Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Òbí Kọ̀ Mí Sílẹ̀—Ṣùgbọ́n Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Mi

Àwọn Òbí Kọ̀ Mí Sílẹ̀—Ṣùgbọ́n Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Mi

Àwọn Òbí Kọ̀ Mí Sílẹ̀—Ṣùgbọ́n Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Mi

GẸ́GẸ́ BÍ BERNADETTE FINN ṢE SỌ Ọ́

Mi ò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́rin nígbà tí wọ́n kó èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin mẹ́ta lọ sílé àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Birdie ọmọ ọdún méjìlá, Phyllis, ọmọ ọdún mẹ́jọ, àti Annamay, ọmọ ọdún méje rántí bí mo ṣe sunkún fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ láìdáwọ́dúró tí mo ń wá àwọn òbí mi. Kí ló dé tí wọ́n fi kó wa lọ síbẹ̀?

INÚ ìdílé ńlá kan tó jẹ́ ti ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni wọ́n bí mi sí ní May 28, 1936. Inú ilé kékeré kan ní Duncormick, County Wexford ní Ireland làwa ọmọ kéékèèké ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí wa. Èmi lọmọ kẹjọ, orí bẹ́ẹ̀dì ńlá kan ni mo sì ń sùn pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi àti arábìnrin mi méje. Inú kọ́bọ́ọ̀dù aṣọ ni àbúrò mi ọkùnrin àtobìnrin tí wọ́n bí láìpẹ́ lẹ́yìn náà ń sùn.

Lébìrà háún-háún tó ń gbaṣẹ́ oko ṣe ni bàbá wa. Owó tó ń rí kò tó nǹkan; nítorí náà oúnjẹ kò fi bẹ́ẹ̀ ká ìdílé wa lẹ́nu. Ṣàṣà ni ìgbà tí Màmá máa ń rí oúnjẹ díẹ̀ gbé fún àwọn ẹ̀gbọ́n mi lọ síléèwé. Ipò òṣì tó gba gbogbo ilẹ̀ Ireland kan àti ìjẹgàba oníkà ti Ìjọ Kátólíìkì ìgbà yẹn ló fà á tí ipò wa fi rí bẹ́ẹ̀.

Ìdílé wa máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé, síbẹ̀ Màmá ò torí ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tẹ̀mí lọ títí. Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ṣì rántí pé àwọn máa ń rí i tó ń ka àwọn ìwé ẹ̀sìn kan nígbà tó bá jókòó níwájú ààrò. Ó máa ń gbìyànjú láti ṣàlàyé díẹ̀ lára àwọn ohun tó kà fún wa.

“Màmá Mi Dà?”

Mi ò jẹ́ gbàgbé ọjọ́ tí wọ́n mú mi lọ sílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé láéláé. Àwọn òbí mi dúró lọ́dẹ̀dẹ̀ wọ́n sì ń fi gbogbo ara bá obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan sọ̀rọ̀, lèmí bá bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọmọbìnrin kéékèèké tó kù ṣeré ní tèmi, tínú mi ń dùn ṣìnkìn láìmọ̀ ohun tí wọ́n ń sọ. Mo kàn ṣàdédé wò yíká, sí ìyàlẹ́nu mi, Màmá àti Bàbá ti pòórá. Ni mo bá lọgun tòò pé: “Màmá mi dà?” Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ ni mo fi ké bẹ́ẹ̀.

Ó kéré tán, àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin mẹ́ta tó wà níbẹ̀ fún mi ní ìtùnú díẹ̀. Ṣùgbọ́n nítorí pé apá ibòmíì làwọ́n wà nínú ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà, ń kì í fi bẹ́ẹ̀ rí wọn. Nítorí pé wákàtí méjì lẹ́yìn táwa ọmọ wẹ́wẹ́ bá ti lọ sùn lálẹ́ làwọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ń lọ sùn, ń kì í sùn títí dìgbà tí màá fi gbúròó pé wọ́n ti fẹ́ lọ sùn. Màá wá yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kúrò lórí bẹ́ẹ̀dì mi, màá sì gun àtẹ̀gùn lọ sókè káwọn arábìnrin mi lè juwọ́ sí mi. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń retí pé kí wọ́n juwọ́ sí mi.

Ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé yìí kò fi bẹ́ẹ̀ fàyè gba pé kí àwọn òbí máa wá, nítorí náà a kì í fi bẹ́ẹ̀ rí àwọn òbí wa. Ohun tí ìyapa yẹn dá sí mi lára kì í ṣe kékeré. Àní sẹ́, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tí mo rántí pé àwọn òbí mi wá bẹ̀ mí wò, mi ò sún mọ́ wọn bẹ́ẹ̀ làwọn náà ò wá sọ́dọ̀ mi. Àmọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ṣì lè rántí ìwọ̀nba ìbẹ̀wò tí wọ́n ṣe.

Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà sí ìdílé mi, ilé mi, àti gbogbo ìgbésí ayé mi. Fún gbogbo ọdún méjìlá tí mo fi wà níbẹ̀, ẹ̀ẹ̀mejì péré ni mo gbójúgbóyà jáde. Ìrìn táa rìn jáde lọ sí àgbègbè àrọko yìí gbádùn mọ́ mi gan-an ni, nítorí a rí àwọn igi àtàwọn ẹranko. Bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àwa ọ̀dọ́bìnrin kò rí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, bọ́ọ̀sì, tàbí àwọn ilé ìtajà rí láyé wa, àní, ekukáká lá fi máa ń rí àwọn ọkùnrin, àyàfi àlùfáà.

Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nílé Àwọn Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Ìnìkàngbé

Oríṣiríṣi ni ìgbésí ayé nílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, díẹ̀ nínú wọn dáa, ọ̀pọ̀ ni kò sì sunwọ̀n. Obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ tó níwà tó dáa gan-an kọ́ wa nípa Ọlọ́run débi tó mọ̀ ọ́n dé. Ó sọ fún wa pé bàbá onífẹ̀ẹ́ ni Ọlọ́run. Ìyẹn dùn mọ́ mi nínú, mo sì pinnu láti ọjọ́ náà lọ pé màá máa wo Ọlọ́run bíi bàbá mi torí ó nífẹ̀ẹ́ ó sì láàánú ju bàbá tó bí mi lọ. Látìgbà náà lọ ni mo ti máa ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ gan-an, lọ́nà jẹ́jẹ́ tọ́mọdé fi máa ń gbàdúrà. Ó dùn mí gan-an nígbà tí obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà lọ.

Wọ́n kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ ìwé tó pọndandan tó sì yè kooro, mo sì ṣọpẹ́ fún èyí. Síbẹ̀ mi ò gbàgbé àwọn tí wọ́n ń pè ní “àwọn ọmọbìnrin iléèwé àárọ̀” tí wọ́n máa ń ṣe ojúsàájú sí nígbà tí wọ́n bá wá síléèwé nílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Ìdílé ọlọ́rọ̀ ni wọ́n ti wá, tí wọ́n bá sì ti dé, a gbọ́dọ̀ fi yàrá ìkàwé sílẹ̀. Gbogbo ìgbà làwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà máa ń rán wa létí pé ọmọ aláìlóbìí lásánlàsàn ni wá nítorí náà ká yáa mọ̀wọ̀n ara wa.

Àìmọye òfin ló wà nílé ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Àwọn kan bọ́gbọ́n mu, ìyẹn jẹ́ kí ọ̀pọ̀ jù lọ wa lóye ìdí tí wọ́n fi wúlò. Àwọn ẹ̀kọ́ tó ń ṣeni láǹfààní lórí ìwà, ìṣesí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ wà. Mi ò gbàgbé wọn rárá, wọ́n sì ti wúlò fún mi ni gbogbo ìgbésí ayé mi. Àmọ́ àwọn òfin kan wà tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tó sì dà bíi pé wọ́n ní ojúsàájú nínú, nígbà táwọn míì ń dani lọ́kàn rú tí wọ́n sì ń múnú èèyàn bà jẹ́. Ọ̀kan lára irú àwọn òfin bẹ́ẹ̀ fàyè gba fífi ìyà jẹ ẹni tó bá tọ̀ sílé lóru; òmíràn fàyè gba fífìyàjẹni nítorí pé èèyàn fẹ́ẹ́ lọ gbọnsẹ̀ lóru.

Lọ́jọ́ kan, bí mo ti ń gun àtẹ̀gùn lọ, mo ń bá ọmọbìnrin tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi sọ̀rọ̀. Ni obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan bá pè mí ó sì fìyà jẹ mí fún pé mo ń sọ̀rọ̀. Irú ìyà wo? Aṣọ tí mo ń wọ̀ lásìkò ooru náà ni màá wọ̀ jálẹ̀ gbogbo ìgbà òtútù tó máa ń mú burúkú burúkú ní Ireland! Mo jẹ́ ọmọ tó máa ń ṣàìsàn gan-an, ìgbà gbogbo ni ikọ́ fée àti egbò ọ̀nà ọ̀fun sì máa ń hàn mí léèmọ̀. Mo ṣàìsàn gidigidi ikọ́ ẹ̀gbẹ sì kọ lù mí. Ohun kan náà ló sì ṣe àwọn ọmọbìnrin mìíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kó wa sọ́tọ̀, wọn ò fún wa ní ìtọ́jú kankan, àwọn kan sì kú, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kan wà nínú wọn.

Ìyà ni wọ́n máa ń fi í ṣomi ọbẹ̀ fún àwọn kan lára wa látàrí pé wọ́n rú kékeré lára àwọn òfin náà. Nígbà kan tí gbogbo wa wà lórí ìlà, a ń wo ọmọbìnrin kan bí wọ́n ṣe ń nà án fún ohun tó ju wákàtí méjì lọ. Ńṣe ni gbogbo wa ń bá a sunkún. Àmọ́ ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà ló kúkú rorò bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ohun tó ṣì ń rú mi lójú títí dòní ni bí ẹnì kan ṣe lè ya òǹrorò tó bẹ́ẹ̀ sáwọn ọmọdé tí wọn ò lẹ́ni tó lè gbà wọ́n sílẹ̀. Kò lè yé mi láéláé.

Kò pẹ́ kò jìnnà, Birdie àti Phyllis kúrò nílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà, ó wá ku èmi àti Annamay níbẹ̀. A ò ní ẹlòmíì láyé kọjá àwa méjèèjì. Annamay máa ń tù mí nínú pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ń sọ nípa báwọn òbí wa ṣe máa wá mú wa kúrò nílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé lọ́jọ́ kan lọ síbi táwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ò ti ní rí wa láéláé. Nígbà tí Annamay náà tún wá kúrò, ìbànújẹ́ fẹ́rẹ̀ẹ́ gbé mi mì. Mo lo ọdún mẹ́ta gbáko sí i níbẹ̀.

Kíkọ́ Láti Gbé Níta

Fífi ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé sílẹ̀ nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún da jìnnìjìnnì bò mí. Mi ò mọ nǹkankan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé yìí kọjá ti ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, ṣìbáṣìbo sì bá mi gbáà. Nígbà tí mo wọ bọ́ọ̀sì, wọ́n béèrè owó lọ́wọ́ mi, àmọ́ mi ò mọ ohun tó ń jẹ́ pé wọ́n ń sanwó mọ́tò. Nígbà tí mi ò sì kúkú lówó kankan lọ́wọ́, kíá ni wọ́n lé mi bọ́ọ́lẹ̀ tí mo sì fẹsẹ̀ mi rìn débi tí mo ń lọ. Nígbà kan mo tún fẹ́ wọ bọ́ọ̀sì lọ síbì kan, ni bọ́ọ̀sì kankan kò bá wá. Mi ò mọ̀ pé ńṣe lèèyàn máa lọ sí ibùdókọ̀.

Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo ṣara gírí mi ò sì ṣe bi ẹni pé ẹ̀rù ń bà mí, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ohun tó yẹ kí n ṣe. Mo wá iṣẹ́ kan tó máa rọrùn fún mi láti ṣe, àmọ́ lẹ́yìn tí mo ṣe é fún oṣù bíi mélòó kan, mo pinnu láti padà sílé láti lọ rí màmá mi. Nígbà tí mo débẹ̀, mo rí díẹ̀ lára àwọn àbúrò mi tí mi ò rí rí, lásìkò yẹn, àwọn ẹ̀gbọ́n àtàbúrò tí mo ní lápapọ̀ jẹ́ mẹ́rìnlá. Níwọ̀n bí kò ti sí yàrá tí mo lè máa gbé pẹ̀lú wọn, àwọn òbí mi ṣètò pé kí n lọ sí Wales láti lọ máa gbé pẹ̀lú arábìnrin mi, Annamay. Bàbá mi tẹ̀ lé mi débẹ̀, àmọ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló padà.

Mi ò ní gá, mi ò ní go, síbẹ̀ mo ń bá a yí. Lẹ́yìn ìgbà náà, ní 1953, mo ṣí lọ sí London, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, níbi tí mo ti dara pọ̀ mọ́ Ẹgbẹ́ Mary, ìyẹn ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re kan ti Ìjọ Roman Kátólíìkì. Ṣùgbọ́n, ìjákulẹ̀ gbáà ni bíbá tí mo bá wọn ṣiṣẹ́ mú bá mi, níwọ̀n bí mo ti retí pé kí ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ mú nǹkan tẹ̀mí lọ́wọ́. Mo fẹ́ràn láti máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tẹ̀mí, àmọ́ kìkì ohun tayé ni iṣẹ́ tí mo ń bá Ẹgbẹ́ Mary ṣe dá lé, ó sì dà bíi pé kò sí àkókò kankan fún ìjíròrò tẹ̀mí.

Nígbà tí mo ń gbé ní London, mo pàdé Patrick, ọ̀rẹ́ àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin. A nífẹ̀ẹ́ ara wa gan-an a sì ṣègbéyàwó ní 1961. Ibẹ̀ la bí àwọn ọmọ wa méjì àkọ́kọ́, Angela àti Stephen sí. Lẹ́yìn náà, ní 1967, a ṣí lọ sí Ọsirélíà níbi táa ti bí Andrew, ọmọ wa kẹta. Ìlú Bombala tí kò fi bẹ́ẹ̀ lajú ní New South Wales la tẹ̀dó sí.

Oúnjẹ Tẹ̀mí Nígbẹ̀yìngbẹ́yín

Kò pẹ́ táa dé sí Ọsirélíà, Bill Lloyd kàn sí wa ní ìlú Bombala láti bá wa sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Inú mi dùn gan-an láti rí i pé tààràtà ló ń fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ̀ pé òtítọ́ wà nínú ohun tí Bill ń sọ, mo máa ń bá a jiyàn gan-an, kí n ṣáà lè dá a dúró kí n sì lè túbọ̀ gbọ́ àlàyé sí i látinú Bíbélì. Bill mú Bíbélì àtàwọn ìwé ìròyìn díẹ̀ wá fún mi lẹ́yìn náà láti kà.

Mo gbádùn àwọn ìwé ìròyìn náà gan-an, àmọ́ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi láti rí i pé àwọn èèyàn tó ṣe wọ́n ò gba Mẹ́talọ́kan gbọ́. Ni mo bá kó àwọn ìwé ìròyìn náà pa mọ́, kí kíkà wọ́n má bàa ba ìgbàgbọ́ Patrick jẹ́. Mo pinnu pé ńṣe ni màá kó wọn padà fún Bill tó bá ti dé, àmọ́ nígbà tó padà bẹ̀ wá wò, ó fi hàn mí pé ẹ̀kọ́ pé ẹni mẹ́ta ló para pọ̀ di Ọlọ́run kan kò bá ohun tí Bíbélì fi kọ́ni mu níbì kankan. Kò pẹ́ tó fi ṣe kedere sí mi pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù jẹ́, pé Jèhófà Ọlọ́run tí í ṣe Bàbá rẹ̀ ló dá a—nípa bẹ́ẹ̀, ó ní ìbẹ̀rẹ̀—àti pé Bàbá ju Jésù lọ.—Mátíù 16:16; Jòhánù 14:28; Kólósè 1:15; Ìṣípayá 3:14.

Kò pẹ́ tí mo fi rí i pé àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n ti fi kọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kò tọ̀nà. Fún àpẹẹrẹ, Bíbélì kò kọ́ni pé àwa ènìyàn ní ọkàn kan tí kì í kú tàbí pé ọ̀run àpáàdì kan wà níbi táa ti ń dá èèyàn lóró. (Oníwàásù 9:5, 10; Ìsíkíẹ́lì 18:4) Ìtura ńlá gbáà ni mímọ̀ tí mo mọ ìyẹn jẹ́! Lọ́jọ́ kan mo bẹ̀rẹ̀ sí í jó kiri nínú ilé ìgbọ́únjẹ nítorí inú mi dùn pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo rí Bàbá náà tí mo ti nífẹ̀ẹ́ tipẹ́ àmọ́ tí mi ò mọ̀. Ebi tẹ̀mí tó ń pa mí bẹ̀rẹ̀ sí lọ. Ayọ̀ mi tún wá kún sí i nígbà tí Patrick náà fi irú ìtara kan náà hàn fún ìgbàgbọ́ táa ṣẹ̀ṣẹ̀ rí yìí.

Bill ní ká wá sí àpéjọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ní Temora, tó wà ní ìlú mìíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà jìn, tayọ̀tayọ̀ la fi gba ìkésíni rẹ̀ a sì dé sí Temora lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday. Láàárọ̀ Sátidé, àwọn èèyàn kóra jọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́ nínú gbọ̀ngàn àpéjọpọ̀ náà láti lọ fún ìwàásù láti ilé dé ilé. Inú èmi àti Patrick dùn báa ti ń dúró dé jíjáde lọ náà, nígbà tó kúkú jẹ́ pé ó ṣe díẹ̀ táa ti ń fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, Bill sọ pé a ò ní lè kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà nítorí àwa méjèèjì la ṣì ń mu sìgá. Síbẹ̀, bí Bill ṣe kúrò báyìí, lèmi àti Patrick bá dára pọ̀ mọ́ àwùjọ mìíràn. Wọ́n rò pé Ẹlẹ́rìí ni wá ni wọ́n bá mú wa lọ.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà táa wá mọ àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè láti lè tóótun fún kíkópa nínú ìwàásù ìhìn rere náà. (Mátíù 24:14) Níkẹyìn, a jáwọ́ sìgá mímu, èmi àti Patrick sì fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wa sí Jèhófà Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi nínú omi ní October 1968.

Ìdánwò Ìgbàgbọ́ Wa

Báa ti ń dàgbà nínú ìmọ̀ Bíbélì àti nínú àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà, ìgbàgbọ́ táa ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run di èyí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Patrick di alàgbà nínú ọ̀kan lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Canberra, olú ìlú Ọsirélíà. A ṣe gbogbo ohun táa lè ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ wa dàgbà nínú ìlànà èrò orí Jèhófà, táa sì kojú gbogbo àwọn ìpèníjà tó ń wà nínú títọ́ àwọn èwe dàgbà.—Éfésù 6:4.

Ó bà wá nínú jẹ́ pé, nígbà tí Stephen ọmọkùnrin wa pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, ó kú nínú ìjàǹbá ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan. Láìkà ti ìbànújẹ́ ọkàn wa sí, a rí ògidì ìtùnú nínú pé Stephen jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà. A ń fojú sọ́nà láti tún padà rí i nígbà tí Jèhófà bá jí àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí dìde. (Jòhánù 5:28, 29) Ní 1983, ìyẹn ọdún tò tẹ̀ lé e, mo dára pọ̀ mọ́ Angela, ọmọbìnrin wa, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, mò sì wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ yẹn di báa ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí. Ṣíṣàjọpín ìrètí wa táa gbé karí Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ti ràn mí lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́ nípa ìgbésí ayé, ó sì tún ti ṣèrànwọ́ láti dín ìbànújẹ́ ọkàn mi kù. Inú mi dùn gan-an láìpẹ́ yìí nígbà tí mo gbọ́ pé Annamay arábìnrin mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Wales.

Ní 1984, àìsàn kan tó dà bí ohun tójú ò rí rí nígbà yẹn kọ lu Patrick. Nígbà tó yá wọ́n ṣàwárí rẹ̀ pé àmì àárẹ̀ aṣeni-lemọ́lemọ́ ni. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ó di pé kó fi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ sílẹ̀, ó sì pa sísìn bíi Kristẹni alàgbà tì. A láyọ̀ pé ara rẹ̀ ti yá díẹ̀ báyìí, ó sì ti ń padà sìn bí ìránṣẹ́ kan tí a yàn nínú ìjọ.

Ìgbà ọmọdé mi ti kọ́ mi láti mọ̀wàá hù àti láti ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, ó tún kọ́ mi láti gbé ìgbésí ayé ìwọ̀ntúnwọ̀nsì kí n sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀. Àmọ́ ìdí tí wọ́n fi mú àwa ọmọbìnrin mẹ́rin lọ sílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tí wọ́n sì fi àwọn ọmọ mọ́kànlá yòókù sílẹ̀ nílé kò tíì yé mi. Ohun tí mo fi ń tu ara mi nínú ni pé àwọn òbí mi, tí wọ́n ti kú báyìí ní bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lábẹ́ ipò tí mi ò rò pé mo lè lóye rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Àwọn àkókò yẹn kò rọrùn rárá, ó sì ń béèrè pé kí wọ́n ṣe àwọn ìpinnu líle koko. Láìka èyí sí, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí mi fún ẹ̀bùn ìwàláàyè tí wọ́n fún mi tí wọ́n sì bójú tó mi débi tí agbára wọn ká a dé. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó ṣe bàbá fún mi.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìgbà táa ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Nígbà táwọn ọmọ wa wà ní kékeré

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Èmi àti Patrick lónìí