Àwọn Èwe Wà Nínú Ewu
Àwọn Èwe Wà Nínú Ewu
“Ní oṣù méjì sẹ́yìn, kokoko lára mi máa ń le tínú mi sì máa ń dùn ṣìnkìn. Àmọ́ ní báyìí, gbogbo ìgbà tí mo bá ti fẹ́ ṣe nǹkan ló máa ń rẹ̀ mí tẹnutẹnu tí mi ò sì ní lè ṣe é. Ìbànújẹ́ ti dorí mi kodò, n kì í sì í pẹ́ tutọ́ sókè fojú gbà á, mi ò tiẹ̀ rò pé ẹnì kan lè gba ohun tí mo ń ṣe mọ́ra. Mi ò lè ṣàlàyé ohun tó mú kí n di òṣónú lọ́sàn-án gangan bẹ́ẹ̀.”—Paul.
“Ńṣe ni mo máa ń sunkún àsun-ùn-dákẹ́ tí ìdààmú ọkàn á sì bá mi. Ìgbà tí ìdààmú ọkàn ò bá sí gan-an, màá kàn dà bí òkú ni. Kò sóhun tó ń gbádùn mọ́ mi. N kì í fẹ́ rí àwọn ọ̀rẹ́ mi sójú mọ́ pàápàá. Oorun ni mo máa ń sùn ràì. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni n kì í lè dìde láti múra iléèwé, mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sí gbòdo jọ.”—Melanie.
KÌ Í ṣe Paul àti Melanie nìkan ló ní irú ìṣòro yìí. Àwọn ìwádìí fi hàn pé nǹkan bí ìpín mẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́langba ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni oríṣi ìsoríkọ́ kan tàbí òmíràn ń bá jà àti pé nǹkan bí ìpín mẹ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ló ń ní ìṣòro ìsoríkọ́ tó lékenkà lọ́dọọdún. Ṣùgbọ́n ìṣirò yìí kò ṣàlàyé gbogbo ohun tó wà nídìí ọ̀ràn náà tán, nítorí pé nǹkan mìíràn làwọn èèyàn máa ń fi ìsoríkọ́ pè lọ́pọ̀ ìgbà tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máà kà á sí rárá. Afìṣemọ̀rònú àwọn ọ̀dọ́langba náà David G. Fassler, kọ̀wé pé: “Ká sòótọ́, lẹ́yìn tí mo gbé ìwádìí tí mo ṣe láàárín àwọn èwe yẹ̀ wò, mo rí i pé èyí tó ju ọ̀kan nínú mẹ́rin àwọn èwe ló máa níṣòro ìsoríkọ́ tó
burú jáì tó bá fi máa pé ọmọ ọdún méjìdínlógún.”Ìgbẹ̀yìn Rẹ̀ Kì Í Dára
Ohun tó ń tìdí ìsoríkọ́ yọ fáwọn ọ̀dọ́langba kì í dára rárá. Àwọn ògbóǹkangí tiẹ̀ gbà pé ipa tó gadabú ló ń kó nínú ìṣòro àìjẹun bó ṣe yẹ, àwọn àrùn tí ìrònú àti ìmọ̀lára ń fà, kára má balẹ̀ nílé ìwé, àti lílo oògùn olóró.
Èyí tó túbọ̀ bani nínú jẹ́ níbẹ̀ ni pé, ìsoríkọ́ wà lára ohun tó ń mú káwọn èwe máa fọwọ́ ara wọn para wọn. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìlera Ọpọlọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe sọ, iye tó pọ̀ tó ìpín méje nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èwe tí wọ́n níṣòro ìsoríkọ́ ló ń fúnra wọn gbẹ̀mí ara wọn. a Èyí gan-an kò tí ì fi bí ìṣòro náà ṣe gbòòrò tó hàn, nítorí àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé báa bá fi rí ọ̀dọ́ kan tó gbẹ̀mí ara rẹ̀, ọ̀pọ̀ ló ti máa gbìyànjú láti ṣe ohun kan náà. Ìdí pàtàkì rèé tí ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Ìdàgbàsókè Àwọn Ọ̀dọ́ ní Carnegie fi sọ pé: “Fífọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ọ̀ràn ìṣòro àwọn ọ̀dọ́ lóde òní dà bí ìgbà téèyàn bá ń fọwọ́ pa idà àjálù lójú. Irú àìka nǹkan sí bẹ́ẹ̀ máa ń fi àwọn èwe sínú ewu lóòótọ́.”
Ṣé Pé Kò Sí Ìṣòro Nínú Ìgbésí Ayé Wọn?
Kò rọrùn fáwọn kan láti gbà pé àwọn ọ̀dọ́langba lè níṣòro ìsoríkọ́. Àwọn àgbàlagbà kan lè máa ronú pé ‘ṣebí ọmọdé ṣì ni wọ́n. Kò sí ìṣòro nínú ìgbésí ayé wọn, gbogbo àníyàn táwọn àgbàlagbà máa ń ní kò kàn wọ́n.’ Àbí ó kàn wọ́n? Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn èwe ń dojú kọ ìpèníjà tó lékenkà kọjá ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà lérò lọ. Dókítà Daniel Goleman sọ pé: “Látìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún [ogún] ni ewu ìsoríkọ́ tó lékenkà ti ń wu àwọn èwe kárí ayé lọ́nà tó lágbára ju tàwọn òbí wọn lọ, kì í ṣe pé inú wọn kì í dùn nìkan ni, àmọ́ ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń mú wọn, ìbànújẹ́ máa ń dorí wọn kodò, wọ́n á wá máa káàánú ara wọn, wọ́n á sì di aláìnírètí nígbèésí ayé wọn. Àárọ̀ ọjọ́ sì ni ìṣòro ìsoríkọ́ yìí ti máa ń bẹ̀rẹ̀.”
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ọ̀pọ̀ òbí ṣì lè sọ pé: ‘Àwa náà ṣáà ti wà léwe rí a kò sì níṣòro ìsoríkọ́. Báwo ni tọmọ wa ti wá jẹ́ tí ìbànújẹ́ fi dorí rẹ̀ kodò tó bẹ́ẹ̀?’ Àmọ́ kò yẹ káwọn àgbàlagbà máa fi bí nǹkan ṣe rí nígbà tí wọ́n wà léwe wé bó ṣe rí nígbà tàwọn èwe òde òní. Ó ṣe tán, ojú tí olúkúlùkù fi ń wo ohun tó wà lágbègbè rẹ̀ àti bí kálukú ṣe ń hùwà yàtọ̀ síra wọn.
Yàtọ̀ síyẹn, ìpèníjà táwọn èwe òde òní ń dojú kọ ti kúrò ní kékeré. Dókítà Kathleen McCoy kọ ọ́ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Understanding Your Teenager’s Depression pé: “Inú ayé tí wọ́n ti ń dàgbà yàtọ̀ sí èyí tí àwọn òbí wọn ti ṣe èwe.” Lẹ́yìn tó ti sọ àwọn ìyípadà díẹ̀ tó ti ṣẹlẹ̀ láwọn ọdún bíi mélòó kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó parí ọ̀rọ̀ pé: “Àwọn èwe òde òní kò fi bẹ́ẹ̀ láàbò, wọn kò dára wọn lójú tó bó ṣe yẹ, wọn kò sì nírètí irú èyí táwa ní láyé ọjọ́un.”
Bí ìṣòro ìsoríkọ́ ṣe wá gbòde kan láàárín àwọn èwe báyìí, àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e á jíròrò ìbéèrè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀:
• Kí làwọn àmì ìsoríkọ́ àwọn èwe?
• Kí lohun tó ń fà á?
• Báwo làwọn èwe tó níṣòro ìsoríkọ́ ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ògbóǹkangí kan gbà gbọ́ pé iye yìí jù bẹ́ẹ̀ lọ fíìfíì, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ikú tí wọ́n sọ pé ńṣe ló ṣèèṣì ṣẹlẹ̀ ló jẹ́ pé fífọwọ́ ẹni gbẹ̀mí ara ẹni ló fà á.