Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Ribiribi Làwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Ń Ṣe

Iṣẹ́ Ribiribi Làwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Ń Ṣe

Iṣẹ́ Ribiribi Làwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Ń Ṣe

NÍ GBOGBO ọ̀sán Friday, Sirley, olùkọ́ kan tó jẹ́ ẹni nǹkan bí àádọ́ta ọdún ní Brazil máa ń sọ yàrá rẹ̀ di kíláàsì tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́. Nǹkan bí aago méjì ọ̀sán ni Amélia, ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń dé. Kì í pa kíláàsì jẹ, ó sì ti mọ̀wèé kà ju ọ̀pọ̀ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga lọ. Ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin ni Amélia.

Àpẹẹrẹ àwọn aráàlú kan tí wọ́n ju ọgọ́ta lọ tí wọ́n sì jẹ́ àgbàlagbà ni Amélia tẹ̀ lé, tí wọ́n ti gboyè jáde láti kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà ọ̀fẹ́ tí Sirley ń darí ní ìlú rẹ̀. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n gbé iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni tí Sirley ń ṣe jáde nínú ìwé ìròyìn Brazil náà, Jornal do Sudoeste. Lẹ́yìn tí àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn yìí ti sọ pé Sirley ti “ṣiṣẹ́ takuntakun láti mú kí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn àgbègbè náà túbọ̀ ní láárí,” ó tún sọ pé ọ̀nà tí Sirley ń gbà kọ́ àwọn àgbàlagbà náà dára débi pé “lẹ́yìn wíwá sí kíláàsì fún ọgọ́fà wákàtí péré, wọ́n ti ń lè kọ lẹ́tà, wọ́n ti ń ka ìwé ìròyìn, wọ́n sì ti ń lè ṣe ìṣirò díẹ̀díẹ̀ àtàwọn nǹkan míì téèyàn ń ṣe lójoojúmọ́.” Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé, ìwé kékeré kan tó ń jẹ́ Learn to Read and Write táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe jáde ni Sirley ń lò. a

Ẹni Tí Ojú Ń Tì Tẹ́lẹ̀ Tó Wá Dẹni Iyì

Dona Luzia, ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rin tóun náà kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Sirley sọ pé, ojú máa ń ti òun láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nígbà tóun kò tíì mọ̀ọ́kọ tàbí mọ̀ọ́kà. Àtilọ sọ́jà pàápàá, iṣẹ́ ni. Ó sọ pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ pé: “Báyìí mo ti ń kọ lẹ́tà sáwọn ẹbí mi tó wà nílùú mìíràn, mo sì mọ bí mo ṣe lè ṣọ́ owó mi ná. Kò sí pé ẹni kan tún ń ṣẹ́ ṣéńjì mi mọ́ka mọ́.” Bákan náà ni Maria tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rin sọ pé ńṣe lojú máa ń ti òun nígbà tóun bá ń tẹ̀ka sórí ìwé sọ̀wédowó láti gba owó ìfẹ̀yìntì òun. Ó ní: “Ńṣe ló máa ń dà bíi pé aláìlera ni mí.” Àmọ́ ọpẹ́ ni fún kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, tìdùnnú-tìdùnnú ni Maria fi ń buwọ́ lùwé fúnra rẹ̀ báyìí.

Ọ̀rọ̀ oríyìn tó ń wá látọ̀dọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Sirley àtàwọn tó ti kọ́ darí ti jẹ́ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó ń ṣe lọ́fẹ̀ẹ́ di èyí tó gbajúgbajà débi pé yàrá rẹ̀ kò gbèrò mọ́. Kò ní pẹ́ mọ́ tó máa kó kíláàsì náà lọ síbi tó túbọ̀ láyè dáadáa.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Kan Tó Gba Ẹ̀bùn

Sirley jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó dájú pé iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni kì í ṣàjèjì sí ìwọ náà. Àmọ́ Sirley nìkan kọ́ ló ṣàṣeyọrí o. Kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tí wọ́n ń dárí nínú ọgọ́rọ̀ọ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba jákèjádò Brazil ti ran àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [22,000] lórílẹ̀-èdè yẹn lọ́wọ́ láti mọ̀ọ́kọ àti láti mọ̀ọ́kà.

Irú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe láwọn apá ibòmíràn láyé náà ti ṣàṣeyọrí. Fún àpẹẹrẹ, ní Burundi, orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, inú Ọ́fíìsì Ìjọba fún Ẹ̀kọ́ Àgbà (ẹ̀ka Ilé Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀kọ́ kan) dùn gan-an sí àbájáde ìtòlẹ́sẹẹsẹ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà táwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe débi pé ó fún mẹ́rin lára àwọn olùkọ́ tó ń mójú tó ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní ẹ̀bùn fún “iṣẹ́ taakuntaakun tí wọ́n ń ṣe láti kọ́ àwọn mìíràn láti mọ̀wéé kà.” Ohun tó dùn mọ́ àwọn aláṣẹ nínú jù ni pé, ìpín márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó kọ́ láti kàwé kí wọ́n sì kọ ọ́ sílẹ̀ jẹ́ àwọn obìnrin tí wọ́n ti dàgbà, àwọn tó jẹ́ pé irú wọn ló sábàá máa ń sá fún irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ bẹ́ẹ̀.

Ní Mòsáńbíìkì, ẹgbẹ̀rún mẹ́rin èèyàn ló ń kẹ́kọ̀ọ́ báyìí láwọn kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, láàárín ọdún mẹ́rin tó sì kọjá, àwọn tó ti mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà ti lé lẹ́gbẹ̀rún márùn-ún. Ẹnì kan tó ti kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ nígbà kan kọ̀wé pé: “Màá fẹ́ láti fi ìmọrírì mi àtọkànwá hàn. Ọpẹ́lọpẹ́ iléèwé náà, mo ti lè kà kí n sì kọ báyìí.”

Ìpèsè Ìrànwọ́ Tó “Gbéṣẹ́ Dípò Èyí Táa Kàn Ṣe Bẹ́ẹ̀ Bẹ́ẹ̀”

Ìpèsè ìrànwọ́ tún jẹ́ oríṣi iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni míì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìgbòkègbodò bíbùáyà kan wáyé ní ilé ẹrù ńlá kan ní Paris ní ilẹ̀ Faransé. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni bí irínwó ló lo òpin ọ̀sẹ̀ wọn láti di àwọn páálí tó kún fún oúnjẹ, aṣọ, àti oògùn. Nígbà tí òpin ọ̀sẹ̀ yẹn máa fi parí, àwọn àpótí ẹrù fàkìàfakia mẹ́sàn-án tó kún fún àwọn ẹrù ìrànwọ́ tówó wọn ń lọ sí bíi mílíọ̀nù kan owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà ló ti dúró wámúwámú, tó jẹ́ pé kí wọ́n máa gbé wọn lọ ló kù. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni àwọn ẹrù yìí gúnlẹ̀ sáwọn orílẹ̀ èdè tó wà ní Àárín Gbùngbùn Áfíríkà, níbi táwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò náà ti pín wọn láìjáfara. Bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí ló dá èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹrù yìí jọ.

Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Congo (Kinshasa) kan gbóríyìn fún iṣẹ́ àánú táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun kan tó “gbéṣẹ́ dípò èyí táa kàn ṣe bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀.” Bákan náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UNHCR) sọ pé gbágbáágbá làwọ́n wà lẹ́yìn wọn. Inú ọ̀kan lára wọn ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Ilẹ̀ Congo dùn sí bí iṣẹ́ ìrànwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe wà létòlétò tó bẹ́ẹ̀ tó fi gbé ọkọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ pé kí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà lò ó. Ó tún mórí àwọn aládùúgbò wú pẹ̀lú. Nígbà táwọn tó ń wò wọ́n rí bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn ìpèsè ìrànwọ́ náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó wà nínú ìṣòro láìjáfara, tìyanutìyanu làwọn kan fi béèrè pé: “Báwo lẹ ṣe ṣètò ara yín débi pé ẹ kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀?”

Méjì péré ni iṣẹ́ ìpèsè ìrànwọ́ àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà yìí jẹ́ lára àwọn iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe káàkiri ayé láti ẹ̀wádún wá. Àmọ́, iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni kan tún wà táwọn Ẹlẹ́rìí tún fi ara wọn fún, ìyẹn ni iṣẹ́ kan tí àǹfààní rẹ̀ wà títí lọ gbére. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò ṣàlàyé ìyẹn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe ìwé kékeré náà, Learn to Read and Write (ó wà ní èdè mẹ́fà) àti Apply Yourself to Reading and Writing tó jáde láìpẹ́ yìí, (ó wà ní èdè mọ́kàndínlọ́gbọ̀n). Tóo bá fẹ́ ẹ̀dà kan lọ́fẹ̀ẹ́, kàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò rẹ tàbí sí àwọn òǹṣèwé ìwé ìròyìn yìí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Ìyípadà Ń Dé Bá Iṣẹ́ Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni

Bí Julie bá ti ń bá ìrìn-àjò iṣẹ́ ajé rẹ̀ káàkiri, ó máa ń gbìyànjú láti wá àyè díẹ̀ fún iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni, bíi kó lo wákàtí díẹ̀ níbí tàbí kó lo ọjọ́ kan níbòmíì. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, nígbà tó wà ní Gúúsù Amẹ́ríkà, ó fi ọ̀sán ọjọ́ kan ṣèrànwọ́ ní ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí tó wà ní ìlú Santiago, lórílẹ̀-èdè Chile. Ó sọ pé rírin ìrìn àjò ń fún òun ní “àǹfààní tó pọ̀ gan an” láti yọ̀ǹda ara òun.

Bíi ti Julie, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ń yọ̀ǹda àkókò wọn, àmọ́ lọ́nà tó túbọ̀ ń kéré sí i. Sara Meléndez tó jẹ́ ọ̀gá àgbà fún àwùjọ tó ń wádìí tó sì ń ṣàkọsílẹ̀ ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni sọ pé: “Àṣà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé nìyẹn. Àwọn èèyàn ń yọ̀ǹda ara wọn lóòótọ́, àmọ́ ó máa ń jẹ́ ní ìdákúrekú.” Àbájáde èyí ni pé, àwọn elétò náà ń jìyà ohun táwọn kan pè ní “ọ̀wọ́ngógó olùyọ̀ǹda ara ẹni,” wọ́n sì ń làkàkà láti rí àwọn èèyàn tó máa bá wọn ṣe àwọn ohun tí wọ́n ní í ṣe.

“Iṣẹ́ Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Bágbára-Ṣe-Mọ”

Àwọn olùṣekòkáárí kan ronú pé àṣà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọjú yìí, ìyẹn káwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni máa fi àkókò tó kéré sílẹ̀ jẹ́ nítorí ìṣesí wọn tó yí padà. Susan Ellis ẹni tí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni máa ń kàn sí sọ pé: “O ò tún lè gbọ́ káwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni sọ pé ‘mo wà fún yín lọ́jọ́kọ́jọ́.’ Àwọn èèyàn kò fẹ́ fara wọn jìn fún nǹkan mọ́.” Eileen Daspin tó jẹ́ akọ̀ròyìn náà gbà pẹ̀lú rẹ̀. Lẹ́yìn tó ti fọ̀rọ̀ wá àwọn tó ń darí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni bíi mélòó kan lẹ́nu wò nípa àìtó àwọn èèyàn, ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “ìyà àìmúratán àwọn èèyàn láti yọ̀ǹda ara wọn di ìgbàkigbà ń jẹ iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni lójú méjèèjì.”

Àmọ́ o, Kathleen Behrens, olùdarí ẹgbẹ́ tó ń jẹ́ New York Bìkítà, táa mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ ọ̀wọ́ yìí wòye pé, kì í ṣe pé àwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn fún ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ kò fẹ́ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ, àkókò tí wọ́n ò ní ló fà á. Kò lè ṣeé ṣe rárá fáwọn èèyàn tó ń fi ohun tó lé ní àádọ́ta wákàtí ṣiṣẹ́ lọ́sẹ̀, tí wọ́n á tún bójú tó ọmọ tàbí àwọn òbí àgbà láàárín ẹ̀ láti máa yọ̀ǹda ara wọn ní gbogbo ìgbà. Ó sọ pé: “Síbẹ̀ náà, pé àwọn èèyàn tọ́wọ́ wọn dí yìí kàn tiẹ̀ ń lò lára ìgbésí ayé wọn fún iṣẹ́ tó kan gbogbo èèyàn fi hàn pé wọ́n dìídì fẹ́ fara wọn jìn ni.”

Behrens sọ pé, fún irú àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí àkókò kò yọ sílẹ̀ fún yìí, “iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni bágbára-ṣe-mọ” nìkan ni ọ̀nà àbáyọ. Ọ̀pọ̀ àjọ ìyọ̀ǹda ara ẹni ló ti fàyè gba ṣíṣe kódà iṣẹ́ ọjọ́ kan báyìí. “Èyí ń jẹ́ káwọn èèyàn lè yọ̀ǹda ara wọn lọ́nà tí wọ́n túbọ̀ máa fi wúlò sí i tí yóò sì rọ̀ wọ́n lọ́rùn láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan-lọ́gbọ̀n.”

Yàtọ̀ síyẹn, ńṣe làwọn èèyàn tó ń yọ̀ǹda ara wọn látorí kọ̀ǹpútà wọn nínú ilé túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tí wọ́n á gba ìsọfúnni sínú kọ̀ǹpútà tí wọ́n á sì ṣèwádìí lórí ẹ̀. Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé: “Bóyá ni kì í ṣe iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni orí kọ̀ǹpútà lohun tó ṣàjèjì jù lọ, àwọn kan sì ti sọ pé òun ló máa ṣàṣeyọrí jù lọ táa bá ń sọ nípa ohun tí wọ́n ń pè ní ‘iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni bágbára-ṣe-mọ.’”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Wọ́n Lọ Ṣèrànwọ́ ní Kobe!

Ní January 1995 tí ìsẹ̀lẹ̀ kan sẹ̀ ní ìlú Kobe elérò rẹpẹtẹ tó wà létíkun kan ní Japan, ìparun tó fà kò ṣe é fẹnu sọ. Òun ni ìsẹ̀lẹ̀ tó tíì ṣekú pa àwọn èèyàn jù lọ ní Japan láti ọdún 1923 pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún márùn-ún èèyàn tó kú. Kíá làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Japan àti káàkiri àgbáyé bẹ̀rẹ̀ sí i ṣèrànwọ́ fáwọn tí ìsẹ̀lẹ̀ náà kàn. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dá owó ìrànwọ́ náà, ó lé ní mílíọ̀nù kan dọ́là tí wọ́n dá láàárín ọjọ́ mẹ́ta. Ńṣe làwọn nǹkan ìrànwọ́ lóríṣiríṣi ń ya wọ Kobe.

Alàgbà Kristẹni kan tó kópa nínú iṣẹ́ pípèsè ìrànwọ́ náà rí i pé kò pẹ́ rárá tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn fi kún pitimọ fún àwọn nǹkan ìrànwọ́ tó pọ̀ kọjá ohun tí wọ́n lè lò. Kí ni wọ́n máa wá fi ẹrù rẹpẹtẹ tó ṣẹ́ kù yìí ṣe? Ó dá a lábàá pé kí wọ́n fi díẹ̀ tọrẹ fún ọsibítù kan tó wà nítòsí. Làwọn Ẹlẹ́rìí bá di ọkọ̀ ẹrù kan kún bámú wọ́n sì kọrí síbẹ̀ láàárín àwọn àwókù ilé lọ́tùn-ún lósì. Ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n fi rìnrìn náà dípò ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ tó yẹ kó gbà. Nígbà tí wọ́n dé ọsibítù ọ̀hún, wọ́n fa àwọn nǹkan ìrànwọ́ náà lé dókítà àgbà lọ́wọ́, tí àwọn nǹkan bíi bùláńkẹ́ẹ̀tì, matírẹ́ẹ̀sì, ìtẹ́dìí ọmọdé, èso, àtàwọn oògùn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ wà nínú wọn. Pẹ̀lú ìdùnnú ni dókítà náà fi sọ pé gbogbo nǹkan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá fẹ́ fún àwọn làwọ́n máa fi tayọ̀tayọ̀ gbà. Àwọn èso inú rẹ̀ ló dùn mọ́ wọn nínú jù, nítorí pé àwọn oúnjẹ eléso kò kárí gbogbo àwọn tó ń gbàtọ́jú náà.

Bí àwọn Ẹlẹ́rìí ti ń já àwọn ẹrù náà sílẹ̀, ńṣe ni dókítà náà kàn rọra dúró tó ń wò wọ́n ṣáá, láìka bí iṣẹ́ rẹ̀ ṣe jẹ́ kánjúkánjú sí. Ẹ̀yìn náà ló wá fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ tẹrí ba tó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Bí wọ́n ti ń wa ọkọ̀ wọn kúrò níbẹ̀, kò yisẹ̀ níbi tó dúró sí láti fi bó ṣe kún fún ọpẹ́ tó hàn. Alàgbà tó kópa náà sọ pé, ọsibítù yẹn ti wá di èyí tó ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ gan-an pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bá lọ gbàtọ́jú níbẹ̀.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Iṣẹ́ Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni—Tó Mú Èrè Ńlá Wá

Nígbà tí àwùjọ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni kan ní Kabezi, ìlú kékeré kan ní Burundi, fẹ́ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, aláṣẹ àdúgbò náà béèrè fún ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó béèrè bóyá àwọn Ẹlẹ́rìí náà á lè ṣàtúnṣe ọ̀nà kan tó gba ẹ̀gbẹ́ ibi tí wọ́n fẹ́ kọ́ ọ sí kọjá. Tayọ̀tayọ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí ọ̀hún fi gbà láti tún ojú ọ̀nà tó ti bà jẹ́ náà ṣe, ọwọ́ lásán ni wọ́n sì fi ṣe gbogbo iṣẹ́ náà. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà ṣe iṣẹ́ ọ̀hún dáradára débi pé, àwọn òṣìṣẹ́ àdúgbò náà sọ̀rọ̀ ìmọrírì wọn jáde fún iṣẹ́ takuntakun àti ẹ̀mí ìmúratán tí wọ́n ní. Ẹ̀yìn ìgbà náà làwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn tí àwòrán rẹ̀ wà lókè yìí. Wọ́n ti ní ibì kan tó gbayì báyìí, èyí tó máa ṣèrànwọ́ fún gbígbé ẹ̀kọ́ Bíbélì lárugẹ fún ọ̀pọ̀ ọdún lọ́jọ́ iwájú. Kò sí àní-àní pé, iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni, irú èyí tó wù kó jẹ́, lè mú àwọn èrè tó máa wà pẹ́ títí wá.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Sirley ń gbádùn kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn láti mọ̀wéé kà

[Credit Line]

Nelson P. Duarte-Jornal do Sudoeste