Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Àdúrà Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?

Báwo Ni Àdúrà Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Àdúrà Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?

“Àdúrà ló jẹ́ kí n lè tún ayé mi ṣe.”—Brad. a

Ọ̀PỌ̀ ọ̀dọ́ máa ń gbàdúrà, kódà ju béèyàn ṣe rò lọ. Ìwádìí Tí Gallup Ṣe Nípa Àwọn Ọ̀dọ́ tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́tàlá sí mẹ́tàdínlógún ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé ìpín mẹ́rìndínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló máa ń gbàdúrà kí wọ́n tó jẹun. Ìwádìí tí wọ́n sì ṣe nípa àwọn tó dàgbà jù wọ́n lọ díẹ̀ fi hàn pé ìpín méjìlélọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló ń gbàdúrà lójoojúmọ́.

Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni àdúrà kò jẹ́ nǹkan kan fún tàbí tí wọ́n kàn kà á sí ohun ṣákálá kan lásán. Ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn ọ̀dọ́ tó ní ohun tí Bíbélì pè ní “ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.” (Kólósè 1:9, 10) Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run kò fi fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé wọn. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́langba nínú ìwádìí kan bóyá wọ́n tiẹ̀ béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run rí pé kó kọ́ wọn mọ̀ ọ́n ṣe nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Ọmọdébìnrin kan dáhùn pé: “Ìgbà gbogbo ni mo máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó tọ́ mi sọ́nà kí n lè yan ipa ọ̀nà tó tọ́ nínú ìgbésí ayé.” Síbẹ̀, ó jẹ́wọ́ pé: “Mi ò lè rántí ìpinnu èyíkéyìí tí mo kọ́kọ́ gbàdúrà kí n tó ṣe é.” Abájọ nígbà yẹn, tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò dá lójú pé àdúrà ní agbára kankan tàbí pé á ṣiṣẹ́ fún wọn!

Àmọ́ o, bíi ti Brad táa fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èwe ló ti fúnra wọn rí agbára tí àdúrà ní. Tìrẹ náà lè rí bẹ́ẹ̀! Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí jẹ́ ká rí ìdí táa fi lè fọkàn balẹ̀ pé Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà wa. b Ìbéèrè tó wá wà ńlẹ̀ ni pé, Ọ̀nà wo làdúrà lè gbà ràn ọ́ lọ́wọ́? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, jẹ́ ká wo ọ̀nà tí Ọlọ́run máa ń gbà dáhùn àdúrà wa.

Bí Ọlọ́run Ṣe Máa Ń Dáhùn Àdúrà

Ní àsìkò tí a kọ Bíbélì, àwọn ọkùnrin ìgbàgbọ́ kan rí ìdáhùn tààràtà gbà sí àdúrà wọn, kódà lọ́nà iṣẹ́ ìyanu tún ni. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Hesekáyà Ọba mọ̀ pé òun ti ń ṣàìsàn tó máa gbẹ̀mí òun, ó bẹ Ọlọ́run pé kó dá òun nídè. Ọlọ́run dá a lóhùn pé: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ. Mo ti rí omijé rẹ. Kíyè sí i, èmi yóò mú ọ lára dá.” (2 Àwọn Ọba 20:1-6) Àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin mìíràn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run kò ṣàì rí ìdáhùn gbà sí àdúrà tiwọn náà.—1 Sámúẹ́lì 1:1-20; Dáníẹ́lì 10:2-12; Ìṣe 4:24-31; 10:1-7.

Àmọ́ o, ó ṣọ̀wọ́n kí Ọlọ́run dáhùn ní tààràtà, kódà lákòókò tí a kọ Bíbélì pàápàá. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe lọ́nà iṣẹ́ ìyanu ni Ọlọ́run ń gbà dáhùn àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jẹ́ kí wọ́n “kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ rẹ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí.” (Kólósè 1:9, 10) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ń ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ nípa fífún wọn lókun tẹ̀mí àti agbára láti hùwà rere, ó ń fún wọn lọ́gbọ́n àti ìmọ̀ láti ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Nígbà kan, tí àwọn Kristẹni wà nínú ìṣòro, kì í kúkú ṣe pé Ọlọ́run mú wàhálà náà kúrò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fún wọn ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” kí wọ́n bàa lè fara dà á!—2 Kọ́ríńtì 4:7; 2 Tímótì 4:17.

Lónìí bákan náà, ìdáhùn tóo máa rí gbà sí àdúrà rẹ lè máà wá lọ́nà àràmàǹdà. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe látẹ̀yìnwá, ó lè fún ọ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó sì fún ọ lókun láti kápá ipòkípò tóo bá dojú kọ. (Gálátíà 5:22, 23) Láti ṣàpèjúwe èyí, jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àdúrà fi lè ràn ọ́ lọ́wọ́.

Ó Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Láti Ṣe Àwọn Ìpinnu

Karen ń fẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan sọ́nà tó ṣe bí ẹni tó ń lépa àwọn ohun tẹ̀mí tó ga. Ó sọ pé: “Ìgbà gbogbo ló máa ń sọ fún mi pé òun fẹ́ láti di alàgbà nínú ìjọ.” Ó sì máa ń dùn mọ́ mi láti gbọ́ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ “ó tún ti máa ń sọ̀rọ̀ jù nípa iṣẹ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àti gbogbo nǹkan tóun máa rówó rà fún mi. Ara bẹ̀rẹ̀ sí í fu mí sí i.” Karen gbàdúrà nípa rẹ̀. Ó ní: “Mo bẹ Jèhófà pé kó là mí lọ́yẹ̀ kó sì jẹ́ kí n mọ àwọn ohun tó yẹ kí n mọ̀ nípa rẹ̀.”

Nígbà míì, kìkì gbígbà téèyàn gbàdúrà máa ń ṣàǹfààní, níwọ̀n bó ti lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fara balẹ̀ wo ọ̀ràn náà lọ́nà tí Jèhófà á gbà wò ó. Àmọ́ Karen tún nílò ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́. Ṣé pé ọ̀nà ìyanu ló máa gbà rí ìdáhùn? Yẹ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nínú Bíbélì nípa Dáfídì Ọba wò ná. Nígbà tó gbọ́ pé Áhítófẹ́lì ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́ ń fún Ábúsálómù ọmọ òun tó ti ya ọlọ̀tẹ̀ nímọ̀ràn, Dáfídì gbàdúrà pé: “Jọ̀wọ́, Jèhófà, sọ ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì di ti òmùgọ̀!” (2 Sámúẹ́lì 15:31) Àmọ́ Dáfídì tún gbégbèésẹ̀ níbàámu pẹ̀lú àdúrà rẹ̀. Ó fa iṣẹ́ yìí lé Húṣáì ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ pé: “Nígbà náà ni kí o bá mi mú ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì já sí pàbó.” (2 Sámúẹ́lì 15:34) Nírú ọ̀nà yìí kan náà, Karen gbégbèésẹ̀ níbàámu pẹ̀lú àdúrà rẹ̀, ó bá Kristẹni alàgbà kan tó mọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀ yìí dáadáa sọ̀rọ̀. Ìyẹn ló wá fìdí ẹ̀rù tó ti ń bà á múlẹ̀: Àfẹ́sọ́nà rẹ̀ kò ní ìtẹ̀síwájú kankan nípa tẹ̀mí.

Karen sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí n rí agbára tí àdúrà ní.” Ó bani nínú jẹ́ pé, àfẹ́sọ́nà rẹ̀ tẹ́lẹ̀ yìí lépa owó títí tí kò fi sin Ọlọ́run mọ́. Karen ní: “Ká ni mo ti lọ fẹ́ ẹ ni, bóyá èmi nìkan ni ǹ bá máa wá sípàdé báyìí.” Àdúrà ran Karen lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.

Ó Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Láti Kápá Ìbínú Rẹ

Bíbélì sọ nínú Òwe 29:11 pé: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.” Ìṣòro ọ̀hún ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni wàhálà ńlá ń bá fínra tí wọn kò sì lè mú sùúrù, àtúbọ̀tán rẹ̀ nígbà míì kì í sì í dáa. Brian tó jẹ́ ọ̀dọ́ sọ pé: “Àárín èmi àti ẹnì kan táa jọ ń ṣiṣẹ́ kò gún. Ló bá fa ọ̀bẹ yọ lọ́jọ́ kan.” Tó bá jẹ́ ìwọ ni, kí lò bá ṣe? Brian gbàdúrà. Ó ní: “Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti mú sùúrù, mo sì pẹ̀tù sí alábàáṣiṣẹ́ mi nínú tí kò fi lo ọ̀bẹ náà. Ó jù ú sílẹ̀ ó sì bá tiẹ̀ lọ.” Bí Brian ṣe ṣàkóso ìrònú ara rẹ̀ ni kò jẹ́ kó fàbínú yọ, ó sì dà bíi pé ìyẹn ló dáàbò bò ẹ̀mí rẹ̀.

O lè máà bára ẹ níbi tẹ́nì kan á ti yọ ọ̀bẹ sí ọ. Àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ táá béèrè pé kóo bomi sùúrù mu. Àdúrà lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fiyè dénú.

Ó Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Téèyàn Bá Ní Ìdààmú

Barbara ní òun rántí “ìgbà kan tí wàhálà bá òun” ní bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. Ó ní: “Àti iṣẹ́ o, àti ìdílé o, àtàwọn ọ̀rẹ́ o, kò tiẹ̀ sí ọ̀kankan tó jọ pé ó lójútùú. Mi ò mọ ohun tí màá ṣe.” Ni Barbara bá ṣáà gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́. Àmọ́ ìṣòro kan wà níbẹ̀. Ó sọ pé: “Mi ò mọ nǹkan tí màá ní kí Jèhófà ṣe fún mi. Níkẹyìn, mo béèrè pé kó fún mi ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Alaalẹ́ ni mo ń sọ fún un pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n yé ṣàníyàn nípa gbogbo nǹkan mọ́.”

Báwo làdúrà ṣe ràn án lọ́wọ́? Ó ní: “Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo rí i pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro mi kò tíì lọ, mi ò tún gbé e sọ́kàn mọ́ tàbí dààmú nípa rẹ̀ mọ́.” Bíbélì ṣèlérí pé: “Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 4:6, 7.

Ó Lè Ranni Lọ́wọ́ Láti Sún Mọ́ Ọlọ́run

Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Paul. Ó ní: “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ ń gbé lọ́dọ̀ ìdílé kan nígbà yẹn ni. Lálẹ́ ọjọ́ kan, ìbànújẹ́ gbé mi mì pátápátá. Kò tíì pẹ́ tí mo jáde iléèwé gíga, àárò gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi sì ń sọ mi. Lálẹ́ ọjọ́ náà, ńṣe lomi ń dà lójú mi bí mo ti ń rántí àwọn àkókò alárinrin táa ti jọ gbádùn pa pọ.” Kí ni Paul máa ṣe? Fún ìgbà àkọ́kọ́, ó fi taratara gbàdúrà. Ó ní: “Mo sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi fún Jèhófà mo sì ní kó fún mi ní okun àti ìbàlẹ̀ ọkàn.”

Kí ló tibẹ̀ jáde? Paul sọ pé: “Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, bí mo ṣe jí, gágá ni ara mi yá lọ́nà tí mi ò rírú ẹ̀ rí láyé mi. Bí mo ṣe kúrò láti orí ìrònú tó ń roni lára bọ́ sórí ‘àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ’ nìyẹn.” Ní báyìí tọ́kàn Paul ti wálẹ̀, ó wá ṣeé ṣe fún un láti wo àwọn nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Kò sì pẹ́ tó fi wá rí i lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé, ‘àwọn àkókò tó pè ní alárinrin’ kì í ṣe alárinrin rárá. (Oníwàásù 7:10) Ká sòótọ́, “àwọn ọ̀rẹ́” tó ń dùn ún pé òun kò rí mọ́ kì í ṣe àwọn tó nípa tó dára lórí rẹ̀.

Èyí tó ṣe pàtàkì jù ńbẹ̀ ni pé, Paul wá rí i fúnra rẹ̀ pé Jèhófà bìkítà nípa òun. Ó rí òtítọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ Jákọ́bù 4:8 pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” Àkókò ìyípadà ńlá gbáà lèyí jẹ́ nínú ìgbésí ayé Paul. Ìyẹn sún un láti fi Jèhófà ṣáájú nínú gbogbo ohun tó ń ṣe ní ìgbésí ayé rẹ̀ àti láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún un.

Bá Ọlọ́run Sọ̀rọ̀!

Àwọn ìrírí tó ní àbájáde tó dára yìí pèsè ìdánilójú pé àdúrà lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Àmọ́ o, àyàfi tóo bá mú mímọ Ọlọ́run ní ọ̀kúnkúndùn, tóo sì bá a dọ́rẹ̀ẹ́ nìkan nìyẹn fi lè ṣeé ṣe. Ó wá ṣeni láàánú pé, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń gbé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Inú ìdílé Kristẹni ni wọ́n ti tọ́ Carissa dàgbà. Àmọ́ ó jẹ́wọ́ pé: “Ó dà bí ẹni pé ẹnu ọdún àìpẹ́ yìí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ ìjẹ́pàtàkì àjọṣe aláìlẹ́gbẹ́ táa ní pẹ̀lú Jèhófà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.” Wọ́n tọ́ Brad táa mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ náà dàgbà gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, àmọ́ ó pa ìjọsìn tòótọ́ tì fún bí ọdún mélòó kan. Ó sọ pé: “Ìgbà tí nǹkan tí mo gbé sọnù ṣẹ̀ṣẹ̀ yé mi ni mo tó padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Báyìí, mo ti wá mọ̀ pé ìgbésí ayé kì í dùn bẹ́ẹ̀ sì ni kì í lárinrin láìsí àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà.”

Bó ti wù kó rí, máà jẹ́ kó dìgbà tóo bá rí wàhálà kóo tó sún mọ́ Ọlọ́run. Bẹ̀rẹ̀ sí í bá a sọ̀rọ̀ báyìí, máa bá a sọ̀rọ̀ déédéé! (Lúùkù 11:9-13) ‘Tú ọkàn-àyà rẹ jáde níwájú rẹ̀.’ (Sáàmù 62:8) Kò ní pẹ́ rárá tí wàá fi mọ̀ pé lóòótọ́ ni àdúrà lè ràn ọ́ lọ́wọ́!

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti pa àwọn orúkọ kan dà.

b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ṣé Ọlọ́run Máa Dáhùn Àdúrà mi?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti July 8, 2001.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àdúrà Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Láti

● Ṣe àwọn ìpinnu tó túbọ̀ dára

● Ṣe sùúrù nígbà wàhálà

● Rí ìtura kúrò nínú ìdààmú

● Túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run