Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Gbé Àlàáfíà Lárugẹ Dípò Ogun

Mo Gbé Àlàáfíà Lárugẹ Dípò Ogun

Mo Gbé Àlàáfíà Lárugẹ Dípò Ogun

BÍ DOROTHY HORLE ṢE SỌ Ọ́

Ní 1919, wọ́n bí mi sínú ìdílé ará Ítálì kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ní Wilmington, Delaware, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àwọn òbí mi ò dé ṣọ́ọ̀ṣì jọ́sìn rí, àmọ́ wọ́n máa ń sọ fún èmi àtàwọn arábìnrin mi méjì pé kí á lọ. Bí ṣọ́ọ̀ṣì ṣe máa ń rí kẹ̀ǹkẹ̀-kẹ̀ǹkẹ̀ àti ọ̀nà àràbarà tí wọ́n gbà kọ́ wọn, pẹ̀lú ère inú wọn àtàwọn pẹ́pẹ́fúúrú tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ máa ń mórí mi wú.

BỌ́DÚN ti ń gorí ọdún, ìfẹ́ tí mo ní nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì pòórá. Ṣọ́ọ̀ṣì kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ nípa Bíbélì, èyí tí bàbá mi bọ̀wọ̀ fún tó sì máa ń kà déédéé. Ìwé àtìgbàdégbà ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n má ń to orúkọ àwọn tó dáwó àti iye tí wọ́n dá sínú ẹ̀ máa ń kọ mí lóminú. Àìmọye àhesọ ni mo tún gbọ́ nípa àwọn àlùfáà oníwàkiwà. Nígbà tí màá fi di ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mi ò fi gbogbo ara ṣẹ̀sìn Kátólíìkì mọ́. Èyí ló túbọ̀ fún mi láyè láti lépa ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú iṣẹ́ ọnà.

Fífi Iṣẹ́ Ọnà Ṣiṣẹ́ Ṣe

Ní 1940, nígbà tí mo pé ọdún mọ́kànlélógún, mo fẹ́ William Horle, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó gbádùn yíya ohunkóhun tó bá ṣáà ti jẹ mọ́ togun, bí ọkọ̀ òfúúrufú, sójà, àti ọkọ̀ òkun. Inú Bill dùn pé mo jẹ́ ayàwòrán, ó sì ra ọ̀wọ́ àwọn ọ̀dà tí màá kọ́kọ́ ní fún mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ bí mo ṣe lè di ọ̀gá nínú yíya nǹkan.

Lẹ́yìn bí ọdún méjì táa ṣègbéyàwó, Bill bẹ̀rẹ̀ sí fi òjé ṣe àwọn nǹkan kéékèèké tó jẹ mọ́ tológun. Ṣé àwọn sójà tọ́mọdé máa ń fi ṣeré? Rárá o! Fífi iṣẹ́ ọnà ṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ ojúlówó lohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Àwọn oníṣẹ́ ọnà kan máa ń lo ike, igi, tàbí ẹfun, àmọ́ òjé tí Bill ń lò fún tiẹ̀ dáa gan-an ni, nítorí ó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí bó ṣe lè fẹ̀rọ ṣe é.

Á kọ́kọ́ ya àwòrán, á wá ṣe ère rẹ̀, lẹ́yìn èyí lá wá yọ́ òjé lé e. Kò pẹ́ rárá tó fi dọ̀gá nínú títo ẹ̀yà ara ère, jíjó wọn pọ̀, fífá ara wọn, àti mímú kí wọ́n máa dán gbinrin. Nígbà tó yá, kò lo ẹfun mọ́ àwọn àpòpọ̀ kan tó le bí eyín ló wá ń lò. Ìyẹn túbọ̀ wá mú kí iṣẹ́ rẹ̀ gbayì gan-an.

Lẹ́yìn tó bá ti fi mẹ́táàlì ṣe nǹkan kan tán, iṣẹ́ tèmi ni láti parí ìyókù. Nípa ṣíṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí, a mọ bí aṣọ àwọn ológun ayé àtijọ́ ṣe ń rí, títí kan bí bọ́tìnnì wọn ṣe rí, okùn tí wọ́n ń gbà, báàjì tó ń fi ipò wọn hàn àti irú àwọ̀ tí wọ́n ní.

Nípa lílo nǹkan tó máa ń sọ àwòrán di ńlá, màá fi ọ̀dà tí wọ́n dìídì ṣe fún mẹ́táàlì kùn wọ́n. Èyí ló túbọ̀ máa wá gbé ògo àwọn ère wa kéékèèké yọ. Látinú yàrá kékeré táa ń gbé ní Filadẹ́fíà, Pennsylvania, la ti ń ṣe ère àwọn Àmẹ́ríńdíà, àwọn sójà tó ja Ogun Abẹ́lé, àwọn Ọmọ Ogun Abẹ́ Omi ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àwọn ẹṣin àtàwọn ẹlẹ́ṣin bíi Napoleon, Mamluks ti Íjíbítì, Zouaves ti Algeria, àtàwọn mìíràn.

Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, Ẹ̀ka Ológun kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ké sí Bill láti wá ṣe àwòrán àwọn agẹṣin-jagun àkọ́kọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ rán jáde ṣáájú 1939 ní Peking (tó ti di Beijing báyìí) ní ilẹ̀ China. A ò sùn a ò wo nítorí iṣẹ́ yìí, nígbà tó sì di 1954, a fà á lé Àjọ Smithsonian ti Washington, D.C. lọ́wọ́. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Ààrẹ Lyndon Johnson béèrè bóyá wọ́n lè ko o lọ sí Ilé Ìjọba Àpapọ̀. Tọkàntara la fi gbà.

A ò ta àwọn àwòrán wa rí, àmọ́ ńṣe ni Bill fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún wọn tọrẹ. Níre-níre ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ wa nínú àwọn ìwé tó ní àwòrán àwọn sójà nínú. Wọ́n pàtẹ iṣẹ́ wa níbi Ìpàtẹ Àgbáyé lọ́dún 1965 ní Flushing Meadow, ní Queens, ìlú New York. Wọ́n tún béèrè fún àwọn àwòrán wa láti kó wọn sáwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí. Bruce Catton, tó jẹ́ òpìtàn nípa Ogun Abẹ́lé, lo bí mélòó kan lára àwọn ère wa àti àwòrán wa kéékèèké láti fi ṣe àwọn ìwé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́.

Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìgbésí Ayé Túbọ̀ Ń Rú Yọ

Nígbà tí mo fi máa pé ẹni ogójì ọdún, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà fún mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí i ṣe kàyéfì nípa Ọlọ́run. Lọ́jọ́ Kérésìmesì kan, àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì márùn ún jóná ráúráú sínú ilé nígbà táwọn òbí wọ́n wà ní ṣọ́ọ̀ṣì. Mo wá rò ó pé, ‘Báwo ni Ọlọ́run ṣe lè gbà irú nǹkan bẹ́ẹ̀ láyè kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ìbí rẹ̀?’ Mo rí ìwé kan tó ṣàlàyé lẹ́sẹẹsẹ nípa ìwà ìkà bíburú jáì tó wáyé nígbà tí wọ́n pa àwọn Júù nípakúpa. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí àtàwọn míì tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé wá mú mi béèrè pé, ‘Ibo ni Ọlọ́run wà? Kò ṣe ohun tó yẹ kó ṣe rárá!’

Látinú àpẹẹrẹ bàbá mi tí mo rí nígbà tí mo kéré, mo ronú pé ó yẹ kí ìdáhùn wà nínú Bíbélì. Mo bá lọ síbi táwọn àlùfáà Kátólíìkì ń gbé nítòsí ilé wa ní Filadẹ́fíà mo sì sọ fún àlùfáà kan pé màá wá pàdé ẹ̀ ká lè jọ jíròrò Bíbélì. Mó dúró dúró, àmọ́ mi ò rí i kó yọjú. Fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rin gbáko ni mo fi ń lọ síbẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ṣùgbọ́n èmi àti àlùfáà yìí kò jọ sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan rí.

Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, pẹ̀lú ìbànújẹ́ ńlá, mó gbójú mi sókè ọ̀run, mo sì gbàdúrà pé: “Mi ò mọ̀ ẹ́. Mi ò mọ èwo gan-an ni ìsìn tóo fara mọ́, àmọ́ mo mọ̀ pé o wà. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n mọ̀ ẹ́!” Kò pẹ́ rárá sígbà yẹn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sẹ́nu ọ̀nà mi.

Mo ti máa ń rí àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tẹ́lẹ̀, tí wọ́n máa páàkì ọkọ̀ wọn, tí wọ́n á jáde nínú ẹ̀ tí wọ́n á sì máa lọ sẹ́nu ọ̀nà ilé kiri. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ nǹkan kan nípa wọn tàbí ìdí tí wọ́n fi máa ń wá, ohun tí wọ́n ńṣe máa ń jọ mí lójú.

Lọ́jọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí wá yẹn ní 1961, inú mi ò dùn rárá nítorí pé mi ò tíì rí Ọlọ́run òtítọ́ tí mò ń wá. Obìnrin kan báyìí tí kò dàgbà púpọ̀, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Marge Brion gòkè wá bá mi níbi tí mo ti ń fọ ilẹ̀kùn iwájú ilé mi, ó sì kí mi. Mi ò kọ́kọ́ bojú wẹ̀yìn láti wo ẹni tó ń sọ̀rọ̀. Àmọ́ bó ṣe sọ̀rọ̀ dórí pé ayé máa di párádísè ẹlẹ́wà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fọkàn sí ọ̀rọ̀ tó ń sọ lọ́kọ̀ọ̀kan. Níkẹyìn, ó béèrè pé, “Ǹjẹ́ ò ń gbọ́ mi?”

Gbogbo ohun tó sọ pátá ni mo tún sọ fún un, títí kan ẹsẹ Bíbélì tó ṣàyọlò rẹ̀ látinú Aísáyà 55:11. Ni mo bá yíjú padà, mo gbá a lápá mú mo sì sọ pé, “Ó yá, wọlé wá!” Ó fún mi ní Bíbélì tí màá kọ́kọ́ ní àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń jẹ́, Lati Paradise T’a Snu Si Paradise T’a Jere-Pada. Ó tún máa ń wá bá mi jíròrò Bíbélì déédéé—irú ìkẹ́kọ̀ọ́ tí mò ń retí gan-an pé kí Ìjọ Kátólíìkì fún mi.

Mi ò fi ìkẹ́kọ̀ọ́ mi jáfara torí pé ẹ̀ẹ̀mejì ni mo ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sẹ̀. Kò pẹ́ rárá tó fi hàn kedere pé mo ti rí òtítọ́. Mímọ orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, jẹ́ ohun tó ru ìmọ̀lára mi sókè gidigidi. (Sáàmù 83:18) Rò ó wò ná, Ọlọ́run tí mo ti ń yán hànhàn láti mọ̀ látìgbà kékeré mi nìyí! Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, kì í ṣe apá kan ọlọ́run ẹlẹ́ni mẹ́ta tó jẹ́ àdììtú. (Jòhánù 14:28) Kò pẹ́ kò jìnnà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ń wù mí gan-an láti di olùpòkìkí ìhìn Bíbélì alákòókò kíkún.

Ṣíṣe Àwọn Yíyàn Pàtàkì

Ìṣòro mi tó tóbi jù lọ ti wá dé báyìí o. Ṣé màá wá fòpin sí iṣẹ́ ọnà tí William àti Dorothy Horle ti jọ ń pawọ́ pọ̀ ṣe ni? Báwo ni mo sì ṣe lè sọ pé mo ń sin Ọlọ́run àlááfíà àti Ọmọ rẹ̀, Aládé Àlàáfíà, nígbà tí mo bá ń fi iṣẹ́ ọnà gbé ogun lárugẹ? (Aísáyà 9:6) Ǹjẹ́ Jèhófà kò ṣèlérí pé òun máa mú kí “ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé”? (Sáàmù 46:9) Kí wá ló dé tó jẹ́ pé nǹkan tí Ọlọ́run máa kásẹ̀ rẹ̀ nílẹ̀ ni màá máa ṣe nìṣó? Àbí ṣé Aísáyà náà kò sàsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò fi “idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀” tí wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́? (Aísáyà 2:4) Mó ronú púpọ̀ nípa rẹ̀ mo sì gbàdúrà kíkankíkan. Ìpinnu mi ni pé, “Mi ò ní kùn wọ́n mọ́!” Ní April 25, 1964, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi nínú omi.

Bill ti máa ń sọ tẹ́lẹ̀ pé ó ń dun òun gan-an pé, ọjọ́ kan á jọ́kan tíkú á yà wá. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo máa ń sọ fún un pé: “Wò ó Bill, a lè gbé títí láé nínú ayé tuntun Ọlọ́run!” (Aísáyà 25:8; Ìṣípayá 21:4, 5) Àfi bíi pé orí mi ti dàrú ló jọ lójú ẹ̀. Nígbà tí mo wá ṣàlàyé fún un pé ẹ̀rí ọkàn mi kò lè gbà mí láyè mọ́ láti máa kun àwòrán ológun, orí ẹ̀ kanrin ó sì halẹ̀ pé òun máa fi mí sílẹ̀. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó yá.

Bill ń dá ṣe àwọn ère ológun kéékèèké yẹn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́ ibi tó kó lọ kò jìnnà, ìgbà gbogbo ló sì máa ń ṣètìlẹ́yìn fún èmi àti ọmọkùnrin wa, Craig, táa bí ní 1942. Ní 1988, Bill padà wá, a sì jọ wà pa pọ̀ fún ọdún mẹ́wàá kó to di pé ó kú.

Ní báyìí ná, láti 1966, ọwọ́ mi ti tẹ góńgó mi ti dídi aṣáájú ọ̀nà. Látìgbà náà wá, mi ò bojú wẹ̀yìn. Mo ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n mi obìnrin. Ó tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, Ẹlẹ́rìí tó ń ṣe déédéé sì ni títí dòní. Bàbá mi tẹ́tí sí ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì, àárín ọ̀sẹ̀ méjì péré ló sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó ṣe batisí lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ́rin, ó sì ń báa lọ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí tó fi kú ní ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin. Màmá mi náà tẹ́wọ́ gba Jèhófà ní Ọlọ́run rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ṣe ìyàsímímọ́ rẹ̀ tó fi kú. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún nígbà náà.

Bọ́dún ti ń gorí ọdún, Jèhófà, Ọlọ́run àlàáfíà ti bù kún mi rẹpẹtẹ. Ní báyìí, tí mo ti pé ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin, mo ṣì jẹ́ aṣáájú ọ̀nà síbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò rọrùn fún mi láti rìn káàkiri. Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ̀rọ̀ rí lára mi, ẹni tó kọ̀wé pé: “Mo kún fún ìmoore sí Kristi Jésù Olúwa wa, ẹni tí ó fi agbára fún mi, nítorí tí ó kà mí sí olùṣòtítọ́ nípa yíyan iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lé mi lọ́wọ́.” (1 Tímótì 1:12) Iṣẹ́ ìsìn ológo gbáà ló jẹ́! Ọ̀pọ̀ àwọn tí mo bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ti yááfì àwọn ohun kan láti sin Ọlọ́run wa aláàánú.

Ó dùn mí gan-an pé kì í ṣe gbogbo mẹ́ńbà ìdílé mi ló tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì. Bóyá ọ̀pọ̀ á ṣì ṣe bẹ́ẹ̀ bí àkókò ti ń lọ. Àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ti já sí òtítọ́ fún mi pé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yóò “gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún nísinsìnyí ní sáà àkókò yìí, àwọn ilé àti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá àti àwọn ọmọ.” (Máàkù 10:30) Àní, Jèhófà ti sọ mí di ọlọ́rọ̀. Ọlá àti ayọ̀ ló mà jẹ́ fún mi o, láti fi Ọlọ́run àti àlàáfíà rọ́pò òkìkí àti ogun!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Èmi àti Ọ̀gágun L. C. Shepherd, Kékeré ní 1954

[Credit Line]

Fọ́tò Ẹ̀ka Aláàbò (Marine Corps)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

(Bí wọ́n ṣe rí gangan)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin, mo ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ohun tó lé lọ́gbọ̀n ọdún