Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọ̀dọ́langba Nìkan Kọ́ Ló Wà Fún

Àwọn Ọ̀dọ́langba Nìkan Kọ́ Ló Wà Fún

Àwọn Ọ̀dọ́langba Nìkan Kọ́ Ló Wà Fún

Jolanta, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sọ nínú lẹ́tà kan tó kọ sí ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Poland pé, ìbànújẹ́ ti dorí òun kodò. Aláàbọ̀ ara ni kò sì lè rìn, ìyá rẹ̀ àti ìyá ìyá rẹ̀ tún kú láàárín oṣù mẹ́fà síra wọn. Ìgbà yẹn ló bẹ̀rẹ̀ sí ka ìtẹ̀jáde náà Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. Ó kọ̀wé pé:

“Àwọn ọ̀dọ́langba nìkan ni mo rò pé ìwé yìí wúlò fún kì í ṣe èmi. Àmọ́ èrò mi yìí kò tọ̀nà páàpáà! Bí mo ṣe kẹ́kọ̀ọ́ orí kejìlá sí ìkẹrìndínlógún ìwé náà, mo rí ìdáhùn tó ṣe kedere sáwọn ìbéèrè mi bíi: ‘Kí ló dé tí ìbànújẹ́ fi máa ń dorí mi kodò táá sì dà bíi pé mo dá wà?’ ‘Èé ṣe tí mi ò fi fẹ́ràn ara mi?’ àti ‘Kí ló dé ti mo ṣì fi ń ṣọ̀fọ̀ gidigidi lẹ́yìn táwọn èèyàn mi kú?’”

Ó tún sọ pé: “Àwọn kókó méjì tó wà lójú ìwé 130 wù mí gan-an, èyí tó sọ pé: ‘Mímọ̀ pe ẹ̀dùn ọkàn rẹ jẹ ohun kan ti o bojumu jẹ́ igbesẹ nla kan ní kikawọ rẹ̀. Ṣugbọn o wulẹ ń mú ẹ̀dùn ọkàn pọ̀ siwaju ni lati maa baa lọ ní sísẹ́ ohun ti o jẹ otitọ gidi.’ Àwọn ọ̀rọ̀ tí mo kà yìí fún ìgbàgbọ́ tí mo ní lókun pé mo máa rí àwọn tó ti sùn nínú ikú, èyí sì mú kí ìgbésí ayé mi túbọ̀ nítumọ̀ sí i.”

Bóo bá fẹ́ borí ìbànújẹ́ tó dorí rẹ kodò kí ìgbésí ayé rẹ sì nítumọ̀, a lérò pé ìwọ náà á jàǹfààní nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. O lè rí ẹ̀dà kan ìwé yìí gbà tí o bá kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tí a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.