“Àwọn Wo Ló Ń Fi Òtítọ́ Kọ́ Gbogbo Orílẹ̀-Èdè?”
Wáá Gbọ́ Àsọyé fún Gbogbo Ènìyàn Lọ́fẹ̀ẹ́
“Àwọn Wo Ló Ń Fi Òtítọ́ Kọ́ Gbogbo Orílẹ̀-Èdè?”
Bíṣọ́ọ̀bù kan sọ nígbà kan rí pé: “Kò sẹ́nì kankan nínú wa tọ́wọ́ rẹ̀ lè tẹ òtítọ́ tí kò lábùlà.” Ṣóòótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn? Àbí orísun kan wà táa ti lè rí ojúlówó òtítọ́? Ṣé ó máa ṣeé ṣe pé àkókò kan yóò dé tí gbogbo èèyàn á máa sọ òtítọ́?
Bẹ̀rẹ̀ lóṣù October, àsọyé tí àkọlé rẹ̀ wà lókè yìí la óò gbọ́ láwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè mẹ́rìndínlógóje [136] tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò ṣe jákèjádò ilẹ̀ Nàìjíríà. Ẹṣin ọ̀rọ̀ Àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí ni “Àwọn Olùkọ́ni Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Àní, àsọyé yìí ni yóò jẹ́ lájorí ọ̀rọ̀ ní gbogbo ẹgbẹ̀rún méjì àpéjọpọ̀ irú rẹ̀ tí yóò wáyé ní nǹkan bí àádọ́jọ orílẹ̀-èdè jákèjádò ayé.
Lára àwọn ìbéèré tí àsọyé náà yóò dáhùn ni: Ibo ni òtítọ́ ti ṣẹ̀ wá? Báwo ni òtítọ́ ṣe ń fara hàn? Ìwé wo ló ṣe pàtàkì jù lọ tó ń fi òtítọ́ hàn?
O lè gbọ́ àsọyé pàtàkì yìí ní àpéjọpọ̀ kan tó sún mọ́ ibi tí o ń gbé. Kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ, tàbí kóo kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí láti mọ èwo ló sún mọ́ ọ jù lọ. Gbogbo ibi tí a óò ti ṣe àpéjọpọ̀ yìí ní Nàìjíríà ni a tò sínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ May 1, 2001, tó jẹ́ èkejì ìwé ìròyìn yìí.