Àwọn Ohun Tó Ń fa Ìkórìíra
Àwọn Ohun Tó Ń fa Ìkórìíra
ÌKÓRÌÍRA ti bẹ̀rẹ̀ láti kùtùkùtù ìtàn ìran ènìyàn. Àkọsílẹ̀ Bíbélì ní Jẹ́nẹ́sísì 4:8 sọ pé: “Ó wá ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí wọ́n wà nínú pápá, Kéènì bẹ̀rẹ̀ sí fipá kọlu Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.” Jòhánù tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì béèrè pé: “Nítorí kí ni ó sì ṣe fikú pa á? Nítorí pé àwọn iṣẹ́ tirẹ̀ burú, ṣùgbọ́n àwọn ti arákùnrin rẹ̀ jẹ́ òdodo.” (1 Jòhánù 3:12) Ọ̀kan lára àwọn ohun tó sábàá máa ń fa ìkórìíra ló fa ikú Ébẹ́lì, ìyẹn ni owú. Ìwé Òwe 6:34, sọ pé: “Owú ni ìhónú abarapá ọkùnrin.” Lónìí, owú ti mú káwọn èèyàn máa jin ara wọn lẹ́sẹ̀ lórí ipò tẹ́nì kan wà láwùjọ, nítorí ọrọ̀, àtàwọn ohun mèremère míì.
Àìmọ̀kan àti Ìbẹ̀rù
Àmọ́ ńṣe ni owú wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan péré lára àwọn nǹkan tó ń fa ìkórìíra. Ìwà àìmọ̀kan àti ìbẹ̀rù ló tún máa ń súnná sí ìkórìíra lọ́pọ̀ ìgbà. Ọmọdékùnrin kan tó wà nínú ẹgbẹ́ oníjàgídíjàgan tí kì í fẹ́ ráwọn ẹ̀yà míì sójú sọ pé: “Kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra àwọn èèyàn, ẹ̀rù ló kọ́kọ́ máa ń bà mí.” Àìmọ̀kan ló sì máa ń fa irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia, sọ pé ohun tó bá ti wà lọ́kàn àwọn ẹlẹ́tanú ni wọ́n máa ń ṣe, “kò sóhun tó kàn wọ́n kan ẹ̀rí tó fara hàn kedere. . . . Gbogbo òkodoro òtítọ́ tó bá ti lè tako èrò wọn ni wọ́n á dorí rẹ̀ kodò,
wọ́n á ṣe é báṣubàṣu, wọ́n tiẹ̀ lè gbà á sódì tàbí kí wọ́n máà kà á sí pàápàá.”Ibo làwọn èrò báyìí tiẹ̀ ti ń wá gan-an? Ìsọfúnni kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sọ pé: “Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ló ń fa àìmọye rògbòdìyàn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, àmọ́ bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà ló tún máa ń fa ọ̀pọ̀ ìkórìíra táa ní.”
Fún àpẹẹrẹ, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, òwò ẹrú ló fa ẹ̀tanú láàárín àwọn aláwọ̀ funfun àtàwọn Adúláwọ̀—ẹ̀tanú ọ̀hún kò sì dẹwọ́ títí dòní olónìí. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí máa ń fi èròkérò nípa ẹ̀yà mìíràn sọ́kàn àwọn ọmọ wọn. Èyí ló mú kí aláwọ̀ funfun kan tó fúnra rẹ̀ jẹ́wọ́ pé òun kórìíra ẹ̀yà mìíràn sọ pé “òun kò tiẹ̀ tíì rí àwọn aláwọ̀ dúdú rí” tóun ti kórìíra wọn burúkú burúkú.
Àwọn kan tún wà tí wọ́n gbà gbọ́ pé kò sóhun rere eléépìnnì lára àwọn èèyàn tó bá ti yàtọ̀ sí wọn. Èyí lè jẹ́ nítorí pé wọ́n ti wàákò lẹ́ẹ̀kan rí pẹ̀lú ẹnì kan tí ó wá láti ẹ̀yà kan tó yàtọ̀ sí tiwọn. Wọ́n á wá torí ìyẹn parí èrò sí pé oníwàkiwà ni gbogbo ẹni tó bá ti wá látinú ẹ̀yà náà.
Nǹkan burúkú gbáà ni káwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máà fẹ́ gba èrò àwọn ẹlòmíràn, bó bá wá lọ di ti gbogbo èèyàn lórílẹ̀-èdè kan tàbí ẹ̀yà kan, ó lè di pé kí òkú máa sùn lọ bẹẹrẹbẹ. Èrò pé orílẹ̀-èdè èèyàn, àwọ̀, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, tàbí èdè ń mú kéèyàn sàn ju ẹlòmíràn lọ kì í jẹ́ kéèyàn lè gba èrò ẹlòmíràn, èèyàn kò sì ní fẹ́ rí àjèjì sójú pàápàá. Àìfẹ́ gba tẹlòmíràn yìí ti yọrí sí ìwà ipá ní ọ̀rúndún ogún.
Àmọ́ o, kì í ṣe ọ̀rọ̀ àwọ̀ tàbí orílẹ̀-èdè nìkan ló ń fa ìkórìíra àti àìfẹ́ gba èrò ẹlòmíràn. Clark McCauley, tó jẹ́ olùwádìí ní Yunifásítì Pennsylvania kọ ọ́ pé “pípín téèyàn ṣàdéédéé pín sí àwùjọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lè mú káwọn kan nífẹ̀ẹ́ àwùjọ wọn ju èkejì lọ.” Ohun tí olùkọ́ kan ṣe nìyí
nígbà tó ń ṣe àyẹ̀wò pàtàkì kan. Ó pín àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ sí àwùjọ méjì, ọ̀kan jẹ́ tàwọn ọmọ tí wọ́n ní ẹyinjú aláwọ̀ búlúù, èkejì sì jẹ́ tàwọn tí wọ́n ní ẹyinjú aláwọ̀ ilẹ̀. Kó tó pajú pẹ́ẹ́, gbúngbùngbún ti bẹ̀rẹ̀ láàárín àwùjọ méjèèjì. Kódà ohun kékeré bí kéèyàn fẹ́ràn ẹnì kan ju òmíràn lọ láàárín ẹgbẹ́ eléré ìdárayá kan náà lè tanná ran ẹ̀tanú.Èé Ṣe Tí Ìwà Ipá Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
Kí ló fà á tó fi jẹ́ pé ìwà jàgídíjàgan lọ̀nà táwọn èèyàn ń lò láti fi ẹ̀tanú wọn hàn? Àwọn olùwádìí ti ṣèwádìí títí lórí àwọn ọ̀ràn yìí àmọ́ kìkì àbá lórí ohun tó lè fà á ni wọ́n kàn ń gbé kalẹ̀. Clark McCauley ṣàkọsílẹ̀ jàn-ànràn jan-anran lórí ìwádìí tó ṣe nípa ìwà ipá àti ìwà jàgídíjàgan táwọn èèyàn ń hù. Ó tọ́ka sí ìwádìí kan tó fi hàn pé “ogun jíjà àti ìjagunmólú ló ń fa ìwà ọ̀daràn tó burú jáì.” Àwọn olùwádìí náà rí i pé “àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ja Ogun Àgbáyé Kìíní àti Èkejì, àgàgà àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ́gun túbọ̀ ń pààyàn sí i lẹ́yìn tí ogun náà ti parí.” Àkókò ogun la wà yìí gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ. (Mátíù 24:6) Ǹjẹ́ àwọn ogun wọ̀nyí kò ti pa kún onírúurú ìwà ipá tó ń pọ̀ sí i yìí?
Àwọn olùwádìí mìíràn fẹ́ fi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè ṣàlàyé ohun tó fa ìwà jàgídíjàgan téèyàn ń hù. Ìwádìí kan tiẹ̀ gbìyànjú láti sọ pé “àìtó bó ṣe yẹ àwọn ohun tín-tìn-tín kan nínú ọpọlọ” ló máa ń fa ìwà jàgídíjàgan. Àbá mìíràn tó tún gbayì ni pé ìwà jàgídíjàgan jẹ́ àbùdá ènìyàn. Ògbóǹkangí kan nínú ìmọ̀ ìṣèlú tiẹ̀ sọ pé: “Èèyàn lè jogún [ìkórìíra].”
Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ pé a bí ìwà búburú àti àbùkù mọ́ ẹ̀dá ènìyàn aláìpé. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5; Diutarónómì 32:5) Lóòótọ́, ẹ̀dá èèyàn láwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn bá wí. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló kàn máa ń kórìíra ẹlòmíràn bẹ́ẹ̀. Kíkọ́ ni wọ́n ń kọ́ ọ. Èyí ló mú kí afìṣemọ̀rònú táa mọ̀ bí ẹni mowó náà Gordon W. Allport, kíyè sí i pé àwọn ìkókó “kì í hùwà tó lè fi hàn pé a bí ìwà màdàrú mọ́ wọn. . . . Àwọn ìkókó kì í ro ibi ro ẹnì kan, wọn kì í bá ẹnikẹ́ni ṣọ̀tá, gbogbo èèyàn ni wọ́n ń yọ̀ mọ́.” Irú àkíyèsí yìí kín in lẹ́yìn pé ìkórìíra jẹ́ ìwà téèyàn ń kọ́! Agbára téèyàn ní láti kọ́ ìkórìíra yìí làwọn tó ń fi kọ́ni ń lò lójú méjèèjì.
Sísọ Èrò Inú Dìdàkudà
Àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ ìkórìíra ló ń mú ipò iwájú, irú bí ẹgbẹ́ àwọn afáríkodoro alátakò ìjọba Násì àti ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ Ku Klux Klan. Àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí sábàá máa ń tan àwọn èwe tí ìdílé wọ́n kò tòrò láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ wọn. Àwọn èwe tó dà bí ẹni pé wọn kò láàbò tàbí pé wọn kò níláárí bí àwọn ẹgbẹ́ wọn lè rò pé àwọn ẹgbẹ́ ìkórìíra á ṣe alátìlẹyìn fún àwọn.
Àwọn kan ti tún lo Íńtánẹ́ẹ̀tì láti gbé ìkórìíra lárugẹ. Gẹ́gẹ́ bí ìṣirò kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí ṣe fi hàn, ó ṣeé ṣe kí àwọn ibi tí wọ́n ń kó ìsọfúnni tó ń gbé ìkórìíra lárugẹ sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ẹgbẹ̀rún. Ìwé ìròyìn The Economist sọ bí ọ̀gbẹ́ni kan tó ni ọ̀kan lára àwọn ibi ìkósọfúnnisí yẹn ṣe ń fọ́nnu pé: “Íńtánẹ́ẹ̀tì ti fún wa láǹfààní láti jẹ́ káwọn èèyàn nílé lóko àti lẹ́yìn odi mọ̀ nípa èrò wa.” Ibi tó ń kó ìsọfúnni tirẹ̀ sí ní ibì kan tó wà fún “Kìkì Àwọn Èwe.”
Nígbà táwọn ọ̀dọ́langba bá ń wá orin kiri lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wọ́n lè ṣàdédé kan àwọn ibi tí orin tó ń gbé ìkórìíra lárugẹ wà. Irú orin bẹ́ẹ̀ sábàá máa ń dún kíkankíkan á sì jẹ́ oníwà ipá,
àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ gan-an máa ń gbé kíkórìíra ẹ̀yà mìíràn lárugẹ. Àwọn ibi tí wọ́n ń kó ìsọfúnni sí wọ̀nyí tún máa ń fún èèyàn láǹfààní láti dé àwọn ibùdó ìròyìn, ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí kọ̀ǹpútà, tàbí àwọn ibi ìkósọfúnnisí mìíràn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ń polówó ìkórìíra.Àwọn ibùdó ìkósọfúnnisí kan wà tí wọ́n ní àwọn ibì kan láyè ọ̀tọ̀ fún eré ìdárayá àtàwọn ìgbòkègbodò mìíràn fáwọn ọ̀dọ́. Ibi ìkósọfúnnisí kan tó jẹ́ ti ẹgbẹ́ àwọn olólùfẹ́ ìjọba Násì ti gbìyànjú láti fi Bíbélì ti ìwà ẹ̀yà-tèmi-lọ̀gá àti kíkórìíra àwùjọ àwọn Júù lẹ́yìn. Ẹgbẹ́ yìí tiẹ̀ tún ti ṣí ibùdó kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ní àwọn àdììtú tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ń mú kéèyàn kórìíra ẹ̀yà mìíràn nínú. Kí ni ète rẹ̀? “Láti jẹ́ káwọn aláwọ̀ funfun tó jẹ́ ọ̀dọ́ mọ ohun tí ẹgbẹ́ wa ń jà fún.”
Àmọ́ kì í kúkú ṣe gbogbo àwọn tó ń gbé ogun lárugẹ ló jẹ́ ayírí. Onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá tó kọ̀wé nípa rògbòdìyàn tó wáyé láìpẹ́ yìí ní àgbègbè Balkan sọ̀rọ̀ nípa àwọn òǹkọ̀wé jàǹkàn-jàǹkàn kan àtàwọn kan tẹ́nu wọn tólẹ̀ láwùjọ pé: “Kàyéfì ńlá gbáà ló jẹ́ fún mi láti rí bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé lọ́nà tó ń mú káwọn èèyàn máa hùwàkiwà, kí wọ́n máa kórìíra àwọn èèyàn gan-an, wọn ò sì wá ní lè ṣe ìpinnu tó dáa torí ohun tí wọ́n gbọ́ ni pé wọn kò gbọ́dọ̀ sọ pé ìwà kan kò dára kìkì nítorí pé kò bá ìwà rere mu . . . , bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ń dorí òdodo ọ̀rọ̀ kodò.”
Níbi tọ́ràn dé yìí, a ò gbọ́dọ̀ gbójú fo ipa táwọn àwùjọ àlùfáà ń kó. Òǹkọ̀wé James A. Haught ṣe àkíyèsí kan tó ń múni gbọ̀n rìrì nínú ìwé rẹ̀ Holy Hatred: Religious Conflicts of the ‘90’s, ó sọ pé: “Ohun tó tojú súni gan-an ní àwọn ọdún 1990 sí 1999 ni pé ìsìn—tó yẹ kó jẹ́ orísun inúure àti àjọṣe tó dán mọ́rán láàárín ẹ̀dá—ló wá di baba ìsàlẹ̀ fáwọn ohun tó ń fa ìkórìíra, ogun, àti ìpániláyà.”
A ti wá rí i báyìí pé ohun tó ń fa ìkórìíra pọ̀ lọ jàra ó sì díjú. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé kò sọ́nà tọ́mọ ẹ̀dá lè gbé e gbà láti jáwọ́ nínú ìwà ìkórìíra tó ti ń báa bọ̀ látọjọ́ pípẹ́ yìí ni? Ṣé ohun kan wà táa lè ṣe lẹ́nìkọ̀ọ̀kan tàbí lápapọ̀ láti gbógun ti àìgbọ́ra-ẹni-yé, àìmọ̀kan, àti ìbẹ̀rù tó bí ìkórìíra?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Ńṣe lèèyàn ń kọ́ ìwà ẹ̀tanú àti ìkórìíra o!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
A kò bí. . .
. . . ìkórìíra àti àìfẹ́ gba èrò ẹlòmíràn mọ́ wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ẹgbẹ́ ìkórìíra máa ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì láti fa àwọn èwe wọnú ẹgbẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìsìn ti súnná sí ogun
[Credit Line]
Fọ́tò AP