Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Ń Fara Da Ìbànújẹ́ Ńláǹlà Kan

Mo Ń Fara Da Ìbànújẹ́ Ńláǹlà Kan

Mo Ń Fara Da Ìbànújẹ́ Ńláǹlà Kan

GẸ́GẸ́ BÍ JAMES GIARRANO ṢE SỌ Ọ́

Níní ọmọ-ọmọ jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ń fún èèyàn láyọ̀ jù lọ ní ìgbésí ayé. Ara èmi àti Vicki ìyàwó mi ti wà lọ́nà gan-an báa ti ń retí ìbí ọmọ-ọmọ wa àkọ́kọ́. Ìbẹ̀rẹ̀ oṣù October 2000 ni ọmọbìnrin wa, Theresa, àti Jonathan ọkọ rẹ̀ ń retí ìkókó wọn yìí. Kò sóhun tó lè mú wa máa ronú láé pé ìbànújẹ́ tó ju ìbànújẹ́ lọ máa tó wọlé tọ̀ wá.

ÈMI, ìyàwó mi, ọmọ wa ọkùnrin àti ìyàwó rẹ̀ lọ fún ìsinmi ní Sátidé, September 23. A fẹ́ lọ pàdé àwọn ẹbí wa tó kù ká sì lo ọ̀sẹ̀ kan ní Erékùṣù Oníyanrìn ti North Carolina. Theresa àti Jonathan ti sọ pé àwọn kò ní lè lọ fún ìsinmi náà nítorí oyún rẹ̀ ti wọ oṣù kẹsàn-án ibi táa sì ń lọ jìnnà, yóò tó wákàtí mọ́kànlá láti ilé wa ní Ohio.

A kọ́kọ́ fẹ́ fi àkókò ìsinmi wa sígbà míì, àmọ́ Theresa ní dandan ká máa lọ. Ó ní kò ní sí nǹkan kan. Yàtọ̀ síyẹn, dókítà rẹ̀ ti sọ pé bóyá loyún ẹ̀ máa kọjá oṣù mẹ́sàn-án, ọ̀sẹ̀ méjì sígbà yẹn sì nìrètí wà pé á bímọ.

Wednesday, September 27, 2000 ti lọ wà jù fún wa, ó mú mi rántí ìdí tí ìdílé wa fi yan àgbègbè yìí fún ibi ìsinmi láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn. A ò mọ̀ rárá pé ilẹ̀ ọjọ́ yẹn ò ní ṣú tí ìgbésí ayé wa fi máa dorí kodò.

“A Ò Rí Theresa!”

Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, àbúrò mi ọkùnrin pè mí lórí tẹlifóònù láti Ohio. Kò mọ bó ṣe máa sọ̀rọ̀ rárá, bẹ́ẹ̀ lohùn rẹ̀ sì ń gbọ̀n. Nígbà tó jàjà sọ̀rọ̀, ló bá sọ pé: “A ò rí Theresa!” Ọ̀rọ̀ ti di tàwọn ọlọ́pàá nítorí ọ̀nà tó fi dàwátì mú ìfura dání. Nígbà tí Jonathan délé lọ́sàn-án ọjọ́ náà, kò bá ilẹ̀kùn ní títì. Oúnjẹ tó yẹ kí Theresa jẹ láàárọ̀ ọjọ́ yẹn ṣì wà lórí tábìlì níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò mú àpamọ́wọ́ rẹ̀ lọ. Ohun tó tún wá ṣeni ní kàyéfì ni pé: Bàtà kan ṣoṣo tó ṣeé wọ̀ fún un látìgbà tí oyún rẹ̀ ti wọ oṣù kẹsàn-án wà lẹ́nu ọ̀nà níbẹ̀.

Jonathan ti kọ́kọ́ pè é lórí fóònù ní nǹkan bí aago mẹ́sàn-án ààbọ̀ àárọ̀. Theresa sọ fún un pé obìnrin kan pè lórí fóònù pé òun fẹ́ wá wo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn tí wọ́n fẹ́ tà. Lẹ́yìn náà, Theresa á wá jáde lọ láti lọ ṣe àwọn nǹkan kan. Lákòókò oúnjẹ ọ̀sán, Jonathan fóònù ilé, àmọ́ kò rí i bá sọ̀rọ̀. Ní gbogbo ọ̀sán ló ń pè, síbẹ̀ kò gbọ́ nǹkan kan. Nígbà tó délé láago mẹ́rin kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ó rí i pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà kò sí níbẹ̀ mọ́. Ó fóònù ọsibítù, torí o ń ronú pé bóyá ńṣe lọmọ ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú Theresa. Kò sí níbẹ̀ náà. Ó tún pe àwọn mẹ́ńbà ìdílé míì, àmọ́ kò sẹ́ni tó rí i. Ojora bò ó, ló bá ké sí àwọn ọlọ́pàá. Ní nǹkan bí aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́, àwọn ọlọ́pàá rí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà níbì kan tí kò jìnnà sílé wọn. Àmọ́ wọn ò rí Theresa.

Ìròyìn yìí kó ṣìbáṣìbo bá wa ní North Carolina lọ́hùn-ún. Lèmi àti ìyàwó mi, pẹ̀lú ọmọkùnrin wa àti ìyàwó rẹ̀ bá palẹ̀ ẹrù wa mọ́, ó dilé. Ìrìn-àjò yẹn gùn, kò sì rọrùn fún wa rárá. A fi gbogbo òru rìn a sì délé ní Ohio láàárọ̀ ọjọ́ kejì.

A Jàjà Gbọ́ Nǹkan Kan

Ní gbogbo ìgbà yẹn, Jonathan àtàwọn ẹbí wa kan, àwọn ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ wa, àtàwọn míì ti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọlọ́pàá ní wíwá Theresa, tòrutòru ni wọ́n sì fi ń wá a. Ọjọ́ márùn-ún gbáko ni wọ́n fi ń bá wíwá yìí nìṣó. Níkẹyìn, ní Monday, October 2, la jàjà tó gbọ́ nǹkan kan. Nígbà yẹn, àwọn ọlọ́pàá ti tọpasẹ̀ ìkésíni tí Theresa gbà láàárọ̀ ọjọ́ Wednesday yẹn. Obìnrin kan tí ilé rẹ̀ kò jìnnà sí wọn ló fi tẹlifóònù tí wọ́n máa ń mú rìn pè é.

Lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá ti fọ̀rọ̀ wá obìnrin náà lẹ́nu wò, wọ́n fura sí i. Nígbà tó dìrọ̀lẹ́, àwọn ọlọ́pàá padà sílé obìnrin náà. Àmọ́ bí wọ́n ti ń sún mọ́ ẹnu ọ̀nà, wọ́n gbúròó ìbọn. Bí wọ́n ṣe já wọlé, wọ́n bá obìnrin náà tó ti kú. Ó ti yìnbọn para rẹ̀. Ó yà wọ́n lẹ́nu láti rí ọmọkùnrin jòjòló kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí nínú iyàrá kan ní àjà kejì. Ó ṣòroó gbà gbọ́ pé, láàárín gbogbo wàhálà yìí, ńṣe ló sùn lọ fọnfọn!

Síbẹ̀ a ò rẹ́ni tó jọ Theresa o. Fún bíi wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn náà làwọn ọlọ́pàá fi tú gbogbo inú ilé náà láti rí nǹkan tó tiẹ̀ máa fi hàn bóyá ó wá síbẹ̀. Àárọ̀ kùtù ọjọ́ Tuesday ni ìwákiri ọ̀hún parí ní ilé ìgbọ́kọ̀sí. Wọ́n rí òkú Theresa nínú sàréè kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìn. Dókítà tó yẹ̀ ẹ́ wò sọ pé, wọ́n fi nǹkan lù ú ni tí kò sì mọ nǹkan kan mọ́, ẹ̀yìn náà ni wọ́n wá yìnbọn fún un lẹ́yìn. Ó kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé ọmọ tó wà níkùn rẹ̀ jáde. Nígbà táa wò ó lọ wò ó bọ̀, ara tún tù wá díẹ̀ pé kò japoró ikú.

Wọ́n gbé ọmọ ọwọ́ náà lọ sí ọsibítù, wọ́n sì ri í pé koko lara rẹ̀ le, kò sí kinní kan tó ṣe é lára! Àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fún un fi hàn pé ọmọ-ọmọ wa ni lóòótọ́. Jonathan sọ́ ọ lórúkọ tóun àti Theresa ti ní lọ́kàn, ó pè é ní Oscar Gavin. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ ní ọsibítù, wọ́n gbé ọmọ-ọmọ wa tó wọn kìlógíráàmù mẹ́rin fún bàbá rẹ̀ ní Thursday, October 5. Inú wa dùn gan-an láti rí ọmọ-ọmọ wa, àmọ́ a ò lè sọ bí ọkàn wa ti bàjẹ́ tó pé Theresa kò sí níbẹ̀ láti gbé e mọ́ra.

Ipá Táwọn Èèyàn Sà

Pòròpòrò lomi ń bọ́ lójú èmi àti ìdílé mi nígbà táa rí báwọn èèyàn ṣe gbárùkù tì wá—àwọn tá ò mọ̀ rí ló sì pọ̀ jù nínú wọn. Ní gbogbo ìgbà táa ń wá Theresa, ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló yọ̀ǹda ara wọn láti bá wa wá a. Ọ̀pọ̀ nínú wọn gbé owó kalẹ̀. Àwọn ilé ìtajà kan tó ń ta àwọn ohun èlò ọ́fíìsì tẹ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé ìléwọ́ fún wa lọ́fẹ̀ẹ́ láti fi bá wa wá a. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn sì bá wa pín in dé àwọn ibi tó fi ọ̀pọ̀ kìlómítà kọjá ilé Theresa.

Ọ̀kan lára àwọn Kristẹni arábìnrin wa ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ agbẹjọ́rò kan, nígbà tó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa fún un, ó sọ pé òun á ṣèrànwọ́. A gbà, èyí sí já sí ìbùkún ńláǹlà fún wa. Ó bá wa bójú tó ọ̀ràn tó jẹ mọ́ tàwọn oníròyìn àtàwọn ọ̀ràn òfin kan tó dìde. Láfikún sí i, ó dábàá àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ méjì kan fún wa tí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ gidigidi nídìí ọ̀ràn náà. Ojúlówó àníyàn tí wọ́n fi hàn sí wa jọ wá lójú gan-an ni.

Lẹ́yìn tí wọ́n gbé ọmọ-ọmọ wa fún wa tán, ìtìlẹ́yìn ọ̀hún tún wa pọ̀ sí i. Àwọn ilé ìtajà kan fi oúnjẹ àtàwọn ohun èèlò inú ilé ránṣẹ́ sí wa. Àwọn èèyàn tó fi aṣọ ta Oscar lọ́rẹ kò lóǹkà, títí kan àwọn ìtẹ́dìí àlòkósọnù, oúnjẹ ọmọdé, àtàwọn nǹkan ìṣeré. Ohun táa gbà ju nǹkan tí Oscar lè lò lọ fíìfíì, la bá fi ìyókù tọrẹ fún ilé ìtọ́jú àwọn aláboyún kan ládùúgbò. Nítorí pé àwọn oníròyìn gbé ìròyìn náà síta, ẹgbẹẹgbẹ̀rún káàdì àti lẹ́tà la gbà, kì í wá ṣe látọ̀dọ̀ àwọn tó wà ládùúgbò wa nìkan o, àmọ́ yíká ayé ni.

Níbi ọ̀rọ̀ ìsìnkú Theresa, èyí tó wáyé ní Sunday, ọjọ́ kẹjọ, oṣù October, ni ìtìlẹ́yìn àwọn èèyàn ti fara hàn jù lọ. A mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ẹ́ wá, àmọ́ ohun táa rí kọjá ohun táa lérò. Gbọ̀ngàn àpéjọ ilé ẹ̀kọ́ gíga àdúgbò kan la ṣètò fún lílò, àwọn èèyàn tó ju egbèje [1,400] lọ sì kún inú rẹ̀ fọ́fọ́. Lára àwọn tó wá síbẹ̀ ni àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́, àwọn ọlọ́pàá, olórí ìlú àtàwọn mìíràn láti àgbègbè wa. Àwọn òṣìṣẹ́ láti iléeṣẹ́ ìròyìn pésẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì làwọn tẹlifíṣọ̀n àdúgbò gbé àsọyé náà sáfẹ́fẹ́, wọ́n sì tún fi hàn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì bí wọ́n ti ń sọ ọ́ lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló wà lórí ìdúró láwọn ibi tí àlejò máa ń dúró sí ní iléèwé náà táwọn mìíràn sì kóra jọ lábẹ́ agbòjò nínú òjò tó ń mótútù níta, tí wọ́n ń gbọ́rọ̀ látinú àwọn gbohùngbohùn tó wà káàkiri. Àsọyé náà fún ọ̀pọ̀ jaburata èèyàn ní ìjẹ́rìí nípa àwọn ohun táa gbà gbọ́ èyí táa gbé karí Bíbélì.

Lẹ́yìn náà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn fi sùúrù tò lórí ìlà láti fi ìbákẹ́dùn wọn hàn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó wákàtí mẹ́ta táa fi dúró, táa ń gbá gbogbo àwọn tó wá mọ́ra táa sì ń kí wọn pé wọ́n kú ìdìde. Lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ ìsìnkú parí, òtẹ́ẹ̀lì kan ládùúgbò fi inúrere pèsè oúnjẹ fún èyí tó lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún lára àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́, àtàwọn míì tí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ láti ri ọmọ-ọmọ wa.

Ẹnu wa kò gbọpẹ́ fún nǹkan táwọn èèyàn ṣe láti ràn wá lọ́wọ́, pàápàá jù lọ àwọn tá ò mọ̀ rí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú ká túbọ̀ pinnu ju tìgbàkigbà rí lọ láti kópa ní kíkún nínú iṣẹ́ ìsìn Kristẹni, nítorí ọ̀pọ̀ àwọn tó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn ló ṣì wà táa máa fẹ́ láti mú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ wọn.—Mátíù 24:14.

Ohun Tí Ìjọ Ṣe

Àtìgbà tí wàhálà yìí ti bẹ̀rẹ̀ làwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí a jọ jẹ́ Kristẹni ti dúró tì wá gbágbáágbá. Ìtìlẹyìn tí kò dáwọ́ dúró yìí wá látọ̀dọ̀ àwọn ará ìjọ wa tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ìjọ tó wà yí wa ká.

Kódà, ká to dé sílé láti North Carolina làwọn alàgbà nínú ìjọ wa ti ṣètò bí wọ́n ṣe máa wá Theresa rí. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ló gbàyè lẹ́nu iṣẹ́ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń wá a. Àwọn kan tiẹ̀ sọ fáwọn agbanisíṣẹ́ wọn pé àwọn ò kọ̀ káwọn pàdánù owó oṣù àwọn, àmọ́ wọ́n fún àwọn kan láyè wọ́n sì tún sanwó fún wọn. Ní gbogbo ọjọ́ táa fi wá Theresa, ńṣe làwọn arákùnrin wa kan nípa tẹ̀mí wá dúró ti Jonathan kó má báà ṣòun nìkan. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin díẹ̀ tiẹ̀ dìídì wá láti rí sí i pé ilé wa wà ní mímọ́ tónítóní. Àwọn míì ṣèrànwọ́ láti pèsè oúnjẹ fáwọn tó yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n sì bá wa gba ìpè lórí tẹlifóònù.

Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́fà lẹ́yìn ikú Theresa, iṣẹ́ wíwúwo kan dojú kọ ìyàwó mi àti Jonathan, ìyẹn pípalẹ̀ àwọn nǹkan Theresa mọ́ kúrò nínú ilé. Jonathan ní òun ò lè gbé inú ilé tí òun àti Theresa ti jọ ń gbé mọ́, ló bá pinnu láti tà á. Kò rọrùn fún wọn rárá láti kó àwọn ẹrù Theresa jọ, gbogbo ẹ̀ pátá ló ń mú wọn rántí rẹ̀ àti bí wọn ò ṣe rí i mọ́. Àmọ́ àwọn ará wa kò tún jẹ́ ká ṣe wàhálà nípa èyí náà. Wọ́n bá wa di gbogbo nǹkan rẹ̀ sínú àpótí, wọ́n tiẹ̀ tún bá wa tún àwọn nǹkan tó bàjẹ́ nínú ilé náà ṣe kó lè wà ní sẹpẹ́ fún títà.

Èyí tó wá jẹ́ pàtàkì jù lọ ni pé, àwọn arákùnrin wa àtàwọn arábìnrin wa pèsè ìtìlẹyìn nípa tẹ̀mí àwọn sì ni alábàárò fún ìdílé wa. Wọ́n á pè wá lórí tẹlifóònù wọ́n á tún bẹ̀ wá wò láti fún wa níṣìírí. Ọ̀pọ̀ nínú wọn fí àwọn káàdì àtàwọn lẹ́tà tó ń wúni lórí ránṣẹ́. Ìtìlẹyìn onífẹ̀ẹ́ yìí kò dáwọ́ dúró láàárín àwọn ọjọ́ àti ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ o, ó ń báa lọ fún ọ̀pọ̀ oṣù.

Àwọn mélòó kan lára àwọn arákùnrin wa àti arábìnrin wa sọ fún wa pé ká jẹ́ káwọn mọ̀ táa bá nílò ẹnì kan láti fara balẹ̀ gbọ́ wa, a sì ti tẹ́wọ́ gba ìpèsè onífẹ̀ẹ́ wọn yìí. Ó mà ń tuni lára o, láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tóo nífẹ̀ẹ́ tóo sì fọkàn tán láti bá ẹ pín nínú ìbànújẹ́ rẹ! Ká sòótọ́, wọ́n ti fi àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀ tó wà nínú òwe Bíbélì náà hàn, tó sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17; 18:24.

Ipa Tó Ní Lórí Ìdílé Wa

Báà bá ní tanra wa jẹ, kò rọrùn rárá fún èmi àti ìdílé mi láti ṣara gírí lórí ikú Theresa. Ó ti yí ìgbésí ayé wa padà pátápátá gbáà. Àwọn ìgbà míì wà tínú á bí mi pé mi ò rí i mọ́. Àárò bó ṣe máa ń dì mọ́ mi tó sì máa ń fẹnu kò mí lẹ́nu máa ń sọ mí.

Ìyàwó mi ló sún mọ́ Theresa jù lọ. Ọjọ́ kan kò lọ rí kí wọ́n má jọ sọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n sì ti fi jọ sọ̀rọ̀ nípa oyún Theresa. Ṣe ni wọ́n jọ to yàrá tí ìkókó máa dé sí.

Vicki sọ bó ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Òfò náà kúrò ní kékeré. Mi ò lè jáde pẹ̀lú rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù mọ́. A ò tún lè jọ lọ ra nǹkan lọ́jà mọ́. Èyí tó wá dùn mí jù lọ ni bi mi ò ṣe rí òun àti ọmọ rẹ̀ pa pọ̀, ó dùn mí gan-an ni. Mo mọ bó ṣe fẹ́ràn Oscar tó kódà nígbà tí kò tíì bí i. Ó ti mọ̀ pé ọkùnrin lòún máa bí. Nígbà tí mo ṣe bùláńkẹ́ẹ̀tì kan fún ọmọ rẹ̀ tí mo sì mú un fún un, Theresa kọ káàdì yìí ránṣẹ́ sí mi:

‘Mọ́mì Mi Ọ̀wọ́n,

Ẹ ṣeun mo dúpẹ́ gan-an fún bùláńkẹ́ẹ̀tì rírẹwà tẹ́ẹ ṣe. Mo mọrírì iṣẹ́ takuntakun tẹ́ẹ ṣe lórí rẹ̀. Mo ń fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín lẹ́ẹ̀kan sí i fún gbogbo ìrànwọ́ àti ìṣírí tẹ́ẹ fún mi láti la díẹ̀ lára àwọn àkókò tó nira jù lọ nínú ìgbésí ayé mi já. Gbogbo ìgbà ni màá máa rántí yín tí màá sì máa dúpẹ́ fún ìyẹn. Mo ti máa ń gbọ́ tí wọ́n ń sọ pé ọjọ́ kan á jọ́kan téèyàn á mọ̀ pé kò sẹ́ni tó lè ṣe bí ìyá. Tóò, mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lójoojúmọ́ pé kò pẹ́ jù kí ń tó mọ̀ pé òótọ́ ni. Títí ni màá máa nífẹ̀ẹ́ yín.’”

Ó tún dùn wá gan-an láti rí ohun tí ojú ọkọ ọmọ wa kàn. Ní gbogbo ìgbà tí Oscar wà ní ọsibítù, Jonathan ní láti ṣe nǹkan kan tó ṣòro tí kò ṣe rí láyé rẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tó ti ní òun máa wá gbé lọ́dọ̀ wa fúngbà díẹ̀, ó ní láti kó gbogbo ẹrù ọmọ tóun àti Theresa ti tò jọ ní sẹpẹ́ sínú ilé wọn kúrò. Ó palẹ̀ àwọn nǹkan ìṣeré bí ẹṣin, bẹ́ẹ̀dì ọmọ, àtàwọn ẹranko tí wọ́n fi aṣọ ṣe mọ́ kúrò, ó sì kó wọn wá sílé wa.

Ohun Tó Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fara Dà Á

Nígbà tóo bá pàdánù èèyàn rẹ kan lọ́nà tó ń bani nínú jẹ́ bẹ́ẹ̀, àìmọye ìbéèrè tó ń dani lọ́kàn rú àti onírúurú ìrònú ló máa dìde lọ́kàn rẹ. Gẹ́gẹ́ bí alàgbà Kristẹni kan, àwọn àkókò kan wà tí mo ti gbìyànjú láti tu àwọn mìíràn tí irú àwọn ìbéèrè àti ìrònú bẹ́ẹ̀ ń dà láàmú nínú tí mo sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ìwọ gan-an lọ̀fọ̀ ṣẹ̀, oríṣiríṣi èrò lè máà jẹ́ kóo ronú bó ti yẹ.

Fún àpẹẹrẹ, níwọ̀n bí mo ti mọ ipò tí Theresa wà, tó sì jẹ́ pé a ò ní sí nílé fún ọ̀sẹ̀ kan, mo gbàdúrà pé kí Jèhófà dáàbò bò ó. Àmọ́, nígbà tó wá jẹ́ pé òkú ẹ̀ la rí, mo gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ pé ẹnu kọ́kọ́ yà mí ìdí tí Ọlọ́run kò fi dáhùn àdúrà mi. Lóòótọ́, mo mọ̀ dájú pé Jèhófà kò ṣèlérí láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lọ́nà iṣẹ́ ìyanu. Mo ṣáà ń bá a lọ ní gbígbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún mi lóye. Mímọ̀ pé Jèhófà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nípa tẹ̀mí ti fún mi ní ìtùnú—pé, ó ń pèsè ohun táa nílò láti lè pa àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ mọ́. Irú ààbò yẹn ló sì dára jù lọ, nítorí ó lè nípa lórí ọjọ́ ọ̀la wa ayérayé. Lọ́nà yẹn, Jèhófà dáàbò bo Theresa; títí tó fi kú ló ń fi ìdúróṣinṣin sìn ín. Mímọ̀ pé ìwàláàyè rẹ̀ ọjọ́ iwájú wà lọ́wọ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ti fi mí lọ́kàn balẹ̀.

Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi mélòó kan ti tù mí nínú lọ́nà tó ṣe pàtàkì. Díẹ̀ lára àwọn tó ti ràn mí lọ́wọ́ láti fara dà á nìyí:

“Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ó pẹ́ tí mo ti nígbàgbọ́ nínú ìlérí Bíbélì nípa àjíǹde sínú párádísè orí ilẹ̀ ayé, àmọ́, ìrètí yẹn ti wá túbọ̀ ṣe pàtàkì sí mi báyìí. Kìkì mímọ̀ pé yóò tún ṣeé ṣe fún mi láti gbá Theresa mọ́ra lẹ́ẹ̀kan sí i ti fún mi lókun láti fara dà á jálẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

“Jèhófà . . . kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè, nítorí gbogbo wọn wà láàyè lójú rẹ̀.” (Lúùkù 20:37, 38) Ìtùnú púpọ̀ ló wà nínú mímọ̀ pé “gbogbo” àwọn òkú tí a óò jí dìde lọ́jọ́ kan “wà láàyè” lójú Jèhófà, àní nísinsìnyí pàápàá. Nítorí náà, lójú rẹ̀, Theresa wa ọ̀wọ́n wà dáadáa.

Vicki náà á fẹ́ sọ díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ti fún un lókun ní pàtàkì:

“‘Kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.’ (Hébérù 6:18; Títù 1:2) Nítorí pé Jèhófà kò lè purọ́, mo mọ̀ pé á mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ láti jí àwọn òkú dìde.

“‘Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.’ (Jòhánù 5:28, 29) Ọ̀rọ̀ náà ‘ibojì ìrántí’ fi hàn pé Theresa wà ní ìrántí Jèhófà títí tó fi máa ní kí Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, jí i dìde. Mo mọ̀ pé kò tún síbì kan tó bọ́ lọ́wọ́ ewu tó lè wà ju inú ìrántí Jèhófà pípé pérépéré lọ.

“‘Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.’ (Fílípì 4:6, 7) Ní pàtàkì jù, mo máa ń gbàdúrà fún ẹ̀mí Jèhófà láti fún mi lókun. Nígbà tí ìbànújẹ́ bá dorí mi kodò, mo máa ń tọ Jèhófà lọ tí màá sì sọ fún un pé, ‘mo nílò ẹ̀mí mímọ́ rẹ sí i,’ ó sì máa ń ràn mí lọ́wọ́ jálẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ìgbà míì máa ń wà tí n kò ní mọ bí màá ṣe gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀, àmọ́, ó máa ń fún mi lókun láti máa bá a nìṣó.”

Dájúdájú, Jèhófà ti ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìbànújẹ́ ńláǹlà yìí. Ó mà ṣe o, ikú Theresa wa ọ̀wọ́n ṣì ń kó ìbànújẹ́ bá wa. A mọ̀ pé ìbànújẹ́ ọkàn wa kò lè tán pátápátá títí dìgbà táa máa fi gbá a mọ́ra nínú ayé tuntun Jèhófà. Títí ìgbà náà, a múra tán ju tìgbàkigbà rí lọ láti fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà. Jonathan ti ṣe tán láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti tọ́ Oscar dàgbà láti fẹ́ràn Jèhófà àti láti sìn ín, èmi àti Vicki náà á sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà tó bá ṣeé ṣe. Ìfẹ́ wa àtọkànwá ni láti wà nínú ayé tuntun Ọlọ́run láti kí Theresa káàbọ̀ ká sì fi ọmọ tí kò ṣeé ṣe fún un láti gbé mọ́ra hàn án.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Theresa, ọmọbìnrin wa, níbi tó ti ń tẹ́tí sí ìlùkìkì ọkàn ọmọ rẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Orí wa wú nígbà táa rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tí wọ́n gbárùkù tì wá níbi ọ̀rọ̀ ìsìnkú náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Èmi àti ìyàwó mi, Vicki, níbi ìgbéyàwó Theresa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Oscar, ọmọ-ọmọ wa