn ewu kan wà nínú mímu igbó.
Yunifásítì Havard ṣe àyẹ̀wò kan fún àwùjọ kan tó máa ń mugbó lójoojúmọ́ àti àwùjọ kan tó máa ń mu ún lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ nínú bí ọpọlọ wọn ṣe ń ṣiṣẹ́ sí. Àmọ́ ṣá, nínú àyẹ̀wò nípa agbára láti mú ara wọn bá ipò tuntun mu tí wọ́n ṣe fún wọn, àwọn tó ń mugbó lójú méjèèjì kò ṣe dáadáa.
Ó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún gbáko tí yunifásítì mìíràn fi ṣàyẹ̀wò àwùjọ kan tó ń mugbó déédéé àti àwùjọ kan tó ń mu sìgá. Àwọn tó ń mugbó náà sábàá máa ń mu ọ̀pá mẹ́ta tàbí mẹ́rin lójúmọ́, tí àwọn tó ń mu sìgá sì ń mu ogún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Iye èèyàn kan náà làwọn tó ń wúkọ́ tí àrùn gbọ̀fungbọ̀fun sì ń bá jà nínú àwùjọ méjèèjì. Àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀fóró fi hàn pé bákan náà ni àwọn nǹkan tín-tìn-tín inú ara àwọn àwùjọ méjèèjì ṣe bà jẹ́ tó.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń mugbó kì í mu ún ní gbogbo ìgbà, àyẹ̀wò fi hàn pé èéfín tó ń jáde nínú ọ̀pá kan fi ìgbà mẹ́ta ju ti ọ̀pá sìgá kan lọ. Kò tán síbẹ̀, ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Àwọn tó ń mugbó máa ń fà á ságbárí gan-an ni, tí wọ́n sì máa ń séèémí fúngbà pípẹ́ ju ti àwọn amusìgá.”
Láfikún sí i, wọ́n ti ríi pé àwọn kòkòrò tó ń dènà àrùn nínú ẹ̀dọ̀fóró àwọn tó ń mugbó kò lágbára láti kojú àrùn bíi tàwọn amusìgá.
[Credit Line]
U.S. Navy photo
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
“Ẹ̀bi” Àwọn Òbí
Ọ̀rọ̀ olóòtú kan nínú ìwé ìròyìn Gúúsù Áfíríkà náà, Saturday Star, fi hàn bí ọ̀rọ̀ ṣe ká àwọn èèyàn lára lórí báwọn ọ̀dọ́ ṣe túbọ̀ ń loògùn olóró ní Gúúsù Áfíríkà, ó sọ pé:
“Ẹ̀bi àwa òbí àti àwùjọ lápapọ̀ ló sábà máa ń jẹ́ pé àwọn ọmọ wa ń lo oògùn olóró. Àṣekúdórógbó iṣẹ́ la máa ń ṣe nítorí owó kí nǹkan sì lè rọ̀ṣọ̀mù. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ògo wẹẹrẹ wa ń fẹ́ gbogbo èrò inú àti okun wa. Lílo àkókò tó nítumọ̀ pẹ̀lú wọn ńkọ́? Ká ṣáà ti tọwọ́ bọ̀pò ká sì fún wọn lówó kí wọ́n lè jẹ́ ká ráyè ṣe tiwa là ń fẹ́. Èyí ló máa ń rọ̀ wá lọ́rùn ju fífetí sílẹ̀ sí wọn lọ, ká fara balẹ̀ gbọ́ ìṣòro wọn, ìrètí wọn, àtàwọn ohun tó ń dà wọ́n lọ́kàn rú. Lálẹ́ òní, báa bá jókòó táa ń gba fàájì nílé oúnjẹ kan tàbí nídìí tẹlifíṣọ̀n kan, ǹjẹ́ a tiẹ̀ máa mọ ohun tí wọ́n ń ṣe?”
Àní ká tún fi kún un, ǹjẹ́ a tiẹ̀ máa mọ ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
A ti sún ọ̀pọ̀ láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró