Ṣíṣàwárí Àwọn Nǹkan Tó Ń Fa Ìsoríkọ́
Ṣíṣàwárí Àwọn Nǹkan Tó Ń Fa Ìsoríkọ́
“Àgbájọ àwọn ohun tó ń fa másùnmáwo ló sábà máa ń fa ìsoríkọ́ èwe, kì í ṣe ohun kan péré ló ń fà á.”—Dókítà Kathleen McCoy.
KÍ LÓ ń fa ìsoríkọ́ àwọn èwe? Onírúurú nǹkan ló lè fà á. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ìyípadà ara àti èrò inú tó máa ń wáyé nígbà ìbàlágà lè mú káwọn nǹkan máà dá wọn lójú kí ẹ̀rù sì máa bà wọ́n, èyí ló sì máa ń mú kí èrò òdì kún ọkàn wọn. Èyí nìkan kọ́, àwọn èwe sábàá máa ń ní ìmọ̀lára òdì bí wọ́n bá rí i pé àwọn ojúgbà wọn tàbí ẹnì kan tí ìfẹ́ rẹ̀ ti kó sí wọn lórí kò gba tiwọn mọ́. Kò tán síbẹ̀, gẹ́gẹ́ báa ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ wa ìṣáájú, inú ayé kan tó ń múni sorí kọ́ làwọn èwe òde òní ti ń dàgbà. Kò sírọ́ níbẹ̀ pé “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” la ń gbé yìí.—2 Tímótì 3:1.
Ohun tó ń mú kí ìṣòro náà túbọ̀ pọ̀ sí i ni pé ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn èwe máa dojú kọ pákáǹleke tó wà nínú ìgbésí ayé rèé, òye wọn àti ìrírí wọn kò sì tó tàwọn àgbàlagbà. Èyí ló máa ń mú káwọn ọ̀dọ́langba dà bí arìnrìn àjò afẹ́ kan tó ń wá ọ̀nà tó máa gbà ní àgbègbè tí kò mọ̀ rí, ńṣe ni gbogbo nǹkan máa ń dàrú mọ́ wọn lójú, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn kì í sì í fẹ́ béèrè pé kí ẹnì kan ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn nǹkan wọ̀nyí lè fa ìsoríkọ́.
Àmọ́ àwọn nǹkan mìíràn tún wà tó lè mú káwọn ọ̀dọ́langba sorí kọ́. Ẹ jẹ́ ká gbé bíi mélòó kan lára wọn yẹ̀ wò.
Ìsoríkọ́ àti Àdánù
Nígbà míì, èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí sorí kọ́ bó bá pàdánù ohun kan tó ṣeyebíye, bí ìgbà tí èèyàn ẹni bá kú tàbí báwọn òbí èèyàn bá kọra wọn sílẹ̀. Kódà láwọn orílẹ̀-èdè kan, ikú ohun ọ̀sìn lè mú kí èwe kan sorí kọ́.
Àwọn àdánù kan tún wà téèyàn ò fí bẹ́ẹ̀ kà sí. Irú bíi kéèyàn ṣí lọ sí àdúgbò mìíràn, tó túmọ̀ sí pé èèyàn á fi àgbègbè tó ti mọ́ ọn lára àtàwọn ọ̀rẹ́ àtàtà sílẹ̀. Àní tọ́wọ́ èèyàn bá tẹ ohun ribiribi kan tó ti ń lé tipẹ́tipẹ́—bíi kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ jáde nílé ẹ̀kọ́—ó lè mú kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí nímọ̀lára pé òun pàdánù àwọn ohun kan. Ó ṣe tán, dídáwọ́ lé
nǹkan tuntun nínú ìgbésí ayé máa ń mú kéèyàn pàdánù ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì àti ìfọ̀kànbalẹ̀ tó ti ń gbé tẹ́lẹ̀. Àwọn èwe kan sì wà tí wọ́n ń bá àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ yí. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, másùnmáwo pé èèyàn kò bá ẹgbẹ́ mu, bóyá kí wọ́n tiẹ̀ pa èèyàn tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan pàápàá lè mú kí ọ̀dọ́langba kan ronú pé òun kò já mọ́ nǹkankan.Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ èwe wà tó ń kojú irú àdánù bẹ́ẹ̀ láìjẹ́ kó gbé àwọn mì. Inú wọn máa ń bà jẹ́, wọ́n máa ń sunkún, wọ́n máa ń ṣọ̀fọ̀, àmọ́ tó bá yá wọ́n á ṣara gírí. Kí ló wá fà á nígbà náà tó fi jẹ́ pé bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀dọ́langba kan ṣe ń ṣara gírí tí wọ́n á sì fara da àwọn hílàhílo ìgbésí ayé ni àwọn mìíràn ń jẹ́ kí ìsoríkọ́ gbé wọn mì? Kò ṣe é dáhùn ní tààrà, nítorí pé ìsoríkọ́ jẹ àìsàn tó ṣòroó ṣàlàyé. Àmọ́ ìsoríkọ́ lè tètè rọ́wọ́ tó àwọn èwe kan ju àwọn mìíràn.
Bó Ṣe Kan Ìṣiṣẹ́ Inú Ara
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìlera ọpọlọ gbà gbọ́ pé àwọn ohun kan nínú ọpọlọ tí wọ́n ò rí bó ṣe yẹ kí wọ́n rí ni ohun tó ń fa ìsoríkọ́. a Àwọn òbí lè kó àrùn yìí ran àwọn ọmọ wọn, àwọn olùwádìí ti rí i pé ó ṣeé ṣe káwọn èwe táwọn òbí wọn ní ìṣòro ìsoríkọ́ náà ní ìṣòro ọ̀hún. Ìwé Lonely, Sad and Angry sọ pé: “Nínú ọ̀ràn tó pọ̀ jù lọ, àwọn èwe tó sorí kọ́ máa ń ní òbí kan ó kéré tán tóun náà níṣòro ọ̀hún.”
Ìbéèrè tí èyí wá gbé dìde ni pé, Ṣé lóòótọ́ làwọn ọmọ máa ń jogún ìsoríkọ́ ni àbí wọ́n máa ń kọ́ ọ látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn tó níṣòro náà? ‘Ìbéèrè nípa ipa tí àbùdá àti àyíká ń kó nínú ọ̀ràn yìí’ ṣòro láti dáhùn torí pé bí ọpọlọ ṣe díjú lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ náà làwọn nǹkan mìíràn tó lè fa ìsoríkọ́ èwe ṣe díjú.
Ìsoríkọ́ àti Ìdílé
Wọ́n ti sọ pé ọ̀ràn ìdílé ni ìsoríkọ́ jẹ́, wọ́n sì rí ìyẹn wí. Báa ti sọ ṣáájú, ó ṣeé ṣe kí ohun kan wà nínú àbùdá èèyàn tó ń tan ìsoríkọ́ kálẹ̀ láti ìran kan sí òmíràn. Àmọ́ bí ìdílé ṣe rí tún lè kó ipa kan níbẹ̀. Dókítà Mark S. Gold kọ ọ́ pé: “Àwọn ọmọ táwọn òbí wọn ń ṣe níṣekúṣe wà nínú ewu ńláǹlà pé kí wọ́n ní ìṣòro ìsoríkọ́. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọ táwọn òbí wọn le koko ju bó ṣe yẹ tí wọ́n sì máa ń wonkoko mọ́ ìkùdíẹ̀ káàtó àwọn ọmọ.” Ọmọ kan tún lè níṣòro ìsoríkọ́ báwọn òbí rẹ̀ bá ń kẹ́ ẹ ní àkẹ́jù tí wọn kò jẹ́ jẹ́ kí èèrà rà á. Àmọ́ ṣá, olùwádìí kan rí i pé àwọn ọmọ lè túbọ̀ níṣòro ìsoríkọ́ táwọn òbí ò bá nífẹ̀ẹ́ wọn.
Bó ti wù kó rí, èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn ọ̀dọ́langba tó níṣòro ìsoríkọ́ ló jẹ́ pé àwọn òbí wọn tó ṣe wọ́n níṣekúṣe ló fà á. Irú èrò tí kò tọ̀nà bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ ká lè fiyè sí àwọn ohun mìíràn tó lè fa ìṣòro ọ̀hún. Síbẹ̀, bí ìdílé bá ṣe rí lè nípa lórí ìṣòro náà nínú àwọn ọ̀ràn kan. Dókítà David G. Fassler, kọ̀wé pé: “Àwọn ọmọ tó jẹ́ pé òní ẹjọ́ ọ̀la àròyé lọ̀ràn àwọn òbí wọn wà nínú ewu ìsoríkọ́ ju àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí wàhálà nínú ilé wọn lọ. Ìdí kan ni pé gbọ́nmi-si-omi-ò-tó làwọn òbí tó ń bára wọn jà yìí á gbájú mọ́ tí wọn ò fi ní ráyè gbọ́ tàwọn ọmọ wọn. Ìdí mìíràn ni pé nítorí àwọn ọmọ làwọn òbí mìíràn ṣe máa ń bára wọn ní gbólóhùn asọ̀, èyí sì lè jẹ́ káwọn èwe máa nímọ̀lára ẹ̀bi, kí wọ́n bínú, kí wọ́n sì di ọlọ̀tẹ̀.”
Ohun díẹ̀ làwọn wọ̀nyí jẹ́ lára àwọn ohun tó ń mú káwọn ọ̀dọ́ sorí kọ́. Àwọn mìíràn tún wà. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ògbóǹkangí kan sọ pé ipò àyíká (irú bí àìsí oúnjẹ tó ń ṣara lóore, májèlé, lílo oògùn olóró àti ọtí líle) lè fa ìsoríkọ́. Àwọn mìíràn sọ pé oríṣi àwọn egbòogi kan (bí egbòogi antihistamines àti egbòogi amárarọni) náà lè fà á. Bákan náà, ó dà bí ẹni pé ìsoríkọ́ tètè máa ń rọ́wọ́ tó àwọn ọmọ tí ọpọlọ wọn ò jí sí ìwé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí pé wọn kì í níyì mọ́ tí wọ́n bá rí i pé àwọn ò bá àwọn ẹlẹgbẹ́ àwọn mu.
Bó ti wù kó rí, ohun yòówù kó fà á, ó ṣe pàtàkì láti gbé ìbéèrè náà yẹ̀ wò pé, Báwo la ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ tó níṣòro ìsoríkọ́ lọ́wọ́?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn kan ti kíyè sí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n ń bí ìṣòro yìí mọ́ àwọn ọmọ kan tó ní i, àwọn mìíràn wà tára wọ́n á le koránkorán, ṣùgbọ́n tí ìsoríkọ́ á wá gbé wọn dè nígbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan ba kó ìdààmú bá ọpọlọ wọn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Gbọ́nmi-si-omi-ò-tó nínú ìdílé sábàá máa ń fa ìsoríkọ́