Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Burú Kéèyàn Máa Ṣọ̀fọ̀?

Ǹjẹ́ Ó Burú Kéèyàn Máa Ṣọ̀fọ̀?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Ó Burú Kéèyàn Máa Ṣọ̀fọ̀?

“JÙ BẸ́Ẹ̀ LỌ, Ẹ̀YIN ARÁ, A KÒ FẸ́ KÍ Ẹ ṢE ALÁÌMỌ̀ NÍPA ÀWỌN TÍ Ń SÙN NÍNÚ IKÚ; KÍ Ẹ MÁ BÀA KÁRÍSỌ GẸ́GẸ́ BÍ ÀWỌN YÒÓKÙ TÍ KÒ NÍ ÌRÈTÍ TI Ń ṢE PẸ̀LÚ.”—1 TẸSALÓNÍKÀ 4:13.

BÍBÉLÌ pèsè ìrètí kan fún àwọn tó ti kú. Jíjí tí Jésù jí àwọn òkú dìde àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ń tọ́ka sí àkókò kan tí àwọn òkú á padà wá sí ìyè. (Mátíù 22:23-33; Máàkù 5:35, 36, 41, 42; Lúùkù 7:12-16) Báwo ló ṣe yẹ kí ìrètí yìí nípa lórí wa? Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù táa fà yọ lókè fi hàn pé ìrètí yìí lè tù wá nínú nígbà téèyàn wa kan bá kú.

Téèyàn rẹ kan bá ti kú rí, ó dájú pé wàá ti mọ bí ọ̀ràn ìbànújẹ́ yìí ṣe máa ń rí lára. Theresa, tí ọkọ rẹ̀ tó ti ń bá gbé fún ọdún méjìlélógójì kú ní gbàrà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ ọkàn fún un tán, sọ pé: “Jìnnìjìnnì kò tíì bò mí tó bẹ́ẹ̀ rí! Ńṣe làyà mi kọ́kọ́ pami. Ẹ̀yìn náà ni ìbànújẹ́ tó gogò wá dorí mi kodò tó sì ń bá a lọ bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́. Ńṣe ni mo ń sunkún ṣáá.” Ṣé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wá túmọ̀ sí pé èèyàn kò nígbàgbọ́ nínú ìlérí Jèhófà láti jí àwọn òkú dìde ni? Ṣé ohun tọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù túmọ̀ sí ni pé ó burú kéèyàn máa ṣọ̀fọ̀?

Àpẹẹrẹ Àwọn Tó Ṣọ̀fọ̀ Nínú Bíbélì

A lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yẹn nípa ṣíṣàyẹ̀wò àpẹẹrẹ àwọn tó ṣọ̀fọ̀ nínú Bíbélì. Ní ọ̀pọ̀ ibi tó ti ṣẹlẹ̀, ó ní sáà àkókò kan tí wọ́n sábàá máa ń fi ṣọ̀fọ̀ ikú mẹ́ńbà kan nínú ìdílé. (Jẹ́nẹ́sísì 27:41; 50:7-10; Sáàmù 35:14) Ẹ̀dùn ọkàn tó sì máa ń bá ọ̀fọ̀ náà rìn máa ń lágbára gan an ni.

Ṣàyẹ̀wò bí àwọn ọkùnrin ìgbàgbọ́ kan ṣe ṣọ̀fọ̀ ikú àwọn èèyàn wọn kan. Fún àpẹẹrẹ, Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ tó dúró gbọn-in pé Ọlọ́run lè jí àwọn òkú dìde. (Hébérù 11:19) Àmọ́ pẹ̀lú ìdánilójú tó ní yìí, nígbà tí Sárà, ìyàwó rẹ̀ kú, ó ‘wọlé láti pohùn réré ẹkún àti láti sunkún lórí rẹ̀.’ (Jẹ́nẹ́sísì 23:1, 2) Nígbà táwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù purọ́ fún un pé Jósẹ́fù, ọmọkùnrin tó jẹ́ ààyò rẹ̀ ti kú, Jékọ́bù “gbọn aṣọ àlàbora rẹ̀ ya, [ó] . . . sì ń bá a lọ láti sunkún nítorí rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 37:34, 35) Àní sẹ́, ìrònú ikú ọmọkùnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n yìí ṣì kó ìdààmú bá Jékọ́bù gan-an fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà! (Jẹ́nẹ́sísì 42:36-38) Dáfídì Ọba pẹ̀lú bara jẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà táwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjì, Ámínónì àti Ábúsálómù kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjèèjì ti kó ìrora ọkàn bá Dáfídì àti ìdílé rẹ̀, síbẹ̀, ọmọ rẹ̀ ṣì ni wọ́n, ikú wọn sì kó ìbànújẹ́ púpọ̀ bá a.—2 Sámúẹ́lì 13:28-39; 18:33.

Nígbà míì, gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lápapọ̀ ló máa ń ṣọ̀fọ̀, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣe nígbà tí Mósè kú. Diutarónómì 34:8 sọ fún wa pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sunkún fún ọgbọ̀n ọjọ́ nítorí ikú rẹ̀.

Ní paríparí, a tún ní àpẹẹrẹ ti Jésù Kristi. Lásárù, ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kú. Nígbà tí Jésù rí bí àwọn arábìnrin Lásárù, Màtá àti Màríà àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn ṣe ń sunkún, “ó kérora nínú ẹ̀mí, ó sì dààmú.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé láìpẹ́ sígbà yẹn òun á mú ọ̀rẹ́ òun padà sí ìyè, síbẹ̀ ó “bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.” Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n, Màtá àti Màríà. Nítorí náà ara rẹ̀ kò gbà á mọ́ nígbà tó rí ìbànújẹ́ tó bá wọn nítorí ikú arákùnrin wọn.—Jòhánù 11:33-36.

Ábúráhámù, Jékọ́bù, Dáfídì, àti Jésù, gbogbo wọn pátá ló ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà, síbẹ̀ wọ́n bọkàn jẹ́. Ṣé pé bí wọ́n ṣe ṣọ̀fọ̀ yẹn túmọ̀ sí pé wọ́n ní àìlera tẹ̀mí? Ṣé pé àìní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde ló mú wọn bọkàn jẹ́ bẹ́ẹ̀? Kò sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá! Ṣíṣọ̀fọ̀ jẹ́ ọ̀nà tí a máa ń gbà fi ìbànújẹ́ hàn bí èèyàn wa kan bá kú, kò sì sóhun tó burú nínú rẹ̀ rárá.

Ìdí Táa Fi Ń Ṣọ̀fọ̀

Kì í ṣe ète Ọlọ́run rárá pé kí ìran ènìyàn máa kú. Ète Jèhófà ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ ọ́ fún Ádámù àti Éfà ni pé kí ilẹ̀ ayé di Párádísè ẹlẹ́wà, tí ìdílé onífẹ̀ẹ́ àti aláyọ̀ kún inú rẹ̀. Àyàfi tí tọkọtaya àkọ́kọ́ bá ṣàìgbọràn sí Jèhófà ni ikú fi lè ṣẹlẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:17) Ó mà ṣe o, Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, “ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 5:12; 6:23) Nítorí náà, ikú jẹ́ ọ̀tá rírorò tí kì bá tí sí rárá.—1 Kọ́ríńtì 15:26.

Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé, nígbà tí ikú tí Ọlọ́run kò dá mọ́ wa yìí bá pa ẹnì kan tó sún mọ́ wa, ó máa ń fa ìrora ńláǹlà bá àwọn tó kàn. Òfò ńlá gbáà ló máa ń jẹ́ nínú ìgbésí ayé wọn. Theresa, opó táa sọ̀rọ̀ bá lókè sọ nípa ọkọ rẹ̀ pé: “Mo mọ̀ dájú pé màá rí i nígbà àjíǹde, àmọ́ bí kò ṣe sí mọ́ yìí kò bá mi lára mu rárá. Ìyẹn gan an lohun tó ń dùn mí ńbẹ̀.” Ikú òbí lè rán wa létí pé àwa náà lè kú lọ́jọ́ kan. Ikú ẹnì kan tó bá jẹ́ ọ̀dọ́ ló máa ń dùn wá jù nítorí ìbànújẹ́ náà pé ó kú ní rèwerèwe.—Aísáyà 38:10.

Bẹ́ẹ̀ ni o, a kò dá ikú mọ́ wa. Òun ni ìrora tó ń fà kò fi ṣàjèjì, Jèhófà kò sì wo ṣíṣọ̀fọ̀ bíi àìní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú àpẹẹrẹ Ábúráhámù, Jékọ́bù, Dáfídì, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, àti Jésù, fífi ìbànújẹ́ wa hàn kì í ṣe ẹ̀rí pé ìgbàgbọ́ wa kò tó. a

Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé àwa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni máa ń ṣọ̀fọ̀ tí ikú bá ṣẹlẹ̀, a kì í kárí sọ “bí àwọn yòókù tí kò ní ìrètí ti ń ṣe.” (1 Tẹsalóníkà 4:13) A kì í banú jẹ́ kọjá ààlà nítorí kò sóhun tó rú wa lójú nípa ipò táwọn òkú wà. A mọ̀ pé wọn ò sí nínú ìrora tàbí ìbànújẹ́ ṣùgbọ́n wọ́n wà nínú ipò táa lè fi wé oorun àsùnwọra, oorun àlááfíà. (Oníwàásù 9:5; Máàkù 5:39; Jòhánù 11:11-14) Ọkàn wa tún balẹ̀ dẹ́dẹ́ pé Jésù, tí í ṣe “àjíǹde àti ìyè” yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ láti mú “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí” padà sí ìyè.—Jòhánù 5:28, 29; 11:24, 25.

Nítorí náà, ká ní o ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, jẹ́ kí mímọ̀ pé Jèhófà lóye ohun tó ń bá ọ fínra fún ọ ní ìtùnú. Ǹjẹ́ kí ìmọ̀ yìí àti ìrètí rẹ nínú àjíǹde dín ìbànújẹ́ rẹ kù kó sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fara da àdánù tó dé bá ọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìrànwọ́ láti lè fara da ìbànújẹ́, wo ojú ìwé 14-19 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.